Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 13

“Òfin Jèhófà Pé”

“Òfin Jèhófà Pé”

1, 2. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í fọwọ́ pàtàkì mú òfin, àmọ́ èrò wo la máa ní nípa àwọn òfin Jèhófà tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn?

 LÓNÌÍ, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè làwọn èèyàn ò ti fọwọ́ pàtàkì mú òfin. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé, òfin ṣòroó lóye. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó ń ṣàkóso kì í ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ìyà jẹ àwọn èèyàn. Táwọn èèyàn bá tún gbé ọ̀rọ̀ kan lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n lè jà fẹ́tọ̀ọ́ wọn, owó ńlá ni wọ́n máa ná, ńṣe làwọn adájọ́ á sì máa fòní dónìí, fọ̀la dọ́la.

2 Àmọ́ onísáàmù kan sọ ọ̀rọ̀ kan ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje (2,700) ọdún sẹ́yìn. Ohun tó sọ yàtọ̀ pátápátá sí èrò àwọn èèyàn nípa òfin bá a ṣe rí i nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú. Ó sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” (Sáàmù 119:97) Kí nìdí tí òfin yìí fi wu onísáàmù náà? Ìdí ni pé ọ̀dọ́ Jèhófà Ọlọ́run ni òfin náà ti wá, kì í ṣe ti ìjọba èèyàn. Bí ìwọ náà bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn òfin Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ̀ bíi ti onísáàmù yìí. Èyí á sì jẹ́ kó o túbọ̀ lóye bí Jèhófà tó jẹ́ onídàájọ́ tó ga jù lọ láyé àtọ̀run ṣe ń ronú.

Afúnnilófin Tó Ga Jù Lọ

3, 4. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ Afúnnilófin?

3 Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan ṣoṣo ni Afúnnilófin àti Onídàájọ́.” (Jémíìsì 4:12) Ká sòótọ́, Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Afúnnilófin tòótọ́. Kódà, òfin tó gbé kalẹ̀ ló fi ‘ń darí àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run.’ (Jóòbù 38:33) Jèhófà tún ní òfin tó ń darí àìmọye àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ mímọ́ bí wọ́n ṣe ń sìn ín, ìdí nìyẹn tí gbogbo wọn fi ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níṣọ̀kan, bí ipò wọn tiẹ̀ yàtọ̀ síra.​—Sáàmù 104:4; Hébérù 1:7, 14.

4 Bákan náà, Jèhófà fún àwa èèyàn lófin. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ní ẹ̀rí ọkàn tó dà bí òfin tó ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tó sì ń tọ́ wa sọ́nà ká lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Róòmù 2:14) Torí pé ẹni pípé ni Ádámù àti Éfà, ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé òfin díẹ̀ ni Ọlọ́run fún wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Àmọ́ aláìpé làwa, torí náà a nílò òfin tó pọ̀ ká lè máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Jèhófà jẹ́ káwọn olórí ìdílé bíi Nóà, Ábúráhámù àti Jékọ́bù mọ àwọn òfin òun, wọ́n sì ṣàlàyé àwọn òfin náà fáwọn ìdílé wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:22; 9:3-6; 18:19; 26:4, 5) Jèhófà di Afúnnilófin lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nígbà tó lo Mósè láti fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àkópọ̀ òfin kan tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Òfin Mósè. Àkópọ̀ òfin yìí jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ìdájọ́ òdodo.

Díẹ̀ Lára Àwọn Òfin Mósè

5. Ṣé òfin tó pọ̀, téèyàn ò lè tètè lóye, tí kò sì rọrùn láti pa mọ́ ni Òfin Mósè, kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

5 Ọ̀pọ̀ èèyàn lè máa rò pé Òfin Mósè ti pọ̀ jù, èèyàn ò lè tètè lóye ẹ̀, kò sì rọrùn láti pa mọ́. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kò tọ̀nà rárá. Lóòótọ́, àpapọ̀ òfin náà ju ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) lọ, ìyẹn sì lè mú kó dà bíi pé ó pọ̀. Àmọ́, rò ó wò ná: Nígbà tó fi máa di oṣù January ọdún 1990, òfin tí ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nìkan ní kún ìwé òfin tó jẹ́ ìdìpọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), ojú ìwé rẹ̀ lápapọ̀ sì ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́jọ (160,000) lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, láàárín ọdún 1990 sí September 1999 wọ́n ti fi òfin tó tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti ogójì (540) kún un! Torí náà, tá a bá fi Òfin Mósè wé òfin táwọn èèyàn ń gbé kalẹ̀, a máa rí i pé Òfin Mósè ò pọ̀ rárá. Síbẹ̀, Òfin yìí jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tí wọ́n máa ṣe láwọn ipò kan tó jẹ́ pé òfin táwọn èèyàn ṣe ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ rárá. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn Òfin Mósè.

6, 7. (a) Kí ló mú kí Òfin Mósè yàtọ̀ sí òfin táwọn èèyàn ṣe, èwo ló sì ṣe pàtàkì jù nínú Òfin náà? (b) Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lè fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà?

6 Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ. Èyí mú kí Òfin Mósè yàtọ̀ pátápátá sí òfin táwọn èèyàn ṣe. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú òfin náà lèyí tó sọ pé: “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni. Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun? Ó fẹ́ kí wọ́n máa sin òun, kí wọ́n sì fara mọ́ ọn pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso wọn.​—Diutarónómì 6:4, 5; 11:13.

7 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi hàn pé àwọn fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà tí wọ́n bá ń tẹrí ba fáwọn tí Jèhófà yàn pé kó máa bójú tó wọn. Ìyẹn àwọn òbí, àwọn ìjòyè, àwọn onídàájọ́, àwọn àlùfáà, àtàwọn ọba nígbà tó yá. Jèhófà sọ pé òun gangan lẹni tó bá ṣọ̀tẹ̀ sáwọn èèyàn yìí ń ṣọ̀tẹ̀ sí. Àmọ́, àwọn tó wà nípò àṣẹ náà ò gbọ́dọ̀ ṣi agbára wọn lò, Jèhófà sọ pé tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun máa fìyà jẹ wọ́n. (Ẹ́kísódù 20:12; 22:28; Diutarónómì 1:16, 17; 17:8-20; 19:16, 17) Torí náà, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí kan àwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó wọn ló gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà.

8. Báwo ni Òfin Mósè ṣe jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe lè wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run?

8 Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe lè wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́” fara hàn ní ìgbà tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín ogún (280) nínú Òfin Mósè. Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun mímọ́ àti ohun tí kò mọ́, ó jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan bí àádọ́rin (70) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó lè sọ ẹnì kan di aláìmọ́, tí kò fi ní láǹfààní láti jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù. Àwọn òfin yìí sọ nípa ìmọ́tótó ara àti àyíká, ọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ, títí kan bí wọ́n ṣe lè máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀. Àwọn òfin yẹn dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì mú kí ìlera wọn dáa gan-an. a Àmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún máa rí àǹfààní tó jùyẹn lọ tí wọ́n bá ń pa Òfin yẹn mọ́, á jẹ́ kí wọ́n rí ojúure Jèhófà, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n máa hùwà ìbàjẹ́ bíi tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.

9, 10. Òfin wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí, àǹfààní wo lòfin náà sì ṣe wọ́n?

9 Òfin Mósè sọ pé àwọn tó bá ní ìbálòpọ̀ máa jẹ́ aláìmọ́ láàárín àkókò kan, kódà tó bá jẹ́ pé tọkọtaya làwọn méjèèjì. Òfin náà tún sọ pé obìnrin tó bímọ máa jẹ́ aláìmọ́ láàárín àkókò kan. (Léfítíkù 12:2-4; 15:16-18) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé ẹ̀ṣẹ̀ ni kí tọkọtaya ní ìbálòpọ̀ tàbí kí wọ́n bímọ, ó ṣe tán ẹ̀bùn pàtàkì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:18-25) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Òfin yìí kí wọ́n lè máa jẹ́ mímọ́, kí wọ́n má sì lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké. Ìbálòpọ̀ àti ìbímọlémọ wà lára ìjọsìn àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká. Bákan náà, ìbálòpọ̀ wà lára ohun táwọn ará Kénáánì máa ń ṣe nínú ìjọsìn wọn, tọkùnrin tobìnrin ló sì máa ń ṣe é. Èyí fa ìwà ìbàjẹ́ tó burú gan-an, ìwà yìí sì tàn kálẹ̀. Àmọ́ ní tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ńṣe ni Òfin Mósè mú kí wọ́n ya ìjọsìn Jèhófà sọ́tọ̀, láì pa á pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. b Ọ̀nà míì tún wà tí Òfin yìí gbà ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní.

10 Àwọn òfin yẹn tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. c Òótọ́ ni pé ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí jẹ́ ẹ̀bùn tí kò lábààwọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, síbẹ̀ ipasẹ̀ ìbálòpọ̀ àti ọmọ bíbí ni ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù gbà ń tàn láti ìran kan dé òmíì. (Róòmù 5:12) Torí náà, ńṣe ni Òfin Ọlọ́run ń rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí wọn sí. Ó ṣe tán, àtìgbà tí wọ́n ti bí wa ni gbogbo wa ti jogún ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 51:5) Àmọ́, ẹni mímọ́ ni Ọlọ́run jẹ́. Torí náà, ó dìgbà tí ẹnì kan bá rà wá pa dà, tí Ọlọ́run sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá ká tó lè sún mọ́ ọn.

11, 12. (a) Ìlànà pàtàkì wo ló túbọ̀ ṣe kedere nínú Òfin Mósè? (b) Àwọn nǹkan wo ni Òfin Mósè sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kí wọ́n lè máa ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́?

11 Òfin Mósè jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo. Òfin Mósè fi hàn pé tẹ́nì kan bá ṣẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ bá ẹni náà wí níbàámu pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀. Òfin náà sọ pé: “Kí o gba ẹ̀mí dípò ẹ̀mí, ojú dípò ojú, eyín dípò eyín, ọwọ́ dípò ọwọ́, ẹsẹ̀ dípò ẹsẹ̀.” (Diutarónómì 19:21) Torí náà, tí wọ́n bá ń ṣèdájọ́ ọ̀daràn kan, ìyà tó dọ́gba pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi jẹ ẹ́. Òfin Mósè jẹ́ ká rí i pé ìlànà yìí ṣe pàtàkì gan-an sí Jèhófà. Tá a bá sì lóye ìlànà yìí, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ ìdí tí Jèhófà fi yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ pé kó wá kú fún wa kó lè rà wá pa dà. A máa túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà ni Orí 14 ìwé yìí.​—1 Tímótì 2:5, 6.

12 Òfin Mósè tún jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ bí wọ́n ṣe lè máa dájọ́ lọ́nà tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá fẹ̀sùn kan ẹnì kan, ó kéré tán ẹni méjì gbọ́dọ̀ jẹ́rìí sí i, káwọn adájọ́ tó lè gbà pé ẹ̀sùn náà jẹ́ òótọ́. Tẹ́nì kan bá jẹ́rìí èké, ìyà kékeré kọ́ lẹni náà máa jẹ. (Diutarónómì 19:15, 18, 19) Yàtọ̀ síyẹn, Òfin Mósè ò fàyè gba káwọn èèyàn máa hùwà ìbàjẹ́ tàbí kí wọ́n máa gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (Ẹ́kísódù 23:8; Diutarónómì 27:25) Kódà, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣòwò, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà ìdájọ́ òdodo Jèhófà. (Léfítíkù 19:35, 36; Diutarónómì 23:19, 20) Ká sòótọ́, Òfin Mósè ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní gan-an!

Òfin Tó Kọ́ni Ní Ìdájọ́ Òdodo àti Àánú

13, 14. Báwo ni Òfin Mósè ṣe ń mú kí wọ́n dá ẹjọ́ ẹni tó jalè àti ẹni tí wọ́n jí nǹkan ẹ̀ lọ́nà tó tọ́?

13 Ṣé òfin tó le koko, tí kò sì fàyè gba àánú ni Òfin Mósè? Rárá o! Ọlọ́run mí sí Ọba Dáfídì láti kọ̀wé pé: “Òfin Jèhófà pé.” (Sáàmù 19:7) Ọba Dáfídì mọ̀ dáadáa pé Òfin Mósè kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa fi àánú hàn, kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Báwo ni Òfin náà ṣe ṣe bẹ́ẹ̀?

14 Láwọn orílẹ̀-èdè kan lónìí, ó jọ pé òfin ń ṣe àwọn ọ̀daràn láǹfààní ju ẹni tí wọ́n hùwà àìdáa sí lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní kí ẹnì kan tó jalè lọ lo àsìkò kan lẹ́wọ̀n. Àmọ́, ẹni tí wọ́n jà lólè lè má rí ẹrù ẹ̀ gbà pa dà. Síbẹ̀, ẹni náà tún gbọ́dọ̀ máa san owó orí tí wọ́n máa ń lò láti fi bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n tí olè náà wà àti oúnjẹ tó ń jẹ. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí bí nǹkan ṣe rí ní Ísírẹ́lì àtijọ́, torí pé Òfin Mósè ní àwọn ìlànà tó máa jẹ́ kí wọ́n gba ti ẹni tí wọ́n hùwà àìdáa sí rò, kí wọ́n má sì hùwà ìkà sí ọ̀daràn. Bí àpẹẹrẹ, kò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbà yẹn, bó ṣe wà lóde òní. Òfin tún sọ pé ìyà tí wọ́n máa fi jẹ ọ̀daràn kan ò gbọ́dọ̀ pọ̀ jù. (Diutarónómì 25:1-3) Àmọ́, ẹni tó jalè gbọ́dọ̀ san ohun tó jí pa dà. Ó tún gbọ́dọ̀ fún ẹni tó jà lólè ní nǹkan kan láfikún sí ohun tó jí. Èló ni olè náà máa san? Ó máa ń yàtọ̀ síra. Ó jọ pé Jèhófà fún àwọn onídàájọ́ lómìnira láti ṣàyẹ̀wò bọ́rọ̀ náà bá ṣe rí, irú bíi bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ti ronú pìwà dà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìdí nìyẹn tí ohun tí Léfítíkù 6:1-7 sọ pé ẹni tó jalè máa san fi kéré sí ohun tí Ẹ́kísódù 22:7 sọ.

15. Báwo ni Òfin Mósè ṣe ń mú kí wọ́n dá ẹjọ́ tó tọ́ fún ẹni tó ṣèèṣì pa èèyàn, kí ẹni náà sì jàǹfààní àánú Ọlọ́run?

15 Òfin Mósè fi hàn pé aláàánú ni Jèhófà, ó gbà pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ló jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀dá. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹni tó ṣèèṣì pa èèyàn bá tètè sá lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò tó wà káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọn ò ní pa á láti fi ẹ̀mí ẹ̀ dípò ti ẹni tó pa. Lẹ́yìn táwọn onídàájọ́ tí Jèhófà yàn sípò bá ti gbé ẹjọ́ ẹni náà yẹ̀ wò, ó gbọ́dọ̀ máa gbé inú ìlú ààbò títí dìgbà tí àlùfáà àgbà fi máa kú. Lẹ́yìn náà, ó lè lọ gbé níbikíbi tó bá wù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó máa jàǹfààní àánú Ọlọ́run. Bákan náà, òfin yìí jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé ẹ̀mí èèyàn ṣe pàtàkì gan-an sí Jèhófà.​—Nọ́ńbà 15:30, 31; 35:12-25.

16. Báwo ni Òfin Mósè ṣe dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn?

16 Òfin Mósè kọ́ àwọn èèyàn pé ó yẹ kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíì. Àpẹẹrẹ kan ni bó ṣe ń dáàbò bo àwọn tó bá jẹ gbèsè. Òfin yìí sọ pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wọnú ilé ẹni tó jẹ gbèsè láti lọ fipá gba ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìta lẹni tó yá èèyàn ní nǹkan máa dúró sí títí dìgbà tẹ́ni tó jẹ gbèsè á fi mú ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró wá fún un. Èyí fi hàn pé ẹnikẹ́ni ò kàn lè já wọ ilé onílé. Tó bá jẹ́ pé aṣọ àwọ̀lékè lẹni tó jẹ gbèsè náà fi ṣe ohun ìdúró, ẹni tó yá a ní nǹkan gbọ́dọ̀ dá a pa dà lálẹ́, torí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé aṣọ yẹn lẹni tó jẹ gbèsè náà fẹ́ fi bora sùn.​—Diutarónómì 24:10-14.

17, 18. Tó bá dọ̀rọ̀ ogun jíjà, báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè tó kù, kí sì nìdí?

17 Jèhófà tún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin tí wọ́n máa tẹ̀ lé nípa ogun jíjà. Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n jẹ́ arógunyọ̀ tàbí kí wọ́n máa jà torí kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn lágbára. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá fẹ́ ja “Àwọn Ogun Jèhófà” nìkan ni wọ́n máa ń lọ sójú ogun. (Nọ́ńbà 21:14) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fún àwọn ọ̀tá wọn láǹfààní láti wá àlááfíà kí wọ́n má bàa bá wọn jagun. Táwọn èèyàn náà bá kọ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè wá gbógun tì wọ́n, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé òfin tí Ọlọ́run fún wọn nípa ogun jíjà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀ tàbí kí wọ́n kàn bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn èèyàn nípakúpa bíi tàwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè míì. Kódà, àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ gé àwọn igi eléso wọn dà nù tàbí kí wọ́n ba àyíká wọn jẹ́ lọ́nàkọnà. d Kò sí orílẹ̀-èdè kankan nígbà yẹn tó ń tẹ̀ lé irú òfin yìí tí wọ́n bá ń jagun.​—Diutarónómì 20:10-15, 19, 20; 21:10-13.

18 Ṣé kì í bà ọ́ nínú jẹ́ tó o bá gbọ́ pé wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọdé níṣẹ́ ogun jíjà láwọn orílẹ̀-èdè kan? Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ẹni tí kò bá tíì pé ọmọ ogún ọdún ò lè wọ ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (Nọ́ńbà 1:2, 3) Kódà, tí ọkùnrin tó ti lé lógún ọdún bá ń bẹ̀rù jù, wọn ò ní fi dandan mú un pé kó lọ sójú ogun. Bákan náà, tí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, òfin sọ pé kò gbọ́dọ̀ lọ sójú ogun fún ọdún kan kó má bàa fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu, á sì lè wà nílé nígbà tí ìyàwó ẹ̀ bá bí àkọ́bí wọn. Òfin Mósè sọ pé èyí á jẹ́ kí ọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó náà “dúró sílé kó lè máa múnú ìyàwó rẹ̀ dùn.”​—Diutarónómì 20:5, 6, 8; 24:5.

19. Báwo ni Òfin Mósè ṣe ń dáàbò bo àwọn obìnrin, ọmọdé, ìdílé, opó àtàwọn ọmọ aláìlóbìí?

19 Òfin Mósè tún jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n máa bójú tó àwọn obìnrin, ọmọdé àti ìdílé, kí wọ́n sì máa pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Jèhófà pàṣẹ fáwọn òbí pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn láwọn nǹkan táá mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ òun. (Diutarónómì 6:6, 7) Jèhófà tún sọ pé àwọn ìbátan ò gbọ́dọ̀ bá ara wọn lò pọ̀, tírú ẹ̀ bá sì ṣẹlẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa pa àwọn tó ṣe é. (Léfítíkù, orí 18) Bákan náà, Jèhófà sọ pé àwọn tó ti ṣègbéyàwó ò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì, torí pé ńṣe nìyẹn máa ń tú ìdílé ká, kì í sì í jẹ́ kí àwọn tó wà nínú ìdílé ní iyì àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Òfin Mósè jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn opó àti ọmọ aláìlóbìí ká Jèhófà lára, kódà ó fi àwọn ọ̀rọ̀ tó lágbára gan-an kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ wọ́n.​—Ẹ́kísódù 20:14; 22:22-24.

20, 21. (a) Kí nìdí tí Òfin Mósè fi fàyè gbà á pé káwọn ọkùnrin fẹ́ ju ìyàwó kan lọ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi fàyè gbà á pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa kọ aya wọn sílẹ̀ kí Jésù tó dé?

20 Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé Òfin Mósè ń dáàbò bo àwọn obìnrin, ọmọdé, ìdílé, opó àtàwọn ọmọ aláìlóbìí, àwọn kan lè wá máa ronú pé, ‘Kí nìdí tí Òfin Mósè fi fàyè gbà á pé káwọn ọkùnrin máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ?’ (Diutarónómì 21:15-17) Ó yẹ ká ronú nípa bí nǹkan ṣe rí láyé nígbà tí Jèhófà fún wọn lófin yẹn. Torí pé àṣà wọn àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan nígbà yẹn yàtọ̀ sí tòde òní. (Òwe 18:13) Nígbà tí Jèhófà dá ìgbéyàwó sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, ohun tó fẹ́ ni pé kí ọkùnrin kan fẹ́ aya kan, káwọn méjèèjì sì máa wà pa pọ̀ títí láé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 20-24) Àmọ́, nígbà tí Jèhófà fi máa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lófin, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọkùnrin wọn ló ti fẹ́ ju ìyàwó kan lọ, èyí sì ti ń ṣẹlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Jèhófà mọ̀ pé “alágídí” làwọn èèyàn yẹn, kódà ó mọ̀ pé wọ́n á máa rú àwọn òfin tó ṣe pàtàkì jù lọ, irú bí èyí tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà. (Ẹ́kísódù 32:9) Torí náà, Jèhófà rí i pé kò tíì tó àsìkò tóun máa ṣàtúnṣe gbogbo àṣàkaṣà tí wọ́n ti mú wọnú ìgbéyàwó. Àmọ́, ẹ rántí pé Jèhófà kọ́ ló ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ. Síbẹ̀, ó lo Òfin Mósè láti fi dáàbò bo àwọn obìnrin, káwọn ọkùnrin má bàa máa hùwà àìdáa sí wọn.

21 Bákan náà, Òfin Mósè gbà kí ọkùnrin kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí oríṣiríṣi ẹ̀sùn tó burú gan-an. (Diutarónómì 24:1-4) Jésù sọ pé “torí pé ọkàn [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] le” ni Ọlọ́run fi gbà kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, àsìkò díẹ̀ ni Jèhófà fi fàyè gbà á pé kí wọ́n máa kọ ìyàwó wọn sílẹ̀. Torí pé nígbà tí Jésù wá sáyé, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ nígbà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀.​—Mátíù 19:8.

Òfin Mósè Kọ́ni Pé Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì Gan-an

22. Àwọn ọ̀nà wo ni Òfin Mósè gbà fúnni níṣìírí pé ó yẹ ká máa fìfẹ́ hàn, àwọn wo ló sì sọ pé ká máa fìfẹ́ hàn sí?

22 Lónìí, kò sí orílẹ̀-èdè tó lófin tó ń kọ́ni pé ó yẹ kéèyàn máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Àmọ́, Òfin Mósè kọ́ni pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Kódà, nínú ìwé Diutarónómì nìkan, ó ju ogún (20) ìgbà lọ tí ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” fara hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, òfin kejì tó ga jù lọ nínú Òfin Mósè sọ pé: “O . . . gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18; Mátíù 22:37-40) Kì í ṣe ara wọn nìkan ni òfin yìí sọ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́, àmọ́ ó tún sọ pé ó yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì tó wà láàárín wọn, kí wọ́n máa rántí pé àwọn náà ti fìgbà kan rí jẹ́ àjèjì. Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aláìní àtàwọn ẹni tíyà ń jẹ, kí wọ́n pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn, kí wọ́n má sì fìyà jẹ wọ́n torí pé wọn ò lẹ́ni tó máa gbèjà wọn. Kódà, Òfin tún sọ pé kí wọ́n máa ṣenúure sáwọn ẹranko, kí wọ́n sì máa gba tiwọn rò.​—Ẹ́kísódù 23:6; Léfítíkù 19:14, 33, 34; Diutarónómì 22:4, 10; 24:17, 18.

23. Kí ni ìfẹ́ tí onísáàmù kan ní fún òfin Ọlọ́run mú kó ṣe, kí làwa náà lè pinnu láti ṣe?

23 Kò sí orílẹ̀-èdè kankan tó ní òfin tó ń ṣeni láǹfààní bí òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Abájọ tí onísáàmù kan fi sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” Kì í ṣe pé ó kàn sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà. Àmọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òfin náà, ó wù ú kó máa pa á mọ́ nígbà gbogbo. Ó tún sọ pé: “Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni mò ń ronú lé e lórí.” (Sáàmù 119:11, 97) Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òfin Jèhófà déédéé, ó sì dájú pé ìyẹn mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin náà. Bákan náà, ìyẹn mú kó túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Afúnnilófin náà. Tíwọ náà bá ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà, Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo àti Afúnnilófin tó ga jù lọ, ìfẹ́ tó o ní fún un á máa lágbára sí i, èyí á sì mú kó o túbọ̀ máa sún mọ́ ọn.

a Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ pẹ́ tí Òfin Ọlọ́run ti ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́lẹ̀, kí wọ́n máa sé ẹni tó ní àrùn mọ́ àti pé kí ẹni tó bá fọwọ́ kan òkú rí i pé òun wẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ lóye ìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn máa ṣe bẹ́ẹ̀.​—Léfítíkù 13:4-8; Nọ́ńbà 19:11-13, 17-19; Diutarónómì 23:13, 14.

b Àwọn ọmọ Kénáánì máa ń ní yàrá kan nínú tẹ́ńpìlì wọn táwọn tó wá jọ́sìn níbẹ̀ ti lè ní ìbálòpọ̀. Àmọ́, Òfin Mósè sọ pé tẹ́nì kan bá ní ìbálòpọ̀, ó máa di aláìmọ́ láàárín àkókò kan, kò sì gbọ́dọ̀ wọnú tẹ́ńpìlì. Torí náà, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń pa òfin yìí mọ́, wọn ò ní fi ìbálòpọ̀ kún ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe nínú ilé Jèhófà.

c Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí Òfin wà fún ni pé kó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Kódà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé ohun tí toh·rahʹ tí wọ́n máa ń pe “òfin” lédè Hébérù túmọ̀ sí ni “ìtọ́ni.”

d Nínú Òfin Mósè, Ọlọ́run béèrè pé: “Ṣé ó yẹ kí o gbógun ti igi inú igbó bí ẹni ń gbógun ti èèyàn ni?” (Diutarónómì 20:19) Nígbà tí Júù kan tó ń jẹ́ Philo, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ń ṣàlàyé òfin yìí, ó sọ pé: “Táwọn èèyàn bá ń jà, tí wọ́n wá lọ ń fìkanra mọ́ àwọn nǹkan tó wà láyìíká wọn láìṣe pé àwọn nǹkan náà ṣẹ̀ wọ́n, ìwà àìtọ́ ni wọ́n hù yẹn” lójú Ọlọ́run.