Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 30

‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’

‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’

1-3. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà?

 “AYỌ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan, ìyẹn ni pé: Tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn látọkàn wá, ó máa ṣe wá láǹfààní. Òótọ́ ni pé a máa ń láyọ̀ táwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn sí wa, àmọ́ táwa fúnra wa bá fìfẹ́ hàn sáwọn míì, ayọ̀ tá a máa ní á pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.

2 Kò sẹ́ni tó lóye òtítọ́ yìí tó Baba wa ọ̀run. Bá a ṣe ṣàlàyé láwọn orí tó ṣáájú nínú apá yìí, Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ hàn. Kò sẹ́ni tó tíì fìfẹ́ hàn lọ́nà tó ga bíi ti Jèhófà, ó sì pẹ́ gan-an tó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó bá a mu bí Bíbélì ṣe pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.”​—1 Tímótì 1:11.

3 Ó wu Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ pé ká fara wé òun, ní pàtàkì tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ hàn. Éfésù 5:1, 2 sọ fún wa pé: “Ẹ máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìfẹ́.” Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bíi ti Jèhófà, a máa rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni. Inú wa tún máa dùn pé à ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, torí pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé ká “máa nífẹ̀ẹ́ ara [wa].” (Róòmù 13:8) Àmọ́ àwọn ìdí míì tún wà tó fi yẹ ká “máa rìn nínú ìfẹ́.”

Ìfẹ́ Ṣe Pàtàkì

Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká fọkàn tán àwọn ará wa

4, 5. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa?

4 Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Ìdí ni pé ká tó lè sọ pé ẹnì kan jẹ́ Kristẹni tòótọ́, ó gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Tá ò bá sì nífẹ̀ẹ́, a ò lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Èyí tó wá bani nínú jẹ́ jù ni pé a ò ní wúlò fún Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìdí tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn.

5 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín. Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Kíyè sí gbólóhùn tí Jésù lò yẹn: “Bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.” Èyí fi hàn pé, bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ló ṣe fẹ́ káwa náà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì. Ní Orí 29, a kẹ́kọ̀ọ́ pé, àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìfẹ́, torí ìfẹ́ ló mú kó yááfì àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí i kó lè ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan, ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó sì yẹ ká ṣe é tọkàntọkàn débi pé àwọn tí kì í ṣe Kristẹni bíi tiwa máa rí i pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ ara wa. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ ara wa bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, ńṣe là ń fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá.

6, 7. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an? (b) Kí ni kókó ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8?

6 Téèyàn kan ò bá wá nífẹ̀ẹ́ ńkọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tí mi ò [bá] ní ìfẹ́, mo ti di abala idẹ tó ń dún tàbí síńbálì olóhùn gooro.” (1 Kọ́ríńtì 13:1) Tí wọ́n bá fi síńbálì méjì gbá ara wọn, ńṣe ló máa ń han èèyàn létí. Abala idẹ ńkọ́? Ńṣe lòun náà máa ń han èèyàn létí. Àwọn àpèjúwe yìí mà bá a mu o! Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ dà bí ohun èlò ìkọrin tó ń han èèyàn létí, tí kò sì dùn ún gbọ́ létí. Ká sòótọ́, ó máa ṣòro fáwọn èèyàn láti sún mọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: ‘Tí mo bá ní gbogbo ìgbàgbọ́ láti ṣí àwọn òkè nípò pa dà, àmọ́ tí mi ò ní ìfẹ́, mi ò já mọ́ nǹkan kan.’ (1 Kọ́ríńtì 13:2) Torí náà, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn, àmọ́ tí kò nífẹ̀ẹ́, kò sí bó ṣe lè wúlò fún Jèhófà. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn.

7 Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8. Nínú àwọn ẹsẹ yẹn, kì í ṣe bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tàbí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ lé lórí gangan. Kàkà bẹ́ẹ̀, kókó ọ̀rọ̀ ẹ̀ ni bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sí ara wa. Ó ṣàlàyé àwọn nǹkan tí àá máa ṣe àtàwọn nǹkan tá ò ní ṣe tá a bá nífẹ̀ẹ́.

Ohun Tí Ìfẹ́ Máa Ń Ṣe

8. Báwo ni sùúrù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì?

8 “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù.” Èyí túmọ̀ sí pé tá a bá ń ṣe sùúrù fáwọn èèyàn, tá a sì ń fara dà á fún wọn, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. (Kólósè 3:13) Ká sòótọ́, ó yẹ ká máa ní sùúrù. Torí pé aláìpé làwa àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n lè ṣẹ̀ wá tàbí káwa náà ṣẹ̀ wọ́n. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù àti ìfaradà, àá máa gbójú fo àwọn àṣìṣe tí kò tó nǹkan, a ò sì ní máa dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ.

9. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá fi hàn pé a jẹ́ onínúure?

9 “Ìfẹ́ máa ń ní . . . inú rere.” Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tá a sì ń sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé a gba tiwọn rò, ńṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ onínúure. Ìfẹ́ máa ń mú ká wá ọ̀nà tá a lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ní pàtàkì àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ jù. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe arákùnrin tàbí arábìnrin àgbàlagbà kan bíi pé kò rẹ́ni fojú jọ, ó sì lè nílò ẹni táá ràn án lọ́wọ́ tàbí ẹni táá fún un níṣìírí. Ìyá kan tó ń dá tọ́mọ tàbí arábìnrin kan tó wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè nílò ẹni tó máa ràn án lọ́wọ́. Tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn tàbí tó níṣòro tó le gan-an, ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn tẹ́nì kan tó sún mọ́ ọn bá bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ kára lè tù ú. (Òwe 12:25; 17:17) Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà yìí, àá fi hàn pé a jẹ́ onínúure, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́.​—2 Kọ́ríńtì 8:8.

10. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká rọ̀ mọ́ òtítọ́, ká sì máa sọ òtítọ́, kódà nígbà tí ò bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?

10 “Ìfẹ́ . . . máa ń yọ̀ lórí òtítọ́.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ìfẹ́ . . . máa ń fi tayọ̀tayọ̀ gbè sẹ́yìn òtítọ́.” Ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká rọ̀ mọ́ òtítọ́, ó sì máa ń jẹ́ ká “bá ara [wa] sọ òtítọ́.” (Sekaráyà 8:16) Bí àpẹẹrẹ, téèyàn wa kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà á jẹ́ ká fara mọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run. Torí náà, a ò ní máa gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ tàbí ká máa wí àwíjàre tàbí ká tiẹ̀ máa parọ́ nípa ohun tẹ́ni náà ṣe. Òótọ́ ni pé ó lè ṣòro láti gbà pé ẹni náà ṣe ohun tí kò dáa. Síbẹ̀, tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lóòótọ́, tá a sì fẹ́ káyé ẹ̀ dáa, àá fara mọ́ ọn pé kí Jèhófà bá a wí kó lè ṣàtúnṣe. (Òwe 3:11, 12) Bákan náà, tá a bá fẹ́ fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a máa “jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

11. Nítorí pé ìfẹ́ “máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra,” kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí ibi táwọn ará wa kù sí tàbí tí wọ́n bá ṣàṣìṣe?

11 “Ìfẹ́ . . . máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra.” Ní èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ohun tí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí ni pé ìfẹ́ máa ń “bo gbogbo nǹkan.” Ìwé 1 Pétérù 4:8 sọ pé: “Ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa látọkàn wá, a ò ní máa sọ̀rọ̀ nípa àṣìṣe wọn àti ibi tí wọ́n kù sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àṣìṣe àwọn ará wa kì í tó nǹkan, torí náà a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá gbójú fo àṣìṣe wọn.​—Òwe 10:12; 17:9.

12. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán Fílémónì, kí la sì rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?

12 “Ìfẹ́ . . . máa ń gba ohun gbogbo gbọ́.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé ìfẹ́ “máa ń múra tán láti gba ẹ̀rí àwọn èèyàn jẹ́.” Kò yẹ ká máa fura òdì sáwọn ará wa, ńṣe ló yẹ ká gbà pé ohun tó dáa ló wà lọ́kàn wọn tí wọ́n fi ń ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe. Ìfẹ́ ń jẹ́ ká ‘gba ẹ̀rí àwọn ará wa jẹ́,’ ká sì fọkàn tán wọn. a Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Fílémónì. Ónísímù sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀, ìyẹn Fílémónì, àmọ́ Ónísímù di Kristẹni nígbà tó yá. Torí náà, Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà yìí sí Fílémónì láti rọ̀ ọ́ pé kó tẹ́wọ́ gbà á nígbà tó bá pa dà wálé. Pọ́ọ̀lù ò fi dandan mú Fílémónì láti gba Ónísímù pa dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fìfẹ́ rọ̀ ọ́. Ó fọkàn tán Fílémónì pé ó máa ṣe ohun tó tọ́, ó sọ pé: “Mò ń kọ̀wé sí ọ torí ó dá mi lójú pé o máa ṣe ohun tí mo sọ. Mo sì mọ̀ pé wàá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá.” (Ẹsẹ 21) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tá a sì fọkàn tán wọn, èyí á mú kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe ohun tó dáa.

13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń retí pé àwọn ará wa ṣì máa ṣe dáadáa?

13 “Ìfẹ́ . . . máa ń retí ohun gbogbo.” Bí ìfẹ́ ṣe ń jẹ́ ká fọkàn tán àwọn ará wa, ó tún máa ń jẹ́ ká retí pé wọ́n ṣì máa ṣe dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, tí arákùnrin kan bá “ṣi ẹsẹ̀ gbé kó tó mọ̀,” ó máa ń wù wá pé kó tẹ́tí sáwọn tó fẹ́ ràn án lọ́wọ́, kó sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ. (Gálátíà 6:1) Bákan náà, ó máa ń wù wá pé káwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára dẹni tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. A máa ń mú sùúrù fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, a sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára. (Róòmù 15:1; 1 Tẹsalóníkà 5:14) Tí èèyàn wa kan bá tiẹ̀ fi Jèhófà sílẹ̀, a ò ní yéé rétí pé lọ́jọ́ kan ó máa ronú pìwà dà, á sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, bíi ti ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù.​—Lúùkù 15:17, 18.

14. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tó lè gba pé ká ní ìfaradà, báwo ni ìfẹ́ sì ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?

14 “Ìfẹ́ . . . máa ń fara da ohun gbogbo.” Ìfaradà máa ń jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà tá a bá níṣòro tàbí tí nǹkan bá tojú sú wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe ohun tó dùn wá tàbí ohun tó lè fa ìṣòro fún wa. Àmọ́ nígbà míì, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà náà lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Torí pé aláìpé ni wọ́n, wọ́n lè ṣe ohun tó dùn wá. Ẹnì kan lè sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wa, kó sì dùn wá gan-an. (Òwe 12:18) Ó sì lè jẹ́ pé nǹkan kan ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ, tá a gbà pé àwọn alàgbà ò bójú tó dáadáa. Tí arákùnrin kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún bá hùwà kan tó bí wa nínú, a lè máa rò ó pé: ‘Báwo lẹni tó pera ẹ̀ ní Kristẹni ṣe lè hu irú ìwà yẹn?’ Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé àá wá torí ìyẹn sọ pé a ò ní sin Jèhófà mọ́ ni? A ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ní ìfẹ́! Ó dájú pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tẹ́nì kan bá tiẹ̀ ṣẹ̀ wá, a ò ní torí ìyẹn gbà pé kò síbi tẹ́ni náà dáa sí rárá, tàbí ká wá máa fojú burúkú wo gbogbo àwọn ará nínú ìjọ. Bákan náà tá a bá ní ìfẹ́, àá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àá sì máa dúró ti àwọn ará wa nínú ìjọ, kódà tí èèyàn aláìpé bíi tiwa bá ṣe ohun tó dùn wá.​—Sáàmù 119:165.

Ohun Tí Ìfẹ́ Kì Í Ṣe

15. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa jowú, báwo sì ni ìfẹ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

15 “Ìfẹ́ kì í jowú.” Kò yẹ ká máa jowú àwọn èèyàn torí àwọn ohun tí wọ́n ní, ẹ̀bùn àbínibí wọn tàbí àwọn ohun míì tí wọ́n lè ṣe. Tá a bá ń jowú àwọn èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé tara wa nìkan la mọ̀, ó sì lè ṣàkóbá fún wa àtàwọn ẹlòmíì. Tá ò bá sì wá nǹkan ṣe sí i, a lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní máa ṣe ìlara? (Jémíìsì 4:5) Ìfẹ́ ló máa ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ní ìfẹ́, ńṣe làá máa bá àwọn míì yọ̀ tí wọ́n bá ní ohun táwa ò ní. (Róòmù 12:15) Bákan náà, a ò ní máa bínú tàbí ká máa jowú tí wọ́n bá gbóríyìn fún ẹnì kan torí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ tó ní tàbí torí ó ṣe ohun kan dáadáa.

16. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́, kí nìdí tá ò fi ní máa fàwọn àṣeyọrí wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe fọ́rífọ́rí?

16 “Ìfẹ́ . . . kì í fọ́nnu, kì í gbéra ga.” Tá a bá nífẹ̀ẹ́, a ò ní máa fi àwọn ẹ̀bùn àbínibí tàbí àṣeyọrí wa ṣe fọ́rífọ́rí. Torí tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà la máa ń fọ́nnu nítorí ohun tá a ṣe láṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tàbí nítorí àwọn àǹfààní tá a ní nínú ìjọ, ìyẹn lè mú káwọn ará wa rẹ̀wẹ̀sì. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ sì lè mú kí wọ́n máa wo ara wọn bíi pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, a ò ní máa fàwọn àṣeyọrí tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa yán wọn lójú, àá máa rántí pé Jèhófà ló ràn wá lọ́wọ́ tá a fi ṣàwọn àṣeyọrí náà. (1 Kọ́ríńtì 3:5-9) Ó ṣe tán, ìfẹ́ “kì í gbéra ga,” tàbí bí Bíbélì kan ṣe túmọ̀ ẹ̀, ‘ìfẹ́ kì í jẹ́ kéèyàn máa ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.’ Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká máa rò pé a dáa ju àwọn míì lọ.​—Róòmù 12:3.

17. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, àwọn nǹkan wo làá máa ṣe, àwọn nǹkan wo la ò sì ní máa ṣe?

17 “Ìfẹ́ . . . kì í hùwà tí kò bójú mu.” Ẹni tó ń hùwà lọ́nà tí kò bójú mu máa ń hùwà àìnítìjú, ó sì máa ń hùwà tó lè kan àwọn míì lábùkù. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ìfẹ́ torí ìwà tó ń hù fi hàn pé kò ka àwọn èèyàn sí, kò sì gba tiwọn rò. Àmọ́ tá a bá ní ìfẹ́, a máa jẹ́ onínúure, a ò sì ní fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ṣeré rárá. Bákan náà, ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká hùwà ọmọlúwàbí, ká máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn, á sì jẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Torí náà tá a bá ní ìfẹ́, a ò ní hu “ìwà àìnítìjú,” ìyẹn ìwà èyíkéyìí tí kò ṣeé gbọ́ sétí tàbí tó máa múnú bí àwọn ará wa.​—Éfésù 5:3, 4.

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi dandan mú àwọn èèyàn láti fara mọ́ èrò wa?

18 “Ìfẹ́ . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.” Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ìfẹ́ kì í rin kinkin mọ́ èrò tiẹ̀.” Ẹni tó ní ìfẹ́ kì í sọ pé èrò tòun nìkan ló tọ̀nà, kò sì ní máa sọ pé nǹkan tóun bá sọ làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe. Kò ní máa fọgbọ́n àyínìke darí àwọn èèyàn, kò sì ní fi dandan yí wọn lérò pa dà kí wọ́n lè ṣe ohun tó fẹ́. Ńṣe nirú ìwà yìí fi hàn pé ẹni náà jẹ́ alágídí àti agbéraga, Bíbélì sì sọ pé: “Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun.” (Òwe 16:18) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lóòótọ́, àá máa ka ọ̀rọ̀ wọn sí pàtàkì, àá sì máa fara mọ́ èrò wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Irú ìwà yìí bá ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ mu. Ó sọ pé: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 10:24.

19. Tá a bá ní ìfẹ́, kí la máa ṣe táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá?

19 “Ìfẹ́ . . . kì í tètè bínú. Kì í di èèyàn sínú.” Tá a bá ní ìfẹ́, a ò ní tètè máa bínú táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tàbí tí wọ́n ṣe ohun tó dùn wá. Òótọ́ ni pé inú lè bí wa táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá. Àmọ́ tí ìdí bá tiẹ̀ wà fún wa láti bínú lóòótọ́, ìfẹ́ ò ní jẹ́ ká yarí kanlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ò ní yanjú. (Éfésù 4:26, 27) A ò ní gbé ohun tẹ́nì kan ṣe tó dùn wá sọ́kàn, bí ẹni pé a lọ kọ ọ́ síbì kan tá ò ti ní gbàgbé, ká lè ṣíwèé kàn án lọ́jọ́ iwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ní ìfẹ́ á mú ká fìwà jọ Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́. Bá a ṣe rí i ní Orí 26, Jèhófà máa ń dárí jini nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Tó bá sì ti dárí jì wá, ó gbàgbé nìyẹn, ìyẹn ni pé kò ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ yẹn jẹ wá mọ́ lọ́jọ́ iwájú. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà kì í dì wá sínú!

20. Kí ni kò yẹ ká ṣe tí ọ̀kan lára àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà bá kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ìyà sì wá ń jẹ ẹ́?

20 “Ìfẹ́ . . . kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ìfẹ́ kì í yọ̀ rárá nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ohun tí kò dáa.” Ìfẹ́ kì í fi ìwà àìṣòdodo ṣayọ̀. Torí náà, a ò ní fàyè gba ìwà ìṣekúṣe èyíkéyìí. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ọ̀kan lára àwọn ará wa bá kó sí pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ìyà sì wá ń jẹ ẹ́? Tá a bá nífẹ̀ẹ́, a ò ní máa yọ̀, ká wá máa sọ lọ́kàn wa pé, ‘Ọwọ́ ti bà á! Kò tán nídìí ẹ̀!’ (Òwe 17:5) Àmọ́, a máa ń yọ̀ nígbà tí arákùnrin kan tó ṣi ẹsẹ̀ gbé bá ṣàtúnṣe, tó sì pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

“Ọ̀nà Tó Ta Yọ”

21-23. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé”? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kẹ́yìn?

21 “Ìfẹ́ kì í yẹ̀ láé.” Kí ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí túmọ̀ sí? Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń sọ bọ̀ àtèyí tó sọ lẹ́yìn gbólóhùn yìí fi hàn pé ẹ̀bùn ẹ̀mí táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní ló ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àwọn ẹ̀bùn yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà wà pẹ̀lú ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo Kristẹni ló lè mú aláìsàn lára dá, kì í ṣe gbogbo wọn ló lè sọ àsọtẹ́lẹ̀, gbogbo wọn kọ́ ló sì lè fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀. Tẹ́nì kan ò bá tiẹ̀ wá láwọn ẹ̀bùn yìí, kì í ṣe nǹkan bàbàrà, torí pé bó pẹ́ bó yá, ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu ò ní sí mọ́. Àmọ́, ohun kan wà tí kò ní dópin láé tó yẹ kí gbogbo Kristẹni ní. Ó ṣe pàtàkì ju àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu lọ, ó sì máa wà pẹ́ jù wọ́n lọ. Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ pè é ní “ọ̀nà tó ta yọ.” (1 Kọ́ríńtì 12:31) Kí ni “ọ̀nà tó ta yọ” yìí? Ìfẹ́ ni.

22 Ká sòótọ́, ìfẹ́ Kristẹni tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ “kì í yẹ̀ láé,” ìyẹn ni pé, kò ní dópin láé. Títí di báyìí, ohun táwọn èèyàn fi ń dá àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù mọ̀ ni bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. Irú ìfẹ́ yìí sì wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé. Ìfẹ́ yẹn máa wà títí láé, ó ṣe tán Jèhófà ti ṣèlérí fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé wọ́n máa wà láàyè títí láé. (Sáàmù 37:9-11, 29) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè “máa rìn nínú ìfẹ́.” Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá rí ayọ̀ púpọ̀ tó wà nínú fífúnni. Ní pàtàkì jù lọ, a máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé, títí ayérayé làá sì máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́.

Ohun táwọn èèyàn fi ń dá àwọn èèyàn Jèhófà mọ̀ ni bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn

23 Nínú ìwé yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó gbawájú jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀, ọgbọ́n rẹ̀ àti ìfẹ́ tó ta gbogbo wọn yọ. A tún ti rí bí àwọn ànímọ́ yìí ṣe ń ṣe wá láǹfààní. Ní báyìí tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́?’ A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú orí tó kẹ́yìn ìwé yìí.

a Òótọ́ ni pé ìfẹ́ “máa ń gba ohun gbogbo gbọ́,” àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn tàn wá. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa ṣọ́ àwọn tó ń fa ìyapa àti ìkọ̀sẹ̀ . . . , kí ẹ sì yẹra fún wọn.”​—Róòmù 16:17.