Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èèpo Ẹ̀yìn Ìwé

Èèpo Ẹ̀yìn Ìwé

Àìsáyà 40:11 sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Ó máa bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ, ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.” Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ, tó o bá rí bí ara ṣe tu ọ̀dọ́ àgùntàn tí olùṣọ́ àgùntàn kan gbé sí àyà rẹ̀? Ṣé kì í wù ẹ́ pé kí ìwọ náà sún mọ́ Baba rẹ ọ̀run tímọ́tímọ́ bíi ti àgùntàn yẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀nà wo lo lè gbà sún mọ́ Jèhófà?