Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsọ̀rí 3

“Ọlọ́gbọ́n Ní Ọkàn-àyà”

“Ọlọ́gbọ́n Ní Ọkàn-àyà”

Ojúlówó ọgbọ́n jẹ́ ọ̀kan nínú ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ tó yẹ kéèyàn wá kàn. Jèhófà nìkan ṣoṣo ni orísun ọgbọ́n yìí. Ní ìsọ̀rí yìí, a óò túbọ̀ ṣàyẹ̀wò àwámárìídìí ọgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí Jóòbù olóòótọ́ sọ nípa rẹ̀ pé: “Ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ọkàn-àyà.”—Jóòbù 9:4.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 17

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

Kí nìdí tí ọgbọ́n Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì ju ìmọ̀ àti òye rẹ̀ lọ?

ORÍ 18

Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì dípò kó lo àwọn áńgẹ́lì tàbí kóun fúnra rẹ̀ ṣe é?

ORÍ 19

“Ọgbọ́n Ọlọ́run Nínú Àṣírí Ọlọ́wọ̀ Kan”

Kí ni àṣírí ọlọ́wọ̀ tí Ọlọ́run fi pa mọ́ nígbà kan àmọ́ tó ti ṣí payá báyìí?

ORÍ 20

Ó Jẹ́ “Ọlọ́gbọ́n ní Ọkàn-Àyà”—Síbẹ̀ Onírẹ̀lẹ̀ Ni

Báwo ni Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé àti ọ̀run ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

ORÍ 21

Jésù Fi “Ọgbọ́n Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” Hàn

Báwo ni ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ àwọn èèyàn ṣe mú kí àwọn ọmọ ogun tó wá mú un pa dà lọ́wọ́ òfo?

ORÍ 22

Ǹjẹ́ Ò Ń Lo “Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè” Nígbèésí Ayé Rẹ?

Bíbélì jẹ́ ká mọ nǹkan mẹ́rin tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run