Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 6

Agbára Ìparun​—“Jagunjagun Tó Lágbára Ni Jèhófà”

Agbára Ìparun​—“Jagunjagun Tó Lágbára Ni Jèhófà”

1-3. (a) Inú ewu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì? (b) Kí ni Jèhófà ṣe láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là?

 ÀWỌN ọmọ Ísírẹ́lì wà láàárín gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti òkun kan tí kò ṣeé rọ́ lù. Àwọn ọmọ ogun Íjíbítì tún ń lé wọn bọ̀ lẹ́yìn. Òǹrorò làwọn ọmọ ogun náà, ṣe ni wọ́n sì fẹ́ pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run. a Síbẹ̀, Mósè rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má sọ̀rètí nù. Ó sọ fún wọn pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ máa jà fún yín.”​—Ẹ́kísódù 14:14.

2 Síbẹ̀, Mósè ṣì ké pe Jèhófà, Jèhófà sì dá a lóhùn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ké pè mí? . . . Mú ọ̀pá rẹ, kí o na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí o sì pín in níyà.” (Ẹ́kísódù 14:15, 16) Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì rẹ̀, ọwọ̀n ìkùukùu tó wà níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ sẹ́yìn wọn. Ó ṣeé ṣe kí ìkùukùu náà dà bí ògiri, kíyẹn sì dí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjà. (Ẹ́kísódù 14:19, 20; Sáàmù 105:39) Ni Mósè bá na ọwọ́ rẹ̀. Ẹ̀fúùfù líle wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́, ó sì pín òkun náà níyà. Ó gbá omi náà jọ sí ọ̀tún àti sí òsì bí ògiri, ó sì dúró bí omi tó dì. Àlàfo tó wà láàárín ẹ̀ fẹ̀ débi pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbabẹ̀ kọjá!​—Ẹ́kísódù 14:21; 15:8.

3 Nígbà tí Fáráò rí gbogbo nǹkan ìyanu tó ṣẹlẹ̀ yìí, ṣebí ńṣe ló yẹ kó sọ fáwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n pa dà sílé. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ o, kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé agbéraga ni, ṣe ló pàṣẹ fáwọn ọmọ ogun ẹ̀ pé kí wọ́n máa lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 14:23) Báwọn ará Íjíbítì ṣe tẹ̀ lé wọn gba ọ̀nà tó wà láàárín òkun náà nìyẹn, àmọ́ wọn ò tíì rìn jìnnà tí nǹkan fi yíwọ́. Àgbá kẹ̀kẹ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ kúrò lára àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn. Lẹ́yìn tí Jèhófà rí i pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kúrò nínú òkun náà, ó sọ fún Mósè pé: “Na ọwọ́ rẹ sórí òkun, kí omi náà lè pa dà, kó sì bo àwọn ará Íjíbítì, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti àwọn agẹṣin wọn.” Ni omi tó dúró bí ògiri yẹn bá ya wálẹ̀, ó sì bo Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́lẹ̀!​—Ẹ́kísódù 14:24-28; Sáàmù 136:15.

4. (a) Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Jèhófà ṣe ní Òkun Pupa? (b) Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn kan tí wọ́n bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ jagunjagun tó lágbára?

4 Bí Jèhófà ṣe gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì là ní Òkun Pupa kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà. Ó jẹ́ ká rí i pé “jagunjagun tó lágbára” ni Jèhófà. (Ẹ́kísódù 15:3) Àmọ́, báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o mọ̀ pé jagunjagun ni Jèhófà? Torí pé ogun ti fìyà jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn, tó sì ti mú kí nǹkan nira fún wọn, èyí lè mú káwọn kan máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Ọlọ́run tí Bíbélì pè ní jagunjagun tó lágbára. Àmọ́, ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé ó máa ń fi agbára ẹ̀ jagun nígbà míì?

Ní Òkun Pupa, Jèhófà fi hàn pé “jagunjagun tó lágbára” lòun jẹ́

Ogun Tí Ọlọ́run Ń Jà Yàtọ̀ sí Tàwa Èèyàn

5, 6. (a) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti pe Ọlọ́run ní “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun”? (b) Kí ló mú kí ogun tí Ọlọ́run ń jà yàtọ̀ sí tàwa èèyàn?

5 Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgọ́rin (280) ìgbà ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pe Ọlọ́run ní “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,” ìgbà méjì ló sì fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. (1 Sámúẹ́lì 1:11) Torí pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, àìmọye àwọn áńgẹ́lì tí Bíbélì pè ní ọmọ ogun ló wà níkàáwọ́ ẹ̀. (Jóṣúà 5:13-15; 1 Àwọn Ọba 22:19) Àwọn ọmọ ogun yìí lágbára gan-an débi pé wọ́n lè pa àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. (Àìsáyà 37:36) Lóòótọ́, inú wa kì í dùn tá a bá gbọ́ pé àwọn kan pa run. Àmọ́, ó yẹ ká rántí pé ogun tí Ọlọ́run ń jà yàtọ̀ sí tàwa èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ogun àtàwọn aṣáájú olóṣèlú máa ń sọ pé torí kí nǹkan lè dáa làwọn fi ń jagun. Àmọ́, tá a bá wádìí ẹ̀ wò, àá rí i pé ìwọra àti ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń mú kí wọ́n jagun.

6 Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwa èèyàn, ó máa ń ronú dáadáa kó tó ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Diutarónómì 32:4 sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, torí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú; olódodo àti adúróṣinṣin ni.” Bíbélì tún sọ pé ìwà ìkà àti ìwà ipá ò dáa, kò sì yẹ kéèyàn máa bínú sódì. (Jẹ́nẹ́sísì 49:7; Sáàmù 11:5) Torí náà, Jèhófà kì í jagun láìnídìí. Kì í dédé pa àwọn èèyàn run, ìgbà tọ́ràn bá dójú ẹ̀ tán ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ó sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé: “ ‘Ǹjẹ́ inú mi máa ń dùn sí ikú ẹni burúkú?’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Ṣebí ohun tí mo fẹ́ ni pé kó yí ìwà rẹ̀ pa dà kó sì máa wà láàyè?’ ”​—Ìsíkíẹ́lì 18:23.

7, 8. (a) Èrò wo ni Jóòbù ní nípa ìyà tó ń jẹ ẹ́? (b) Báwo ni Élíhù ṣe tún èrò Jóòbù ṣe? (d) Kí la rí kọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù?

7 Kí wá nìdí tí Jèhófà fi ń lo agbára rẹ̀ láti pa àwọn èèyàn run? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Jóòbù. Sátánì fẹ̀sùn kan Jóòbù àtàwa èèyàn lápapọ̀, ó sọ pé a ò lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà tá a bá dojú kọ àdánwò. Báwo ni Jèhófà ṣe wá dá sí ọ̀rọ̀ náà? Ó gbà kí Sátánì dán Jóòbù wò. Nípa bẹ́ẹ̀, Jóòbù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn tó le gan-an, ó pàdánù gbogbo ohun tó ní, àwọn ọmọ ẹ̀ sì tún kú. (Jóòbù 1:1–2:8) Torí pé Jóòbù ò mọ ohun tó fa ìṣòro náà, ó gbà pé ńṣe ni Ọlọ́run kàn ń fìyà jẹ òun láìnídìí. Ó wá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé kí nìdí tó fi “dájú sọ” òun, tó sì ka òun sí “ọ̀tá.”​—Jóòbù 7:20; 13:24.

8 Èrò Jóòbù yìí ò tọ̀nà, ìdí nìyẹn tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Élíhù fi tún èrò ẹ̀ ṣe. Ó bi í pé: “Ṣé ó dá ọ lójú pé o jàre tí wàá fi sọ pé, ‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ’?” (Jóòbù 35:2) Òótọ́ ni, kò bọ́gbọ́n mu ká máa rò pé a mọ̀ ju Ọlọ́run lọ tàbí ká máa ronú pé kò ṣe ohun tó tọ́. Élíhù sọ pé: “Ó dájú pé Ọlọ́run tòótọ́ kò ní hùwà burúkú, pé Olódùmarè kò ní ṣe ohun tí kò dáa!” Ó tún sọ pé: “Ó kọjá agbára wa láti lóye Olódùmarè; agbára rẹ̀ pọ̀ gan-an, kì í ṣe ohun tó lòdì sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ tó pọ̀ gidigidi.” (Jóòbù 34:10; 36:22, 23; 37:23) Torí náà, ó dá wa lójú pé tí Ọlọ́run bá jagun, ó máa ní ìdí pàtàkì tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ìdí tí Ọlọ́run àlàáfíà fi máa ń jagun nígbà míì.​—1 Kọ́ríńtì 14:33.

Ìdí Tí Ọlọ́run Àlàáfíà Fi Máa Ń Jagun

9. Kí nìdí tí Ọlọ́run mímọ́ fi máa ń jagun?

9 Lẹ́yìn tí Mósè pe Ọlọ́run ní “jagunjagun tó lágbára,” ó wá sọ pé: “Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run? Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́?” (Ẹ́kísódù 15:11) Bákan náà, wòlíì Hábákúkù sọ pé: “Ojú rẹ ti mọ́ jù láti wo ohun búburú, ìwọ kò sì ní gba ìwà burúkú láyè.” (Hábákúkù 1:13) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́, ó tún jẹ́ Ọlọ́run mímọ́, olódodo àti onídàájọ́ òdodo. Àwọn ìwà àti ìṣe yìí ló máa ń mú kó fi agbára rẹ̀ pani run nígbà míì. (Àìsáyà 59:15-19; Lúùkù 18:7) Torí náà tí Ọlọ́run bá jagun, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kì í ṣe Ọlọ́run mímọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé ó jẹ́ Ọlọ́run mímọ́ gangan ló ń mú kó jagun. ​—Ẹ́kísódù 39:30.

10. Kí lohun kan ṣoṣo tó máa fòpin sí ìkórìíra tí Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́, báwo nìyẹn sì ṣe máa ṣe àwọn olódodo láǹfààní?

10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí tọkọtaya àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ká sọ pé Jèhófà ò ṣe nǹkan nípa ìwà àìṣòdodo tí wọ́n hù ni, Jèhófà ò ní fi hàn pé òun lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Torí pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó di dandan pé kó dájọ́ ikú fáwọn ọlọ̀tẹ̀ náà. (Róòmù 6:23) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì, ó sọ pé àwọn ìránṣẹ́ òun máa di ọ̀tá àwọn alátìlẹyìn “ejò” náà, ìyẹn Sátánì. (Ìfihàn 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Jèhófà sì mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo tó máa yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé kí Sátánì pa run. (Róòmù 16:20) Àmọ́ ìparun yẹn máa ṣe àwọn olódodo láǹfààní gan-an, torí pé ó máa fòpin sí gbogbo wàhálà tí Sátánì ti fà, ìyẹn á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti gbádùn ayé nínú Párádísè. (Mátíù 19:28) Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, àwọn alátìlẹ́yìn Sátánì á máa ta ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, wọ́n á máa ṣenúnibíni sí wọn, wọ́n á sì máa gbìyànjú láti pa wọ́n run. Torí náà, àtìgbàdégbà ló máa ń di dandan pé kí Jèhófà jà nítorí àwọn èèyàn ẹ̀.

Ọlọ́run Jà Kó Lè Mú Ìwà Ibi Kúrò

11. Kí nìdí tó fi di dandan kí Ọlọ́run mú ìkún omi wá sórí gbogbo ayé?

11 Ọ̀kan lára ìgbà tí Ọlọ́run rí i pé ó yẹ kóun jà ni ìgbà ayé Nóà. Jẹ́nẹ́sísì 6:11, 12 sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ rí i pé ayé ti bà jẹ́, ìwà ipá sì kún ayé. Ọlọ́run wo ayé, àní ó ti bà jẹ́; ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara ń hù ní ayé.” Ṣé Ọlọ́run á wá gbà káwọn oníwà ipá àtàwọn oníṣekúṣe yẹn pa ìwọ̀nba èèyàn rere tó kù sáyé run ni? Rárá o. Jèhófà rí i pé ó di dandan kóun fi ìkún omi pa àwọn èèyàn burúkú náà run.

12. (a) Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé òun máa pa àwọn Ámórì run?

12 Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run pinnu láti pa àwọn ọmọ Kénáánì run. Jèhófà ti ṣèlérí fún Ábúráhámù pé nípasẹ̀ ọmọ ẹ̀ ni gbogbo ìdílé ayé máa gba ìbùkún fún ara wọn. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Ọlọ́run sọ pé òun máa fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní ilẹ̀ Kénáánì, ibi táwọn ọmọ Ámórì ń gbé. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe é tó fi máa jàre tó bá fipá lé àwọn èèyàn yẹn jáde kúrò ní ilẹ̀ wọn? Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé òun ò ní lé wọn jáde títí di nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún sí ìgbà yẹn, ìyẹn títí di ìgbà tí “ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Ámórì” fi máa “kún rẹ́rẹ́.” b (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-3; 13:14, 15; 15:13, 16; 22:18) Láàárín àkókò yìí, kàkà kí wọ́n yí pa dà, ńṣe ni ìwà ìbàjẹ́ àwọn Ámórì ń pọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń bọ̀rìṣà, wọ́n ń pa èèyàn, wọ́n sì ń ṣe ìṣekúṣe tó burú gan-an. (Ẹ́kísódù 23:24; 34:12, 13; Nọ́ńbà 33:52) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tú ń sun àwọn ọmọ wọn nínú iná láti fi rúbọ. Ṣé Ọlọ́run mímọ́ á wá gbà kí àwọn èèyàn rẹ̀ máa gbé láàárín àwọn èèyàn burúkú yìí? Rárá o! Ọlọ́run sọ pé: “Ilẹ̀ náà jẹ́ aláìmọ́, màá fìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jẹ ẹ́, ilẹ̀ náà yóò sì pọ àwọn tó ń gbé ibẹ̀ jáde.” (Léfítíkù 18:21-25) Ṣé gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ni Jèhófà máa pa run? Rárá. Ó dá àwọn tó ní ọkàn tó dáa lára àwọn ọmọ Kénáánì sí, irú bíi Ráhábù àtàwọn ará Gíbéónì.​—Jóṣúà 6:25; 9:3-27.

Ó Ń Jà Nítorí Orúkọ Rẹ̀

13, 14. (a) Kí nìdí tó fi di dandan kí Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

13 Torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, orúkọ rẹ̀ náà jẹ́ mímọ́. (Léfítíkù 22:32) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: ‘Kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́.’ (Mátíù 6:9) Nígbà tí Ádámù àti Éfà tẹ́tí sí Sátánì, tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run nínú ọgbà Édẹ́nì, ńṣe ni wọ́n ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, tí wọ́n sì dọ́gbọ́n sọ pé ọ̀nà tó gbà ń ṣàkóso ò dáa. Irú nǹkan báyìí ò lè ṣẹlẹ̀ kí Jèhófà má ṣe nǹkan sí i, ó dájú pé ó máa mú ẹ̀gàn tí wọ́n mú bá orúkọ rẹ̀ kúrò.​—Àìsáyà 48:11.

14 Tún wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé máa gba ìbùkún fún ara wọn. Ká ní Jèhófà ò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní oko ẹrú, ó lè jọ pé ìlérí yẹn ò ní ṣẹ. Àmọ́, Jèhófà gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, ó sì sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè, ìyẹn sì mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀. Abájọ tí wòlíì Dáníẹ́lì fi sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, Ìwọ tí o fi ọwọ́ agbára mú àwọn èèyàn rẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, tí o sì ṣe orúkọ fún ara rẹ.”​—Dáníẹ́lì 9:15.

15. Kí nìdí tí Jèhófà fi mú àwọn Júù kúrò nígbèkùn Bábílónì?

15 Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé, nígbà tí Dáníẹ́lì gbàdúrà yìí, àwọn Júù ń retí pé kí Jèhófà gba àwọn sílẹ̀ kó lè mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ rẹ̀. Lásìkò yẹn, àwọn Júù wà nígbèkùn ní Bábílónì torí pé wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú wọn ti di ahoro. Dáníẹ́lì mọ̀ pé tí Jèhófà bá mú àwọn Júù pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìyẹn á mú ògo bá orúkọ rẹ̀. Torí náà, Dáníẹ́lì gbàdúrà pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì. Jèhófà, jọ̀ọ́ fiyè sí wa, kí o sì gbé ìgbésẹ̀! Má ṣe jẹ́ kó pẹ́, torí tìẹ, Ọlọ́run mi, torí orúkọ rẹ la fi pe ìlú rẹ àti àwọn èèyàn rẹ.”​—Dáníẹ́lì 9:18, 19.

Ó Ń Jà Nítorí Àwọn Èèyàn Rẹ̀

16. Ṣé bí Jèhófà ṣe fẹ́ràn láti máa gbèjà orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí pé aláìláàánú àti onímọtara-ẹni-nìkan ni? Ṣàlàyé.

16 Torí pé Jèhófà fẹ́ràn láti máa gbèjà orúkọ rẹ̀, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé aláìláàánú àti onímọtara-ẹni-nìkan ni? Rárá o. Kì í ṣe torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ tó sì nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo nìkan ló fi máa ń jà, ó tún máa ń jà kó lè dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Jẹ́ ká wo ohun tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì orí kẹrìnlá. Orí yẹn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọba mẹ́rin tó gbógun ja ìlú Sódómù àti Gòmórà, tí wọ́n sì mú Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù àti ìdílé rẹ̀ lẹ́rú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá náà lágbára ju Ábúráhámù lọ, Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun wọn! Ó jọ pé ìtàn bí Jèhófà ṣe ran Ábúráhámù lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá yìí ni wọ́n kọ́kọ́ kọ sínú “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà,” ìyẹn ìwé kan tó ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn ogun míì tí Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa wọn. (Nọ́ńbà 21:14) Ọ̀pọ̀ ogun làwọn èèyàn Jèhófà tún jà tí wọ́n sì ṣẹ́gun lẹ́yìn ìyẹn.

17. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ń jà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n wọ ilẹ̀ Kénáánì? Sọ àpẹẹrẹ kan.

17 Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì, Mósè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Jèhófà Ọlọ́run yín máa lọ níwájú yín, ó sì máa jà fún yín, bó ṣe jà fún yín ní Íjíbítì tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.” (Diutarónómì 1:30; 20:1) Jèhófà sì jà fáwọn èèyàn rẹ̀ lóòótọ́, torí ó mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ayé Jóṣúà tó rọ́pò Mósè àtìgbà ayé àwọn Onídàájọ́, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ìṣàkóso àwọn ọba Júdà tó jẹ́ olóòótọ́.​—Jóṣúà 10:1-14; Àwọn Onídàájọ́ 4:12-17; 2 Sámúẹ́lì 5:17-21.

18. (a) Kí nìdí tọ́kàn wa fi balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò yí pa dà? (b) Kí ni Jèhófà máa ṣe nígbà táwọn alátìlẹyìn Sátánì bá dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́nà tó rorò gan-an?

18 Jèhófà ò tíì yí pa dà; bẹ́ẹ̀ ni ohun tó ní lọ́kàn pé kí ayé yìí di Párádísè kò tíì yí pa dà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ọlọ́run ṣì kórìíra ìwà ibi. Àmọ́, ó fẹ́ràn àwọn èèyàn ẹ̀ gan-an, ó sì máa jà fún wọn láìpẹ́. (Sáàmù 11:7) Kódà, ìkórìíra tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ máa le sí i láìpẹ́ débi pé àwọn alátìlẹyìn Sátánì á dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́nà tó rorò gan-an. Àmọ́, Jèhófà máa fi hàn pé “jagunjagun tó lágbára” lòun lẹ́ẹ̀kan sí i, kó lè sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ kó sì dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀!​—Sekaráyà 14:3; Ìfihàn 16:14, 16.

19. (a) Ṣé ó yẹ ká máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Ọlọ́run torí pé ó ń fi agbára ẹ̀ pa àwọn èèyàn burúkú run? Sọ àpèjúwe kan. (b) Báwo ló ṣe yẹ kó rí lára wa bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run ń fẹ́ láti jà fún wa?

19 Wo àpèjúwe yìí: Ká sọ pé ẹranko búburú kan yọ sí ìdílé ọkùnrin kan, ọkùnrin náà wá dojú kọ ẹranko yìí, ó bá a jà, ó sì pa á. Ṣé o rò pé ohun tí ọkùnrin náà ṣe á mú kí ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ máa bẹ̀rù ẹ̀? Rárá o, ńṣe ni wọ́n máa mọyì bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó sì dáàbò bò wọ́n. Bákan náà, kò yẹ ká máa bẹ̀rù láti sún mọ́ Jèhófà torí pé ó ń fi agbára ẹ̀ pa àwọn èèyàn burúkú run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ torí pé ó ń dáàbò bò wá. Ó sì yẹ ká túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún un torí pé agbára rẹ̀ kò lópin. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè máa “ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀.”​—Hébérù 12:28.

Sún Mọ́ Jèhófà Tó Jẹ́ “Jagunjagun Tó Lágbára”

20. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ka ìtàn Bíbélì kan nípa ogun tí Ọlọ́run jà, tá ò sì mọ ìdí tó fi ja ogun náà? Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

20 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Bíbélì máa ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìdí tí Jèhófà fi pinnu láti ja àwọn ogun kan. Àmọ́, ó yẹ kó dá wa lójú pé: Jèhófà kì í jagun torí kó lè fi ṣèkà tàbí torí pé agbára ń gùn ún, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa ń lo agbára rẹ̀ lọ́nà tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Torí náà, tá a bá ka ìtàn kan nínú Bíbélì, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn ìtàn náà kí ìtàn náà lè yé wa dáadáa. (Òwe 18:13) Tá ò bá tiẹ̀ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan, tá a bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tá a sì ń ronú lórí àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀, a ò ní ṣiyèméjì mọ́, àá sì rí i pé ó yẹ ká fọkàn tán Jèhófà Ọlọ́run wa.​—Jóòbù 34:12.

21. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà máa ń di “jagunjagun tó lágbára” nígbà míì, kí làwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ nípa rẹ̀?

21 A ti rí i pé “jagunjagun tó lágbára” ni Jèhófà torí ó máa ń jà nígbà tó bá rí i pé ó di dandan kóun ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé ó fẹ́ràn láti máa jagun. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run, ìrísí Jèhófà dà bíi tẹnì kan tó múra ogun láti bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà. Àmọ́, Ìsíkíẹ́lì tún rí òṣùmàrè tó yí Jèhófà ká, bẹ́ẹ̀ sì rèé àmì àlàáfíà ni òṣùmàrè. (Jẹ́nẹ́sísì 9:13; Ìsíkíẹ́lì 1:28; Ìfihàn 4:3) Èyí fi hàn pé ọlọ́kàn tútù àti ẹni àlàáfíà ni Jèhófà jẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Gbogbo ìwà àti ìṣe Jèhófà ló máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́nà tó pé pérépéré. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní, pé a lè sún mọ́ Ọlọ́run tí agbára rẹ̀ ò lópin, síbẹ̀ tó tún jẹ́ onífẹ̀ẹ́!

a Nígbà tí òpìtàn Júù kan tó ń jẹ́ Josephus ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn ọmọ ogun Íjíbítì tó ń lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pọ̀ tó, ó sọ pé “wọ́n ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) kẹ̀kẹ́ ẹṣin, àwọn tó ń gun ẹṣin lára wọn tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000), wọ́n sì ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì (200,000) ọmọ ogun tó di ìhámọ́ra.”​—Jewish Antiquities, Apá Kejì, ojú ìwé 324 [xv, 3].

b Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn èèyàn Kénáánì lápapọ̀ ni Bíbélì pè ní “àwọn Ámórì.”​—Diutarónómì 1:6-8, 19-21, 27; Jóṣúà 24:15, 18.