Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 12

“Ṣé Ọlọ́run Jẹ́ Aláìṣòdodo Ni?”

“Ṣé Ọlọ́run Jẹ́ Aláìṣòdodo Ni?”

1. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí wọ́n bá rẹ́ ẹnì kan jẹ?

 ÀWỌN gbájú-ẹ̀ gba gbogbo owó tí arúgbó kan tó jẹ́ opó ti kó jọ láti máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ọ̀dájú abiyamọ kan gbọ́mọ ẹ̀ jòjòló jù síbì kan ó sì sá lọ. Wọ́n ju ọkùnrin kan sẹ́wọ̀n torí ẹ̀ṣẹ̀ tí kò mọ ohunkóhun nípa ẹ̀. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá gbọ́ irú àwọn nǹkan yìí? Ó dájú pé inú máa ń bí wa, ó sì máa ń ká wa lára gan-an tá a bá gbọ́ nípa irú àwọn ìwà burúkú bẹ́ẹ̀. Kódà, tí wọ́n bá rẹ́ ẹnì kan jẹ, a máa ń fẹ́ kí wọ́n ran ẹni náà lọ́wọ́, kẹ́ni tó rẹ́ni jẹ sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Tí kò bá wá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú ká máa béèrè pé: ‘Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé? Kí nìdí tí kò fi wá nǹkan ṣe sí i?’

2. Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ṣe rí lára Hábákúkù, kí sì nìdí tí Jèhófà kò fi bá a wí nítorí ohun tó sọ?

2 Ọjọ́ pẹ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Hábákúkù gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí nìdí tí o fi ń jẹ́ kí ohun búburú ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí o fi fàyè gba ìnilára? Kí nìdí tí ìparun àti ìwà ipá fi ń ṣẹlẹ̀ níṣojú mi? Kí sì nìdí tí ìjà àti aáwọ̀ fi wà káàkiri?” (Hábákúkù 1:3) Àwọn ìbéèrè tí Hábákúkù béèrè yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ yẹn ká a lára gan-an, Jèhófà ò sì bá a wí rárá, torí pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló dá wa lọ́nà tá a fi lè kórìíra ìrẹ́jẹ. Bá ò tiẹ̀ lè ṣe bíi ti Jèhófà lọ́nà tó pé, a lè fìwà jọ ọ́ torí pé ó dá wa láwòrán ara ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń wù wá kí nǹkan lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Jèhófà Kórìíra Ìwà Ìrẹ́jẹ

3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ń rí ìwà ìrẹ́jẹ tó ń lọ láyé jù wá lọ?

3 Kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run, torí náà ó ń kíyè sí báwọn èèyàn ṣe ń hùwà ìrẹ́jẹ lónìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà ayé Nóà, ó sọ pé: “Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5) Jẹ́ ká wo ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a mọ̀ nípa ìwà ìrẹ́jẹ kò ju ohun tá a gbọ́ tàbí tó ṣẹlẹ̀ sáwa fúnra wa. Àmọ́ ní ti Jèhófà, ó ń rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù kárí ayé. Gbogbo ẹ̀ ló ń rí! Yàtọ̀ síyẹn, ó mọ gbogbo èrò burúkú tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, tó ń mú kí wọ́n máa rẹ àwọn ẹlòmíì jẹ.​—Jeremáyà 17:10.

4, 5. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n ń rẹ́ jẹ ṣe pàtàkì sí Jèhófà? (b) Báwo ni wọ́n ṣe hùwà àìdáa sí Jèhófà fúnra ẹ̀?

4 Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn dákẹ́ tó ń wo gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tó ń lọ láyé o. Ó ń kíyè sí àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ, ó sì máa ń káàánú wọn. Nígbà táwọn ọ̀tá ń ni àwọn èèyàn Jèhófà lára, àánú wọn ṣe é “torí pé àwọn tó ń ni wọ́n lára àtàwọn tó ń fìyà jẹ wọ́n mú kí wọ́n máa kérora.” (Àwọn Onídàájọ́ 2:18) Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé táwọn èèyàn bá ń rí ìwà ìrẹ́jẹ lemọ́lemọ́, tó bá yá kò ní fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan kan mọ́ lójú wọn, àwọn náà sì lè wá di ọ̀dájú. Àmọ́, ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀! Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ọdún tó ti ń rí oríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń rẹ́ni jẹ, síbẹ̀ ó ṣì kórìíra ìrẹ́jẹ. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kórìíra àwọn ìwà bí “ahọ́n èké,” “ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,” àti “ẹlẹ́rìí èké tí kò lè ṣe kó má parọ́.”​—Òwe 6:16-19.

5 Jẹ́ ká wo ẹ̀rí míì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kórìíra kí wọ́n máa rẹ́ èèyàn jẹ lóòótọ́. Nígbà tó kíyè sí báwọn aṣáájú ní Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, ó bá wọn wí lọ́nà tó le gan-an. Jèhófà rán wòlíì Míkà sí wọn, ó ní kó bi wọ́n pé: “Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ ohun tó tọ́?” Lẹ́yìn tí Jèhófà ṣàpèjúwe báwọn ọkùnrin oníwà ìbàjẹ́ yẹn ṣe ń ṣi agbára lò, ó wá sọ ohun tó máa gbẹ̀yìn wọn, ó ní: “Wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́, àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn. Ó máa fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wọn ní àkókò yẹn, torí ìwà burúkú wọn.” (Míkà 3:1-4) Ẹ ò rí i bí Jèhófà ṣe kórìíra ìrẹ́jẹ tó! Kódà, òun fúnra ẹ̀ mọ bó ṣe máa ń rí, torí pé wọ́n ti hùwà àìdáa sóun náà rí! Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń pẹ̀gàn ẹ̀. (Òwe 27:11) Bákan náà, àwọn èèyàn ṣe ohun tó dun Jèhófà gan-an nígbà tí wọ́n fìyà jẹ Ọmọ ẹ̀, tí wọ́n sì pa á bí wọ́n ṣe ń pa ọ̀daràn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (1 Pétérù 2:22; Àìsáyà 53:9) Ó dá wa lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ àwọn tí wọ́n ń rẹ́ jẹ, ó sì dájú pé ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

6. Báwo ló ṣe sábà máa ń rí lára wa tí wọ́n bá rẹ́ àwa tàbí àwọn míì jẹ, kí sì nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀?

6 Lóòótọ́, a mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìrẹ́jẹ àti pé ó máa ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀, àmọ́ ó ṣì máa ń ká wa lára táwọn èèyàn bá rẹ́ wa jẹ tàbí tá a bá gbọ́ pé wọ́n rẹ́ ẹnì kan jẹ. Ìyẹn ò burú rárá, torí pé ńṣe ni Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, ìwà ìrẹ́jẹ sì lòdì sírú ẹni tí Jèhófà jẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Kí wá nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ìrẹ́jẹ?

Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Kan

7. Báwo ni Sátánì ṣe ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ tó sì ta ko ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso?

7 Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Bá a ṣe mọ̀, Ẹlẹ́dàá wa ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé yìí àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀. (Sáàmù 24:1; Ìfihàn 4:11) Àmọ́, kò pẹ́ sígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ lẹnì kan ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, tó sì tún sọ pé Ọlọ́run ò lè ṣàkóso wọn lọ́nà tó dáa. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀? Jèhófà pàṣẹ fún Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, pé kò gbọ́dọ̀ jẹ èso ọ̀kan lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ ẹ́? Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Ó dájú pé o máa kú.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún Ádámù àti Éfà aya rẹ̀ kò ṣòro rárá. Àmọ́, Sátánì sọ fún Éfà pé ńṣe ni Ọlọ́run ò fẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n. Kí ni Sátánì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ tí Éfà bá jẹ lára èso yẹn? Sátánì sọ fún un pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú. Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.”​—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.

8. (a) Kí ni Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ fún Éfà nípa Jèhófà? (b) Kí ni Sátánì sọ nípa ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso?

8 Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ fún Éfà ni pé ńṣe ni Jèhófà ń parọ́ fún un, tí kò sì jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó yẹ kó mọ̀. Ó fẹ́ kí Éfà máa rí Jèhófà bí ẹni burúkú. Bí Sátánì ṣe kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run nìyẹn, tó sì tún ta ko ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso. Òótọ́ kan ni pé Sátánì ò sọ pé Jèhófà ò láṣẹ lórí gbogbo ohun tó dá. Àmọ́, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé ipò yẹn ò tọ́ sí Ọlọ́run. Ó tún sọ pé ọ̀nà tó dáa kọ́ ni Ọlọ́run gbà ń lo àṣẹ tó ní àti pé ìṣàkóso rẹ̀ ò lè ṣeni láǹfààní.

9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló sì jẹ yọ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?

9 Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n jẹ lára èso igi tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ. Ọlọ́run ti sọ pé wọ́n máa kú tí wọ́n bá jẹ ẹ́, torí náà wọ́n kú. Ẹ ò rí i pé irọ́ ni Sátánì pa fún wọn! Àmọ́, ohun tí Sátánì sọ mú kí àwọn ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ. Ṣé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àwa èèyàn lóòótọ́, àbí èèyàn ló yẹ kó máa ṣàkóso ara ẹ̀? Ṣé Jèhófà ń ṣàkóso bó ṣe yẹ lóòótọ́? Jèhófà lágbára láti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, ẹ rántí pé Sátánì ò sọ pé Ọlọ́run ò lágbára, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, tó sì sọ pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. Torí náà, ká sọ pé Jèhófà ti pa Ádámù, Éfà àti Sátánì run lójú ẹsẹ̀, Jèhófà ì bá má fi hàn pé alákòóso tó dáa lòun. Ńṣe ló kàn máa dà bíi pé òótọ́ lohun tí Sátánì sọ. Ọ̀nà kan ṣoṣo táwọn èèyàn fi lè mọ̀ bóyá wọ́n máa lè ṣàkóso ara wọn láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé kí Ọlọ́run fún wọn láyè kí wọ́n gbìyànjú ẹ̀ wò.

10. Kí ni ìtàn jẹ́ ká mọ̀ nípa ìṣàkóso èèyàn?

10 Kí làwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn jẹ́ ká mọ̀ nípa ìjọba èèyàn? Oríṣiríṣi ìjọba làwọn èèyàn ti dán wò, irú bí ìjọba apàṣẹwàá, ìjọba tiwa-n-tiwa, ìjọba àjùmọ̀ní àti ìjọba Kọ́múníìsì. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ ni gbogbo rẹ̀ pa dà ń já sí, ó ní: “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Àbájọ tí wòlíì Jeremáyà fi sọ pé: “Jèhófà, mo mọ̀ dáadáa pé ọ̀nà èèyàn kì í ṣe tirẹ̀. Àní kò sí ní ìkáwọ́ èèyàn tó ń rìn láti darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”​—Jeremáyà 10:23.

11. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà káwọn èèyàn ṣàkóso ara wọn?

11 Jèhófà mọ̀ látìbẹ̀rẹ̀ pé ìyà máa jẹ àwa èèyàn gan-an tá a bá ń ṣàkóso ara wa láìsí ìrànlọ́wọ́ òun. Ṣé a lè wá sọ pé ìkà ni Ọlọ́run bó ṣe gbà káwọn èèyàn ṣàkóso ara wọn? Rárá o! Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Ká sọ pé o lọ́mọ kan tó ń ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí ẹ̀, táwọn dókítà sì sọ pé ó dìgbà tí wọ́n bá ṣe iṣẹ́ abẹ fún un kí ara ẹ̀ tó lè yá. O mọ̀ pé iṣẹ́ abẹ yìí máa fa ìrora fún ọmọ rẹ, ìyẹn sì bà ẹ́ nínú jẹ́ gidigidi. Síbẹ̀, o mọ̀ pé iṣẹ́ abẹ yẹn á jẹ́ kí ọmọ rẹ ní ìlera tó dáa sí i lọ́jọ́ iwájú. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run mọ̀, ó sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé bóun ṣe gbà káwọn èèyàn ṣàkóso ara wọn máa jẹ́ kí wàhálà dé bá wọn, á sì mú kí ìyà jẹ wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19) Àmọ́, Ọlọ́run tún mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí ìtura dé bá àwọn èèyàn ni pé kóun jẹ́ kí wọ́n fojú ara wọn rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn tí wọ́n bá ń ṣàkóso ara wọn láìsí ìrànlọ́wọ́ òun. Ìyẹn á wá yanjú bí Sátánì ṣe ta ko ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso, ọ̀rọ̀ náà ò sì ní gbérí mọ́ láé.

Kí Nìdí Táwa Èèyàn Fi Ń Sin Ọlọ́run?

12. Bá a ṣe rí i nínú àpẹẹrẹ Jóòbù, ẹ̀sùn wo ni Sátánì fi kan gbogbo àwa èèyàn?

12 Kì í ṣe pé Sátánì ta ko Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso àwa èèyàn nìkan, àmọ́ ó tún ba àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lórúkọ jẹ́ torí ó sọ pé a ò lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí Sátánì sọ fún Jèhófà nípa ọkùnrin olódodo tó ń jẹ́ Jóòbù, Sátánì sọ pé: “Ṣebí o ti ṣe ọgbà yí i ká láti dáàbò bo òun, ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní? O ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sì ti pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà. Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu gbogbo ohun tó ní, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.”​—Jóòbù 1:10, 11.

13. Kí ni Sátánì dọ́gbọ́n sọ nígbà tó fẹ̀sùn kan Jóòbù, báwo lọ̀rọ̀ náà sì ṣe kan gbogbo èèyàn?

13 Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé torí pé Jèhófà ń dáàbò bo Jóòbù ló ṣe ń sin Jèhófà. Ohun tọ́rọ̀ Sátánì yẹn túmọ̀ sí ni pé ẹ̀tàn ni gbogbo bí Jóòbù ṣe ń sọ pé òun ń pa ìwà títọ́ mọ́ àti pé torí ohun tí Jóòbù máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló ṣe ń sìn ín. Sátánì sọ pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé èèyàn dáadáa ni Jóòbù, tí Ọlọ́run ò bá bù kún un mọ́, ó máa bú Ọlọ́run. Sátánì mọ̀ pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jóòbù jẹ́, ó rí i pé “olódodo àti olóòótọ́ èèyàn ni, ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.” a Àmọ́, Sátánì gbà pé tóun bá lè mú kí Jóòbù fi Jèhófà sílẹ̀, ó dájú pé òun á lè ṣe ohun kan náà fáwọn èèyàn tó kù. Sátánì wá tipa bẹ́ẹ̀ fẹ̀sùn kan gbogbo èèyàn lápapọ̀ pé torí ohun tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ni wọ́n ṣe ń sìn ín. Èyí sì túbọ̀ ṣe kedere nínú ohun tí Sátánì sọ fún Jèhófà lẹ́yìn ìyẹn, ó ní: “Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.”​—Jóòbù 1:8; 2:4.

14. Kí ló fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan àwa èèyàn?

14 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe ohun tó fi hàn pé irọ́ ni Sátánì ń pa. Bíi ti Jóòbù, àwọn náà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà lójú àdánwò. Ohun tí wọ́n ṣe yìí múnú Jèhófà dùn, ó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti fún Sátánì lésì lórí ohun tó sọ pé tí ìṣòro bá dé bá àwa èèyàn a ò ní sin Ọlọ́run mọ́. (Hébérù 11:4-38) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i jálẹ̀ ayé wọn. Kódà, láwọn àkókò tí nǹkan le koko fún wọn, ńṣe ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, torí wọ́n mọ̀ pé ó máa fún wọn lókun, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fara da ìṣòro wọn.​—2 Kọ́ríńtì 4:7-10.

15. Kí la lè béèrè nípa àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run ti ṣe sẹ́yìn àti èyí tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?

15 Nígbà tí Sátánì ta ko Jèhófà pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ò dáa, tó tún fẹ̀sùn kan àwa èèyàn pé a ò sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, bí Jèhófà ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ká rí i pé onídàájọ́ òdodo ni lóòótọ́. Àmọ́, Jèhófà tún ṣe àwọn nǹkan míì tó jẹ́ ká rí i pé ó jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àtohun tó ṣe lórí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè kan. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ti ń ṣèdájọ́ òdodo àti pé ó máa ṣèdájọ́ òdodo nígbà tó bá ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ lọ́jọ́ iwájú?

Ìdájọ́ Ọlọ́run Ló Dáa Jù Lọ

Ó dájú pé Jèhófà kò ní “pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú”

16, 17. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àìpé kì í jẹ́ káwa èèyàn ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́?

16 Bíbélì sọ pé Jèhófà “ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Òótọ́ sì lọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ a ò lè sọ bẹ́ẹ̀ nípa àwa èèyàn, ó ṣe tán àìpé wa kì í jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn nǹkan, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ká dájọ́ lọ́nà tí kò tọ́ lọ́pọ̀ ìgbà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ábúráhámù. Nígbà tí Jèhófà sọ pé òun máa pa ìlú Sódómù run torí ìwà burúkú táwọn èèyàn ibẹ̀ ń hù, ńṣe ni Ábúráhámù bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jèhófà pé kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wá bi Jèhófà pé: “Ṣé o máa pa olódodo run pẹ̀lú ẹni burúkú ni?” (Jẹ́nẹ́sísì 18:23-33) Ó dájú pé Jèhófà ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Torí ìgbà tí Lọ́ọ̀tì olódodo àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ dé ìlú Sóárì láìséwu ni Jèhófà tó “rọ òjò imí ọjọ́ àti iná lé Sódómù” lórí. (Jẹ́nẹ́sísì 19:22-24) Ní ti Jónà, lẹ́yìn tó kéde pé Ọlọ́run máa pa ìlú Nínéfè run, ńṣe ló ń retí pé kí Jèhófà pa wọ́n run. Àmọ́, àwọn èèyàn náà ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Ọlọ́run sì fàánú hàn sí wọn. Nígbà tí Jónà wá rí i pé Ọlọ́run ò pa wọ́n run mọ́, ‘inú bí i gan-an.’​—Jónà 3:10–4:1.

17 Ohun tí Jèhófà ṣe fún Lọ́ọ̀tì jẹ́ kó túbọ̀ dá Ábúráhámù lójú pé torí pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ó máa dá àwọn olódodo sí tó bá fẹ́ pa àwọn aláìṣòdodo run. Àmọ́, ní ti Jónà ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ará ìlú Nínéfè ló jẹ́ kó túbọ̀ yé e pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an. Jónà wá rí i pé táwọn èèyàn burúkú bá yí ọ̀nà wọn pa dà, Jèhófà ‘ṣe tán láti dárí jì wọ́n.’ (Sáàmù 86:5) Jèhófà ò dà bí àwọn èèyàn, tí wọ́n máa ń fìyà jẹni kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn lágbára, tí wọ́n sì máa ń bẹ̀rù láti fàánú hàn torí káwọn èèyàn máa bàa rò pé ojo ni wọ́n. Ní ti Jèhófà, ó máa ń fàánú hàn ní gbogbo ìgbà tó bá yẹ.​—Àìsáyà 55:7; Ìsíkíẹ́lì 18:23.

18. Sọ àpẹẹrẹ kan látinú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé ohun téèyàn bá ṣe ni Jèhófà máa fi dá a lẹ́jọ́.

18 Òótọ́ ni pé Jèhófà máa ń fàánú hàn nígbà tó bá ń ṣèdájọ́, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó máa ń gbójú fo ìwà burúkú tẹ́nì kan bá hù. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi Jèhófà sílẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. Mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín, torí màá fi ìwà yín san yín lẹ́san.” (Ìsíkíẹ́lì 7:3, 4) Nítorí náà, táwọn èèyàn bá kọ̀ láti jáwọ́ nínú ìwà burúkú, Jèhófà á dá wọn lẹ́jọ́. Kò sì ní dáni lẹ́jọ́ láìsí ẹ̀rí tó dájú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà gbọ́ igbe àwọn èèyàn nípa Sódómù àti Gòmórà, ó sọ pé: “Èmi yóò lọ wò ó bóyá ohun tí mò ń gbọ́ nípa wọn náà ni wọ́n ń ṣe.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ò dà bí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n máa ń fi ìkánjú dáni lẹ́jọ́ láìmọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an! Òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé “Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú” ni.​—Diutarónómì 32:4.

Jẹ́ Kó Dá Ẹ Lójú Pé Ìgbà Gbogbo Ni Jèhófà Máa Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo

19. Kí la lè ṣe tá ò bá mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe àwọn nǹkan kan?

19 Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìdí tí Jèhófà fi dá àwọn kan lẹ́jọ́ nígbà àtijọ́, bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwùjọ èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, tá a bá ka ìtàn tàbí àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Bíbélì tí kò yé wa, tí Bíbélì ò sì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ẹ̀, ṣe ló yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti wòlíì Míkà tó sọ pé: “Màá dúró de Ọlọ́run ìgbàlà mi.”​—Míkà 7:7.

20, 21. Kí ló mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́?

20 Ohun tó dá wa lójú ni pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́. Táwọn kan bá tiẹ̀ ń gbójú fo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù, Jèhófà ṣèlérí pé: “Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san.” (Róòmù 12:19) Tá a bá ṣe sùúrù, tá a sì fọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́, ńṣe làwa náà ń fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ṣé Ọlọ́run jẹ́ aláìṣòdodo ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá!”​—Róòmù 9:14.

21 ‘Àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ là ń gbé yìí. (2 Tímótì 3:1) Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìyà ń jẹ torí pé ìwà ìrẹ́jẹ àti “ìwà ìnilára” pọ̀ láyé. (Oníwàásù 4:1) Àmọ́ Jèhófà ò yí pa dà, ó ṣì kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ. Kódà, àánú àwọn tí wọ́n rẹ́ jẹ máa ń ṣe é, ó sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, tá a sì fara mọ́ ọn pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ, ó máa fún wa lókun ká lè máa fara dà á títí dìgbà tó máa fòpin sí gbogbo ìrẹ́jẹ lábẹ́ Ìjọba rẹ̀.​—1 Pétérù 5:6, 7.

a Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa Jóòbù, ó sọ pé: “Kò sí ẹni tó dà bí rẹ̀ ní ayé.” (Jóòbù 1:8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn ìgbà tí Jósẹ́fù kú ni Jóòbù gbé ayé, ó sì jọ pé Ọlọ́run ò tíì yan Mósè ṣe aṣáájú Ísírẹ́lì nígbà yẹn. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé kò sí ẹnì kankan láyé nígbà yẹn tó jẹ́ olóòótọ́ bíi ti Jóòbù.