Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 25

“Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”

“Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”

1, 2. (a) Kí ni abiyamọ sábà máa ń ṣe nígbà tí ọmọ rẹ̀ bá ń ké? (b) Ta lẹni tó máa ń fàánú hàn lọ́nà tó ju tàwọn abiyamọ lọ?

 LÓRU ọjọ́ kan, abiyamọ kan gbọ́ tí ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ń ké. Kíá nìyá ọmọ náà jí. Kì í kúkú sùn wọra mọ́ látìgbà tó ti bí ọmọ yìí. Kí ọmọ rẹ̀ má tíì ké ni, á ti mọ ohun tó ń ṣe é. Ó máa ń mọ̀ bóyá oúnjẹ lọmọ náà ń fẹ́, tàbí kí wọ́n gbé òun mọ́ra, tàbí kí wọ́n ṣáà tọ́jú òun. Àmọ́, ohun yòówù kó fa ẹkún ọmọ náà, ìyá ẹ̀ ò lè ṣe kó má dá a lóhùn. Ojú ẹ̀ ò ní gbà á.

2 Bí ìyà ṣe máa ń ṣàánú ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kan lára ọ̀nà tó lágbára jù lọ táwa èèyàn máa ń gbà fìfẹ́ hàn. Àmọ́, ojú àánú Jèhófà Ọlọ́run ju tàwa èèyàn lọ fíìfíì. Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú, ó máa wù wá ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú, ká sì wo bí Ọlọ́run wa ṣe máa ń fàánú hàn.

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Aláàánú?

3. Kí nìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n máa ń tú sí “fi àánú hàn” tàbí “ṣe ojú àánú”?

3 Nínú Bíbélì, ìyọ́nú àti àánú kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń lò lédè Hébérù àti Gíríìkì láti fi ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ olójú àánú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sábà máa ń tú ọ̀rọ̀ Hébérù náà ra·chamʹ sí “fi àánú hàn” tàbí “ṣe ojú àánú.” Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ náà ra·chamʹ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹni tó fi tinútinú ṣàánú ẹni tó fẹ́ràn nígbà tó rí i pé ìyà ń jẹ ẹni náà tàbí tó ṣojú àánú sẹ́ni tó nílò ìrànlọ́wọ́.” Ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ni Jèhófà lò láti fi sọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí jọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ilé ọlẹ̀,” wọ́n sì lè túmọ̀ ẹ̀ sí “ojú àánú tí ìyá máa ń ní.” a​—Ẹ́kísódù 33:19; Jeremáyà 33:26.

“Ṣé obìnrin lè gbàgbé . . . ọmọ tó lóyún rẹ̀?”

4, 5. Báwo ni àpèjúwe tó wà nínú Bíbélì nípa bí abiyamọ ṣe ń ṣàánú ọmọ rẹ̀ jòjòló ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí àánú Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó?

4 Bíbélì lo bí ìyá ṣe ń ṣàánú tàbí yọ́nú sí ọmọ rẹ̀ jòjòló láti fi jẹ́ ká mọ bí àánú tàbí ìyọ́nú Jèhófà ṣe pọ̀ tó. Àìsáyà 49:15 sọ pé: “Ṣé obìnrin lè gbàgbé ọmọ rẹ̀ tó ṣì ń mu ọmú tàbí kó má ṣàánú [ra·chamʹ] ọmọ tó lóyún rẹ̀? Tí àwọn obìnrin yìí bá tiẹ̀ gbàgbé, mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.” Àpèjúwe tó wọni lọ́kàn yẹn jẹ́ ká rí bí àánú tí Jèhófà ní fáwọn èèyàn rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Lọ́nà wo?

5 Kò ṣeé gbọ́ sétí pé abiyamọ kan gbàgbé láti tọ́jú ọmọ rẹ̀ tàbí fún un lóúnjẹ. Ó ṣe tán, ọmọ jòjòló ò lè dá nǹkan kan ṣe, torí náà tọ̀sántòru ni ìyá ẹ̀ gbọ́dọ̀ máa tọ́jú ẹ̀ kó sì máa fìfẹ́ hàn sí i. Àmọ́, ó dunni pé àwọn ìyá kan ti pa ọmọ wọn tì, ní pàtàkì láwọn ‘àkókò tí nǹkan le gan-an’ tá a wà yìí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní “ìfẹ́ àdámọ́ni” mọ́. (2 Tímótì 3:1, 3) Síbẹ̀, Jèhófà sọ pé, “mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.” Kò sígbà tí Jèhófà ò ní máa ṣàánú tàbí yọ́nú sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bó ṣe ń ṣàánú wọn lágbára ju bí abiyamọ ṣe ń yọ́nú sí ọmọ rẹ̀ jòjòló tàbí bó ṣe ń ṣàánú ẹ̀. Abájọ tí òǹkọ̀wé kan fi sọ nípa Àìsáyà 49:15 pé: “Tí kì í bá ṣe ọ̀rọ̀ yìí ló lágbára jù lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ Ọlọ́run, á jẹ́ pé ó wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tó lágbára jù.”

6. Èrò wo lọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa ẹni tó bá lójú àánú, àmọ́ kí ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀?

6 Tẹ́nì kan bá lójú àánú, ṣó túmọ̀ sí pé ojo tàbí òmùgọ̀ lẹni náà? Torí pé àwa èèyàn jẹ́ aláìpé, ọ̀pọ̀ ló gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, onímọ̀ ọgbọ́n orí kan tó jẹ́ gbajúmọ̀, tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Seneca, tó gbé ayé nígbà tí Jésù wà láyé, sọ pé “aláìlera lẹni tó bá ní ojú àánú.” Ó gbà pé ì báà jẹ́ ohun tó dáa ló ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan tàbí ohun tí kò dáa, kò yẹ kí onítọ̀hún fi bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ hàn. Seneca sọ pé ẹni tó gbọ́n lè ran ẹni tó wà nínú wàhálà lọ́wọ́, àmọ́ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí káàánú ẹni náà, torí ìyẹn lè mú kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í banú jẹ́. Àmọ́, ńṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ tara ẹ̀ nìkan, kò sì ní lè fàánú hàn látọkàn wá. Ṣùgbọ́n Jèhófà kì í ṣe irú ẹni bẹ́ẹ̀ rárá! Nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun “ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an, [òun] sì jẹ́ aláàánú.” (Jémíìsì 5:11) A máa rí i nínú orí yìí pé tẹ́nì kan bá lójú àánú kò túmọ̀ sí pé ojo lẹni náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí gbogbo wa lójú àánú. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà tó jẹ́ Bàbá onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń fi àánú àti ìyọ́nú hàn.

Jèhófà Yọ́nú sí Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì

7, 8. Ìyà wo ló jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Íjíbítì, kí sì ni Jèhófà ṣe fún wọn?

7 Tá a bá wo àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, a máa rí i pé ó lójú àánú gan-an. Lẹ́yìn tí Jósẹ́fù kú, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló di ẹrú ní Íjíbítì, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n gan-an. Àwọn ará Íjíbítì “ni wọ́n lára gidigidi bí wọ́n ṣe ń mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekára, wọ́n ń fi àpòrọ́ alámọ̀ àti bíríkì ṣiṣẹ́, wọ́n sì ń mú wọn ṣe onírúurú iṣẹ́.” (Ẹ́kísódù 1:11, 14) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ torí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Báwo nìyẹn ṣe rí lára Jèhófà, kí ló sì ṣe?

8 Àánú wọn ṣe Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ igbe wọn torí àwọn tó ń fipá kó wọn ṣiṣẹ́; mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora.” (Ẹ́kísódù 3:7) Jèhófà ò lè rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ tàbí kó gbọ́ igbe ẹkún wọn láìmọ̀ ọ́n lára. Bá a ṣe rí i ní Orí 24 ìwé yìí, Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò. Bá a sì ṣe mọ̀, ẹni tó bá ń fọ̀rọ̀ ro ara ẹ̀ wò máa ń mọ̀ ọ́n lára táwọn míì bá ń jìyà, èyí sì jọra pẹ̀lú kéèyàn lójú àánú. Àmọ́ kì í ṣe pé Jèhófà kàn mọ ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn ẹ̀ lára nìkan ni, ó tún ṣe ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Àìsáyà 63:9 sọ pé: “Ó tún wọn rà nínú ìfẹ́ rẹ̀ àti ìyọ́nú rẹ̀.” Jèhófà fi “ọwọ́ agbára” gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ kúrò ní Íjíbítì. (Diutarónómì 4:34) Lẹ́yìn ìyẹn, ó tún fàánú hàn sí wọn nípa bó ṣe fún wọn lóúnjẹ nínú aginjù, tó sì mú wọn dé Ilẹ̀ Ìlérí.

9, 10. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ léraléra lẹ́yìn tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Jẹ́fútà, kí ló sì mú kí Jèhófà gbà wọ́n sílẹ̀?

9 Jèhófà ń bá a lọ láti máa fàánú hàn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Ìyà sì máa ń jẹ wọ́n tí wọ́n bá ti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ tó bá tún yá wọ́n máa ń ronú pìwà dà, wọ́n á sì bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Léraléra ló ń gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Kí nìdí? “Nítorí pé àánú àwọn èèyàn rẹ̀ . . . ṣe é.”​—2 Kíróníkà 36:15; Àwọn Onídàájọ́ 2:11-16.

10 Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jẹ́fútà. Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ámónì fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ọdún méjìdínlógún torí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pìwà dà. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n wá kó àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò láàárín wọn, wọ́n sì ń sin Jèhófà, débi pé ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ bí Ísírẹ́lì ṣe ń jìyà.” b (Àwọn Onídàájọ́ 10:6-16) Nígbà táwọn èèyàn Jèhófà fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà látọkàn wá, ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ kí ìyà ṣì máa jẹ wọ́n. Torí náà Ọlọ́run yọ́nú sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fún Jẹ́fútà lágbára láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.​—Àwọn Onídàájọ́ 11:30-33.

11. Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kí ló jẹ́ ká mọ̀ nípa ìyọ́nú tàbí ojú àánú?

11 Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kí ló jẹ́ ká mọ̀ nípa ìyọ́nú tàbí ojú àánú? Ohun kan tá a rí kọ́ ni pé tá a bá fẹ́ fi hàn pé a lójú àánú tàbí pé a máa ń yọ́nú sáwọn èèyàn, ó kọjá pé ká kàn bá wọn kẹ́dùn torí oun kan tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Rántí àpẹẹrẹ ìyá tó gbọ́ tí ọmọ ẹ̀ ń ké tó sì lọ tọ́jú ẹ̀ torí pé àánú ẹ̀ ṣe é. Lọ́nà kan náà, tí Jèhófà bá gbọ́ igbe àwọn èèyàn rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, á sì mú kára tù wọ́n torí pé ó lójú àánú. Ohun míì tá a tún kọ́ ni pé tẹ́nì kan bá lójú àánú, kò túmọ̀ sí pé ojo lẹni náà. Bá a ṣe sọ, torí pé Jèhófà lójú àánú ló fi jà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó sì gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Àmọ́, ṣé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀ nìkan ni Jèhófà máa ń yọ́nú sí ni?

Jèhófà Ń Ṣàánú Àwa Èèyàn Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan

12. Báwo ni Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé àánú àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe Jèhófà?

12 Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi hàn pé àánú àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun bìkítà fáwọn òtòṣì. Jèhófà mọ̀ pé àwọn ohun àìròtẹ́lẹ̀ lè ṣẹlẹ̀, tó lè mú kí ọmọ Ísírẹ́lì kan di tálákà. Báwo ló ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn òtòṣì? Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “O ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní. Kí o lawọ́ sí i dáadáa, kí o má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.” (Diutarónómì 15:7, 10) Jèhófà tún pàṣẹ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe kórè eteetí oko wọn tán, kí wọ́n má sì ṣa irè oko tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀ rárá. Ńṣe ló yẹ kí wọ́n fi irú àwọn irè oko bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ fáwọn aláìní. (Léfítíkù 23:22; Rúùtù 2:2-7) Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà tẹ̀ lé òfin tí Jèhófà ṣe tó mú káwọn èèyàn gba tàwọn òtòṣì àárín wọn rò, àwọn aláìní ní Ísírẹ́lì kò di atọrọjẹ. Ẹ̀rí lèyí jẹ́ pé Jèhófà máa ń ṣojú àánú sáwọn aláìní.

13, 14. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà kò fi ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣeré? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà wà nítòsí “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn” àti “àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn”?

13 Bákan náà lóde òní, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ kò fi ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣeré rárá. Ó dájú pé ó ń rí gbogbo ìyà tó ń jẹ wá. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ojú Jèhófà wà lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́. Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.” (Sáàmù 34:15, 18) Ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé àwọn gbólóhùn náà, “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn” àti “àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn” ń tọ́ka sáwọn tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá torí pé wọ́n máa ń ṣàṣìṣe bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìpé, tí wọ́n sì ń rò pé àwọn ò wúlò. Àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa ronú pé Jèhófà jìnnà sí àwọn, àti pé kò lè rójú ráyè tàwọn, torí pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọ̀rọ̀ Dáfídì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn tó ń ronú pé àwọn ò wúlò, kò sì ní pa wọ́n tì. Jèhófà mọ̀ pé ìgbà tá a bá nírú èrò bẹ́ẹ̀ la nílò òun jù lọ, kì í sì í fi wá sílẹ̀ nírú àsìkò bẹ́ẹ̀ torí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan la ṣe pàtàkì sí i.

14 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìyá kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún méjì ò lè mí dáadáa, ó sì sáré gbé e lọ sílé ìwòsàn. Lẹ́yìn táwọn dókítà yẹ ọmọ náà wò, wọ́n sọ fún ìyá ẹ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ dá ọmọ náà dúró sílé ìwòsàn dọjọ́ kejì. Ṣé ìyá náà máa fi ọmọ ẹ̀ sílẹ̀? Fi í sílẹ̀ kẹ̀! Orí àga tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì ọmọ ẹ̀ nílé ìwòsàn ló sùn mọ́jú! Ohun tí ìyá yẹn ṣe fi hàn pé ó fìwà jọ Baba wa ọ̀run tó jẹ́ olójú àánú! Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:18 wọni lọ́kàn gan-an, ó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ní “ọgbẹ́ ọkàn” tàbí tí “àárẹ̀ bá ẹ̀mí” wa, Jèhófà “wà nítòsí” wa bíi ti òbí onífẹ̀ẹ́ àti olójú àánú, ó ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́.

15. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́?

15 Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́? Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń mú ohun tó ń fìyà jẹ wá kúrò. Àmọ́, Jèhófà ti ṣètò ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè mára tu àwọn tó ń ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fún wa láwọn ìmọ̀ràn gidi tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Nínú ìjọ, Jèhófà fún wa ní àwọn alábòójútó táwọn náà jẹ́ olójú àánú bíi tiẹ̀, tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè máa ràn wá lọ́wọ́. (Jémíìsì 5:14, 15) Bákan náà, torí pé Jèhófà jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà,” ó máa ń “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 65:2; Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí yẹn lè fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ká lè fara dà á dìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ìṣòro kúrò. (2 Kọ́ríńtì 4:7) A mà mọyì àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè yìí o! Ńṣe lèyí jẹ́ ara àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun jẹ́ olójú àánú.

16. Kí ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi àánú hàn sí wa, àǹfààní wo lèyí sì ṣe wá?

16 Àmọ́ o, ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi àánú hàn sí wa ni bó ṣe fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n rà wá pa dà. Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe fún wa lẹ́bùn tó ṣeyebíye yìí, èyí ló sì mú ká nírètí láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Rántí pé torí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni Jésù ṣe kú. Abájọ tí Sekaráyà, bàbá Jòhánù Onírìbọmi fi sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹ̀bùn yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé “ojú àánú Ọlọ́run wa” pọ̀ gan-an.​—Lúùkù 1:78.

Àwọn Ìgbà Tí Jèhófà Fawọ́ Ìyọ́nú Rẹ̀ Sẹ́yìn

17-19. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń yọ́nú sáwọn èèyàn? (b) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi ṣojú àánú sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́?

17 Ṣóhun tá à ń sọ ni pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń yọ́nú sí gbogbo èèyàn? Rárá o. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kì í yọ́nú sáwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí i. (Hébérù 10:28) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ká lè mọ púpọ̀ sí i.

18 Léraléra ni Jèhófà máa ń gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, àmọ́ nígbà tó yá kò fàánú hàn sí wọn mọ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò yéé bọ̀rìṣà, kódà wọ́n ṣe é débi pé wọ́n gbé àwọn òrìṣà náà wọnú tẹ́ńpìlì Jèhófà! (Ìsíkíẹ́lì 5:11; 8:17, 18) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Bíbélì tún sọ pé: “Wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ṣẹ̀sín, wọn ò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí, wọ́n sì ń fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, títí ìbínú Jèhófà fi ru sí àwọn èèyàn rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ wọn sì kọjá àtúnṣe.” (2 Kíróníkà 36:16) Ìwà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń hù wá burú débi pé wọn ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń fàánú hàn sí mọ́. Torí náà, ó tọ̀nà bí Jèhófà ṣe bínú sí wọn. Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí?

19 Ká sòótọ́, Jèhófà ò lè ṣojú àánú sáwọn èèyàn yẹn mọ́. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Mi ò ní yọ́nú sí wọn tàbí kí n bá wọn kẹ́dùn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò ní ṣàánú wọn. Kò sì sí ohun tó máa dá mi dúró láti pa wọ́n run.” (Jeremáyà 13:14) Ìdí nìyẹn tí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ fi pa run, tí wọ́n sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Ó máa ń bani nínú jẹ́ gan-an táwọn èèyàn bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Jèhófà débi pé kò ní lè fàánú hàn sí wọn mọ́!​—Ìdárò 2:21.

20, 21. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí Jèhófà bá ti ṣe sùúrù tó fáwọn èèyàn burúkú? (b) Kí la máa jíròrò nínú orí tó kàn?

20 Ṣé Jèhófà ti wá yí pa dà ni? Rárá o. Torí pé ó lójú àánú, ó pàṣẹ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ máa wàásù “ìhìn rere Ìjọba” náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. (Mátíù 24:14) Nígbà táwọn olóòótọ́ ọkàn bá gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà, Jèhófà máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀. (Ìṣe 16:14) Àmọ́ iṣẹ́ yìí máa dópin lọ́jọ́ kan. Tí Jèhófà bá jẹ́ kí ayé burúkú yìí máa bá a lọ, tí kò fòpin sí wàhálà àti ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn, ìyẹn ò ní fi hàn pé ó lójú àánú. Tí Jèhófà bá ti ṣe sùúrù tó fáwọn èèyàn burúkú, ó máa pa wọ́n run. Ojú àánú ló sì máa mú kó ṣe bẹ́ẹ̀, torí kó lè gbé “orúkọ mímọ́” rẹ̀ ga, kó sì lè gba àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ là. (Ìsíkíẹ́lì 36:20-23) Jèhófà máa mú ìwà burúkú kúrò pátápátá, ó sì máa sọ ayé di tuntun. Jèhófà sọ nípa àwọn ẹni burúkú pé: “Mi ò ní ṣàánú wọn, mi ò sì ní yọ́nú sí wọn. Màá fi ìwà wọn san wọ́n lẹ́san.”​—Ìsíkíẹ́lì 9:10.

21 Ní báyìí tí Jèhófà ò tíì pa ayé burúkú yìí run, ó ṣì ń ṣojú àánú sáwọn èèyàn. Kódà ó ṣì fún àwọn èèyàn burúkú láǹfààní láti yí pa dà. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó ga jù tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun lójú àánú ni bó ṣe múra tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Nínú orí tó kàn, a máa jíròrò àwọn àpèjúwe tí Bíbélì fi ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini pátápátá.

a Àmọ́, ní Sáàmù 103:13 wọ́n lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà ra·chamʹ fún irú àánú, tàbí ojú àánú tí bàbá kan ní sáwọn ọmọ ẹ̀.

b Gbólóhùn náà “ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́” tún lè túmọ̀ sí pé kò lè ṣe sùúrù mọ́. Bíbélì Tanakh​—A New Translation of the Holy Scriptures túmọ̀ rẹ̀ sí pé: “Kò lè fara dà á mọ́ kí ìyà máa jẹ Ísírẹ́lì.”