Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 28

“Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”

“Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”

1, 2. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó pẹ́ táwọn èèyàn ti ń hùwà àìṣòótọ́ sí Ọba Dáfídì?

 ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń hùwà àìṣòótọ́ sí Ọba Dáfídì. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń ṣàkóso lé lórí dìtẹ̀ mọ́ ọn, tí wọ́n sì gbìyànjú láti rọ̀ ọ́ lóyè. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan tó ti fìgbà kan rí jẹ́ kòríkòsùn Dáfídì tún dà á. Ọ̀kan lára wọn ni Míkálì, ìyàwó tó kọ́kọ́ fẹ́. Níbẹ̀rẹ̀, Míkálì “nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an,” ó sì dájú pé á ti máa tì í lẹ́yìn nígbà tó jọba. Àmọ́ nígbà tó yá, ó “bẹ̀rẹ̀ sí í pẹ̀gàn [Dáfídì] nínú ọkàn rẹ̀,” kódà ó pè é ní “akúrí.”​—1 Sámúẹ́lì 18:20; 2 Sámúẹ́lì 6:16, 20.

2 Ẹlòmíì tún ni Áhítófẹ́lì, agbaninímọ̀ràn Dáfídì. Àwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún Áhítófẹ́lì gan-an, wọ́n sì máa ń wo ìmọ̀ràn ẹ̀ bí i pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ń fúnni nímọ̀ràn. (2 Sámúẹ́lì 16:23) Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ yìí dalẹ̀ Dáfídì, ó sì bá wọn dìtẹ̀ mọ́ ọn. Ṣùgbọ́n ta ló bẹ̀rẹ̀ ọ̀tẹ̀ yìí? Ábúsálómù ọmọ Dáfídì ni! Ó ń “dọ́gbọ́n fa ojú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì mọ́ra,” ó ta ko bàbá ẹ̀, ó sì sọ ara ẹ̀ di ọba. Ọ̀pọ̀ èèyàn dara pọ̀ mọ́ Ábúsálómù láti dìtẹ̀ mọ́ Ọba Dáfídì, ọ̀rọ̀ yẹn le débi pé Dáfídì ní láti sá kúrò nílùú kí wọ́n má bàa pa á.​—2 Sámúẹ́lì 15:1-6, 12-17.

3. Kí ló dá Dáfídì lójú?

3 Ṣé kò wá sẹ́ni tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Dáfídì ni? Dáfídì mọ̀ pé ẹnì kan wà lẹ́yìn òun ní gbogbo ìgbà tóun bá wà nínú ìṣòro. Ta lẹni náà? Jèhófà Ọlọ́run ni. Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin.” (2 Sámúẹ́lì 22:26) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin, báwo ni Jèhófà sì ṣe fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká jẹ́ adúróṣinṣin?

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin?

4, 5. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ “adúróṣinṣin”? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin àti kéèyàn jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé?

4 Wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “adúróṣinṣin” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti ṣàpèjúwe ẹnì kan tó dúró ti ẹni tó fẹ́ràn, tó sì ń bá a lọ láti máa ran ẹni náà lọ́wọ́. Kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin kọjá pé kó ṣeé gbára lé. Tóri tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ń ṣe àwọn nǹkan tó ń mú káwọn èèyàn gbára lé e, ó lè má jẹ́ ìfẹ́ ló ń mú kó máa ṣe àwọn nǹkan yẹn. Ó kàn lè máa ṣe é torí pé kò ríbi yẹ̀ ẹ́ sí tàbí torí pé ó pọn dandan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìfẹ́ ló máa ń mú kẹ́nì kan jẹ́ adúróṣinṣin. a Yàtọ̀ síyẹn, nígbà míì a lè sọ pé àwọn ohun tí kò lẹ́mìí náà ṣeé gbára lé. Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù kan pe òṣùpá ní “ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé ní ojú ọ̀run” torí pé alaalẹ́ ló máa ń yọ. (Sáàmù 89:37) Àmọ́, a ò lè sọ pé òṣùpá jẹ́ adúróṣinṣin. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ ló ń mú kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin, a sì mọ̀ pé ohun tí kò lẹ́mìí ò lè fìfẹ́ hàn.

Bíbélì pe òṣùpá ní ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbára lé, àmọ́ àwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì nìkan ló lè jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà

5 Tí Bíbélì bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa hàn nínú ìwà ẹni náà. Ẹni tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹlòmíì á máa fìfẹ́ hàn sí ẹni náà, á sì máa ṣe ohun tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹni náà jẹ òun lógún. Ọ̀rọ̀ ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin kò ní rí bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì síwá sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tó ní sí ẹni tó fẹ́ ràn lọ́wọ́ máa lágbára débi pé tí ìṣòro bá dé, kò ní pa onítọ̀hún tì.

6. (a) Báwo làwọn adúróṣinṣin ṣe pọ̀ tó láyé yìí, kí ni Bíbélì sì sọ tí ò jẹ́ kó yà wá lẹ́nu? (b) Ọ̀nà wo ló dáa jù lọ tá a lè gbà mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin?

6 Ó bani nínú jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn ló jẹ́ adúróṣinṣin lónìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ló “ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà.” Ńṣe làwọn tọkọtaya tó ń kọra wọn sílẹ̀ sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Òwe 18:24; Málákì 2:14-16) Àwọn aláìṣòótọ́ àti ọ̀dàlẹ̀ pọ̀ láyé yìí débi táwa náà fi lè sọ bíi ti wòlíì Míkà pé: “Adúrótini ti tán ní ayé.” (Míkà 7:2) Ká sòótọ́, kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwa èèyàn láti jẹ́ adúróṣinṣin, àmọ́ gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó ní ànímọ́ pàtàkì yìí. Ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ adúróṣinṣin ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìfẹ́ ṣe ń mú kí Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin.

Kò Sẹ́ni Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin Bíi Ti Jèhófà

7, 8. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà nìkan ni adúróṣinṣin?

7 Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin.” (Ìfihàn 15:4) Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ṣebí àwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì kan ti ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin? (Jóòbù 1:1; Ìfihàn 4:8) Jésù Kristi náà ńkọ́? Ṣebí òun ni ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn “ẹni ìdúróṣinṣin” Ọlọ́run? (Sáàmù 16:10) Kí wá nìdí tí Bíbélì fi sọ pé Jèhófà nìkan ni adúróṣinṣin?

8 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rántí pé ìfẹ́ ló máa ń mú kéèyàn jẹ́ adúróṣinṣin. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìyẹn ni pé òun ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn. (1 Jòhánù 4:8) Òótọ́ ni pé àwọn áńgẹ́lì àtàwa èèyàn lè gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ, ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó lè jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jèhófà. Òun ni “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” kò sígbà tí Jèhófà kò jẹ́ adúróṣinṣin, torí náà a ò lè fi ìdúróṣinṣin ẹ̀ wé ti èèyàn tàbí áńgẹ́lì èyíkéyìí. (Dáníẹ́lì 7:9) Torí náà, Jèhófà ló jẹ́ adúróṣinṣin lọ́nà tó ga jù lọ. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

9. Báwo ni Jèhófà ṣe “jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe”?

9 Jèhófà “jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.” (Sáàmù 145:17) Lọ́nà wo? A lè rí ìdáhùn nínú Sáàmù 136. Sáàmù náà mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìgbàlà tí Jèhófà ṣe, títí kan bó ṣe mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa kọjá lọ́nà ìyanu. Kíyè sí i pé gbogbo ẹsẹ tó wà nínú sáàmù yìí ló ní gbólóhùn tó sọ pé: “Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.” Sáàmù yìí wà lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tò sábẹ́ “ Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé” lójú ìwé 289. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ yẹn, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ní ti pé ó máa ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lásìkò tó yẹ. (Sáàmù 34:6) Jèhófà ò ní yéé fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n bá ń bá a lọ láti máa jẹ́ adúróṣinṣin sí i. 

10. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin tó bá kan àwọn ìlànà rẹ̀?

10 Ọ̀nà míì tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni pé àwọn ìlànà rẹ̀ kì í yí pa dà. Àwọn èèyàn sábà máa ń yí èrò wọn pa dà torí bí nǹkan bá ṣe rí lára wọn, àmọ́ ní ti Jèhófà èrò rẹ̀ nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ kì í yí pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ojú tí Jèhófà fi ń wo ìbẹ́mìílò, ìbọ̀rìṣà àti ìpànìyàn kò tíì yí pa dà. Ó sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà pé: “Títí o fi máa dàgbà, mi ò ní yí pa dà.” (Àìsáyà 46:4) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé a máa jàǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé òfin tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.​—Àìsáyà 48:17-19.

11. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Jèhófà máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

11 Jèhófà tún máa ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin nípa bó ṣe máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Awí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tó ti ẹnu mi jáde . . . kò ní pa dà sọ́dọ̀ mi láìṣẹ, àmọ́ ó dájú pé ó máa ṣe ohunkóhun tí inú mi bá dùn sí, ó sì dájú pé ohun tí mo rán an pé kó ṣe máa yọrí sí rere.” (Àìsáyà 55:11) Bí Jèhófà ṣe ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ fi hàn pé ó jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn èèyàn rẹ̀. Kì í sọ ohun tí kò bá ní lọ́kàn láti ṣe, kó wá jẹ́ kí wọ́n máa fojú sọ́nà lásán. Jèhófà ṣeé fọkàn tán gan-an, kódà Jóṣúà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kò sí ìlérí tí kò ṣẹ nínú gbogbo ìlérí dáadáa tí Jèhófà ṣe fún ilé Ísírẹ́lì; gbogbo rẹ̀ ló ṣẹ pátá.” (Jóṣúà 21:45) Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní já wa kulẹ̀ láé, kò sì sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ tí ò fi ní mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.​—Àìsáyà 49:23; Róòmù 5:5.

12, 13. Àwọn ọ̀nà wo ni ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ fi wà títí láé?

12 Bá a ṣe sọ ṣáájú, Bíbélì sọ pé ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ “wà títí láé.” (Sáàmù 136:1) Kí ló fi hàn bẹ́ẹ̀? Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀ ni bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Bá a ṣe sọ ní Orí 26, tí Jèhófà bá dárí ji ẹnì kan, kò ní pa dà fìyà jẹ ẹni náà mọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀, wọn ò sì kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,” torí náà ó yẹ kí gbogbo wa máa dúpẹ́ pé ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí láé.​—Róòmù 3:23.

13 Àmọ́, ohun míì wà tó fi hàn pé ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí láé. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé olódodo “máa dà bí igi tí a gbìn sétí odò, tó ń so èso ní àsìkò rẹ̀, tí ewé rẹ̀ kì í sì í rọ. Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.” (Sáàmù 1:3) Fojú inú wo igi kan tó rẹwà , táwọn ewé ẹ̀ sì tutù minimini, ó dájú pé ó máa fani mọ́ra gan-an! Bákan náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ jinlẹ̀, ọkàn wa á balẹ̀, ayé wa á dùn bí oyin, àwọn nǹkan tá à ń ṣe á sì máa yọrí sí rere. Torí pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin, títí láé làwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ á máa gbádùn àwọn nǹkan rere tó ń pèsè fún wọn. Nínú ayé tuntun, títí láé ni Jèhófà á máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn.​—Ìfihàn 21:3, 4.

Jèhófà Ò “Ní Kọ Àwọn Ẹni Ìdúróṣinṣin Rẹ̀ Sílẹ̀”

14. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé òun mọyì báwọn ìránṣẹ́ òun ṣe jẹ́ adúróṣinṣin?

14 Nígbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ti ṣe ohun tó fi hàn pé adúróṣinṣin lòun. Torí pé awí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà, títí láé láá máa jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Onísáàmù kan sọ pé: “Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó, síbẹ̀, mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì, tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri. Nítorí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.” (Sáàmù 37:25, 28) Ká sòótọ́, Jèhófà ló yẹ ká máa sìn torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. (Ìfihàn 4:11) Àmọ́ torí pé ó jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa ń mọyì gbogbo ohun tá a bá ṣe fún un látọkàn wá.​—Málákì 3:16, 17.

15. Ṣàlàyé bí ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé adúróṣinṣin ni.

15 Torí pé Jèhófà ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sáwọn èèyàn rẹ̀, léraléra ló máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dé bá wọn. Onísáàmù kan sọ pé: “Ó ń ṣọ́ ẹ̀mí àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.” (Sáàmù 97:10) Rántí ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tó mú kí wọ́n la Òkun Pupa kọ já, wọ́n kọrin sí i pé: “O fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ṣamọ̀nà àwọn èèyàn tí o rà pa dà.” (Ẹ́kísódù 15:13) Lóòótọ́, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló mú kí Jèhófà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là létí Òkun Pupa. Ìdí nìyẹn tí Mósè fi sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kì í ṣe torí pé ẹ̀yin lẹ pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín tó sì yàn yín, ẹ̀yin lẹ kéré jù nínú gbogbo èèyàn. Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, tó sì ṣe ohun tó búra fún àwọn baba ńlá yín pé òun máa ṣe ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ agbára mú yín kúrò, kó lè rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú, kúrò lọ́wọ́ Fáráò ọba Íjíbítì.”​—Diutarónómì 7:7, 8.

16, 17. (a) Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tó fi hàn pé wọn ò moore, àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe fàánú hàn sí wọn? (b) Kí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tí ọ̀rọ̀ wọn fi “kọjá àtúnṣe,” kí la sì rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn?

16 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn, torí pé lẹ́yìn tó gbà wọ́n là, ńṣe ni “wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ sí [Jèhófà] nìṣó, bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Sáàmù 78:17) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, léraléra ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n pa Jèhófà tì, wọ́n ń bọ òrìṣà, wọ́n tún ń tẹ̀ lé àṣà àwọn kèfèrí tó yí wọn ká, ìyẹn sì sọ wọ́n di ẹlẹ́gbin. Síbẹ̀, Jèhófà ò da májẹ̀mú tó bá wọn dá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ní kí wòlíì Jeremáyà pàrọwà fáwọn èèyàn òun pé: “Pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ . . . mi ò ní wò ọ́ tìbínútìbínú, nítorí adúróṣinṣin ni mí.” (Jeremáyà 3:12) Àmọ́, bá a ṣe ṣàlàyé ní Orí 25, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ronú pìwà dà. Kódà, ńṣe ni “wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín, wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tó yá? Ńṣe ni ‘ìbínú Jèhófà ru sí àwọn èèyàn rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.’​—2 Kíróníkà 36:15, 16.

17 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? A rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé adúróṣinṣin ni Jèhófà, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò ní ṣe nǹkan kan nípa àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Òótọ́ ni pé “ìfẹ́ [Jèhófà] tí kì í yẹ̀ . . . pọ̀ gidigidi,” ó sì ṣe tán láti fàánú hàn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kí ni Jèhófà máa ṣe sí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ò jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù? Ńṣe ni Jèhófà máa ṣe ohun tó bá ìlànà òdodo rẹ̀ mu, tó sì máa fìyà jẹ ẹni náà. Ó sọ fún Mósè pé òun “kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀.”​—Ẹ́kísódù 34:6, 7.

18, 19. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin bó ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú? (b) Kí ni Jèhófà máa ṣe láti fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kú nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn?

18 Jèhófà tún máa ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin nígbà tó bá ń fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú. Lọ́nà wo? Àpẹẹrẹ kan lèyí tó wà nínú ìwé Ìfihàn, níbi tí Jèhófà ti pàṣẹ fáwọn áńgẹ́lì méje kan pé: “Ẹ lọ da abọ́ méje tí ìbínú Ọlọ́run wà nínú rẹ̀ sórí ayé.” Nígbà tí áńgẹ́lì kẹta da ohun tó wà nínú abọ́ rẹ̀ “sínú àwọn odò àti àwọn ìsun omi,” wọ́n di ẹ̀jẹ̀. Áńgẹ́lì náà wá sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ, Ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí, Ẹni ìdúróṣinṣin, jẹ́ olódodo, torí o ti ṣe àwọn ìdájọ́ yìí, torí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn wòlíì sílẹ̀, o sì ti fún wọn ní ẹ̀jẹ̀ mu; ó tọ́ sí wọn.”​—Ìfihàn 16:1-6.

19 Kíyè sí i pé nígbà tí áńgẹ́lì náà ń jẹ́ iṣẹ́ ìdájọ́ yẹn, ó pe Jèhófà ní “Ẹni ìdúróṣinṣin.” Kí nìdí? Ìdí ni pé tí Jèhófà bá pa àwọn ẹni ibi run, ńṣe ló ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn ìránṣẹ́ òun tọ́pọ̀ nínú wọn ti kú nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni sí wọn. Torí pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin, kò ní gbàgbé wọn láé. Ó wù ú kó tún pa dà rí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ yìí, Bíbélì sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa jí wọn dìde, kó lè san wọ́n lẹ́san. (Jóòbù 14:14, 15) Jèhófà kì í gbàgbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ torí pé wọ́n ti kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni “gbogbo wọn wà láàyè” lójú rẹ̀. (Lúùkù 20:37, 38) Bó ṣe ń wu Jèhófà pé kó jí àwọn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ dìde jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé adúróṣinṣin ni.

Torí pé adúróṣinṣin ni Jèhófà, ó máa rántí àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i títí dójú ikú, ó sì máa jí wọn dìde

Ìjọba Násì ló pa Bernard Luimes (lókè) àti Wolfgang Kusserow (láàárín)

Ẹgbẹ́ òṣèlú kan ló fi ọ̀kọ̀ gún Moses Nyamussua pa

Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ló Jẹ́ Ká Nírètí Láti Wà Láàyè Títí Láé

20. Àwọn wo ni “ohun èlò àánú,” báwo ni Jèhófà sì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí wọn?

20 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Kódà, ọ̀pọ̀ ọdún ni Jèhófà ti “fi ọ̀pọ̀ sùúrù gba àwọn ohun èlò ìrunú tó yẹ fún ìparun láyè.” Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó “ṣe èyí láti jẹ́ ká mọ ọrọ̀ ògo rẹ̀ lórí àwọn ohun èlò àánú, èyí tó ti pèsè sílẹ̀ fún ògo.” (Róòmù 9:22, 23) Àwọn “ohun èlò àánú” yìí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn láti jọba pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 19:28) Torí pé Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn ẹni àmì òróró yìí láti rí ìgbàlà, ó fi hàn pé ó dúró lórí májẹ̀mú tó ṣe fún Ábúráhámù nígbà tó sọ fún un pé: “Gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé yóò gba ìbùkún fún ara wọn nípasẹ̀ ọmọ rẹ torí pé o fetí sí ohùn mi.”​—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

Torí pé adúróṣinṣin ni Jèhófà, ọkàn gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ balẹ̀ pé ó máa mú àwọn ìlérí tó ṣe fún wọn ṣẹ lọ́jọ́ iwájú

21. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó nírètí láti la “ìpọ́njú ńlá” já? (b) Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin?

21 Jèhófà tún fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó nírètí láti la “ìpọ́njú ńlá” já, kí wọ́n sì gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Ìfihàn 7:9, 10, 14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn èèyàn yìí, Jèhófà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí wọn torí bó ṣe fún wọn láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Kí ló mú kéyìí ṣeé ṣe? Nípasẹ̀ ìràpadà ni, ìyẹn sì ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8) Ó máa ń wu àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ láti sún mọ́ Jèhófà torí pé ó jẹ́ adúróṣinṣin. (Jeremáyà 31:3) Ní báyìí tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, ṣé kò wu ìwọ náà kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn? Tá a bá pinnu pé a máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, àá fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, èyí á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.

a Ọ̀rọ̀ kan náà tá a túmọ̀ sí “adúróṣinṣin” nínú 2 Sámúẹ́lì 22:26 la túmọ̀ sí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” nínú àwọn ẹsẹ míì.