Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ 14

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Sá fún Ohun Búburú

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Sá fún Ohun Búburú

Sátánì máa ń sún àwọn èèyàn ṣe ohun búburú. Ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ní láti kórìíra ohun tí Jèhófà bá kórìíra. (Sáàmù 97:10) Díẹ̀ lára nǹkan tí àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń yẹra fún rèé:

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.” (Ẹ́kísódù 20:14) Níní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó lòdì pẹ̀lú.—1 Kọ́ríńtì 6:18.

Ìmùtípara. “Àwọn ọ̀mùtípara [kì] yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:10.

Ìṣìkàpànìyàn, oyún ṣíṣẹ́. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.”—Ẹ́kísódù 20:13.

Olè Jíjà. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.”—Ẹ́kísódù 20:15.

Irọ́ Pípa. Jèhófà kórìíra “ahọ́n èké.”—Òwe 6:17.

Ìwà Ipá àti Ìbínú Tí A Ò Ṣàkóso. “Dájúdájú, [Jèhófà] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) “[Apá kan] àwọn iṣẹ́ ti ara [ni] . . . ìrufùfù ìbínú.”—Gálátíà 5:19, 20.

Tẹ́tẹ́ Títa. “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni . . . tí ó jẹ́ . . . oníwọra.”—1 Kọ́ríńtì 5:11.

Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.”—Mátíù 5:43, 44.

Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń sọ fún wa jẹ́ fún ire wa. Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti yẹra fún ṣíṣe ohun búburú. Pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà àti ìrànwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, o lè yẹra fún ṣíṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí.—Aísáyà 48:17; Fílípì 4:13; Hébérù 10:24, 25.