Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 6

Párádísè Sún Mọ́lé!

Párádísè Sún Mọ́lé!

Àwọn ohun búburú tí ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí fi hàn pé Párádísè sún mọ́lé. Bíbélì sọ pé a óò wọnú àwọn àkókò lílekoko kí Párádísè tó dé. Àkókò yẹn gan-an la wà báyìí! Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ rèé:

Ogun ńláǹlà. “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ní ìmúṣẹ. Láti ọdún 1914, ogún àgbáyé méjì àti ọ̀pọ̀ ogun kéékèèké mìíràn ti jà. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ti kú nínú àwọn ogun náà.

Àjàkálẹ̀ àrùn. “Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn” yóò wà “láti ibì kan dé ibòmíràn.” (Lúùkù 21:11) Ǹjẹ́ èyí rí bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọkàn, ikọ́ ẹ̀gbẹ, ibà, àrùn éèdì, àti àwọn àrùn mìíràn ti pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn.

Àìsí oúnjẹ. Jákèjádò ayé, àwọn èèyàn wà tí wọn ò rí oúnjẹ tí ó tó jẹ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lebi ń pa kú lọ́dọọdún. Èyí jẹ́ àmì mìíràn pé Párádísè máa tóó dé. Bíbélì wí pé: “Àìtó oúnjẹ yóò wà.”—Máàkù 13:8.

Ìsẹ̀lẹ̀. “Ìsẹ̀lẹ̀ yóò . . . wà láti ibì kan dé ibòmíràn.” (Mátíù 24:7) Èyí pẹ̀lú ti ṣẹ nígbà tiwa. Láti ọdún 1914, ó ju àádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ti kú nínú àwọn ìsẹ̀lẹ̀.

Àwọn ẹni ibi. Àwọn èèyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ owó” àti “olùfẹ́ ara wọn.” Wọn yóò jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” Àwọn ọmọ yóò jẹ́ “aṣàìgbọràn sí òbí.” (2 Tímótì 3:1-5) Ǹjẹ́ o kò gbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí bẹ́ẹ̀ lónìí? Wọn ò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń da àwọn tó bá gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run láàmú.

Ìwà ọ̀daràn. ‘Ìwà àìlófin yóò tún pọ̀ sí i.’ (Mátíù 24:12) Ìwọ náà lè gbà pé ìwà ọ̀daràn ti burú ju ti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti wà nínú ewu àwọn olè, kí a rẹ́ wọn jẹ, tàbí kí a ṣe wọ́n léṣe.

Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé. Bíbélì wí pé: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Ó jẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọ̀run, tí yóò mú Párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé yìí. Ìjọba Ọ̇lọ́run yóò rọ́pò ìṣàkóso èèyàn.—Dáníẹ́lì 2:44.