APÁ 1
‘Agbára Rẹ̀ Ń Bani Lẹ́rù’
Nínú apá yìí, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàn Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà lágbára láti ṣẹ̀dá, láti pani run, láti dáàbò boni àti láti mú nǹkan bọ̀ sípò. Bá a bá ṣe ń rí i pé ‘agbára Jèhófà ń bani lẹ́rù’ àti pé “okun rẹ̀ tó fi ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yanturu,” ìyẹn á jẹ́ ká nígboyà, ìrètí wa á sì dájú.—Àìsáyà 40:26.
NÍ APÁ YÌÍ
ORÍ 4
‘Agbára Jèhófà Pọ̀’
Ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ alágbára? A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, a sì tún lè sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́.
ORÍ 5
Agbára Ìṣẹ̀dá—“Aṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ayé”
Látorí oòrùn tó ń tú ibú agbára jáde dórí ẹyẹ akùnyùnmù kékeré, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Jèhófà látara àwọn ohun tó dá.
ORÍ 6
Agbára Ìparun—“Jagunjagun Tó Lágbára Ni Jèhófà”
Tó bá jẹ́ pé “Ọlọ́run àlàáfíà” ni Jèhófà lóòótọ́, kí nìdí tó fi ń jagun?
ORÍ 7
Agbára Ààbò—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”
Ọ̀nà méjì ni Ọlọ́run ń gbà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ ọ̀nà kan ṣe pàtàkì ju ìkejì lọ.
ORÍ 8
Agbára Ìmúbọ̀sípò—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Àwọn nǹkan wo ló máa mú bò sípò lọ́jọ́ iwájú?
ORÍ 9
“Kristi Ni Agbára Ọlọ́run”
Kí làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe àtàwọn ohun tó fi kọ́ni jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?
ORÍ 10
“Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé ìwọ náà lágbára láti ṣe àwọn nǹkan kan. Báwo lo ṣe lè lo agbára tó o ní yìí lọ́nà tó dáa?