Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 15

Jésù “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”

Jésù “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”

1, 2. Ìgbà wo ni Jésù bínú, kí sì nìdí?

 LỌ́JỌ́ kan, Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, ó sì rí ohun tó bí i nínú gan-an. Ó lè ṣòro láti gbà gbọ́ pé Jésù bínú, ó ṣe tán èèyàn jẹ́jẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà ni. (Mátíù 21:5) Àmọ́, inú tó bí Jésù ò mú kó ṣe ohun tí ò dáa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìtara tó ní láti ṣe ohun tó tọ́ ló mú kó bínú nígbà tó rí i táwọn èèyàn ń hùwà ìrẹ́jẹ tó burú gan-an. a

2 Jésù fẹ́ràn tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gan-an. Láyé ìgbà yẹn, ibẹ̀ nìkan ló jẹ́ ibi mímọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti máa jọ́sìn Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Àwọn Júù máa ń wá síbẹ̀ láti ibi tó jìnnà gan-an kí wọ́n lè jọ́sìn. Kódà, àwọn Kèfèrí tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń wá síbẹ̀ kí wọ́n lè jọ́sìn ní àgbàlá tẹ́ńpìlì, níbi tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wọn láti máa lò. Àmọ́, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó lọ sínú tẹ́ńpìlì, ó sì rí àwọn nǹkan tó kó o nírìíra gan-an níbẹ̀. Ibẹ̀ ò dà bí ilé ìjọsìn rárá, ṣe ló dà bí ọjà! Ṣe làwọn oníṣòwò àtàwọn tó ń pààrọ̀ owó kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Kí ló wá burú nínú ìyẹn? Ó burú torí pé ńṣe làwọn èèyàn yẹn ń wá sínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run kí wọ́n lè rẹ́ àwọn èèyàn jẹ, kí wọ́n sì jà wọ́n lólè. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?​—Jòhánù 2:14.

3, 4. Báwo làwọn kan ṣe ń rẹ́ni jẹ nínú tẹ́ńpìlì, kí ni Jésù sì ṣe nípa ẹ̀?

3 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn pàṣẹ pé oríṣi owó ẹyọ kan pàtó ni káwọn èèyàn máa fi san owó orí ní tẹ́ńpìlì. Torí náà, àwọn tó bá wá sí tẹ́ńpìlì láti ọ̀nà jíjìn ní láti pààrọ̀ owó wọn kí wọ́n tó lè ní irú owó ẹyọ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn táwọn tó ń pààrọ̀ owó fi dìídì gbé tábìlì wọn wá sínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì ń gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n tó bá wọn pààrọ̀ owó wọn. Ẹran ọ̀sìn làwọn míì ń tà ní tiwọn, wọ́n sì ń rí owó rẹpẹtẹ nídìí ẹ̀. Kì í ṣe pé àwọn tó bá fẹ́ rúbọ ò lè rí ẹran rà lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò míì nínú ìlú, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì lè sọ pé kò ṣeé fi rúbọ. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ inú tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti ra ẹran náà, ó dájú pé wọ́n máa fi rúbọ. Àwọn oníṣòwò yẹn mọ̀ pé ó di dandan káwọn èèyàn ra ẹran lọ́wọ́ àwọn, torí náà wọ́n máa ń gbówó lé e. b Kódà, kì í ṣe pé wọ́n kàn gbówó lé ohun tí wọ́n ń tà, ṣe ni wọ́n ń ja àwọn èèyàn lólè.

4 Jésù ò lè fara mọ́ ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn yẹn ń hù. Ó tún wá lọ jẹ́ pé inú ilé Bàbá rẹ̀ ni wọ́n ti ń hùwàkiwà náà! Ló bá fi okùn ṣe ẹgba, ó sì fi lé àwọn màlúù àti àgùntàn tí wọ́n ń tà jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Lẹ́yìn náà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń pààrọ̀ owó, ó sì dojú àwọn tábìlì wọn dé. Fojú inú wo bí owó ẹyọ wọn á ṣe máa fọ́n káàkiri ilẹ̀ tó ń dán gbinrin yẹn! Lẹ́yìn ìyẹn, ó pàṣẹ fáwọn tó ń ta àdàbà pé: “Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí!” (Jòhánù 2:15, 16) Jésù fìgboyà sọ̀rọ̀ débi pé kò sẹ́ni tó lè ta kò ó.

“Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí!”

Ẹní Bíni Làá Jọ

5-7. (a) Kí ló mú kí Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo bíi ti Jèhófà, kí làwa náà sì máa kọ́ tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ Jésù? (b) Kí ni Jésù ṣe nípa ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà, kí ló sì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú?

5 Àmọ́ o, àwọn oníṣòwò yẹn tún pa dà sínú tẹ́ńpìlì náà. Torí ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn, Jésù tún bá wọn wí lórí ọ̀rọ̀ kan náà, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí ńṣe ni Jésù dìídì lo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fúnra ẹ̀ sọ láti fi bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó sọ ilé Rẹ̀ di “ihò àwọn olè.” (Jeremáyà 7:11; Mátíù 21:13) Nígbà tí Jésù rí bí wọ́n ṣe ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ àti bí wọ́n ṣe sọ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run di ibi àìmọ́, ó ká a lára bó ṣe ń ká Baba rẹ̀ lára. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù náà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo bíi ti Bàbá rẹ̀. Ó ṣe tán, àìmọye ọdún ló ti fi kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Baba rẹ̀ ọ̀run. Wọ́n ṣáà máa ń sọ pé, “Ẹní bíni làá jọ.” Torí náà, ohun tó dáa jù lọ tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ onídàájọ́ òdodo ni pé ká ronú jinlẹ̀ nípa àpẹẹrẹ Jésù Kristi.​—Jòhánù 14:9, 10.

6 Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà wà níbẹ̀ nígbà tí Sátánì pe Jèhófà Ọlọ́run ní òpùrọ́, tó sì tún sọ pé Jèhófà ò lè ṣàkóso lọ́nà tó tọ́. Ẹ ò rí i pé ìbanilórúkọjẹ́ gbáà nìyẹn! Ọmọ yìí tún gbọ́ nígbà tí Sátánì sọ pé torí ohun táwọn èèyàn máa rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà ni wọ́n ṣe ń sìn ín, kì í ṣe torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Torí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, ó dájú pé inú ẹ̀ bà jẹ́ gan-an nígbà tí Sátánì fẹ̀sùn èké kan Bàbá rẹ̀. Àmọ́, inú ẹ̀ dùn gan-an nígbà tó mọ̀ pé Jèhófà máa lo òun láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan, ìyẹn láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé òpùrọ́ ni Sátánì! (2 Kọ́ríńtì 1:20) Báwo ló ṣe máa ṣe é?

7Orí 14, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù Kristi ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, tó sì fi hàn pé irọ́ ni Sátánì pa nígbà tó sọ pé kò sẹ́ni tó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀. Ohun tí Jésù ṣe yẹn ló máa pa Sátánì lẹ́nu mọ́ títí láé, torí ó máa mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jèhófà, á sì jẹ́ kó ṣe kedere pé àkóso Jèhófà ló dáa jù lọ. Jésù ni Olórí Aṣojú Jèhófà, torí náà ó máa fìdí ìdájọ́ òdodo Jèhófà múlẹ̀ láyé àti lọ́run. (Ìṣe 5:31) Ó ṣe tán nígbà tó wà láyé, gbogbo ohun tó ṣe àti ohun tó fi kọ́ni bá ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run mu. Ohun tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ ni pé: “Màá fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀, ó sì máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere sí àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 12:18) Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe ṣẹ sí Jésù lára?

Jésù Jẹ́ Kí “Ìdájọ́ Òdodo Ṣe Kedere”

8-10. (a) Báwo làwọn òfin táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbé kalẹ̀ ṣe mú káwọn èèyàn kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù, kí wọ́n sì tàbùkù sí àwọn obìnrin? (b) Báwo làwọn òfin táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù gbé kalẹ̀ ṣe mú kó nira fáwọn èèyàn láti pa òfin tí Jèhófà ṣe nípa Sábáàtì mọ́?

8 Jésù fẹ́ràn Òfin Jèhófà, ó sì máa ń pa á mọ́. Àmọ́ ní tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé Jésù, dípò tí wọ́n á fi jẹ́ káwọn èèyàn lóye Òfin náà, ṣe ni wọ́n ń túmọ̀ ẹ̀ sódì. Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! . . . Ẹ ò ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, àánú àti òtítọ́.” (Mátíù 23:23) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí ló yẹ kó máa kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run, àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe jẹ́ kó nira fáwọn èèyàn láti mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà ń ṣe bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan.

9 Jèhófà sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. (1 Àwọn Ọba 11:1, 2) Àmọ́, aláṣejù làwọn kan lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, ṣe ni wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù. Kódà, nínú ìwé kan táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ṣe, wọ́n pàṣẹ fáwọn èèyàn pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ẹran ọ̀sìn yín sílẹ̀ sọ́dọ̀ àwọn kèfèrí torí wọ́n lè bá ẹranko náà lò pọ̀.” Kò dáa rárá bí wọ́n ṣe ń ṣẹ̀tanú sí àwọn tí kì í ṣe Júù yìí, ó sì lòdì sí ohun tí Jèhófà kọ́ wọn nínú Òfin Mósè. (Léfítíkù 19:34) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òfin àtọwọ́dá míì tí wọ́n gbé kalẹ̀ tàbùkù sí àwọn obìnrin. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn òfin yẹn sọ pé ìyàwó ò gbọ́dọ̀ rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ ẹ̀, ńṣe ni kó máa rìn lẹ́yìn ẹ̀. Kódà, wọ́n kìlọ̀ fáwọn ọkùnrin pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá obìnrin sọ̀rọ̀ níta gbangba, títí kan ìyàwó wọn pàápàá. Bákan náà, wọn ò gbà káwọn obìnrin jẹ́ ẹlẹ́rìí ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́ bí wọn ò ṣe gbà káwọn ẹrú jẹ́rìí nílé ẹjọ́. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn tiẹ̀ máa ń gba àdúrà kan tí wọ́n fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àwọn kì í ṣe obìnrin.

10 Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn gbé oríṣiríṣi òfin kalẹ̀, ìyẹn sì mú kó ṣòro fáwọn èèyàn láti lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fún wọn lófin. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí òfin Sábáàtì sọ ò ju pé àwọn èèyàn ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sábáàtì, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ kí wọ́n ya ọjọ́ náà sọ́tọ̀ láti fi jọ́sìn Jèhófà, kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan táá mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ ọn, kí wọ́n sì sinmi. Àmọ́, àwọn Farisí mú kó nira fáwọn èèyàn láti máa pa òfin náà mọ́. Wọ́n gbà pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí òfin náà pè ní “iṣẹ́.” Wọ́n wá pín ohun tí wọ́n kà sí iṣẹ́ sí ìsọ̀rí mọ́kàndínlógójì (39), bí àpẹẹrẹ iṣẹ́ ìkórè àti iṣẹ́ ọdẹ. Ohun tí wọ́n ṣe yìí mú káwọn èèyàn ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtèyí tí kò yẹ kí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá pa eégbọn lọ́jọ́ Sábáàtì, ṣé a lè sọ pé ńṣe lẹni náà ṣọdẹ? Téèyàn bá fọwọ́ já hóró ọkà mélòó kan sẹ́nu tó sì ń jẹ ẹ́ bó ṣe ń rìn lọ, ṣéyẹn fi hàn pé ó ti kórè? Téèyàn bá mú ẹni tó ń ṣàìsàn lára dá, ṣéyẹn túmọ̀ sí pé ó ti ṣiṣẹ́? Káwọn aṣáájú ẹ̀sìn lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ṣe ni wọ́n tún ṣe àwọn òfin jàn-àn-ràn jan-an-ran tó ṣòro láti pa mọ́.

11, 12. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kì í ṣe òótọ́ làwọn Farisí fi ń kọ́ni?

11 Ọ̀pọ̀ èèyàn làwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ti ṣì lọ́nà, àmọ́ báwo ni Jésù ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí? Ńṣe ló fìgboyà ta ko àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn. Ó jẹ́ káwọn èèyàn rí i nínú ìwà ẹ̀ àti ohun tó ń kọ́ni pé òótọ́ kọ́ làwọn aṣáájú ẹ̀sìn náà fi ń kọ́ni. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jésù kọ́ni. Ó bẹnu àtẹ́ lu oríṣiríṣi òfin táwọn aṣáájú ẹ̀sìn gbé kalẹ̀, ó ní: “Ẹ̀ ń . . . fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yín, tí ẹ fi lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ.”​—Máàkù 7:13.

12 Jésù fìtara kọ́ àwọn èèyàn pé èrò táwọn Farisí ní nípa òfin Sábáàtì kò tọ̀nà rárá, àti pé wọn kò lóye ìdí tí Jèhófà fi fún wọn ní òfin náà. Torí pé Jésù ni Mèsáyà, ó sọ fún wọn pé òun ni “Olúwa Sábáàtì,” òun sì lẹ́tọ̀ọ́ láti woni sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Mátíù 12:8) Kí Jésù lè mú kó dá wọn lójú pé òótọ́ lòun sọ, ó mú àwọn aláìsàn lára dá lójú ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Lúùkù 6:7-10) Èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣe kárí ayé lọ́jọ́ iwájú nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀. Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn ló máa jẹ́ Sábáàtì tó ga jù lọ, torí pé ìgbà yẹn gangan làwọn olóòótọ́ máa sinmi, tí wọ́n sì máa rí ìtura kúrò nínú gbogbo wàhálà ti ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti mú bá wọn láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

13. Òfin wo ni Jésù gbé kalẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí Òfin Mósè?

13 Jésù tún jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí nípa bó ṣe gbé òfin tuntun kan kalẹ̀, ìyẹn “òfin Kristi.” Òfin náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́yìn tí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. (Gálátíà 6:2) Òfin tuntun yìí yàtọ̀ sí Òfin Mósè ní ti pé ìlànà ló pọ̀ jù nínú ẹ̀, kì í ṣe àṣẹ. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò sí àṣẹ nínú òfin tuntun yìí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù pe ọ̀kan lára òfin náà ní “àṣẹ tuntun.” Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. (Jòhánù 13:34, 35) Irú ìfẹ́ yìí ló máa jẹ́ ká dá gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé “òfin Kristi” mọ̀.

Jésù Máa Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo

14, 15. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun, kí sì nìdí tí èyí fi fi wá lọ́kàn balẹ̀?

14 Jésù tipasẹ ohun tó sọ àti ohun tó ṣe kọ́ àwọn èèyàn pé ó yẹ kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́. Gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé òun fúnra ẹ̀ ń tẹ̀ lé “òfin Kristi.” Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó ṣe tó fi hàn pé ó mú kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere.

15 Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó má bàa rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti kíyè sí i pé ìgbéraga àti ìkọjá àyè ló sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rẹ́ni jẹ. Àmọ́, Jésù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan wá bá Jésù, ó sọ fún un pé: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kó pín ogún fún mi.” Kí wá ni Jésù sọ fún un? Ó sọ pé: “Ọkùnrin yìí, ta ló yàn mí ṣe adájọ́ tàbí alárinà láàárín ẹ̀yin méjèèjì?” (Lúùkù 12:13, 14) Kí ni ohun tó sọ yìí kọ́ wa nípa Jésù? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé làákàyè àti ọgbọ́n Jésù ju ti ẹnikẹ́ni lọ, àṣẹ tí Jèhófà fún un sì ju ti ẹnikẹ́ni lọ, kò ṣèpinnu fún ọkùnrin yẹn torí pé Ọlọ́run ò fún un láṣẹ láti dá sí ọ̀rọ̀ náà. Jésù mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kódà ni gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó fi wà lọ́run kó tó wá sáyé, kò kọjá àyè ẹ̀ rí. (Júùdù 9) Onírẹ̀lẹ̀ ni, ó sì gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o!

16, 17. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé onídàájọ́ òdodo lòun nínú bó ṣe wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí ni ọ̀nà kẹta tí Jésù gbà fi hàn pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo? Ṣàlàyé.

16 Ìkejì, Jésù fi hàn pé onídàájọ́ òdodo lòun nínú bó ṣe wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kì í ṣe ojúsàájú, gbogbo èèyàn ló wàásù fún, ì báà jẹ́ olówó tàbí tálákà. Òdìkejì ohun tí Jésù ṣe làwọn Farisí ń ṣe ní tiwọn, wọ́n gbà pé èèyàn lásán làwọn tálákà, wọ́n sì máa ń pè wọ́n ní ʽam-ha·ʼaʹrets, tó túmọ̀ sí “àwọn ẹni ilẹ̀.” Jésù fìgboyà sọ fún wọn pé ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn ò dáa. Jésù wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, ó bá wọn jẹun, ó pèsè oúnjẹ fún wọn, ó mú wọn lára dá, kódà ó jí àwọn tó ti kú dìde. Àwọn nǹkan tó ṣe yìí àti ọ̀nà tó gbà ṣe é fi hàn pé ó ń fara wé Jèhófà Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo, ẹni tó fẹ́ gba “onírúurú èèyàn” là. c​—1 Tímótì 2:4.

17 Ọ̀nà kẹta tí Jésù gbà fi hàn pé òun jẹ́ onídàájọ́ òdodo ni bó ṣe máa ń ṣàánú àwọn èèyàn látọkàn wá. Ó gbé ìgbésẹ̀ láti ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. (Mátíù 9:11-13) Gbogbo ìgbà ló máa ń wá bó ṣe máa ṣèrànwọ́ fáwọn tí kò lẹ́ni tó máa gbèjà wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ò fara mọ́ ohun táwọn Farisí ń kọ́ni pé ńṣe ló yẹ kéèyàn kórìíra àwọn tí kì í ṣe Júù àti pé wọn ò ṣeé fọkàn tán. Jésù máa ń ṣàánú àwọn tí kì í ṣe Júù, ó sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ni Jèhófà dìídì rán an sí. Bí àpẹẹrẹ, ó gbà láti wo ìránṣẹ́ ọ̀gágun Róòmù kan sàn, ó ní: “Mi ò tíì rí ẹnì kankan ní Ísírẹ́lì tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó báyìí.”​—Mátíù 8:5-13.

18, 19. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà buyì kún àwọn obìnrin? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe jẹ́ ká rí i pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà kó tó lè máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu?

18 Bákan náà, dípò tí Jésù á fi fara mọ́ ojú táwọn èèyàn ìgbà yẹn fi ń wo àwọn obìnrin, ṣe ló fìgboyà ṣe ohun tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, láyé ìgbà yẹn ojú kan náà làwọn Júù fi ń wo àwọn tí kì í ṣe Júù àtàwọn obìnrin tó jẹ́ ará Samáríà, ńṣe ni wọ́n kà wọ́n sí aláìmọ́. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí Jésù tijú láti wàásù fún obìnrin ará Samáríà tó rí létí kànga kan nílùú Síkárì. Kódà, obìnrin yìí ni Jésù kọ́kọ́ sọ fún ní tààràtà pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòhánù 4:6, 25, 26) Àwọn Farisí sọ pé kò yẹ kí wọ́n kọ́ àwọn obìnrin lófin Ọlọ́run, àmọ́ Jésù máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò àti okun rẹ̀ láti kọ́ àwọn obìnrin. (Lúùkù 10:38-42) Bákan náà, nínú àṣà àwọn Júù, tí obìnrin bá ṣe ẹlẹ́rìí lórí ọ̀rọ̀ kan, wọn kì í gbà pé òótọ́ lohun tó sọ. Àmọ́ Jésù fún àwọn obìnrin kan láǹfààní láti kọ́kọ́ rí òun lẹ́yìn tó jíǹde, èyí sì buyì kún wọn gan-an. Kódà, Jésù tún sọ fáwọn obìnrin yẹn pé kí wọ́n lọ ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì náà fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tó jẹ́ ọkùnrin!​—Mátíù 28:1-10.

19 Ká sòótọ́, Jésù jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí gan-an. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé ẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà kó tó lè máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “Kìnnìún ẹ̀yà Júdà.” (Ìfihàn 5:5) Rántí pé ẹranko tó nígboyà ni kìnnìún, ó sì máa ń dúró fún ìdájọ́ òdodo. Láìpẹ́, Jésù máa ṣe ohun tó ju èyí tó ṣe nígbà yẹn lọ, ó máa túbọ̀ “fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀ ní ayé.”​—Àìsáyà 42:4.

Mèsáyà Ọba “Fìdí Ìdájọ́ Òdodo Múlẹ̀ ní Ayé”

20, 21. Lóde òní, báwo ni Jésù Ọba Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń mú kí ìdájọ́ òdodo wà kárí ayé àti nínú ìjọ Kristẹni?

20 Látìgbà tí Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914, ló ti ń ṣe ohun táá mú kí ìdájọ́ òdodo wà kárí ayé. Àwọn nǹkan wo ló ti ṣe? Ó ti ṣe àwọn nǹkan tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nínú Mátíù 24:14 ṣẹ. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó wà lórí ilẹ̀ ayé ti kọ́ àwọn èèyàn láti onírúurú ilẹ̀ ní òtítọ́ nípa Ìjọba Jèhófà. Bíi ti Jésù, àwọn náà ń wàásù fún gbogbo èèyàn lọ́mọdé lágbà, tọkùnrin tobìnrin, olówó àti tálákà, wọ́n jẹ́ kí gbogbo èèyàn láǹfààní láti mọ Jèhófà, Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo.

21 Jésù tún ń rí sí i pé ìdájọ́ òdodo wà nínú ìjọ Kristẹni. Òun ni Orí ìjọ, bó sì ṣe wà lásọtẹ́lẹ̀, ó ń pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn,” ìyẹn àwọn Kristẹni alàgbà tí wọ́n ń múpò iwájú nínú ìjọ. (Éfésù 4:8-12) Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló ṣeyebíye sí Jésù. Torí náà ó fẹ́ káwọn alàgbà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun, kí wọ́n sì máa bójú tó wọn lọ́nà tó tọ́ láìka ipò wọn sí, yálà wọ́n jẹ́ olówó tàbí tálákà.

22. Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ tó ń pọ̀ sí i láyé yìí ṣe rí lára Jèhófà, kí ló sì sọ pé Ọmọ òun máa ṣe sí i?

22 Láìpẹ́, Jésù máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ, ó sì máa mú kí ìdájọ́ òdodo fìdí múlẹ̀ kárí ayé lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ńṣe ni ìwà ìrẹ́jẹ túbọ̀ ń pọ̀ sí i nínú ayé burúkú yìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọmọdé ló ti kú torí pé wọn ò rí oúnjẹ tó tó jẹ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe làwọn orílẹ̀-èdè ń ná owó ńlá láti fi kó ohun ìjà jọ, táwọn èèyàn kan sì ń fowó ṣòfò torí kí wọ́n lè tẹ́ ara wọn lọ́rùn. Bákan náà, ká sọ pé nǹkan rí bó ṣe yẹ kó rí nílùú, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń kú lọ́dọọdún ni ò ní kú. Gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù láyé yìí ń múnú bí Jèhófà gan-an. Torí náà, ó ti yan Ọmọ rẹ̀ pé kó bá gbogbo ètò búburú ayé yìí jagun kó lè fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ títí láé.​—Ìfihàn 16:14, 16; 19:11-15.

23. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, báwo ni Kristi á ṣe máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu títí láé?

23 Àmọ́ o, ìdájọ́ òdodo Jèhófà kọjá pé kó kàn pa àwọn èèyàn burúkú run. Ó tún ti yan Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” pé kó ṣàkóso. Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, àkóso Jésù máa mú kí àlàáfíà wà kárí ayé, ó sì máa ṣe “ìdájọ́ tí ó tọ́” nígbà tó bá ń jọba. (Àìsáyà 9:6, 7) Inú Jésù máa dùn gan-an láti fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ tó ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn jìyà. Títí láé ni Jésù fi máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, táá sì máa ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo Jèhófà mu. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìdájọ́ òdodo Jèhófà ní báyìí. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.

a Bí Jésù ṣe bínú lọ́nà òdodo yìí, fi hàn pé ó jọ Jèhófà, ẹni tó “ṣe tán láti bínú” nítorí gbogbo ìwà ibi. (Náhúmù 1:2) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà pé wọ́n ti sọ ilé òun di “ihò tí àwọn olè ń fara pa mọ́ sí,” ó ní: “Ìbínú mi àti ìrunú mi yóò dà sórí ibí yìí.”​—Jeremáyà 7:11, 20.

b Ìwé kan tó ń sọ ìtàn àwọn Júù sọ pé lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà àwọn èèyàn kan fẹ̀hónú hàn torí pé iye tí wọ́n ń ta àdàbà nínú tẹ́ńpìlì ti pọ̀ jù. Ọjọ́ yẹn gangan ni wọ́n dín iye tí wọ́n ń tà á kù. Bí àpẹẹrẹ, ká ní wọ́n ń ta ọjà kan ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) náírà, wọ́n sọ ọ́ di náírà mẹ́wàá! Ta ló ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú èrè táwọn oníṣòwò ń rí lórí owó ẹran tí wọ́n ń tà nínú tẹ́ńpìlì yẹn? Àwọn òpìtàn kan sọ pé agbo ilé Ánásì Àlùfáà Àgbà ló ni àwọn ọjà tí wọ́n ń tà nínú tẹ́ńpìlì yẹn, wọ́n sì gbà pé èyí ló sọ agbo ilé àlùfáà náà di ọlọ́rọ̀.​—Jòhánù 18:13.

c Àwọn Farisí sọ pé “ẹni ègún” làwọn tálákà tí kò mọ Òfin. (Jòhánù 7:49) Wọ́n ní ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kò gbọ́dọ̀ bá wọn dòwò pọ̀, kò gbọ́dọ̀ bá wọn jẹun tàbí kó bá wọn gbàdúrà. Wọ́n ní tẹ́nì kan bá gbà kí ọmọbìnrin rẹ̀ fẹ́ ọ̀kan lára wọn, ohun tẹ́ni náà ṣe burú ju pé kó gbé ọmọ ẹ̀ fún ẹranko láti pa á jẹ. Wọ́n tiẹ̀ tún gbà pé kò ní sí àjíǹde fáwọn tálákà tí kò mọ Òfin.