Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 3

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

“Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”

1, 2. Ìran wo ni wòlíì Àìsáyà rí, kí ni ìran náà sì kọ́ wa nípa Jèhófà?

 Ẹ̀RÙ ba Àìsáyà gan-an nígbà tó rí ìran kan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ohun tó rí yẹn yà á lẹ́nu débi tó fi sọ nígbà tó yá pé òun “rí Jèhófà” tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀ gíga lọ́lá, tí etí aṣọ rẹ̀ sì kún inú tẹ́ńpìlì ńlá tó wà ní Jerúsálẹ́mù.​—Àìsáyà 6:1, 2.

2 Ohun tí Àìsáyà gbọ́ tún bà á lẹ́rù. Ó gbọ́ ìró orin kan tó rinlẹ̀ débi tó fi mi tẹ́ńpìlì tìtì dé ìpìlẹ̀ rẹ̀. Àwọn séráfù tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí tí ipò wọn ga gan-an ló ń kọ orin yẹn. Orin tí wọ́n ń kọ náà ò gùn rárá, àmọ́ ó nítumọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Wọ́n ń kọrin pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun. Ògo rẹ̀ kún gbogbo ayé.” (Àìsáyà 6:3, 4) Bí wọ́n ṣe pe ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” lẹ́ẹ̀mẹta nínú orin wọn fi hàn pé ó ṣe pàtàkì gan-an. Bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn, torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ látòkè délẹ̀. (Ìfihàn 4:8) Léraléra ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́. Kódà, ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì ni wọ́n ti lo orúkọ Ọlọ́run àti “mímọ́” tàbí “ìjẹ́mímọ́” pa pọ̀.

3. Kí nìdí táwọn kan ò fi fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run?

3 Ó ṣe kedere nígbà náà pé, ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ nípa òun ni pé òun jẹ́ mímọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni kò fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ mímọ́. Èrò àwọn kan ni pé ṣe lẹni tó bá jẹ́ mímọ́ á máa wo ara ẹ̀ bíi pé òun sàn ju àwọn míì lọ tàbí kó máa ṣojú ayé nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan wà tí wọ́n gbà pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan, torí náà tí wọ́n bá ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ mímọ́, ìyẹn lè kà wọ́n láyà. Ẹ̀rù lè máa bà wọ́n pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó ń sún mọ́ Ọlọ́run mímọ́ yìí rárá. Torí náà, wọn ò ní fẹ́ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú rẹ̀. Èyí mà ṣeni láàánú o, torí pé ọ̀kan pàtàkì lára ìdí tó fi yẹ ká sún mọ́ Ọlọ́run ni bó ṣe jẹ́ mímọ́. Kí nìdí tá a fi gbà bẹ́ẹ̀? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìjẹ́mímọ́ túmọ̀ sí gan-an.

Kí Ni Ìjẹ́mímọ́?

4, 5. (a) Kí ni “ìjẹ́mímọ́” túmọ̀ sí, kí ni kò sì túmọ̀ sí? (b) Ọ̀nà pàtàkì méjì wo ni Jèhófà gbà jẹ́ ẹni tó ‘ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀’?

4 Pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ kò túmọ̀ sí pé ó ń gbéra ga tàbí pé ó ń fi ojú àbùkù wo àwọn ẹlòmíì. Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, kódà Ọlọ́run kórìíra irú ìwà bẹ́ẹ̀. (Òwe 16:5; Jémíìsì 4:6) Torí náà, kí ni ọ̀rọ̀ náà “mímọ́” túmọ̀ sí? Nínú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ tá a túmọ̀ sí mímọ́ wá látinú ọ̀rọ̀ kan tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ “yà sọ́tọ̀.” Torí náà, tá a bá sọ pé ẹnì kan tàbí ohun kan jẹ́ “mímọ́,” ohun tó túmọ̀ sí ni pé a ya ẹni náà tàbí ohun náà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn Ọlọ́run. Bákan náà, tá a bá sọ pé ohun kan jẹ́ mímọ́, ó túmọ̀ sí pé ohun náà ò lábààwọ́n kò sì léèérí. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ṣe ni Jèhófà “ya” ara ẹ̀ “sọ́tọ̀” kúrò lọ́dọ̀ àwa èèyàn, tó sì jìnnà sí wa torí ká má bàa kó èérí àti àbààwọ́n bá a?

5 Rárá o. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ni “Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,” síbẹ̀ ó sọ pé òun ń gbé “láàárín” àwọn èèyàn òun, bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. (Àìsáyà 12:6; Hósíà 11:9) Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni mímọ́ ni Ọlọ́run, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó jìnnà sí wa. Kí ló wá túmọ̀ sí tá a bá sọ pé Jèhófà ‘ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀’? Ọ̀nà pàtàkì méjì ni Jèhófà gbà jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́, ó yàtọ̀ sí gbogbo ohun tó dá torí pé òun ni Ẹni Gíga Jù Lọ láyé àtọ̀run. Ṣe ló mọ́ látòkè délẹ̀ láìní àbààwọ́n tàbí èérí. (Sáàmù 40:5; 83:18) Ìkejì, Jèhófà ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Kí nìdí?

6. Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀, báwo nìyẹn ṣe ń fini lọ́kàn balẹ̀?

6 Ojúlówó ìjẹ́mímọ́ ṣọ̀wọ́n nínú ayé yìí. Gbogbo ohun táwọn èèyàn ń ṣe nínú ayé burúkú yìí ló ní àbùkù lọ́nà kan tàbí òmíì torí pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti kó àbààwọ́n bá gbogbo ẹ̀. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nígbà gbogbo kí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń gbé inú wa má bàa mú ká máa hùwà tí kò dáa. Gbogbo wa la sì gbọ́dọ̀ máa jà fitafita kí ẹ̀ṣẹ̀ má bàa borí wa. (Róòmù 7:15-25; 1 Kọ́ríńtì 10:12) Ní ti Jèhófà, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí i láéláé. Kò lè sún mọ́ ohunkóhun tó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀, kò sì lè ṣe ohun burúkú kankan. Èyí jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Baba tó ju baba lọ ni Jèhófà, ó tún jẹ́ ká rí i pé a lè fọkàn tán an pátápátá. Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn bàbá tó jẹ́ aláìpé. Ẹni mímọ́ ni, kò lè hùwà burúkú, bẹ́ẹ̀ ni kò lè ṣi agbára rẹ̀ lò láé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jèhófà fi ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ búra torí ó mọ̀ pé kò sóhun míì tóun lè fi búra táá sì mú kí ọ̀rọ̀ náà dáni lójú jùyẹn lọ. (Émọ́sì 4:2) Ẹ ò rí i pé ìyẹn fini lọ́kàn balẹ̀ lóòótọ́!

7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ láìkù síbì kan?

7 Jèhófà jẹ́ mímọ́ láìkù síbì kan. Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Wo ọ̀rọ̀ méjì yìí, “èèyàn” àti “àìpé.” Kò sí bá a ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa èèyàn tá ò ní sọ̀rọ̀ nípa àìpé. Aláìpé la jẹ́ látòkè délẹ̀, èyí sì máa ń fara hàn nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Tún wo ọ̀rọ̀ méjì míì tó yàtọ̀ pátápátá sí tẹ̀ẹ̀kan, ìyẹn “Jèhófà” àti “mímọ́.” Jèhófà jẹ́ mímọ́ látòkè délẹ̀. Jèhófà jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà, kò lábààwọ́n, ó sì jẹ́ olódodo. Tá a bá fẹ́ túbọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ dáadáa, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tó túmọ̀ sí tá a bá sọ pé Jèhófà jẹ́ “mímọ́.”

“Ìjẹ́mímọ́ Jẹ́ Ti Jèhófà”

8, 9. Kí ló fi hàn pé Jèhófà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn aláìpé ní àǹfààní láti jẹ́ mímọ́?

8 Torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́ látòkè délẹ̀, a lè sọ pé òun ni orísun ìjẹ́mímọ́. Ohun kan tún ni pé, torí pé Jèhófà lawọ́ gan-an, ó máa ń fún àwọn ẹlòmíì láǹfààní láti jẹ́ mímọ́. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan sí Mósè láti bá a sọ̀rọ̀, ńṣe ni ilẹ̀ ibi tí áńgẹ́lì yẹn ti bá a sọ̀rọ̀ di mímọ́ torí pé áńgẹ́lì Jèhófà wà níbẹ̀.​—Ẹ́kísódù 3:5.

9 Ṣé àwa èèyàn aláìpé lè jẹ́ mímọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ a ò lè jẹ́ mímọ́ pátápátá bíi ti Jèhófà. Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti di “orílẹ̀-èdè mímọ́.” (Ẹ́kísódù 19:6) Ó jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa jọ́sìn òun lọ́nà mímọ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni òfin tí Ọlọ́run fún wọn sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́mímọ́. Kódà, àlùfáà àgbà máa ń so àwo wúrà kan mọ́ iwájú láwàní rẹ̀. Ńṣe ni àwo wúrà náà máa ń tàn yinrin tí ìmọ́lẹ̀ bá ti tàn sí i, gbogbo èèyàn ló sì máa ń rí i. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n fín sára rẹ̀ ni: “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 28:36) Èyí fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí wọ́n jẹ́ mímọ́ nínú ìjọsìn wọn àti nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Jèhófà sọ fún wọn pé: “Kí ẹ jẹ́ mímọ́, torí èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.” (Léfítíkù 19:2) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà kà wọ́n sí mímọ́ tí wọ́n bá ń sa gbogbo ipá wọn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀.

10. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìjọsìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ àti tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká?

10 Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń hùwà mímọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ìjọsìn mímọ́ mú kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sáwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Oníwọra àti ẹlẹ̀tàn làwọn èèyàn náà, òrìṣà ni wọ́n sì ń bọ. Àwọn òrìṣà tí wọ́n ń bọ yìí ò mọ nǹkan kan, oríṣiríṣi ìwà burúkú ni wọ́n sì máa ń hù níbi ìjọsìn wọn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń hùwà ipá, wọ́n sì máa ń ṣèṣekúṣe. Kìkì ẹ̀gbin ni gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Ńṣe làwọn tó ń jọ́sìn àwọn òrìṣà yẹn ń sọ ara wọn di aláìmọ́. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi kìlọ̀ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà yẹn àti ìjọsìn ẹlẹ́gbin tí wọ́n ń ṣe.​—Léfítíkù 18:24-28; 1 Àwọn Ọba 11:1, 2.

11. Báwo làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ṣe jẹ́rìí sí i pé apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà jẹ́ mímọ́? (a) àwọn áńgẹ́lì (b) àwọn séráfù (d) Jésù.

11 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti jẹ́ mímọ́, síbẹ̀ wọn ò lè dà bí àwọn tó wà nínú apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí olóòótọ́ tó ń sin Ọlọ́run yìí ni Bíbélì pè ní “ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.” (Diutarónómì 33:2; Júùdù 14) Bíi ti Jèhófà, àwọn náà jẹ́ mímọ́ láìkù síbì kan. Bá a sì ṣe rí i níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, orin táwọn séráfù tí Àìsáyà rí nínú ìran ń kọ jẹ́ ká rí i pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí ń ṣe iṣẹ́ ribiribi láti sọ ìjẹ́mímọ́ Jèhófà di mímọ̀ láyé àtọ̀run. Àmọ́ o, ẹ̀dá ẹ̀mí kan wà tí ipò rẹ̀ ga ju tàwọn tó kù lọ. Òun ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, ìyẹn Jésù. Lẹ́yìn Jèhófà, òun ló tún jẹ́ mímọ́ jù lọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”​—Jòhánù 6:68, 69.

Orúkọ Mímọ́, Ẹ̀mí Mímọ́

12, 13. (a) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé orúkọ Ọlọ́run jẹ́ mímọ́? (b) Kí nìdí tó fi pọn dandan láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?

12 Orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ wá ń kọ́? Bá a ṣe rí i ní Orí 1, kì í ṣe orúkọ oyè lásán lorúkọ yẹn. Ńṣe ni orúkọ yẹn jẹ́ ká mọ ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ gangan, ó sì tún jẹ́ ká mọ àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ fún wa pé ‘orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́.’ (Àìsáyà 57:15) Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n pa ẹnikẹ́ni tó bá tàbùkù sí orúkọ Ọlọ́run. (Léfítíkù 24:16) Bákan náà, má gbàgbé ohun pàtàkì tí Jésù fi ṣáájú nínú àdúrà rẹ̀, ó ní: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Ohun tó túmọ̀ sí láti sọ ohun kan di mímọ́ ni pé ká yà á sọ́tọ̀, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un torí pé a kà á sí ohun mímọ́. Àmọ́, nígbà tó jẹ́ pé mímọ́ lorúkọ Ọlọ́run, kí nìdí tí Jésù fi sọ pé ká máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́?

13 Ìdí ni pé àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ti bà á lórúkọ jẹ́, wọ́n sì kó ẹ̀gàn bá orúkọ yẹn. Sátánì parọ́ mọ́ Jèhófà nínú ọgbà Édẹ́nì, ó sì dọ́gbọ́n sọ pé Alákòóso tí kò dáa ni Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Láti ìgbà yẹn ni Sátánì tó jẹ́ alákòóso ayé yìí, ti ń mú káwọn èèyàn máa pa oríṣiríṣi irọ́ mọ́ Ọlọ́run. (Jòhánù 8:44; 12:31; Ìfihàn 12:9) Ohun táwọn ẹlẹ́sìn fi ń kọ́ni mu káwọn èèyàn gbà pé Ọlọ́run jẹ́ apàṣẹwàá, ẹni tí kò ṣeé sún mọ́ àti ìkà. Wọ́n ní òun ló ń tì wọ́n lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń pa ara wọn nípakúpa nínú àwọn ogun tí wọ́n ń jà. Táwọn kan bá rí àwọn ohun àrà tí Ọlọ́run dá, dípò kí wọ́n máa yin Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n máa ń sọ pé àwọn nǹkan yẹn ṣàdédé wà ni, pé kò sẹ́ni tó dá wọn. Àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ti tàbùkù sí orúkọ ẹ̀ gan-an ni. Torí náà, ó yẹ kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́; kí ògo orúkọ yẹn tún pa dà máa tàn bó ṣe yẹ. Tọkàntara la fi ń retí ìgbà tí orúkọ rẹ̀ á di mímọ́ pátápátá, tí ẹnikẹ́ni ò sì ní tàbùkù sí i mọ́ títí láé. Èyí sì máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. A ti múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ kí orúkọ Jèhófà lè di mímọ́ pátápátá.

14. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe ẹ̀mí Ọlọ́run ní mímọ́, kí sì nìdí tó fi jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an tẹ́nì kan bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́?

14 Ohun kan tún wà tó jẹ́ mímọ́, tó jẹ́ ti Jèhófà. Ẹ̀mí rẹ̀ tàbí agbára tó fi ń ṣe nǹkan ni. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Kò sóhun tó lágbára tó ẹ̀mí yìí, òun sì ni Jèhófà máa ń lò láti ṣe àwọn nǹkan tó bá fẹ́ ṣe. Gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run máa ń ṣe ló jẹ́ mímọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe ẹ̀mí yẹn ní ẹ̀mí mímọ́. (Lúùkù 11:13; Róòmù 1:4) Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní ìdáríjì, èyí sì kan pé kéèyàn máa mọ̀ọ́mọ̀ ta ko ohun tí Jèhófà fẹ́.​—Máàkù 3:29.

Ìdí Tí Ìjẹ́mímọ́ Jèhófà Fi Mú Ká Sún Mọ́ Ọn

15. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ mímọ́ tó?

15 A ti wá lóye ìdí tí Bíbélì fi jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ronú nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ mímọ́ èyí á mú ká máa bẹ̀rù ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 99:3 sọ pé: “Kí wọ́n yin orúkọ ńlá rẹ, torí ó ń bani lẹ́rù, ó sì jẹ́ mímọ́.” Ohun téyìí túmọ̀ sí ni pé ká ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run àti fún orúkọ rẹ̀. Ó sì bọ́gbọ́n mu kéèyàn ní irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀, torí pé Ọlọ́run mọ́ ju àwa èèyàn lọ gan-an. Ó jẹ́ mímọ́ láìkù síbì kan, kò ní àbààwọ́n, kò sì ní èérí. Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a ò lè sún mọ́ ọn. Kódà, ìyẹn gan-an ló máa mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Kí nìdí?

16. (a) Báwo ni ìjẹ́mímọ́ ṣe so pọ̀ mọ́ ẹwà? Sọ àpẹẹrẹ kan. (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ẹwà àti ìjẹ́mímọ́ Ọlọ́run?

16 Ohun kan ni pé, tí Bíbélì bá sọ pé ohun kan jẹ́ mímọ́, ìyẹn tún máa ń fi hàn pé ohun náà rẹwà. Àìsáyà 63:15 pe ibùgbé Ọlọ́run ní ibi “mímọ́ àti ológo [tàbí, “ẹlẹ́wà,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé] tó ga.” Tí ohun kan bá rẹwà, ó máa ń fani mọ́ra gan-an. Bí àpẹẹrẹ, wo àwòrán tó wà lójú ìwé 33. Ṣé ohun tó wà nínú àwòrán náà ò fani mọ́ra? Kí ló jẹ́ kó fani mọ́ra tó bẹ́ẹ̀? Wo bí omi ibẹ̀ ṣe mọ́ lóló. Kódà, ó dájú pé atẹ́gùn ibẹ̀ á tura, torí ojú sánmà ibẹ̀ mọ́ roro bí ìgbà tí oòrùn yọ lẹ́yìn òjò àrọ̀mọ́jú. Báwo ló ṣe máa rí tí ibi tá à ń wò yẹn bá yí pa dà, kí ìdọ̀tí kún ojú omi yẹn, kí wọ́n fi oríṣiríṣi ìkọkúkọ ba ara àwọn igi àti òkúta ibẹ̀ jẹ́, kí èéfín sì gba gbogbo ibẹ̀ kan? Ó dájú pé kò ní wù wá mọ́, kódà a ò ní fẹ́ wò ó lẹ́ẹ̀mejì. Tá a bá rí ohun kan tó wuyì, tó mọ́ tónítóní, tó sì ń tàn yanran, a sábà máa ń gbà pé nǹkan ọ̀hún rẹwà gan-an. A lè fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí kan náà ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́. Abájọ tó fi máa ń jọ wá lójú gan-an tá a bá kà nípa àwọn ìran tó ṣàpèjúwe bí ògo Jèhófà ṣe rí! Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe Jèhófà Ọlọ́run mímọ́ tó wà lórí ìtẹ́, ó sọ pé ó ń tàn yanran bí ìmọ́lẹ̀, ó ń dán gbinrin bí àwọn òkúta iyebíye, ó sì ń tàn yòò bí iná.​—Ìsíkíẹ́lì 1:25-28; Ìfihàn 4:2, 3.

Tí ohun kan bá rẹwà, ó máa ń fani mọ́ra gan-an, bẹ́ẹ̀ náà ni ohun tó jẹ́ mímọ́ ṣe máa ń fani mọ́ra

17, 18. (a) Báwo ni ìran tí Àìsáyà rí ṣe kọ́kọ́ rí lára ẹ̀? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe lo séráfù kan láti tu Àìsáyà nínú, kí lohun tí séráfù yẹn ṣe sì túmọ̀ sí?

17 Ní báyìí tá a ti wá mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ kọjá ohun tá a lè lóye, ṣó yẹ kíyẹn mú ká máa wo ara wa bí ẹni tó rẹlẹ̀ pátápátá sí Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni. Ká sòótọ́, a ò lè fi ara wa wé Jèhófà rárá. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò lè sún mọ́ ọn? Wo ohun tí wòlíì Àìsáyà ṣe nígbà tó gbọ́ ohùn àwọn séráfù tó ń kéde pé Jèhófà jẹ́ mímọ́. Ó ní: “Mo wá sọ pé: ‘Mo gbé! Mo ti kú tán, torí ọkùnrin tí ètè rẹ̀ kò mọ́ ni mí, àárín àwọn èèyàn tí ètè wọn ò mọ́ ni mo sì ń gbé; torí ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fúnra rẹ̀!’ ” (Àìsáyà 6:5) Nígbà tí Àìsáyà rí bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́ tó, ó túbọ̀ wá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku lòun. Ìyẹn kọ́kọ́ bà á nínú jẹ́ gan-an. Àmọ́ Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀.

18 Kíá ni séráfù kan wá láti tu wòlíì yìí nínú. Kí ni séráfù náà ṣe? Áńgẹ́lì alágbára yìí fò lọ síbi pẹpẹ, ó mú ẹyin iná kan níbẹ̀ ó sì fi kan ètè Àìsáyà. O lè máa wò ó pé ńṣe ni iná yẹn máa pa á lára dípò kó tù ú nínú. Àmọ́, rántí pé ìran la pè é, ṣe làwọn nǹkan tó sì ṣẹlẹ̀ nínú ìran náà ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan tàbí òmíì. Torí pé Júù ni Àìsáyà, ó mọ̀ dáadáa pé ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń rúbọ lórí pẹpẹ ní tẹ́ńpìlì láti fi ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀. Séráfù yẹn wá fìfẹ́ rán Àìsáyà létí pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé “ọkùnrin tí ètè rẹ̀ kò mọ́” tàbí aláìpé ni, Ọlọ́run ṣì lè kà á sí ẹni tó mọ́. a Èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ṣe tán láti ka èèyàn aláìpé sí ẹni mímọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè jẹ́ mímọ́ pátápátá bíi tiẹ̀.​—Àìsáyà 6:6, 7.

19. Bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, kí ló mú kí Jèhófà lè kà wá sí ẹni mímọ́?

19 Bọ́rọ̀ ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Ṣe ni gbogbo ẹbọ tí wọ́n ń rú lórí pẹpẹ ní Jerúsálẹ́mù kàn ń ṣàpẹẹrẹ ohun pàtàkì kan, ìyẹn ẹbọ pípé kan ṣoṣo tí Jésù Kristi rú lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni. (Hébérù 9:11-14) Tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, tá a jáwọ́ nínú ìwà àìtọ́, tá a sì nígbàgbọ́ nínú ẹbọ Kristi, Ọlọ́run máa dárí jì wá. (1 Jòhánù 2:2) Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé Ọlọ́run lè kà wá sí ẹni mímọ́. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi rán wa létí pé: “A ti kọ ọ́ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, torí èmi jẹ́ mímọ́.’ ” (1 Pétérù 1:16) Kíyè sí i pé Jèhófà sọ pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ gẹ́lẹ́ bí òun ṣe jẹ́ mímọ́, torí kì í retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. (Sáàmù 103:13, 14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ká jẹ́ mímọ́ torí pé òun jẹ́ mímọ́. Torí pé “àyànfẹ́ ọmọ” ni wá, a máa ń sa gbogbo ipá wa láti fara wé Jèhófà bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. (Éfésù 5:1) Èyí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ máa sapá nìṣó ká lè máa jẹ́ mímọ́. Tá a bá ń gbìyànjú láti ṣe àwọn nǹkan táá mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́, a máa fi hàn pé ó wù wá láti “jẹ́ mímọ́ pátápátá.”​—2 Kọ́ríńtì 7:1.

20. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ pé Ọlọ́run wa tó jẹ́ mímọ́ lè ka àwa náà sí ẹni mímọ́? (b) Kí ni Àìsáyà ṣe nígbà tí áńgẹ́lì kan ṣe ohun tó mú kó rí i pé Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í?

20 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ohun tó jẹ́ òdodo tó sì jẹ́ mímọ́. Ó kórìíra ẹ̀ṣẹ̀. (Hábákúkù 1:13) Àmọ́, kò kórìíra àwa èèyàn. Tá a bá ṣáà ti kórìíra ohun búburú, tá a nífẹ̀ẹ́ ohun rere, tá a sì ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi Jésù, Jèhófà máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Émọ́sì 5:15; 1 Pétérù 2:21) Tá a bá mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wa tó jẹ́ mímọ́ lè ka àwa náà sí ẹni mímọ́, àá máa sa gbogbo ipá wa ká lè máa jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀. Rántí pé nígbà tí Àìsáyà rí ìran nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́ tó, ìyẹn mú kó túbọ̀ rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku lòun. Kódà, ó kígbe pé: “Mo gbé!” Àmọ́ gbàrà tí áńgẹ́lì kan ṣe ohun tó mú kó rí i pé Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í, ọkàn ẹ̀ balẹ̀. Nígbà tí Jèhófà wá sọ pé òun fẹ́ kẹ́nì kan yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ kan, kíá ni Àìsáyà yọ̀ǹda ara ẹ̀ láì tiẹ̀ tíì mọ irú iṣẹ́ tó jẹ́. Ó kígbe pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”​—Àìsáyà 6:5-8.

21. Kí ló mú kó dá wa lójú pé a lè jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run?

21 Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, torí náà a lè fara wé e, ká sì ṣe àwọn nǹkan táá mú ká sún mọ́ ọn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Gbogbo wa pátá la lè jẹ́ ẹni mímọ́ lójú Ọlọ́run. Tá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ mímọ́, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa tó jẹ́ mímọ́. Bákan náà, nínú àwọn orí tó wà níwájú a máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà, ìyẹn á sì mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn!

a Bíbélì sábà máa ń lo ètè láti fi ṣàpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ tàbí èdè. Ó ṣe tán, ọ̀rọ̀ ẹnu àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé ló sábà máa ń sún wa dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, gbólóhùn náà, “ọkùnrin tí ètè rẹ̀ kò mọ́” bá a mu gan-an.​—Òwe 10:19; Jémíìsì 3:2, 6.