Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 8

Agbára Ìmúbọ̀sípò​—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”

Agbára Ìmúbọ̀sípò​—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”

1, 2. Àwọn nǹkan wo làwa èèyàn máa ń pàdánù, báwo nìyẹn sì ṣe máa ń rí lára wa?

 FOJÚ inú wo ọmọ kékeré kan tó ń wá ohun ìṣeré ẹ̀ tó fẹ́ràn gan-an. Ó wá a títí, kò rí i, ló bá bú sẹ́kún. Ó sunkún débi pé àánú ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ́! Àmọ́, ká sọ pé bàbá tàbí ìyá ọmọ náà bá a rí ohun ìṣeré ẹ̀ tó sọ nù, báwo ló ṣe máa rí lára ọmọ náà? Ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn gan-an. Lójú òbí náà, ó lè dà bíi pé nǹkan kékeré ló ṣe nígbà tó rí nǹkan ìṣeré yẹn. Àmọ́ ní ti ọmọ náà, inú ẹ̀ dùn, ohun tí òbí ẹ̀ ṣe sì jọ ọ́ lójú gan-an. Ó ti pa dà rí ohun ìṣeré rẹ̀ tó rò pé òun ò ní rí mọ́!

2 Baba tó ju baba lọ ni Jèhófà, ó lágbára láti ṣàtúnṣe gbogbo ohun tó dà bíi pé kò ní àtúnṣe mọ́. Ọ̀rọ̀ ohun ìṣeré ọmọdé kọ́ là ń sọ o, ọ̀rọ̀ nípa ayé yìí ni. ‘Àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé, àwọn nǹkan tá a sì ń pàdánù láyé yìí pọ̀ gan-an, kódà ó ju ohun ìṣeré ọmọdé kan tó sọ nù lọ. (2 Tímótì 3:1-5) Bí àpẹẹrẹ, a lè pàdánù ilé tàbí ohun ìní wa, iṣẹ́ lè bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, ara wa sì lè má le bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, inú wa kì í dùn tá a bá ronú nípa báwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́, tí wọ́n sì ń ṣèpalára fáwọn ẹranko àtàwọn ewéko débi tí ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan yìí ò fi sí mọ́. Àmọ́, èyí ò tó nǹkan tá a bá fi wé ẹ̀dùn ọkàn tá a máa ń ní nígbà táwọn èèyàn wa bá kú. Ìrora yẹn máa ń pọ̀ gan-an, nǹkan sì máa ń tojú sú wa.​—2 Sámúẹ́lì 18:33.

3. Kí ni Ìṣe 3:21 sọ pé Ọlọ́run máa ṣe, báwo ni Jèhófà sì ṣe máa ṣe é?

3 Ó dájú pé ọkàn wa máa balẹ̀ tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa agbára tí Jèhófà ní láti mú nǹkan bọ̀ sípò! Nínú orí yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Baba wa ọ̀run lágbára láti tún ṣe, àá sì rí i pé ó wù ú kó tún àwọn nǹkan náà ṣe fún wa. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ṣe ‘ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo.’ (Ìṣe 3:21) Ó máa lo Ìjọba Mèsáyà, tí Jésù Kristi máa ṣàkóso láti ṣe ìmúbọ̀sípò náà. Ẹ̀rí fi hàn pé Ìjọba yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run látọdún 1914. a (Mátíù 24:3-14) Àwọn nǹkan wo ni Ọlọ́run máa mú bọ̀ sípò? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti mú bọ̀ sípò ní báyìí àtàwọn nǹkan tó máa mú bọ̀ sípò lọ́jọ́ iwájú.

Ìmúbọ̀sípò Ìjọsìn Mímọ́

4, 5. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, báwo ni Jèhófà sì ṣe fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?

4 Ohun kan tí Jèhófà ti mú bọ̀ sípò báyìí ni ìjọsìn mímọ́. Ká lè lóye ohun téyìí túmọ̀ sí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọba ń ṣàkóso nílẹ̀ Júdà. Èyí á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà lágbára láti mú àwọn nǹkan bọ̀ sípò.​—Róòmù 15:4.

5 Wo bí nǹkan ṣe máa rí lára àwọn Júù olóòótọ́ nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Wọ́n pa ìlú wọn àtàtà run, wọ́n sì wó odi rẹ̀ palẹ̀. Èyí tó burú jù ni pé, wọ́n wó tẹ́ńpìlì tó rẹwà tí Sólómọ́nì kọ́, tó jẹ́ ibì kan ṣoṣo táwọn èèyàn ti lè máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́. (Sáàmù 79:1) Wọ́n kó gbogbo àwọn èèyàn tó kù nílùú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, wọ́n ba ìlú náà jẹ́ gan-an débi pé àwọn ẹranko búburú nìkan ló wá ń gbébẹ̀. (Jeremáyà 9:11) Lójú àwọn Júù yẹn, ṣe ló dà bíi pé ìlú náà ò ní ṣeé gbé mọ́ láé. (Sáàmù 137:1) Àmọ́, Jèhófà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa mú ìlú náà pa dà bọ̀ sípò, ó ṣe tán òun ló sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa ìlú náà run.

6-8. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà máa ṣe, báwo sì ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe nímùúṣẹ lápá kan? (b) Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò ṣe nímùúṣẹ lásìkò wa yìí?

6 Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì ló sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa mú nǹkan bọ̀ sípò. b Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà mí sí àwọn wòlíì náà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn tó pọ̀ á pa dà máa gbé ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ilẹ̀ náà á máa méso jáde, àwọn ẹranko búburú àtàwọn ọ̀tá ò sì ní yọ wọ́n lẹ́nu. Jèhófà sọ pé ilẹ̀ náà máa dà bíi Párádísè! (Àìsáyà 65:25; Ìsíkíẹ́lì 34:25; 36:35) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, àwọn èèyàn náà á pa dà máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, wọ́n sì máa tún tẹ́ńpìlì kọ́. (Míkà 4:1-5) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn nírètí, ó sì jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á ní gbogbo àádọ́rin ọdún (70) tí wọ́n fi wà nígbèkùn ní Bábílónì.

7 Nígbà tí àsìkò tó, Jèhófà mú àwọn Júù kúrò nígbèkùn ní Bábílónì, ó mú wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. (Ẹ́sírà 1:1, 2) Ní gbogbo àsìkò tí wọ́n fi ń sin Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, Jèhófà ń bù kún wọn, ó ń mú kí ilẹ̀ wọn méso jáde, nǹkan sì ń lọ dáadáa fún wọn. Ó ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn àti lọ́wọ́ àwọn ẹranko búburú tó ti ń gbé ilẹ̀ náà ní gbogbo àsìkò tí wọ́n fi wà nígbèkùn. Ó dájú pé bí Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ láti mú nǹkan bọ̀ sípò máa múnú wọn dùn gan-an! Àmọ́, ńṣe nìyẹn kàn jẹ́ apá kan lára bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò yẹn ṣe máa ṣẹ. Ọlọ́run sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” ìyẹn lásìkò wa yìí, nígbà tí Ọmọ Dáfídì tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa di ọba bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.​—Àìsáyà 2:2-4; 9:6, 7.

8 Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi Jésù jọba ní ọ̀run lọ́dún 1914, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í pèsè ohun táwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà láyé nílò kí wọ́n lè máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. Bí Kírúsì tó jẹ́ olórí ogun ilẹ̀ Páṣíà ṣe dá àwọn Júù nídè kúrò ní Bábílónì lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe dá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ nídè kúrò ní “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé yìí. (Ìfihàn 18:1-5; Róòmù 2:29) Látọdún 1919 làwọn Kristẹni tòótọ́ ti pa dà ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. (Málákì 3:1-5) Àtìgbà yẹn làwọn èèyàn Jèhófà ti ń jọ́sìn rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tó sọ di mímọ́, ìyẹn ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn mímọ́. Kí nìdí téyìí fi ṣe pàtàkì fún wa lónìí?

Ìmúbọ̀sípò Nípa Tẹ̀mí​—Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì

9. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú, àmọ́ kí ni Jèhófà ṣe lásìkò wa yìí?

9 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ sin Jèhófà lọ́nà tó fẹ́, wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ táwọn èèyàn ò ní máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́. (Mátíù 13:24-30; Ìṣe 20:29, 30) Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fara hàn, wọ́n sì ń pọ̀ sí i. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn ń kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n mú látinú ẹ̀sìn èké. Wọ́n ń kọ́ni pé Mẹ́talọ́kan ni Ọlọ́run, wọ́n sì ń mú kó nira fáwọn èèyàn láti sún mọ́ ọn. Bákan náà, wọ́n ní káwọn èèyàn máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Màríà àtàwọn “ẹni mímọ́” míì dípò Jèhófà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti sọ ẹ̀sìn Kristẹni dìdàkudà, tí wọ́n sì ti mú oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ èké wọlé, Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Èyí sì ni ọ̀kan pàtàkì lára àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe lóde òní.

10, 11. (a) Apá méjì wo ni párádísè tẹ̀mí pín sí, báwo lo sì ṣe lè fi hàn pé inú párádísè tẹ̀mí náà lo wà? (b) Irú àwọn èèyàn wo ni Jèhófà ń mú wá sínú Párádísè tẹ̀mí náà, kí ni wọ́n sì máa láǹfààní láti gbádùn?

10 Ní báyìí tí Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbádùn párádísè tẹ̀mí. Apá méjì ni párádísè tẹ̀mí yìí pín sí. Apá àkọ́kọ́ ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn mímọ́ Jèhófà. Ọlọ́run ti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké, ká lè máa jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Ó ń fún wa láwọn nǹkan táá mú ká mọ̀ ọ́n dáadáa, ká sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Jòhánù 4:24) Apá kejì ní í ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà. Wòlíì Àìsáyà sọ pé, “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” Jèhófà máa kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi máa wà lálàáfíà pẹ̀lú ara wọn, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ti ń ṣẹ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, àwa Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí ogun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìpé, Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa gbé “ìwà tuntun” wọ̀. Ó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ní àwọn ìwà tó dáa. (Éfésù 4:22-24; Gálátíà 5:22, 23) Tó o bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ, a jẹ́ pé inú párádísè tẹ̀mí lo wà nìyẹn.

11 Àwọn èèyàn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló ń mú wá sínú párádísè tẹ̀mí yìí. Ìdí tó sì fi ń mú wọn wá ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n fẹ́ràn àlàáfíà, wọ́n sì ń “wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.” (Mátíù 5:3) Àwọn èèyàn yìí máa láǹfààní láti gbádùn àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn àti ayé yìí lọ́jọ́ iwájú.

“Wò Ó! Mò Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”

12, 13. (a) Kí nìdí tá a fi gbà pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò ṣì tún máa nímùúṣẹ lọ́nà míì? (b) Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn fún ayé yìí níbẹ̀rẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?

12 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúbọ̀sípò ṣì tún máa nímùúṣẹ lọ́nà míì. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Àìsáyà sọ̀rọ̀ nípa ìgbà kan tí kò ní sí àìsàn mọ́, táwọn arọ, afọ́jú àti adití sì máa rí ìwòsàn, kódà ó sọ pé Ọlọ́run máa gbé ikú mì títí láé. (Àìsáyà 25:8; 35:1-7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlérí yẹn ò ṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, à ń rí i táwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń nímùúṣẹ nípa tẹ̀mí lónìí, èyí sì mú kó dá wa lójú pé wọ́n máa nímùúṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lọ́jọ́ iwájú. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?

13 Nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn fún ayé yìí, ìyẹn sì ni pé káwọn èèyàn máa láyọ̀, kára wọn le, kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa bójú tó ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀, ó sì fẹ́ kí wọ́n sọ gbogbo ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé, ní báyìí, ayé ò rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀, ó dá wa lójú pé kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Àìsáyà 55:10, 11) Tó bá yá, Jèhófà máa lo Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run láti sọ gbogbo ayé di Párádísè.​—Lúùkù 23:43.

14, 15. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa “sọ ohun gbogbo di tuntun”? (b) Báwo ni nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè, kí ló sì wù ẹ́ jù lọ nínú gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run máa ṣe nígbà yẹn?

14 Ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà tí gbogbo ayé bá di Párádísè! Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa rí nígbà yẹn, ó sọ pé: “Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” (Ìfihàn 21:5) Fojú inú wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn. Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run, á wá ku “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.” Èyí túmọ̀ sí pé ìjọba tuntun kan máa wà lọ́run, á sì máa ṣàkóso lórí àwùjọ èèyàn tuntun tó wà láyé, ìyẹn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (2 Pétérù 3:13) Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ò ní lágbára, wọn ò sì ní lè ṣe ẹnikẹ́ni léṣe. (Ìfihàn 20:3) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Sátánì ti ń ṣi aráyé lọ́nà, àwa èèyàn á bọ́ lọ́wọ́ ìwà burúkú àti ìkórìíra. Ó dájú pé ara máa tu gbogbo wa nígbà yẹn!

15 Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àá lè máa bójú tó ayé tó rẹwà yìí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa ṣe níbẹ̀rẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà dá ayé yìí lọ́nà tó fi lè máa tún ara ẹ̀ ṣe. Táwọn èèyàn ò bá da ìdọ̀tí sínú omi mọ́, àwọn adágún àti odò lè pa dà sọ ara wọn di mímọ́, táwọn èèyàn ò bá sì jagun mọ́, gbogbo ilẹ̀ tí ogun ti sọ dìbàjẹ́ lè pa dà di ibi ẹlẹ́wà. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá tún ayé yìí ṣe kó lè di Párádísè tó rẹwà bíi ti ọgbà Édẹ́nì, tá a sì ń rí oríṣiríṣi ewéko àtàwọn ẹranko tó wà níbẹ̀! Àwọn èèyàn ò ní máa pa àwọn ẹranko àti ewéko run mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe làwa èèyàn àtàwọn ohun alààyè yòókù á máa gbé pa pọ̀ ní àlàáfíà. Kódà, àwọn ọmọdé ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko búburú mọ́.​—Àìsáyà 9:6, 7; 11:1-9.

16. Báwo ni Jèhófà ṣe máa mú nǹkan bọ̀ sípò fún gbogbo olóòótọ́ èèyàn nínú Párádísè?

16 Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni Jèhófà máa mú kí nǹkan pa dà bọ̀ sípò fún. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa là á já nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Ọlọ́run sì máa wo gbogbo wọn sàn lọ́nà ìyanu. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù máa ṣe àwọn nǹkan tó ṣe nígbà tó wà láyé, ó máa lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti la ojú àwọn afọ́jú, ó máa ṣí etí àwọn adití, ó máa mú kí arọ rìn, ó sì máa mú gbogbo àwọn aláìsàn lára dá. (Mátíù 15:30) Inú àwọn arúgbó máa dùn nígbà yẹn, torí ara wọ́n máa le, wọ́n sì máa pa dà lókun bíi tìgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́. (Jóòbù 33:25) Ara tó hun jọ á pa dà máa jọ̀lọ̀, gbogbo ẹ̀yà ara á sì pa dà máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Gbogbo olóòótọ́ èèyàn á máa kíyè sí i pé àwọn ń bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé díẹ̀díẹ̀. Títí ayé làá máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ó lo agbára rẹ̀ lọ́nà àgbàyanu láti sọ gbogbo nǹkan di tuntun! Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa èyí tó máa múnú wa dùn jù lọ lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run máa mú bọ̀ sípò nígbà yẹn.

Ó Máa Jí Àwọn Òkú Dìde

17, 18. (a) Kí nìdí tí Jésù fi bá àwọn Sadusí wí? (b) Kí nìdí tí Èlíjà fi gbàdúrà pé kí Jèhófà jí ọmọ kan dìde?

17 Nígbà ayé Jésù, àwọn Sadusí tí wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ò gbà pé àjíǹde máa wà. Torí náà Jésù bá wọn wí, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti ṣàṣìṣe, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run.” (Mátíù 22:29) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jèhófà ní agbára láti jí òkú dìde. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ tó jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni.

18 Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wòlíì Èlíjà. Opó kan tó ti gba wòlíì náà lálejò fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ gbé ọmọ rẹ̀ dání, ọmọ náà sì ti kú. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa ya Èlíjà lẹ́nu gan-an, torí ṣáájú ìgbà yẹn ni Èlíjà ti gba ẹ̀mí ọmọ náà là kí ebi máa bàa lù ú pa. Kódà, ó ṣeé ṣe kí ọmọ kékeré náà ti mojú Èlíjà. Ní báyìí tí ọmọ náà ti kú, ó dájú pé ikú ẹ̀ máa dun ìyá ẹ̀ gan-an. Ọmọ yìí nìkan ni obìnrin yìí fi ń tu ara ẹ̀ nínú látìgbà tí ọkọ ẹ̀ ti kú. Ó ṣeé ṣe kí obìnrin náà máa ronú pé ọmọ yìí ló máa tọ́jú òun tóun bá darúgbó. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ìdààmú bá obìnrin náà débi tó fi ń ronú pé bóyá ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tóun ti dá sẹ́yìn lòun ń jẹ. Àánú obìnrin náà ṣe Èlíjà gan-an. Ló bá rọra gba òkú ọmọ náà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, ó gbé e lọ sínú yàrá tiẹ̀, ó sì gbàdúrà pé kí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọ náà sọ jí.​—1 Àwọn Ọba 17:8-21.

19, 20. (a) Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun nígbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti jí òkú dìde, kí ló sì mú kó nírú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe san Èlíjà lẹ́san torí pé ó nígbàgbọ́ tó lágbára?

19 Èlíjà kọ́ lẹni àkọ́kọ́ tó gbà pé Ọlọ́run lè jí òkú dìde. Ábúráhámù tó gbé ayé lọ́pọ̀ ọdún ṣáájú Èlíjà náà gbà pé Jèhófà lágbára láti jí òkú dìde. Kí ló mú kó gbà bẹ́ẹ̀? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù ti pé ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún, tí Sérà sì ti pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, Jèhófà lo agbára rẹ̀ láti mú kí Sérà bí ọmọkùnrin kan lọ́nà ìyanu. (Jẹ́nẹ́sísì 17:17; 21:2, 3) Nígbà tọ́mọ náà dàgbà, Jèhófà ní kí Ábúráhámù fi rúbọ. Ábúráhámù nífẹ̀ẹ́ Ísákì gan-an, àmọ́ torí pé ó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó pinnu pé òun máa ṣe ohun tí Jèhófà sọ, torí ó gbà pé Jèhófà lè jí ọmọ náà dìde. (Hébérù 11:17-19) Kí Ábúráhámù tó gorí òkè tó ti fẹ́ fi ọmọ náà rúbọ, ó sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé òun àti Ísákì máa pa dà wá bá wọn. Ó ní láti jẹ́ pé ìgbàgbọ́ tó lágbára tó ní nínú Jèhófà ló mú kó sọ bẹ́ẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 22:5.

“Wò ó, ọmọ rẹ yè”!

20 Àmọ́ o, Jèhófà ò jẹ́ kí Ábúráhámù fi Ísákì rúbọ nígbà yẹn, torí náà kò sídìí tó fi máa jí i dìde. Ní ti ìgbà ayé Èlíjà, ọmọ opó yẹn ti kú ní tiẹ̀. Àmọ́ láìpẹ́ sígbà yẹn, Jèhófà jẹ́ kí Èlíjà jí ọmọ náà dìde torí ìgbàgbọ́ tó lágbára tó ní. Èlíjà wá fa ọmọ náà lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, ọmọ rẹ yè”! Ó dájú pé obìnrin yẹn ò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ yẹn láé!​—1 Àwọn Ọba 17:22-24.

21, 22. (a) Kí nìdí tí àkọsílẹ̀ nípa àwọn tí Jèhófà jí dìde fi wà nínú Bíbélì? (b) Báwo làwọn tó máa jíǹde nínú Párádísè ṣe máa pọ̀ tó, ta ló sì máa jí wọn dìde?

21 Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé Jèhófà lo agbára rẹ̀ láti jí òkú dìde. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà fún Èlíṣà, Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Pétérù lágbára láti jí òkú dìde. Lóòótọ́, àwọn tí wọ́n jí dìde tún pa dà kú nígbà tó yá. Síbẹ̀, ńṣe làwọn àkọsílẹ̀ náà jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.

22 Nínú Párádísè, Jésù máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé òun ni “àjíǹde àti ìyè.” (Jòhánù 11:25) Ó máa jí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn dìde, wọ́n sì máa láǹfààní láti máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Jòhánù 5:28, 29) Ronú nípa bó ṣe máa rí nígbà tó o bá pa dà rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú, tẹ́ ẹ sì dì mọ́ra yín. Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an! Gbogbo èèyàn ló máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ó lo agbára rẹ̀ láti mú nǹkan bọ̀ sípò.

23. Ọ̀nà tó ga jù lọ wo ni Jèhófà gbà lo agbára rẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe mú kó dá wa lójú pé ó máa jí àwọn òkú dìde lóòótọ́?

23 Jèhófà ti ṣe ohun kan tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó lágbára láti jí àwọn òkú dìde lóòótọ́. Ó lo agbára ẹ̀ lọ́nà tó ga jù lọ nígbà tó jí Jésù Ọmọ ẹ̀ dìde, tó sọ ọ́ di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára, tó sì gbé e sípò tó ga ju ti gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó kù lọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde. (1 Kọ́ríńtì 15:5, 6) Ó yẹ kíyẹn jẹ́ ẹ̀rí fáwọn tó ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run máa jí àwọn òkú dìde. Ká sòótọ́, Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde.

24. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde, àǹfààní wo la sì lè rí lọ́jọ́ iwájú?

24 Kì í ṣe pé Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde nìkan ni, ó tún wù ú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run mí sí Jóòbù láti sọ pé ó wu òun gan-an láti jí àwọn tó ti kú dìde. (Jóòbù 14:15) Báwo ló ṣe rí lára ẹ ní báyìí tó o ti rí i pé ó wu Ọlọ́run pé kó lo agbára rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde? Ó dájú pé ó máa wù ẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn! Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú nínú orí yìí, ńṣe ni àjíǹde jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà máa gbà lo agbára rẹ̀ láti mú nǹkan bọ̀ sípò lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, máa ṣe ohun táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó dá ọ lójú pé ìwọ náà lè wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run bá ń “sọ ohun gbogbo di tuntun.”​—Ìfihàn 21:5.

a ‘Àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba Mèsáyà kalẹ̀, tí ẹnì kan tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì Ọba sì gorí ìtẹ́. Jèhófà ṣèlérí fún Dáfídì pé ẹnì kan látinú ìlà ìdílé rẹ̀ á máa ṣàkóso títí láé. (Sáàmù 89:35-37) Àmọ́, lẹ́yìn tí Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kò sẹ́nì kankan láti ìlà ìdílé Dáfídì tó ń ṣàkóso lórí ìtẹ́ Ọlọ́run. Torí pé ìlà ìdílé Dáfídì ni wọ́n bí Jésù sí, Ọlọ́run sì ti fi jọba lọ́run, òun ni Ọba tí Ọlọ́run ṣèlérí náà.

b Bí àpẹẹrẹ, gbogbo àwọn wòlíì yìí ló sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀: Mósè, Àìsáyà, Jeremáyà, Ìsíkíẹ́lì, Hósíà, Jóẹ́lì, Émọ́sì, Ọbadáyà, Míkà àti Sefanáyà.