Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 31

“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Á sì Sún Mọ́ Yín”

“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Á sì Sún Mọ́ Yín”

1-3. (a) Tá a bá ń kíyè sí àjọṣe àárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn jòjòló, kí la lè rí kọ́ nípa ìwà àti ìṣe àwa èèyàn? (b) Táwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn sí wa, kí la máa ń fẹ́ ṣe, ìbéèrè pàtàkì wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

 INÚ àwọn òbí máa ń dùn tí wọ́n bá rí i tí ọmọ wọn jòjòló rẹ́rìn-ín. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n á wo ojú ọmọ náà ní tààràtà, wọ́n á fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bá a sọ̀rọ̀, wọ́n á sì rẹ́rìn-ín sí i. Wọ́n á wá máa retí kí ọmọ náà rẹ́rìn-ín pa dà. Kò sì ní pẹ́ tí wọ́n á fi rí i tọ́mọ náà á la ẹnu ẹ̀, táá sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Ẹ̀rín yẹn ló fi hàn pé ọmọ náà ń fìfẹ́ hàn pa dà sáwọn òbí ẹ̀.

2 Bí ọmọ jòjòló ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́ rán wa létí ohun pàtàkì kan nípa àwa èèyàn. Tẹ́nì kan bá fìfẹ́ hàn sí wa, ó máa ń wu àwa náà ká fìfẹ́ hàn sí i pa dà, torí pé bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn. (Sáàmù 22:9) Bá a ṣe ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ la túbọ̀ ń mọ bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa. Ó ṣeé ṣe kó o rántí bí àwọn òbí, ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fìfẹ́ hàn sí ẹ nígbà tó o ṣì kéré. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú ẹ dùn gan-an, o sì fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ wọn. Bó o ṣe wá ń dàgbà, ó wù ẹ́ kíwọ náà fìfẹ́ hàn sí wọn pa dà. Ṣé bó ṣe rí náà nìyẹn nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run?

3 Bíbélì sọ pé: “A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Ní Apá 1 sí Apá 3 nínú ìwé yìí, a sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ń fìfẹ́ lo agbára rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà kó lè ṣe wá láǹfààní. Bákan náà, ní Apá 4, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí àwa èèyàn lápapọ̀ àti sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Torí náà, ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ ká bi ara wa, ìbéèrè náà ni pé: ‘Kí ni mo lè ṣe láti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́?’

Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

4. Tó bá dọ̀rọ̀ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí ni èrò ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí?

4 Torí pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìfẹ́ ti wá, ó mọ̀ pé tá a bá fìfẹ́ hàn sẹ́nì kan, ó lè mú ká rí àwọn ìwà tó dáa tẹ́ni náà ní. Ìyẹn ló mú kó dá Jèhófà lójú pé bí ọ̀pọ̀ èèyàn bá tiẹ̀ kẹ̀yìn sí òun, àwọn kan ṣì máa ṣohun tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Àìmọye èèyàn ló sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Àmọ́, ohun táwọn ẹ̀sìn èké tó kúnnú ayé tí Sátánì ń darí yìí ń kọ́ àwọn èèyàn kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó túmọ̀ sí láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni pé táwọn bá ṣáà ti ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn náà ti tó. Lóòótọ́, kò burú láti sọ pé èèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kódà ńṣe ló dà bí ìgbà tí ọmọ ọwọ́ kan rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn òbí ẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ọmọ náà bá ṣe ń dàgbà, ó gbọ́dọ̀ máa ṣàwọn nǹkan míì táá fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí ẹ̀.

5. Kí ni Bíbélì sọ pé ó yẹ ká máa ṣe ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀?

5 Jèhófà sọ ohun tó yẹ ká ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òun. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́” Èyí jẹ́ ká rí i pé a ò kàn lè fẹnu lásán sọ pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó yẹ kó hàn nínú ìwà wa. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ kẹ́nì kankan máa sọ ohun táwọn máa ṣe fáwọn. Ṣùgbọ́n, ẹsẹ yìí kan náà fi ọ̀rọ̀ kan tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ kún un, ó ní: “Síbẹ̀ àwọn àṣẹ [Ọlọ́run] kò nira.” (1 Jòhánù 5:3) Àǹfààní wa làwọn òfin àti ìlànà Jèhófà wà fún, kì í ṣe láti ni wá lára. (Àìsáyà 48:17, 18) Ọ̀pọ̀ ìlànà ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó yẹ ká máa ṣe ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn nǹkan náà ni: Ká máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, ká máa jọ́sìn Ọlọ́run, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Máa Bá Jèhófà Sọ̀rọ̀, Kó O sì Máa Fetí sí I

6-8. (a) Báwo la ṣe lè fetí sí Jèhófà? (b) Báwo la ṣe lè máa ka Bíbélì lọ́nà táá fi máa dùn mọ́ wa?

6 Ìbéèrè tá a fi bẹ̀rẹ̀ orí kìíní ìwé yìí ni pé, “Ká ní o kàn dédé gbọ́ ohùn Ọlọ́run, tó ń bá ẹ sọ̀rọ̀, kí lo máa ṣe ná?” Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sáwọn kan rí nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run ran áńgẹ́lì sí Mósè kó lè bá a sọ̀rọ̀. Àmọ́, ṣé Ọlọ́run ṣì ń bá àwa èèyàn sọ̀rọ̀ lóde òní? Jèhófà kì í rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti bá wa sọ̀rọ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà láwọn ọ̀nà tó dáa gan-an tó gbà ń bá wa sọ̀rọ̀ lóde òní. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀, báwo la sì ṣe lè fetí sí i?

7 Torí pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,” tá a bá ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ńṣe là ń fetí sí i. (2 Tímótì 3:16) Ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà fi rọ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “tọ̀sántòru.” (Sáàmù 1:1, 2) Èyí kì í ṣohun tó rọrùn o, ṣùgbọ́n tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jàǹfààní púpọ̀. Ní Orí 18 ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé ńṣe ni Bíbélì dà bí lẹ́tà pàtàkì kan tí Baba wa ọ̀run kọ sí wa. Torí náà, kò yẹ kó máa ro wá lójú láti kà á. Ó yẹ ká máa ka Bíbélì lọ́nà táá fi máa dùn mọ́ wa. Báwo la ṣe lè ṣe é?

8 Bó o ṣe ń ka Bíbélì, máa fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ò ń ka ìtàn wọn. Gbìyànjú láti mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́, bí ìgbé ayé wọn ṣe rí, ìdí tí wọ́n fi ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe àti ipò tí wọ́n wà. Lẹ́yìn náà, ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó o kà, kó o sì bi ara ẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ni ìtàn yìí kọ́ mi nípa Jèhófà? Èwo lára àwọn ìwà àti ìṣe ẹ̀ ni ìtàn yìí gbé yọ? Ìlànà wo ni Jèhófà fẹ́ kí n mọ̀ nínú ìtàn yìí, báwo sì ni mo ṣe lè lò ó nínú ìgbésí ayé mi?’ Tó o bá fẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ẹ́ láǹfààní, máa kà á, máa ṣàṣàrò lé e lórí, kó o sì máa fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á jẹ́rìí sí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára.​—Sáàmù 77:12; Jémíìsì 1:23-25.

9. Ta ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa fetí sí “ẹrú” náà?

9 Jèhófà tún ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà. Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ó yan àwọn ọkùnrin bíi mélòó kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró kí wọ́n lè máa pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tó yẹ” láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí nǹkan nira yìí. (Mátíù 24:45-47) Ẹrú yẹn ń bọ́ wa nípasẹ̀ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì, àwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí  ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Torí náà, ó yẹ ká máa fetí sí ẹrú olóòótọ́ tí Kristi yàn náà, torí pé Jèhófà ń lò ó láti bá wa sọ̀rọ̀.

10-12. (a) Kí nìdí tí àdúrà fi jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu látọ̀dọ̀ Jèhófà? (b) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wa, kí ló sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ó wu Jèhófà láti gbọ́ àdúrà wa?

10 A ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀, àmọ́ ṣé àwa náà lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀? Tá a bá ronú lórí ìbéèrè yìí, ó lè kọ́kọ́ kà wá láyà. Ká sọ pé o fẹ́ lọ sọ ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn fún olórí orílẹ̀-èdè rẹ, ṣé o rò pé wàá lè rí i bá sọ̀rọ̀? Kódà nígbà míì, ńṣe ló máa dà bíi pé o fi ẹ̀mí ara ẹ sínú ewu tó o bá gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀! Nígbà ayé Ẹ́sítà àti Módékáì, ńṣe ni wọ́n máa pa ẹni tó bá lọ yọjú sí ọba Páṣíà láìjẹ́ pé kábíyèsí fúnra ẹ̀ pè é. (Ẹ́sítà 4:10, 11) Ní ti Jèhófà ńkọ́? Òun ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, ipò rẹ̀ sì ga ju ti ẹnikẹ́ni lọ. Kódà, ńṣe làwọn èèyàn tó wà nípò gíga “dà bíi tata” lójú ẹ̀. (Àìsáyà 40:22) Ṣó wá yẹ ká máa bẹ̀rù àtibá Jèhófà sọ̀rọ̀? Rárá o!

11 Jèhófà fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀, ó sì ṣe ohun táá mú kíyẹn ṣeé ṣe ní ti bó ṣe fún wa láǹfààní láti máa gbàdúrà. Kódà, ọmọ kékeré kan lè gbàdúrà sí Jèhófà lórúkọ Jésù, kó sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà náà. (Jòhánù 14:6; Hébérù 11:6) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, a lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un, bí nǹkan ṣe rí lára wa àtàwọn nǹkan míì tá ò lè sọ fún èèyàn èyíkéyìí. (Róòmù 8:26) Kò dìgbà tá a bá jẹ́ ẹni tó mọ ọ̀rọ̀ sọ dáadáa ká tó lè gbàdúrà sí Jèhófà, kì í sì í ṣe bí ọ̀rọ̀ tá a lò nínú àdúrà wa bá ṣe dùn tó tàbí gùn tó láá mú kí Jèhófà gbọ́ wa. (Mátíù 6:7, 8) Ó ṣe tán, Jèhófà fúnra ẹ̀ ò ṣòfin nípa bí àdúrà wa ṣe gbọ́dọ̀ gùn tó, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ iye ìgbà tá a lè gbàdúrà sí òun. Kódà, ńṣe ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé ká “máa gbàdúrà nígbà gbogbo.”​—1 Tẹsalóníkà 5:17.

12 Ṣé o rántí pé Jèhófà nìkan ni Bíbélì pè ní “Olùgbọ́ àdúrà” àti pé ó máa ń tẹ́tí sí wa, ó sì múra tán láti ràn wá lọ́wọ́? (Sáàmù 65:2) Ṣé ó kàn ń rọ́jú gbọ́ àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ni? Rárá o, kódà ṣe ni inú ẹ̀ máa ń dùn táwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ bá gbàdúrà sí i. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi àdúrà wọn wé tùràrí, tí òórùn èéfín ẹ̀ máa ń mára tuni nígbà tí wọ́n bá ń sun ún. (Sáàmù 141:2; Ìfihàn 5:8; 8:4) Àfiwé yìí jẹ́ ká rí i pé inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tó bá gbọ́ àdúrà tá a gbà sí i látọkàn wá. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Torí náà, tó o bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà, máa fi ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí i ní gbogbo ìgbà. Máa sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún un. (Sáàmù 62:8) Jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan tó ń kó ẹ lọ́kàn sókè àtàwọn nǹkan tó ń múnú ẹ dùn, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kó o sì máa sọ àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó o fẹ́ràn jù lọ. Èyí á jẹ́ kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú ẹ̀ túbọ̀ máa lágbára sí i.

Bá a Ṣe Ń Jọ́sìn Jèhófà

13, 14. Kí ló túmọ̀ sí láti sin Jèhófà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

13 A ti rí i pé bá a ṣe ń bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀, tá a sì ń tẹ́tí sí i, bẹ́ẹ̀ lòun náà ń bá wa sọ̀rọ̀ tó sì ń tẹ́tí sí wa. Àmọ́, bí àwa àti Jèhófà ṣe ń bára wa sọ̀rọ̀ yàtọ̀ sí bá a ṣe ń bá àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa sọ̀rọ̀. Kì í ṣe pé ẹnì kan ń sọ̀rọ̀ tí ẹnì kejì kàn ń tẹ́tí sílẹ̀ lásán, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń jọ́sìn Jèhófà, tá a sì ń bọ̀wọ̀ fún un bá a ṣe jọ ń sọ̀rọ̀. Ìjọsìn tòótọ́ kan gbogbo ìgbésí ayé wa látòkè délẹ̀. Bá a ṣe ń jọ́sìn Jèhófà ló ń jẹ́ ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ látọkàn wá àti pé a múra tán láti fi gbogbo ọkàn wa ṣe ohun tó fẹ́. Ìjọsìn yìí ló sì so gbogbo olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà pọ̀ láyé àti lọ́run. Nínú ìran tí Ọlọ́run fi han àpọ́sítélì Jòhánù, ó gbọ́ tí áńgẹ́lì kan kéde pé: “Ẹ jọ́sìn ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.”​—Ìfihàn 14:7.

14 Kí nìdí tó fi yẹ ká sin Jèhófà? Ronú nípa àwọn ànímọ́ tá a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú ìwé yìí. Bí àpẹẹrẹ, a ti sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́mímọ́, agbára, ìkóra-ẹni-níjàánu, ìdájọ́ òdodo, ìgboyà, àánú, ọgbọ́n, ìrẹ̀lẹ̀, ìfẹ́, ìyọ́nú, ìdúróṣinṣin àti oore. A ti rí i pé Jèhófà nìkan ló ní gbogbo ànímọ́ yìí lọ́nà tó ga jù lọ. Tá a bá gbìyànjú láti lóye bí Jèhófà ṣe ń fi àwọn ànímọ́ yìí hàn, àá rí i pé Jèhófà kọjá ẹni tó yẹ ká kàn máa kan sáárá sí. Atóbilọ́la ni, ọ̀nà rẹ̀ sì ga ju tàwa èèyàn lọ. (Àìsáyà 55:9) Ó dájú pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso wa, òun ló sì yẹ ká máa sìn. Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe yẹ ká máa sin Jèhófà?

15. Báwo la ṣe lè sin Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́,” báwo ni àwọn ìpàdé Kristẹni sì ṣe ń jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀?

15 Jésù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ká tó lè máa sin Ọlọ́run “ní ẹ̀mí” a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí Ọlọ́run, ká sì jẹ́ kó máa darí wa. Bákan náà, ìjọsìn wa gbọ́dọ̀ wà níbàámu pẹ̀lú òtítọ́, ìyẹn ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti sin Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” ní gbogbo ìgbà tá a bá pé jọ pẹ̀lú àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Hébérù 10:24, 25) Tá a bá ń kọrin ìyìn sí Jèhófà, tá à ń gbàdúrà sí i pa pọ̀, tá à ń fetí sí ohun tí wọ́n ń sọ látinú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tá a sì ń dáhùn nígbà tó bá yẹ, ńṣe là ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́.

Àwọn ìpàdé Kristẹni máa ń jẹ́ ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì bọ̀wọ̀ fún un

16. Kí ni ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àṣẹ tó ga jù lọ tí Jésù pa fáwa Kristẹni tòótọ́, kí sì nìdí tó fi ń wù wá pé ká pa àṣẹ náà mọ́?

16 A tún ń jọ́sìn Jèhófà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn, torí pé ńṣe nìyẹn máa ń mú ká yìn ín ní gbangba. (Hébérù 13:15) Ká sòótọ́, ọ̀kan pàtàkì lára àwọn àṣẹ tó ga jù lọ tí Jésù pa fáwa Kristẹni tòótọ́ ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tọkàntọkàn la fi ń pa àṣẹ yìí mọ́. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tó o bá ronú nípa bí Sátánì Èṣù, tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ṣe ń “fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́” nípa bó ṣe ń parọ́ mọ́ Jèhófà? Ṣé kì í ṣe ẹ́ bíi pé kó o gbèjà Jèhófà, kó o sì já irọ́ Sátánì? (2 Kọ́ríńtì 4:4; Àìsáyà 43:10-12) Tó o bá sì ronú nípa àwọn àgbàyanu ànímọ́ Jèhófà, ṣé kì í yá ẹ lára láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn? Ká sòótọ́, kò sí àǹfààní míì tó ga tó ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ Baba wa ọ̀run, káwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

17. Àwọn nǹkan míì wo la lè ṣe táá fi hàn pé à ń jọ́sìn Jèhófà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa fi gbogbo ọkàn wa sìn ín?

17 Ìjọsìn wa sí Jèhófà tún kan gbogbo ohun tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa. (Kólósè 3:23) Tá a bá gbà pé Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ wa lóòótọ́, gbogbo ìgbà lá máa wù wá ká ṣe ohun tó fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àá máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nígbà tá a bá wà pẹ̀lú ìdílé wa, tá a bá wà níbi iṣẹ́ àti nígbà tá a bá dá wà, àá sì máa tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀ nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Àá máa gbìyànjú láti ṣe ohun tí Bíbélì sọ, pé ká “fi gbogbo ọkàn” wa sin Jèhófà. (1 Kíróníkà 28:9) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá a sì ń fi gbogbo ọkàn wa sìn ín, a ò ní máa ṣe bíi pé à ń ṣe ohun tó fẹ́ lójú àwọn èèyàn, ká sì tún máa yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á mú ká kórìíra irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ohun míì tó tún máa ràn wá lọ́wọ́ ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, àá máa bọ̀wọ̀ fún un, àá sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Bíbélì sì sọ pé ìyẹn ló máa jẹ́ ká lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.​—Sáàmù 25:14.

Máa Fara Wé Jèhófà

18, 19. Kí ló mú ká gbà pé àwa èèyàn aláìpé lè fara wé Jèhófà Ọlọ́run?

18 Orí tó gbẹ̀yìn apá kọ̀ọ̀kan inú ìwé yìí dá lórí bá a ṣe lè “máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.” (Éfésù 5:1) Ó yẹ ká rántí pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, a ṣì lè fara wé Jèhófà bó ṣe ń lo agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́ rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwa èèyàn aláìpé lè fara wé Olódùmarè? Ẹ rántí pé orúkọ náà Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé ó lè di ohunkóhun tó bá fẹ́ kó lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Èyí jọni lójú gan-an, ó sì yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe rárá láti fara wé Jèhófà ni? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀.

19 Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ìyẹn ló mú káwa èèyàn yàtọ̀ sáwọn nǹkan míì tí Jèhófà dá sáyé. Kì í ṣe ọgbọ́n àdámọ́ni, ìwà tí wọ́n bí mọ́ wa tàbí àwọn tó wà láyìíká wa nìkan ló ń mú wa ṣe àwọn ohun tá à ń ṣe. Jèhófà fún wa ní ẹ̀bùn iyebíye kan, ìyẹn ni òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, tá a sì ní ibi tá a kù sí, a lómìnira láti pinnu irú ẹni tá a fẹ́ jẹ́. Ó yẹ ká rántí pé orúkọ Jèhófà tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó lè mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ di ohunkóhun tó bá fẹ́. Ṣó wù ẹ́ láti jẹ́ onífẹ̀ẹ́, ọlọgbọ́n àti olódodo tí kì í ṣi agbára lò? Ẹ̀mí Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di irú ẹni bẹ́ẹ̀! Wàá rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni wàá lè ṣe.

20. Tá a bá ń fara wé Jèhófà, àwọn nǹkan rere wo la máa ṣe?

20 Ká sòótọ́, wàá múnú Jèhófà dùn, wàá sì mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Kódà, o lè “ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún,” torí pé ó mọ ibi tí agbára rẹ mọ. (Kólósè 1:9, 10) Bó o sì ṣe ń túbọ̀ fara wé Bàbá rẹ onífẹ̀ẹ́, tó ò ń fìwà jọ ọ́, wàá ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan. Nínú ayé táwọn èèyàn ò ti ṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí, wàá máa tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ kí wọ́n lè wá mọ Ọlọ́run. (Mátíù 5:1, 2, 14) Bó o ṣe ń fìwà jọ Jèhófà, wàá lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní. O ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn jẹ́!

“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Á sì Sún Mọ́ Yín”

Túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà

21, 22. Kí làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà á máa ṣe títí láé?

21 Ohun tí Jémíìsì 4:8 gbà wá níyànjú pé ká ṣe yìí kì í ṣe ohun téèyàn ń ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, tàbí téèyàn á ṣe fúngbà díẹ̀, táá sì dáwọ́ dúró. Ohun tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe lọ títí láé ni tá a bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Títí láé làá túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà. Ó ṣe tán, gbogbo ìgbà làá máa rí nǹkan kọ́ nípa rẹ̀. Ká má rò pé ìwé yìí ti kọ́ wa ní gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa Jèhófà. Díẹ̀ la ṣì sọ nínú gbogbo ohun tí Bíbélì kọ́ wa nípa Ọlọ́run wa! Kódà, Bíbélì ò sọ gbogbo ohun tá a lè mọ̀ nípa Jèhófà fún wa. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé tá a bá ní ká kọ gbogbo ohun tí Jésù ṣe nígbà tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, “ayé pàápàá ò ní lè gba àwọn àkájọ ìwé tí a bá kọ ọ́ sí.” (Jòhánù 21:25) Tá a bá lè sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa Ọmọ Ọlọ́run, mélòómélòó wá ni ti Baba fúnra rẹ̀!

22 Kódà, tá a bá wà láàyè títí láé, àá ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Oníwàásù 3:11) Tiẹ̀ ronú nípa bó ṣe máa rí. Lẹ́yìn tá a bá ti gbé ayé fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún, kódà fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún, ohun tá a ti máa mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run máa pọ̀ ju ohun tá a mọ̀ báyìí lọ. Àmọ́, a ṣì máa rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu la ò tíì mọ̀ nípa Jèhófà. Á máa wù wá láti mọ̀ sí i, torí pé gbogbo ìgbà làá máa ronú bíi ti onísáàmù tó kọ ọ́ lórin pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” (Sáàmù 73:28) A ò tiẹ̀ lè finú yàwòrán bí ayé nínú Párádísè ṣe máa dùn tó. Àmọ́ ohun tó máa múnú wa dùn jù ni bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà lójoojúmọ́.

23. Kí ló máa dáa kó o ṣe?

23 Á dáa kíwọ náà fi hàn báyìí pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó o fi gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ara rẹ, gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Máàkù 12:29, 30) Jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, má sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ yẹ̀ láé. Nínú gbogbo ìpinnu tó o bá ń ṣe lójoojúmọ́, ì báà jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tó kéré tàbí èyí tó ṣe pàtàkì gan-an, máa fi sọ́kàn pé ohun tó máa jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àti Bàbá rẹ ọ̀run lágbára sí i lo fẹ́ ṣe. Paríparí ẹ̀, túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, òun náà á sì túbọ̀ máa sún mọ́ ẹ títí láé!