Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 27

“Oore Rẹ̀ Mà Pọ̀ O!”

“Oore Rẹ̀ Mà Pọ̀ O!”

1, 2. Báwo ni oore Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó, kí sì ni Bíbélì sọ nípa oore Jèhófà?

 NÍRỌ̀LẸ́ ọjọ́ kan, àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà kan wà pa pọ̀. Wọ́n ń jẹun, wọ́n ń rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbádùn bí wọ́n ṣe ń wo àwọ̀ mèremère tó wà lójú ọ̀run bí oòrùn ṣe ń wọ̀. Bí àgbẹ̀ kan ṣe bojú wo oko ẹ̀, ó rẹ́rìn-ín músẹ́ bó ṣe rí i pé ojú ọ̀run ṣú dẹ̀dẹ̀, tí òjò àkọ́rọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ sára àwọn irúgbìn ẹ̀. Inú tọkọtaya kan ń dùn ṣìnkìn bí wọ́n ṣe rí ọmọ wọn kékeré tó ń ṣísẹ̀ gáté-gàtè-gáté fúngbà àkọ́kọ́, bó ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.

2 Bóyá àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí mọ̀ àbí wọn ò mọ̀, ńṣe ni wọ́n ń jọlá oore Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ló sábà máa ń sọ pé “rere ni Olúwa” tàbí “Olúwa dára.” Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà tó túbọ̀ ṣe tààràtà. Ó ní: “Oore rẹ̀ mà pọ̀ o!” (Sekaráyà 9:17) Àmọ́, ó jọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ohun tọ́rọ̀ yẹn túmọ̀ sí gangan. Tá a bá sọ pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere, kí ló túmọ̀ sí? Àǹfààní wo la sì ń jẹ torí pé Jèhófà máa ń ṣoore?

Ọ̀kan Pàtàkì Lára Ọ̀nà Tí Jèhófà Gbà Ń Fìfẹ́ Hàn

3, 4. Kí ni ìwà rere, kí sì nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló jẹ́ kó máa ṣe wá lóore?

3 Bíbélì fi hàn pé ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì fani mọ́ra gan-an ni ìwà rere. Tá a bá sọ pé ẹnì kan ní ìwà rere, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún níwà ọmọlúwàbí, ó sì máa ń ṣe ohun tó dáa. Kódà, a lè sọ pé gbogbo ohun tí Jèhófà ń ṣe ló fi hàn pé òun ni olóore tó ga jù lọ. Gbogbo ànímọ́ rẹ̀, títí kan agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ ló dáa látòkèdélẹ̀. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló jẹ́ kó máa ṣoore. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

4 Téèyàn bá jẹ́ ẹni rere, ńṣe láá máa wù ú láti ṣoore. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé téèyàn bá jẹ́ ẹni rere, ó máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra ju kéèyàn jẹ́ olódodo nìkan lọ. (Róòmù 5:7) Ẹni tó jẹ́ olódodo máa ń tẹ̀ lé ohun tí òfin Ọlọ́run bá ti sọ. Ṣùgbọ́n ẹni rere máa ń ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa ń wá ọ̀nà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì máa ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Ohun tá a máa kọ́ ní orí yìí á jẹ́ ká rí i pé ẹni rere ni Jèhófà lóòótọ́. Ó ṣe kedere pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa ló jẹ́ kó máa ṣe wá lóore.

5-7. Kí nìdí tí Jésù ò fi fẹ́ kí ọkùnrin yẹn pe òun ní “Olùkọ́ Rere,” ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ló sì kọ́ wọn?

5 Jèhófà ni olóore tó ga jù lọ. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ọkùnrin kan wá bá a, ó fẹ́ bi í ní ìbéèrè kan, ó wá pè é ní “Olùkọ́ Rere.” Jésù fèsì pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.” (Máàkù 10:17, 18) O lè máa ronú pé “Olùkọ́ Rere” ṣáà ni Jésù lóòótọ́, kí wá nìdí tó fi dáhùn lọ́nà yẹn?

6 Ó hàn gbangba pé ńṣe lọkùnrin yẹn kàn lo gbólóhùn náà “Olùkọ́ Rere” bí orúkọ oyè láti fi pọ́n Jésù lé. Torí pé Jésù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó darí ògo yìí sí Baba rẹ̀ ọ̀run, tó jẹ́ ẹni rere tí kò lẹ́gbẹ́. (Òwe 11:2) Àmọ́, ńṣe ni Jésù tún ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ìyẹn ni pé Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ, torí náà òun nìkan ló láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n má jẹ lára èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, àmọ́ wọ́n ṣàìgbọràn. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Àmọ́, Jésù yàtọ̀ sí wọn pátápátá. Ó níwà ìrẹ̀lẹ̀, ó sì gbà pé Bàbá òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìpinnu yẹn.

7 Yàtọ̀ síyẹn, Jésù mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ohun rere ti ń wá. Jèhófà ló ń fúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jémíìsì 1:17) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni rere nínú bó ṣe lawọ́ sáwọn èèyàn.

Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Oore Jèhófà Pọ̀ Gan-an

8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣoore fún gbogbo èèyàn?

8 Gbogbo èèyàn tó wà láyé ló ti jàǹfààní nínú oore Jèhófà. Sáàmù 145:9 sọ pé: “Jèhófà ń ṣoore fún gbogbo ẹ̀dá.” Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún gbogbo èèyàn? Bíbélì sọ pé: “Kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde, ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.” (Ìṣe 14:17) Ṣé inú ẹ máa ń dùn nígbà tó o bá ń jẹ oúnjẹ aládùn? Bí Jèhófà ṣe dá ayé yìí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló ń mú ká lè máa gbádùn irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣètò bí omi ṣe ń yí po kí òjò lè rọ̀, ó tún fún wa ní “àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde” ká lè máa gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ. Gbogbo èèyàn ni Jèhófà ń ṣoore yìí fún, kì í ṣe àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ nìkan. Jésù sọ pé: “Ó ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”​—Mátíù 5:45.

9. Báwo ni èso ápù ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ olóore?

9 Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọyì àwọn nǹkan dáadáa tí aráyé ń gbádùn, irú bí oòrùn àti òjò. Bákan náà, ó ti láwọn àsìkò tí oríṣiríṣi irè oko máa ń jáde. Àpẹẹrẹ kan ni ti èso ápù. Ọ̀pọ̀ ibi láyé làwọn èèyàn ti mọ èso yìí. Ó rẹwà, ó dùn, omi ẹ̀ àtàwọn èròjà tó wà nínú ẹ̀ sì ń ṣara lóore gan-an. Ṣé o mọ̀ pé kárí ayé, oríṣi èso ápù tó wà tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (7,500)? Kì í ṣe àwọ̀ kan ṣoṣo ni wọ́n ní, wọn ò sì tóbi bákan náà. Wọ́n lè jẹ́ pupa, yẹ́lò, àwọ̀ wúrà tàbí àwọ̀ ewé. Díẹ̀ làwọn ápù kan fi tóbi ju àgbálùmọ̀ lọ, àwọn kan sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó àgbọn. Hóró èso ápù ò ju bíńtín báyìí lọ, ṣùgbọ́n hóró yìí ló ń dàgbà di ọ̀kan lára àwọn igi tó rẹwà jù lọ láyé. (Orin Sólómọ́nì 2:3) Gbogbo ìgbà ìrúwé ni igi ápù máa ń yọ òdòdó aláwọ̀ mèremère, gbogbo ìgbà ìkórè ló sì máa ń so èso. Lọ́dọọdún, ìpíndọ́gba èso tí igi ápù kọ̀ọ̀kan ń so máa ń wúwo tó ọgọ́fà (120) àpò gaàrí, bẹ́ẹ̀ láá sì ṣe máa so lọ́dọọdún fún nǹkan bí ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75)!

Jèhófà “ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde”

Hóró bíńtín yìí ló ń dàgbà di igi tó dùn ún wò, tó sì ń pèsè oúnjẹ fáwọn èèyàn fún ọ̀pọ̀ ọdún

10, 11. Báwo lọ̀nà tí Jèhófà gbà dá wa ṣe fi hàn pé ẹni rere ni?

10 Bí Jèhófà ṣe dá wa “tìyanutìyanu” fi hàn pé Ẹni rere ni, torí pé ó dá wa lọ́nà tá a fi lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn nǹkan tó dá, ká sì lè mọyì wọn. (Sáàmù 139:14) Tún ronú nípa àwọn àpèjúwe tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ká sọ pé o wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn tó o sì àwọn nǹkan yẹn, èwo nínú wọn ló máa múnú ẹ dùn jù? Ó lè jẹ́ ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ tó ń rẹ́rìn-ín, ọ̀wààrà òjò tó ń rọ̀ sórí oko tàbí oríṣiríṣi àwọ̀ mèremère tó máa ń mú kójú ọ̀run rẹwà bí oòrùn ṣe ń wọ̀. Ọlọ́run dá ojú wa lọ́nà tá a fi lè dá oríṣi àwọ̀ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) mọ̀ yàtọ̀! Bákan náà, etí wa máa ń jẹ́ ká gbọ́ oríṣiríṣi ìró. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan tá a nífẹ̀ẹ́ bá ń bá wa sọ̀rọ̀, a máa ń mọ̀ nínú ohùn rẹ̀ pé ńṣe ló ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́. A tún lè gbọ́ ìró atẹ́gùn tó ń fẹ́ ewé àti ẹ̀rín ọmọ kékeré nígbà tínú ẹ̀ bá dùn gan-an. Kí ló jẹ́ ká lè rí àwọn nǹkan yẹn, ká sì gbọ́ àwọn ìró yẹn? Bíbélì sọ pé: “Etí tí a fi ń gbọ́ràn àti ojú tí a fi ń ríran Jèhófà ló dá àwọn méjèèjì.” (Òwe 20:12) Àwọn nǹkan míì wo ni Jèhófà dá mọ́ wa tó jẹ́ ká lè gbádùn ìgbé ayé wa?

11 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere ni bó ṣe fún wa ní imú tá a fi ń gbóòórùn. Àìmọye òórùn ni imú wa lè gbọ́. Díẹ̀ lára wọn ni: ìtasánsán oúnjẹ tá a fẹ́ràn, òórùn òdòdó, òórùn ewé gbígbẹ tó já bọ́ látorí igi, òórùn èéfín tó ń rú túú látinú iná tó ń jó wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Jèhófà tún dá wa ká lè mọ nǹkan lára. Ìyẹn ló ń jẹ́ ká mọ̀ tí atẹ́gùn tó ń tuni lára bá fẹ́ yẹ́ẹ́ sí wa, ó tún máa ń jẹ́ ká mọ̀ ọ́n lára tẹ́nì kan tá a nífẹ̀ẹ́ bá gbá wa mọ́ra, òun náà ló tún ń jẹ́ ká mọ bí èso kan ṣe rí tá a bá fọwọ́ kàn án. Tá a bá wá jẹ èso náà, a máa mọ adùn ẹ̀. Ohun míì tí Jèhófà sì dá mọ́ wa nìyẹn. Bá a ṣe ń jẹ èso yẹn làá máa gbádùn ẹ̀, ahọ́n wa ló sì jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe torí ó ń jẹ́ ká mọ oríṣiríṣi adùn. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà tá a fi lè sọ nípa Jèhófà pé: “Oore rẹ mà pọ̀ o! O ti tò wọ́n jọ fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ.” (Sáàmù 31:19) Àmọ́, àwọn oore wo ni Jèhófà tò jọ fáwọn tó bẹ̀rù ẹ̀?

A Máa Gbádùn Oore Jèhófà Títí Láé

12. Èwo ló ṣe pàtàkì jù lọ lára àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wa, kí sì nìdí?

12 Jésù sọ pé: “A ti kọ ọ́ pé: ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ṣoṣo ló ń mú kí èèyàn wà láàyè, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń ti ẹnu Jèhófà jáde ni èèyàn fi ń wà láàyè.’ ” (Mátíù 4:4) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn, àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Bíbélì máa ṣe wá láǹfààní ju oúnjẹ tara lọ, torí ó lè jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ní Orí 8 ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ti lo agbára ẹ̀ láti mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ẹ̀ lọ́nà tó tọ́, kí wọ́n sì máa gbádùn nínú Párádísè tẹ̀mí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Apá pàtàkì nínú Párádísè yẹn ni ọ̀pọ̀ ohun rere tí Jèhófà ti fún wa ká lè mọ púpọ̀ sí i nípa ẹ̀, ká lè máa ṣohun táá múnú ẹ̀ dùn, ká sì lè sún mọ́ ọn.

13, 14. (a) Kí ni wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, kí sì ni ìran náà túmọ̀ sí? (b) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ kí wọ́n lè nírètí ìyè àìnípẹ̀kun?

13 Ọ̀kan lára àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa mú àwọn nǹkan bọ̀ sípò ni èyí tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Ó rí tẹ́ńpìlì kan tá a mú bọ̀ sípò, tá a sì ṣe lógo. Odò kan ń ṣàn látinú tẹ́ńpìlì yẹn. Odò náà ń fẹ̀ sí i, ó sì ń jìn sí i, títí tó fi di alagbalúgbú omi. Gbogbo ibi tí odò náà bá ṣàn dé ló máa ń ṣe láǹfààní. Àwọn igi ń hù lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò náà, àwọn èso ẹ̀ jẹ́ oúnjẹ, àwọn ewé ẹ̀ sì ń woni sàn. Odò náà mú kí Òkun Òkú tí kò ní ohun ẹlẹ́mìí kankan tẹ́lẹ̀ sọ jí, àwọn ohun ẹlẹ́mìí sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbá yìn-ìn nínú rẹ̀! (Ìsíkíẹ́lì 47:1-12) Àmọ́, kí làwọn nǹkan yìí túmọ̀ sí?

14 Ohun tí ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò káwọn èèyàn lè máa jọ́sìn ẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Bó ṣe jẹ́ pé odò yẹn ń fẹ̀ sí i, tó sì ń jìn sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ kí wọ́n lè wà láàyè títí láé ṣe ń pọ̀ sí i. Látìgbà tí Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò lọ́dún 1919 ló ti ń pèsè àwọn ẹ̀bùn tó ń fúnni ní ìyè fáwọn èèyàn rẹ̀. Lọ́nà wo? Jèhófà ti lo Bíbélì, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣeyebíye. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ẹ̀kọ́ yìí ni ẹbọ ìràpadà Kristi. Torí pé Jésù kú nítorí wa, gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́ láǹfààní láti ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wọ́n sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. a Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ ń pa àwọn èèyàn láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ńṣe làwa èèyàn Jèhófà ń jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù.​—Àìsáyà 65:13.

15. Oore wo ni Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn olóòótọ́ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?

15 Àmọ́ odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran yìí kò ní yéé ṣàn nígbà tí ètò àwọn nǹkan yìí bá dópin. Dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe láá túbọ̀ máa ṣàn sí i nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Nígbà yẹn, Jèhófà máa lo ẹbọ ìràpadà Jésù láti sọ àwọn èèyàn olóòótọ́ di pípé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé àwọn oore tí Jèhófà máa ṣe á múnú wa dùn gan-an!

Àwọn Ọ̀nà Míì Tí Jèhófà Gbà Ń Ṣoore

16. Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà láwọn ìwà àti ìṣe míì tó fi hàn pé ó jẹ́ ẹni rere, kí sì ni díẹ̀ lára wọn?

16 A ti rí i pé Jèhófà jẹ́ ọ̀làwọ́, àmọ́ ó tún láwọn ìwà àti ìṣe míì tó fi hàn pé ó jẹ́ ẹni rere. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Màá mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ, màá sì kéde orúkọ Jèhófà níwájú rẹ.” Lẹ́yìn náà, àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.’ ” (Ẹ́kísódù 33:19; 34:6) Torí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere, ó tún láwọn ìwà àti ìṣe míì tó dáa gan-an. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára wọn.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ṣe sáwa èèyàn aláìpé lásánlàsàn, ànímọ́ wo ló sì ń jẹ́ kó máa ṣe bẹ́ẹ̀?

17 Ọlọ́run “tó ń gba tẹni rò.” Ànímọ́ yìí tan mọ́ àánú, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń pọ́n àwa èèyàn lé àti pé ó ṣeé sún mọ́. Àwọn alágbára sábà máa ń sọ̀rọ̀ sáwọn èèyàn ṣàkàṣàkà, wọ́n máa ń kanra, wọ́n sì máa ń hùwà ìkà, àmọ́ Jèhófà kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Dípò ìyẹn, ó máa ń ní sùúrù, ó sì jẹ́ onínúure àti ẹni jẹ́jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Ábúrámù pé: “Jọ̀ọ́ gbójú sókè níbi tí o wà, kí o sì wo àríwá àti gúúsù, ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn.” (Jẹ́nẹ́sísì 13:14) Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló yọ ọ̀rọ̀ náà “jọ̀ọ́” kúrò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. Ìwádìí táwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe ọ̀rọ̀ àṣẹ, ńṣe ló jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé, àwọn àpẹẹrẹ irú ẹ̀ míì sì wà nínú Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 31:12; Ìsíkíẹ́lì 8:5) Àbẹ́ ò rí nǹkan, Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run ń sọ pé “jọ̀ọ́” fún èèyàn lásánlàsàn! Nínú ayé yìí táwọn èèyàn ti máa ń gbójú mọ́ ara wọn, tí wọ́n máa ń hùwà jàgídíjàgan àti ìwà àfojúdi, ẹ ò rí i pé ó tuni lára láti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wa máa ń gba tẹni rò!

18. Kí ló túmọ̀ sí pé ‘òtítọ́ Jèhófà pọ̀ gidigidi,’ kí sì nìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn fi ń fini lọ́kàn balẹ̀?

18 ‘Òtítọ́ rẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ Ìwà àìṣòótọ́ pọ̀ gan-an lóde òní. Àmọ́ Bíbélì rán wa létí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe èèyàn lásánlàsàn tó máa ń parọ́.” (Nọ́ńbà 23:19) Kódà, Títù 1:2 sọ pé “Ọlọ́run . . . kò lè parọ́.” Torí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere kò lè parọ́ láé. Ìdí nìyẹn tá a fi lè gbára lé gbogbo ìlérí Jèhófà pátápátá, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní lọ láìṣẹ. Bíbélì tiẹ̀ pe Jèhófà ní “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sáàmù 31:5) Ìmọ̀ Jèhófà pọ̀ gan-an, ó sì máa ń fi ibú ọgbọ́n rẹ̀ la àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lóye. b Ó tiẹ̀ tún ń jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fi ohun tó ń kọ́ wọn sílò, kí wọ́n sì jàǹfààní látinú ẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa “rìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 3) Tá a bá ń rántí pé ẹni rere ni Jèhófà, kí lèyí á mú ká máa ṣe?

‘Jẹ́ Kí Inú Ẹ Máa Dùn Nítorí Oore Jèhófà’

19, 20. (a) Kí ni Sátánì ṣe láti mú kí Éfà ronú pé Jèhófà kì í ṣe ẹni rere, kí ló sì yọrí sí? (b) Tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere, kí lèyí á mú ká máa ṣe, kí sì nìdí?

19 Nígbà tí Sátánì dán Éfà wò nínú ọgbà Édẹ́nì, ńṣe ló fẹ́ kí Éfà máa ronú pé Jèhófà kì í ṣe ẹni rere. Jèhófà sọ fún Ádámù pé: “O lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí ní àjẹtẹ́rùn.” Lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún igi tó wà nínú ọgbà náà, ọ̀kan péré ni Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso ẹ̀. Àmọ́, kíyè sí ohun tí Sátánì bi Éfà. Ó ní: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 16; 3:1) Sátánì yí ọ̀rọ̀ Jèhófà pa dà kí Éfà lè máa ronú pé Jèhófà ń fawọ́ ohun rere kan sẹ́yìn. Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà gba Sátánì gbọ́. Éfà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé Jèhófà kì í ṣe ẹni rere, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló fún un ní gbogbo nǹkan tó ní. Látìgbà yẹn sì làwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ń ṣe bíi ti Éfà.

20 A kúkú mọ ìyà ńlá tó ń jẹ àwa èèyàn torí pé Éfà àtàwọn míì kò gbà pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ tó wà ní Jeremáyà 31:12 sọ́kàn. Ó sọ pé: “Inú wọn á dùn nítorí oore Jèhófà.” Ṣe ló yẹ kí oore Jèhófà máa mú wa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. Kò yẹ ká máa ṣiyèméjì rárá nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run wa bá ṣe torí pé ẹni rere ló jẹ́ ní gbogbo ọ̀nà. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, torí pé ohun tó dáa ló máa ń ṣe fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

21, 22. (a) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì oore Jèhófà? (b) Ànímọ́ wo la máa jíròrò ní orí tó kàn, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí oore Jèhófà?

21 Bákan náà, inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá ní àǹfààní láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa oore Ọlọ́run. Sáàmù 145:7 sọ nípa àwọn èèyàn Jèhófà pé: “Wọ́n á máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sọ nípa ọ̀pọ̀ oore rẹ.” Ojoojúmọ́ la máa ń jàǹfààní oore Jèhófà lọ́nà kan tàbí òmíì. O ò ṣe jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lójoojúmọ́ fún oore rẹ̀, kó o sì sọ àwọn oore yẹn ní pàtó? Tá a bá fẹ́ fara wé bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni rere, ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn oore tó ti ṣe fún wa, ká máa dúpẹ́ fún àwọn oore yẹn, ká sì máa sọ fún àwọn míì nípa rẹ̀. Tá a bá ń wá ọ̀nà láti máa ṣe rere bíi ti Jèhófà, èyí á mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹni ọ̀wọ́n, má ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú, àpẹẹrẹ rere ni kí o máa tẹ̀ lé. Ẹni tó bá ń ṣe rere wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”​—3 Jòhánù 11.

22 Oore Jèhófà tún tan mọ́ àwọn ànímọ́ míì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé ‘ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ (Ẹ́kísódù 34:6) Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí, torí náà ànímọ́ yìí yàtọ̀ sí oore tó máa ń ṣe fún gbogbo èèyàn. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nìkan ni Jèhófà máa ń fi ànímọ́ yìí hàn sí. Ní orí tó kàn, a máa mọ bí Jèhófà ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn sí wọn.

a Nínú gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún wa, ìràpadà ló ga jù. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ló wà lọ́run, Jèhófà sì lè yan ọ̀kan nínú wọn láti wá kú torí wa, àmọ́ ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo ló yàn.

b Bíbélì sábà máa ń fi òtítọ́ wé ìmọ́lẹ̀. Onísáàmù kan kọ ọ́ lórin pé: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde.” (Sáàmù 43:3) Jèhófà ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ tàn sórí àwọn tó bá fẹ́ gba ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ ẹ̀.​—2 Kọ́ríńtì 4:6; 1 Jòhánù 1:5.