Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 26

Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

1-3. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì lẹ́yìn tó dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ kí ló mú kára tù ú? (b) Kí ló ṣeé ṣe ká máa rò lẹ́yìn tá a bá dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ kí ni Jèhófà sọ tó fi wá lọ́kàn balẹ̀?

 DÁFÍDÌ kọ̀wé pé: “Àwọn àṣìṣe mi rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí mi; bí ẹrù tó wúwo, wọ́n ti wúwo ju ohun tí mo lè gbé. Ara mi ti kú tipiri, àárẹ̀ sì ti bá mi gidigidi.” (Sáàmù 38:4, 8) Nígbà tí ẹ̀rí ọkàn Dáfídì ń dá a lẹ́bi torí pé ó dẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé ó gbé ẹrù tó wúwo. Àmọ́, ohun kan wà tó mú kára tù ú. Ó mọ̀ pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, kò kórìíra ẹlẹ́ṣẹ̀ náà tó bá ṣáà ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó sì yí pa dà. Ó dá Dáfídì lójú pé ó wu Jèhófà láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Torí náà Dáfídì sọ pé: “Jèhófà, o . . . ṣe tán láti dárí jini.” ​—Sáàmù 86:5.

2 Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀rí ọkàn tiwa náà lè máa dá wa lẹ́bi kó sì dà bíi pé ńṣe la gbé ẹrù tó wúwo. Kò sì burú tí inú wa bá bà jẹ́ torí pé a dẹ́ṣẹ̀. Ìdí ni pé ó lè jẹ́ ká ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ká sì ṣàtúnṣe. Àmọ́, ewu kan wà tó yẹ ká sá fún. Ìyẹn ni pé, ó ṣeé ṣe ká ṣì máa dá ara wa lẹ́bi ká sì máa rò pé Jèhófà ò lè dárí jì wá bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Sátánì fẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, tá a bá jẹ́ kí ‘ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù bò wá mọ́lẹ̀,’ ó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé a ò wúlò mọ́ lójú Jèhófà àti pé irú wa ò yẹ lẹ́ni tó ń sìn ín.​—2 Kọ́ríńtì 2:5-11.

3 Àmọ́, ṣé Jèhófà gbà pé a ò wúlò lóòótọ́? Rárá o! Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ni bó ṣe máa ń dárí jì wá. Nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, òun ṣe tán láti dárí jì wá. (Òwe 28:13) Torí náà, kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ pé Jèhófà lè dárí jì wá. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìdí tí Jèhófà fi máa ń dárí jini àti bó ṣe ń dárí jini kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa dárí jì wá.

Ìdí Tí Jèhófà Fi “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”

4. Kí ni Jèhófà máa ń rántí nípa àwa èèyàn, báwo lèyí ṣe kan bó ṣe ń ṣe sí wa?

4 Jèhófà kì í retí ohun tó kọjá agbára wa. Sáàmù 103:14 sọ pé: “Ó mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” Jèhófà máa ń rántí pé erùpẹ̀ lòun fi dá wa, ó sì mọ̀ pé a lè ṣàṣìṣe nígbà míì torí pé aláìpé ni wá. Gbólóhùn náà ó mọ “ẹ̀dá wa” rán wa létí pé Jèhófà dà bí amọ̀kòkò, a sì dà bí amọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. (Jeremáyà 18:2-6) Bóyá a yàn láti ṣe ohun tó tọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, Jèhófà  máa ń fòye bá gbogbo wa lò torí pé ó mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá kò sì rọrùn fún wa láti ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́ ní gbogbo ìgbà.

5. Báwo ni ìwé Róòmù ṣe ṣàpèjúwe bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lágbára tó?

5 Jèhófà mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lágbára tó. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣàpèjúwe ẹ̀ṣẹ̀ bí agbára tó máa ń darí àwọn èèyàn, tó sì máa ń mú kí wọ́n ṣe ohun tó máa yọrí sí ikú. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lágbára tó? Nínú ìwé Róòmù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: A wà “lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,” bí àwọn ọmọ ogun ṣe máa ń wà lábẹ́ àṣẹ ọ̀gágun wọn (Róòmù 3:9); pé ẹ̀ṣẹ̀ ń “jọba” lórí aráyé bí ọba (Róòmù 5:21); ó “ń gbé” inú wa (Róòmù 7:17, 20); “òfin” rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nínú wa nígbà gbogbo, ó sì fẹ́ máa darí gbogbo nǹkan tá à ń ṣe. (Róòmù 7:23, 25) Ká sòótọ́, ó rọrùn fún ẹ̀ṣẹ̀ láti darí àwa èèyàn torí pé a jẹ́ aláìpé.​—Róòmù 7:21, 24.

6, 7. (a) Tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tó sì bẹ Jèhófà pé kó dárí ji òun, kí ni Jèhófà máa ṣe fún ẹni náà? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú ká wá máa mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀?

6 Torí náà, bó ti wù ká sapá tó láti ṣe ohun tó tọ́, Jèhófà mọ̀ pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣègbọràn sí òun lọ́nà pípé. Àmọ́, ó fi dá wa lójú pé tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn tá a sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, òun máa dárí jì wá. Èyí sì fi wá lọ́kàn balẹ̀. Sáàmù 51:17 sọ pé: “Àwọn ẹbọ tó ń mú inú Ọlọ́run dùn ni ọkàn tó gbọgbẹ́; ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.” Èyí jẹ́ ká rí i pé tí ọkàn ẹnì kan bá “gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú” torí pé ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ń dá a lẹ́bi, ó dájú pé Jèhófà ò ní fi ẹni náà sílẹ̀.

7 Àmọ́, ṣó wá yẹ ká máa mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ torí pé a jẹ́ aláìpé tá a sì mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú? Rárá o! Torí pé Jèhófà jẹ́ aláàánú kò túmọ̀ sí pé ó máa ń gbójú fo ìwà àìtọ́. Àánú rẹ̀ ní ààlà. Ó dájú pé kò ní dárí ji àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, tí wọn ò sì ronú pìwà dà. (Hébérù 10:26) Àmọ́ tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó ṣe tán láti dárí jì í. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tó dáa tí Bíbélì gbà ṣàpèjúwe bí ìfẹ́ ṣe ń sún Jèhófà láti dárí jì wá.

Bí Jèhófà Ṣe Ń Dárí Jini

8. Kí ni Sáàmù 32:5 jẹ́ ká mọ̀ nípa ohun tí Jèhófà máa ń ṣe nígbà tó bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, báwo ló sì ṣe rí lára wa?

8 Lẹ́yìn tí Dáfídì ronú pìwà dà, ó sọ pé: “Níkẹyìn, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ; mi ò bo àṣìṣe mi mọ́lẹ̀. . . . O sì dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi mí.” (Sáàmù 32:5) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí wọ́n tú sí ‘dárí jì’ nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “gbé” tàbí “rù” ní tààràtà. Nínú Sáàmù 32:5, ohun tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run mú “ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìrélànàkọjá” kúrò. Torí náà, ohun tí ibí yìí ń sọ ni pé Jèhófà gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì lọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Ó dájú pé ṣe ló máa dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ẹrù tó wúwo kan kúrò lórí Dáfídì. (Sáàmù 32:3) Àwa náà lè fọkàn balẹ̀ pé Ọlọ́run máa gbé ẹ̀ṣẹ̀ tiwa náà lọ tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù.​—Mátíù 20:28.

9. Báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa tó?

9 Dáfídì lo àpèjúwe míì tó dáa tó jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini. Ó sọ pé: “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.” (Sáàmù 103:12) Oòrùn máa ń yọ ní ìlà oòrùn, ó sì máa ń wọ̀ ní ìwọ̀ oòrùn. Àmọ́ báwo ni ìlà oòrùn ṣe jìnnà tó sí ìwọ̀ oòrùn? Ìlà oòrùn ló jìnnà jù sí ìwọ̀ oòrùn, àwọn méjèèjì ò sì lè pàdé láé. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé gbólóhùn yìí túmọ̀ sí “ibi tó jìnnà gan-an; ibi tó jìnnà jù lọ téèyàn lè ronú kàn.” Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí Dáfídì láti kọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kò ní fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn dá wa lẹ́jọ́ mọ́.

“Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín . . . máa di funfun bíi yìnyín”

10. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa?

10 Ṣó o ti gbìyànjú láti mú àbààwọ́n kúrò lára aṣọ funfun rí? Pẹ̀lú gbogbo bó o ṣe fọ̀ ọ́ tó, àbààwọ́n náà ò kúrò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà sọ tó jẹ́ ká mọ bí ìdáríjì rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ó ní: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín; bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò, wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.” (Àìsáyà 1:18) Bó ṣe wù ká gbìyànjú tó, a ò lè mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò fúnra wa. Àmọ́ Jèhófà lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ tó pupa bí aṣọ rírẹ̀dòdò tàbí èyí tó pọ́n yòò di funfun gbòò bí ìrì dídì tàbí bí irun àgùntàn tí a kò tíì pa láró. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kò yẹ ká máa rò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.

11. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ju ẹ̀ṣẹ̀ wa sẹ́yìn ara rẹ̀?

11 Lẹ́yìn tí Jèhófà mú Hẹsikáyà lára dá nígbà tó ń ṣàìsàn kan tí ì bá gbẹ̀mí ẹ̀, ó kọ orin kan tó wọni lọ́kàn láti fi dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ó sọ pé: “O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.” (Àìsáyà 38:17) Ọ̀rọ̀ tí Hẹsikáyà sọ yìí fi hàn pé ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan tó ti ronú pìwà dà, táá sì jù ú sẹ́yìn ara rẹ̀, níbi tí kò ti ní rí i mọ́. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé ọ̀nà míì téèyàn lè gbà sọ ọ̀rọ̀ Hẹsikáyà yìí ni pé: “O ti jẹ́ kí [ẹ̀ṣẹ̀ mi] dà bí èyí tí kò tiẹ̀ wáyé rí rárá.” Ẹ ò rí i pé èyí fini lọ́kàn balẹ̀!

12. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí wòlíì Míkà sọ ṣe fi hàn pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ńṣe ló máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá?

12 Nígbà tí wòlíì Míkà ń sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe láti mú àwọn èèyàn ẹ̀ pa dà bọ̀ sípò, ó sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó dá a lójú pé Jèhófà máa dárí ji àwọn èèyàn ẹ̀ tó ronú pìwà dà. Ó ní: ‘Ta ló dà bí rẹ Ọlọ́run, ẹni tó ń gbójú fo ìṣìnà àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún rẹ̀? O máa ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí ìsàlẹ̀ òkun.’ (Míkà 7:18, 19) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn máa yé àwọn tó gbé ayé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àbí, tí wọ́n bá ju nǹkan “sí ìsàlẹ̀ òkun,” ṣé èèyàn lè rí i yọ? Rárá o. Torí náà, ọ̀rọ̀ Míkà fi hàn pé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ńṣe ló máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò pátápátá.

13. Kí ni gbólóhùn náà “dárí àwọn gbèsè wa jì wá” túmọ̀ sí?

13 Jésù fi ọ̀rọ̀ ẹni tó yáni lówó àti ẹni tó jẹ gbèsè ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Jésù sọ pé ká máa gbàdúrà pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá.” (Mátíù 6:12) Jésù tipa báyìí fi ẹ̀ṣẹ̀ wé gbèsè. (Lúùkù 11:4) Nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀, “gbèsè” la jẹ Jèhófà yẹn. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘dárí jì’ túmọ̀ sí pé “kẹ́nì kan yọ̀ǹda owó tí wọ́n jẹ ẹ́, kó gbójú fò ó, kó má sì béèrè mọ́.” Èyí túmọ̀ sí pé tí Jèhófà bá dárí jì wá, ṣe ló fagi lé gbèsè tá a jẹ ẹ́. Torí náà, káwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ti ronú pìwà dà lọ fọkàn balẹ̀. Jèhófà ò ní sìn wá ní gbèsè tó ti fagi lé láé!​—Sáàmù 32:1, 2.

14. Báwo ni gbólóhùn náà “kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́” ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe ń dárí jini?

14 Ìṣe 3:19 tún gba ọ̀nà míì ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini pátápátá. Ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí pa dà, kí Ọlọ́run lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí ‘pa rẹ́’ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tún lè túmọ̀ sí “láti nu nǹkan kúrò, . . . fagi lé nǹkan tàbí pa nǹkan run.” Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ńṣe ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń ṣàpèjúwe béèyàn ṣe lè pa ohun tẹ́nì kan fọwọ́ kọ rẹ́. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe láyé ìgbà yẹn? Bẹ́ẹ̀ ni. Àpòpọ̀ èédú, oje igi àti omi ni wọ́n sábà máa ń fi ṣe yíǹkì láyé àtijọ́. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi irú yíǹkì bẹ́ẹ̀ kọ̀wé tán, ó lè fi kànrìnkàn tó ti rẹ sínú omi pa ohun tó kọ rẹ́. Àpèjúwe tó wọni lọ́kàn yìí jẹ́ ká rí i pé àánú Jèhófà pọ̀ gan-an, ó sì máa ń dárí jini! Tó bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ńṣe ló dà bíi pé ó fi kànrìnkàn nu ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò.

15. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ nípa òun?

15 Àwọn àpèjúwe yìí jẹ́ ká túbọ̀ rí i pé ńṣe ni Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun ṣe tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, tó bá rí i pé a ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Torí náà, kò yẹ ká máa bẹ̀rù pé ó ṣì máa fìyà jẹ wá nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ohun míì nípa àánú ńlá Jèhófà tó jẹ́ kí èyí túbọ̀ dá wa lójú, ìyẹn ni pé: Tó bá ti dárí jini, ó gbàgbé ọ̀rọ̀ náà nìyẹn.

Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun “ṣe tán láti dárí jini”

‘Mi Ò Ní Rántí Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn Mọ́’

16, 17. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà ò ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́, kí sì nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

16 Jèhófà ṣèlérí fáwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun pé: “Màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” (Jeremáyà 31:34) Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé tí Jèhófà bá dárí jini, kò lè rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́? Rárá o. Ọ̀pọ̀ èèyàn tí Jèhófà dárí jì ni àkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára wọn ni Dáfídì. (2 Sámúẹ́lì 11:1-17; 12:13) Ó dájú pé Jèhófà ṣì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn, bí wọ́n ṣe ronú pìwà dà àti bí Ọlọ́run ṣe dárí jì wọ́n wà ní àkọsílẹ̀ fún àǹfààní wa. (Róòmù 15:4) Kí wá ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé tí Jèhófà bá ti dárí jini, kì í “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ yẹn mọ́?

17 Ọ̀rọ̀ ìṣe inú èdè Hébérù tá a tú sí ‘mi ò ní rántí mọ́’ kò mọ sórí pé kéèyàn kàn rántí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Ìwé Theological Wordbook of the Old Testament sọ pé “téèyàn bá rántí nǹkan, ó tún túmọ̀ sí pé kí onítọ̀hún ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀.” Torí náà nínú ọ̀rọ̀ yìí, ohun tí “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí ni láti fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan. (Hóséà 9:9) Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run sọ pé “mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́,” ó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tí òun bá ti lè dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, òun ò tún ní fìyà ẹ̀ṣẹ̀ yẹn jẹ ẹ́ mọ́ lọ́jọ́ iwájú. (Ìsíkíẹ́lì 18:21, 22) Èyí jẹ́ ká rí i pé tí Jèhófà bá ti gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í ronú nípa ẹ̀ mọ́ tàbí kó máa wá fìyà rẹ̀ jẹ wá léraléra. Ká sòótọ́, ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé tí Ọlọ́run wa bá ti dárí jì wá, kì í rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́!

Àbájáde Ẹ̀ṣẹ̀ Ńkọ́?

18. Tí Jèhófà bá tiẹ̀ dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà, báwo la ṣe mọ̀ pé ìyẹn ò ní kó má jìyà àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

18 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ẹni náà máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ìwà àìtọ́ rẹ̀? Rárá o. Téèyàn bá ṣe nǹkan tí kò dáa, ó máa jìyà ẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” (Gálátíà 6:7) Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ó lè mú ká láwọn ìṣòro kan. Èyí ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ló ń fìyà jẹ wá lẹ́yìn tó ti dárí jì wá. Tí Kristẹni kan bá níṣòro, kò yẹ kó máa ronú pé, ‘Àbí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti dá sẹ́yìn ni Jèhófà ń fìyà ẹ̀ jẹ mí ni?’ (Jémíìsì 1:13) Àmọ́, ó tún yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í gbà wá lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ wa. Lára àwọn ohun ìbànújẹ́ tó lè jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ ni ìkọ̀sílẹ̀ tàbí oyún ẹ̀sín. Bákan náà, èèyàn lè kó àrùn látinú ìṣekúṣe, ó lè dẹni táwọn èèyàn ò fọkàn tán mọ́ tàbí kó dẹni ẹ̀tẹ́. Rántí pé, lẹ́yìn tí Jèhófà dárí ji Dáfídì nígbà tó bá Bátí-ṣébà ṣèṣekúṣe, tó sì ní kí wọ́n pa Ùráyà, Jèhófà ò dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn àjálù tó dé bá a torí ohun tó ṣe.​—2 Sámúẹ́lì 12:9-12.

19-21. (a) Báwo ni òfin tó wà nínú Léfítíkù 6:1-7 ṣe ṣàǹfààní fún ẹni tá a ṣẹ̀ àti ẹni tó ṣẹ̀? (b) Tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ṣàkóbá fáwọn míì, kí ló yẹ ká ṣe ká lè múnú Jèhófà dùn?

19 Ohun míì wà tó tún lè jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan dá, ní pàtàkì tí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá ṣàkóbá fáwọn míì. Àpẹẹrẹ kan lohun tó wà nínú Léfítíkù orí kẹfà. Orí yìí sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó jí nǹkan ìní ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀ tàbí tó lù ú ní jìbìtì, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá lèyí sì jẹ́ lábẹ́ Òfin Mósè. Ẹlẹ́ṣẹ̀ náà wá sọ pé ńṣe ni wọ́n ń parọ́ mọ́ òun, ó sì tún ń búra èké. Torí pé kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó jẹ̀bi, wọn ò fìyà jẹ ẹ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í da ẹlẹ́ṣẹ̀ náà láàmú, ó sì wá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n kí Ọlọ́run tó lè dárí jì í, ó gbọ́dọ̀ ṣe ohun mẹ́ta yìí: kó dá ohun tó jí pa dà, kó san owó ìtanràn fún ẹni tó jí nǹkan ẹ̀, ìyẹn ìdá márùn-ún ohun tó jí, kó sì fi àgbò kan rú ẹbọ ẹ̀bi. Òfin wá sọ pé: “Kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà, yóò sì rí ìdáríjì.”​—Léfítíkù 6:1-7.

20 Torí pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú ló ṣe ṣòfin yìí. Ó ṣàǹfààní fún ẹni tí wọ́n dá nǹkan rẹ̀ pa dà, ó sì dájú pé ara máa tù ú nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bákan náà, òfin náà ṣàǹfààní fún ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, tó sì ṣàtúnṣe. Àmọ́, ká ní kò jẹ́wọ́, tí kò sì ṣàtúnṣe ni, Ọlọ́run ò ní dárí jì í.

21 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, Òfin yẹn jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà, títí kan ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe kó tó lè dárí jì wá. (Kólósè 2:13, 14) Tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ṣàkóbá fáwọn míì, inú Ọlọ́run máa ń dùn tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣàtúnṣe ọ̀rọ̀ náà. (Mátíù 5:23, 24) Lára ohun tá a lè ṣe ni pé ká gbà pé a jẹ̀bi, ká sì bẹ ẹni tá a ṣẹ̀ pé kó dárí jì wá. Lẹ́yìn náà, a lè wá bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ pé ó ti dárí jì wá.​—Hébérù 10:21, 22.

22. Tí Jèhófà bá tiẹ̀ dárí jì wá, kí ló tún máa ń ṣe nígbà míì torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa?

22 Bí òbí onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń ṣe, tí Jèhófà bá dárí jì wá ó tún lè bá wa wí díẹ̀. (Òwe 3:11, 12) Bí àpẹẹrẹ, tí alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà kan bá tiẹ̀ ronú pìwà dà, àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn ṣì lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ó lè dùn ún pé òun máa pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tóun fẹ́ràn gan-an fún àkókò kan. Àmọ́, irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé Jèhófà ò dárí jì í. Ká má gbàgbé pé, torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ló ṣe máa ń bá wa wí. Ó sì dájú pé tá a bá gba ìbáwí náà, ó máa ṣe wá láǹfààní gan-an.​—Hébérù 12:5-11.

23. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa dárí ji àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà?

23 Ó tuni lára láti mọ̀ pé Ọlọ́run wa “ṣe tán láti dárí jini”! Àṣìṣe yòówù ká ṣe, a ò gbọ́dọ̀ ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá. Tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tá a ṣàtúnṣe tó yẹ, tá a sì gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, ó dájú pé ó máa dárí jì wá. (1 Jòhánù 1:9) Ó yẹ ká fara wé Jèhófà, ká máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá. Ká máa rántí pé Jèhófà kì í dẹ́ṣẹ̀, síbẹ̀ ó máa ń fìfẹ́ dárí jì wá. Ṣé kò wá yẹ káwa tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa dárí ji ara wa?