Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orí 20

Ó Jẹ́ “Ọlọ́gbọ́n ní Ọkàn-Àyà”—Síbẹ̀ Onírẹ̀lẹ̀ Ni

Ó Jẹ́ “Ọlọ́gbọ́n ní Ọkàn-Àyà”—Síbẹ̀ Onírẹ̀lẹ̀ Ni

1-3. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà?

BÀBÁ kan fẹ́ kọ́ ọmọ rẹ̀ kékeré ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ó sì fẹ́ kí ẹ̀kọ́ yìí wọ ọmọ rẹ̀ lọ́kàn ṣinṣin. Ọ̀nà wo ni kó gbé e gbà? Ṣé kó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, kó máa bú mọ́ ọn ni? Tàbí kó bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí ọmọ rẹ̀ fi lè rójú rẹ̀ dáadáa, kó sì máa rọra sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́? Ó dájú pé ńṣe ni bàbá oníwà ìrẹ̀lẹ̀ máa rọra sọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.

2 Irú Bàbá wo ni Jèhófà jẹ́? Ṣé agbéraga ni tàbí onírẹ̀lẹ̀, ẹni tó ń kanra mọ́ni tàbí oníwà pẹ̀lẹ́? Jèhófà mọ ohun gbogbo, òun sì ní ọba ọgbọ́n. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí pé jíjẹ́ onímọ̀ àti onílàákàyè kò fi dandan múni jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe wí, “ìmọ̀ a máa wú fùkẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 3:19; 8:1) Ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó jẹ́ “ọlọ́gbọ́n ní ọkàn-àyà,” ó sì tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Jóòbù 9:4) Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí pé kò ní ọlá-ńlá, ìgbéraga ló kàn jìnnà sí i. Èé ṣe tó fi rí bẹ́ẹ̀?

3 Ìdí ni pé Jèhófà jẹ́ mímọ́. Nítorí náà, ìgbéraga, tó jẹ́ ànímọ́ tó ń sọni di ẹlẹ́gbin jìnnà sí i. (Máàkù 7:20-22) Síwájú sí i, kíyè sí ohun tí wòlíì Jeremáyà sọ fún Jèhófà, ó ní: “Láìkùnà, ọkàn rẹ [ìyẹn Jèhófà fúnra rẹ̀] yóò rántí, yóò sì tẹ̀ ba mọ́lẹ̀ lórí mi.” * (Ìdárò 3:20) Àbí ẹ ò rí nǹkan! Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, ṣe tán láti “tẹ̀ ba mọ́lẹ̀,” tàbí láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ dé ipò rírẹlẹ̀ tí Jeremáyà wà, láti lè tẹ́tí gbọ́ ọkùnrin aláìpé yìí. (Sáàmù 113:7) Onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà lóòótọ́. Ṣùgbọ́n kí ló wé mọ́ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Ọlọ́run ní? Báwo ló ṣe tan mọ́ ọgbọ́n? Kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì fún wa?

Bí Jèhófà Ṣe Ń Lo Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

4, 5. (a) Kí ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀, báwo la ṣe ń fi í hàn, kí sì nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ ṣì í gbé fún àìlera tàbí ẹ̀mí ìbẹ̀rù? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì, báwo sì ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà ti ṣe pàtàkì fún wa tó?

4 Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ni pé kí ó máà sí ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú àti ìgbéraga. Ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ìwà tó ń tinú ọkàn wá, ó sì máa ń hàn nínú ànímọ́ bí ìwà tútù, sùúrù àti ìfòyebánilò. (Gálátíà 5:22, 23) Àmọ́ ṣá, ká má ṣi àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ń fẹ́ yìí gbé fún àìlera tàbí ẹ̀mí ìbẹ̀rù o. Àwọn ànímọ́ yìí kò sì lòdì sí ìbínú òdodo Jèhófà tàbí lílò tó ń lo agbára ìṣèparun rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù Jèhófà ń fi hàn pé ó ní okun àti agbára ńlá láti kó ara rẹ̀ níjàánu pátápátá. (Aísáyà 42:14) Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe tan mọ́ ọgbọ́n? Ìwé ìṣèwádìí kan nípa Bíbélì sọ pé: “Paríparì ohun tá a tú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ sí ni . . . pé ó jẹ́ àìjọra-ẹni-lójú àti pé ó jẹ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì fún gbogbo ọgbọ́n.” Nítorí náà, èèyàn ò lè ní ojúlówó ọgbọ́n àfi tó bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

Bàbá ọlọ́gbọ́n máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá àwọn ọmọ rẹ̀ lò

5 Dáfídì Ọba kọrin sí Jèhófà pé: “Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbé mi ró, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni yóò sọ mí di ńlá.” (Sáàmù 18:35) Ìyẹn ni pé ńṣe ni Jèhófà tẹ̀ ba mọ́lẹ̀ láti lè ní àjọṣe pẹ̀lú ọmọ ènìyàn aláìpé lásánlàsàn yìí, tí Jèhófà ń dáàbò bò ó, tó sì ń gbé e ró lójoojúmọ́. Dáfídì mọ̀ pé, bí òun yóò bá rí ìgbàlà, àní bí òun yóò bá tiẹ̀ di gbajúmọ̀ ọba dé àyè kan, àfi kí Jèhófà mọ̀ọ́mọ̀ rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ láti ran òun lọ́wọ́. Àbí, nínú wa, ta ní lè retí ìgbàlà ká ní pé Jèhófà ò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì ṣe tán láti tẹ ara rẹ̀ ba wálẹ̀ láti lè ní àjọṣe pẹ̀lú wa gẹ́gẹ́ bí Bàbá oníwà pẹ̀lẹ́ àti onífẹ̀ẹ́?

6, 7. (a) Kí nìdí tí Bíbélì ò fìgbà kankan sọ pé Jèhófà jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà? (b) Kí ni ìsopọ̀ tó wà láàárín ìwà tútù àti ọgbọ́n, ta ló sì fi àpẹẹrẹ gíga jù lélẹ̀ ní ti èyí?

6 Ó yẹ ká mọ̀ pé ìyàtọ̀ ń bẹ láàárín ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà. Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà jẹ́ ànímọ́ àtàtà tó yẹ kí àwọn olóòótọ́ èèyàn fi kọ́ra. Òun pẹ̀lú wé mọ́ ọgbọ́n bíi ti ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Òwe 11:2 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” Ṣùgbọ́n o, kò sí ìgbà kankan tí Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ìwé Mímọ́ gbà lo ọ̀rọ̀ náà ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, ó ní ìtumọ̀ ti mímọ ìwọ̀n ara ẹni. Bẹ́ẹ̀ Olódùmarè ò ní ààlà ibi tó lè ṣe nǹkan mọ àyàfi èyí tó bá là kalẹ̀ fún ara rẹ̀ nítorí àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. (Máàkù 10:27; Títù 1:2) Ẹ̀wẹ̀, òun gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá Ògo kò sí lábẹ́ ẹnikẹ́ni. Nípa bẹ́ẹ̀ ọ̀ràn ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ò kan Jèhófà rárá.

7 Àmọ́, Jèhófà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti oníwà tútù. Ó kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ìwà tútù ṣe pàtàkì fẹ́ni tó bá ní ọgbọ́n tòótọ́. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ nípa “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.” * (Jákọ́bù 3:13) Wo bí Jèhófà ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí.

Jèhófà Ń Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Fa Iṣẹ́ Léni Lọ́wọ́ Ó sì Ń Fetí Síni

8-10. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ ìyàlẹ́nu pé Jèhófà ń fẹ́ láti fa iṣẹ́ léni lọ́wọ́ àti pé ó máa ń fetí síni? (b) Báwo ni Olódùmarè ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ bá àwọn áńgẹ́lì lò?

8 Ẹ̀rí dáadáa kan tó fi hàn pé Jèhófà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé ó máa ń fa ẹrú iṣẹ́ léni lọ́wọ́, ó sì ń fetí síni. Ìyàlẹ́nu gan-an ló jẹ́ pé ó tiẹ̀ máa ń fetí síni; Jèhófà ò nílò ìrànlọ́wọ́ tàbí ìmọ̀ràn rárá. (Aísáyà 40:13, 14; Róòmù 11:34, 35) Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì fi hàn wá pé Jèhófà máa ń rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe nǹkan wọ̀nyẹn.

9 Bí àpẹẹrẹ, wo ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Ábúráhámù. Ó ṣẹlẹ̀ pé Ábúráhámù ní àlejò mẹ́ta, ó pe ọ̀kan nínú wọn ní “Jèhófà.” Áńgẹ́lì làwọn àlejò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí o, ṣùgbọ́n ńṣe ni ọ̀kan nínú wọn wá lórúkọ Jèhófà, orúkọ Rẹ̀ ló sì fi ń ṣe ohun tó ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, tí áńgẹ́lì yẹn bá sọ̀rọ̀ tàbí pé ó ṣe nǹkan kan, Jèhófà ló sọ ọ́ tó sì ṣe é nìyẹn. Jèhófà gbẹnu áńgẹ́lì náà sọ fún Ábúráhámù pé òun ti gbọ́ “igbe ìráhùn nípa Sódómù àti Gòmórà.” Jèhófà wá sọ pé: “Mo ti pinnu tán láti sọ̀ kalẹ̀ lọ kí n lè rí bóyá wọ́n hùwà látòkè délẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú igbe ẹkún tí wọ́n ń ké lé e lórí tí ó ti wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá sì jẹ́ bẹ́ẹ̀, èmi a lè mọ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:3, 20, 21) A mọ̀ pé ohun tí Jèhófà sọ yìí kò túmọ̀ sí pé Olódùmarè máa kúkú fúnra rẹ̀ “sọ̀ kalẹ̀” wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn áńgẹ́lì náà ló rán wá ṣojú fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 19:1) Kí nìdí rẹ̀? Ṣé Jèhófà tó ń rí ohun gbogbo kò ‘lè fúnra rẹ̀ mọ’ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an lágbègbè yẹn láìrán oníṣẹ́ ni? Ó dájú pé ó lè mọ̀ ọ́n. Ṣùgbọ́n dípò tí Jèhófà yóò fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ fa iṣẹ́ ọ̀hún lé àwọn áńgẹ́lì lọ́wọ́ pé kí wọ́n lọ ṣèwádìí ọ̀ràn náà, kí wọ́n sì bẹ Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ wò ní Sódómù.

10 Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà máa ń fetí síni. Nígbà kan rí, ó ní kí àwọn áńgẹ́lì òun wá dámọ̀ràn onírúurú ọ̀nà tí Áhábù Ọba á fi lè já kulẹ̀. Lóòótọ́, Jèhófà ò nílò irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, ó gba àbá ọ̀kan nínú àwọn áńgẹ́lì, ó sì ní kí áńgẹ́lì yẹn rí sí i pé ó di ṣíṣe. (1 Àwọn Ọba 22:19-22) Ǹjẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ kọ́ nìyẹn?

11, 12. Báwo ni Ábúráhámù ṣe wá rí bí Jèhófà ṣe ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó?

11 Jèhófà tiẹ̀ ṣe tán láti fetí sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé tó bá ń fẹ́ sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún un pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà kọ́kọ́ sọ fún Ábúráhámù pé òun fẹ́ pa Sódómù àti Gòmórà run, ọ̀rọ̀ náà ṣe ọkùnrin olóòótọ́ yìí ní kàyéfì. Ábúráhámù sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ. Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” Ó wá bi Jèhófà bóyá yóò dá ìlú wọ̀nyẹn sí ká ní a rí àádọ́ta olódodo níbẹ̀. Jèhófà mú kó dá a lójú pé òun á dá wọn sí. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù tún bi Jèhófà bóyá á ṣì dá a sí bí iye wọn ò bá tó bẹ́ẹ̀, tó jẹ́ márùnlélógójì, ogójì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí Jèhófà ṣe ń mú kó dá a lójú pé òun á dá wọn sí ni Ábúráhámù ń dín iye yẹn kù nìṣó títí dóríi mẹ́wàá péré. Bóyá ńṣe ni Ábúráhámù ò tíì mọ bí Jèhófà ṣe jẹ́ aláàánú tó nígbà yẹn. Bó ti wù kó rí ṣá, Jèhófà fi sùúrù àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba Ábúráhámù ìránṣẹ́ àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ láyè kí ó sọ ìdààmú ọkàn rẹ̀ jáde lọ́nà yìí.—Jẹ́nẹ́sísì 18:23-33.

12 Mélòó nínú ọmọ aráyé tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé tí ọpọlọ rẹ̀ jí pépé ló lè ní sùúrù láti fetí sí ẹni tí òye rẹ̀ kéré jìnnàjìnnà sí tirẹ̀? * Ẹ ò rí i pé ìrẹ̀lẹ̀ Ọlọ́run wa pọ̀ gan-an ni. Nígbà ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn kan náà, Ábúráhámù ri í pé Jèhófà “ń lọ́ra láti bínú” pẹ̀lú. (Ẹ́kísódù 34:6) Ó jọ pé ó sọ sí Ábúráhámù lọ́kàn pé òun ò mà láṣẹ láti yẹ Ọ̀gá Ògo lọ́wọ́ wò kẹ̀ẹ, ìyẹn ló fi bẹ̀bẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì pé: “Jọ̀wọ́, kí ìbínú Jèhófà má ṣe gbóná.” (Jẹ́nẹ́sísì 18:30, 32) Jèhófà ò sì bínú lóòótọ́. Dájúdájú, ó ní “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.”

Jèhófà Jẹ́ Afòyebánilò

13. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìfòyebánilò” bí a ṣe lò ó nínú Bíbélì, kí sì nìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi jẹ́ ọ̀nà tó dára láti gbà ṣàpèjúwe Jèhófà?

13 Ànímọ́ àtàtà mìíràn tí Jèhófà ní, ìyẹn ìfòyebánilò, tún fi ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ hàn pẹ̀lú. Ó dunni pé ẹ̀dá aláìpé kì í sábà lo ànímọ́ yìí. Ní ti Jèhófà, yàtọ̀ sí pé ó máa ń fetí sí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ olóye, kì í rinkinkin mọ́ èrò tirẹ̀ bí ohun tí wọ́n wí kò bá ti ta ko àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Ọ̀nà tá a gbà lo ọ̀rọ̀ náà “fòye báni lò” nínú Bíbélì túmọ̀ ní ṣáńgílítí sí “àìrinkinkin mọ́ èrò ẹni.” Ànímọ́ yìí pẹ̀lú ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn. Jákọ́bù 3:17 sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . ń fòye báni lò.” Ọ̀nà wo ni Jèhófà ọba ọgbọ́n gbà jẹ́ afòyebánilò? Lọ́nà kan, ó mọ bí a ṣe ń yíwọ́ padà. Rántí pé orúkọ Jèhófà pàápàá jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń sọ ara rẹ̀ di ohunkóhun tó bá yẹ láti lè mú ète rẹ̀ ṣẹ. (Ẹ́kísódù 3:14) Ǹjẹ́ ìyẹn kò fi ẹ̀mí ìmọwọ́yípadà àti ìfòyebánilò hàn?

14, 15. Kí ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run kọ́ wa nípa ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, báwo ló sì ṣe yàtọ̀ sí àwọn ètò àjọ ènìyàn?

14 Àyọkà Bíbélì pàtàkì kan wà tó mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ní òye bí Jèhófà ṣe mọ ọwọ́ yí padà tó. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí ìran nípa ètò àjọ Jèhófà ní ọ̀run, tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Ó rí àgbàyanu kẹ̀kẹ́ ẹṣin jìmàwò-jimawo kan, ìyẹn “ohun ìrìnnà” tí Jèhófà fúnra rẹ̀ ń lò, tó sì ń bẹ lábẹ́ àkóso Rẹ̀ nígbà gbogbo. Bó ṣe ń rìn gan-an ló yani lẹ́nu jù lọ. Ìhà mẹ́rin ni àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ọ̀hún ní, ó sì kún fún ojú, tó fi jẹ́ pé ibi gbogbo ni wọ́n lè rí, wọ́n sì lè dédé yà síhà èyíkéyìí lórí ìrìn láìsí pé wọ́n dúró tàbí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń lọ́rí. Kì í sì í ṣe pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin ńláǹlà yìí ń wọ́ tìrọ́tìrọ́ bí àwọn ọkọ̀ eléjò táwa ọmọ ènìyàn ṣe. Ó lè sáré kọjá fàì bíi mànàmáná, kódà ó lè yà pẹ̀ẹ́ sọ́tùn-ún tàbí sósì lórí eré! (Ìsíkíẹ́lì 1:1, 14-28) Èyí fi hàn pé ètò àjọ Jèhófà máa ń ṣe bíi ti Olódùmarè Ọba Aláṣẹ tó ń darí rẹ̀, ní ti pé òun pẹ̀lú lè yíwọ́ padà dọ́ba, láti lè kojú ohun tó ń fẹ́ àtúnṣe àti ipò àwọn nǹkan tí kì í dúró sójú kan tó ní láti bójú tó.

15 Ọmọ aráyé kàn lè máa gbìyànjú láti fara wé ọ̀nà pípé tó gbà mọwọ́ yí padà yìí ni. Ṣùgbọ́n ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, ènìyàn àtàwọn àjọ tó gbé kalẹ̀ máa ń wonkoko mọ́ ọ̀nà tiwọn dípò kí wọ́n yíwọ́ padà, wọ́n sábà máa ń rinkinkin jù dípò kí wọ́n máa fòye báni lò. Àpèjúwe rẹ̀ rèé: Ọkọ̀ òkun gìrìwò tó ń gbépo tàbí ọkọ̀ rélùwéè akẹ́rù ńlá lè jẹ́ ohun ìyanu fúnni tá a bá wo títóbi àti agbára rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí ipò nǹkan bá yí padà lójijì, ṣé wọ́n máa ń ṣeé darí láti ṣe ohun tó yẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Tí ohun ìdìgbòlù kan bá wó dínà ọkọ̀ rélùwéè akẹ́rù ńlá kan níwájú, kò lè ṣẹ́rí padà rárá. Awakọ̀ ò sì tún lè dá a dúró lójijì. Tí wọ́n bá kó bíréèkì ọkọ̀ rélùwéè akẹ́rù ńlá yìí, yóò ṣì rìn tó nǹkan bíi kìlómítà méjì kó tó lè dúró! Bákan náà, lẹ́yìn tí wọ́n bá paná gbogbo ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ òkun gìrìwò tó ń gbépo, ó ṣì lè máa lọ ràì tó kìlómítà mẹ́jọ kó tó lè dúró. Kódà bí wọ́n bá fi ẹ̀rọ ọkọ̀ náà sípò pé kó máa fẹ̀yìn rìn, ó ṣì lè kọ́kọ́ rìn tó kìlómítà mẹ́ta síwájú ná kó tó lè padà! Bí ọ̀ràn ètò àjọ ènìyàn, tó sábà máa ń wonkoko mọ́ ọ̀nà tiwọn láìfòye báni lò ṣe rí nìyẹn. Ìgbéraga sábà máa ń mú kí àwọn èèyàn kọ̀ láti yíwọ́ padà bá ohun tó ń fẹ́ àtúnṣe àti ipò nǹkan tó ń yí padà mu. Àìfẹ́yíwọ́padà yìí ti mú kí àwọn ilé iṣẹ́ kan àtàwọn ìjọba kan dojú dé. (Òwe 16:18) A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ ò dà bíi tiwọn!

Bí Jèhófà Ṣe Ń Fòye Báni Lò

16. Báwo ni Jèhófà ṣe fòye bá Lọ́ọ̀tì lò ṣáájú ìparun Sódómù àti Gòmórà?

16 Tún wo ọ̀ràn ìparun Sódómù àti Gòmórà lẹ́ẹ̀kan sí i. Áńgẹ́lì Jèhófà fún Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ ní ìsọfúnni tó ṣe kedere yìí pé: “Sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá.” Ṣùgbọ́n Lọ́ọ̀tì ò fẹ́ ṣe èyí. Ló bá bẹ̀bẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jọ̀wọ́, Jèhófà!” Lọ́ọ̀tì gbà pé òun á kú tóun bá sá lọ sórí àwọn òkè, ó wá bẹ̀bẹ̀ pé kó jẹ́ kí òun àti ìdílé òun sá lọ sí ìlú itòsí kan tó ń jẹ́ Sóárì. Sì rántí pé ńṣe ni Jèhófà fẹ́ pa ìlú yẹn run tẹ́lẹ̀ o. Ẹ̀wẹ̀, ìbẹ̀rù Lọ́ọ̀tì ò tún lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ṣebí Jèhófà lè dáàbò bo ẹ̀mí Lọ́ọ̀tì lórí àwọn òkè yẹn! Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà fara mọ́ ẹ̀bẹ̀ Lọ́ọ̀tì ó sì dá Sóárì sí. Áńgẹ́lì yìí sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: “Kíyè sí i, mo fi ìgbatẹnirò hàn sí ọ dé ìwọ̀n yìí pẹ̀lú.” (Jẹ́nẹ́sísì 19:17-22) Ǹjẹ́ Jèhófà ò fòye bá a lò bí?

17, 18. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ìfòyebánilò nínú ọ̀nà tó gbà hùwà sí àwọn ará Nínéfè?

17 Jèhófà tún máa ń kọbi ara sí ìrònúpìwàdà àtọkànwá, ó máa ń ṣàánú, ó sì máa ṣe ẹ̀tọ́ nígbà gbogbo. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run rán wòlíì Jónà sí Nínéfè, ìlú burúkú oníwà ipá nì. Nígbà tí Jónà ń la àárín ìlú náà lọ, ohun tó ń kéde kò ju pé: Ìlú ńlá yìí yóò pa run láàárín ogójì ọjọ́. Ṣùgbọ́n ní kíá nǹkan yí padà gan-an. Àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà!—Jónà, orí kẹta.

18 Tá a bá fi ìṣarasíhùwà Jèhófà nípa ìyípadà tó wáyé yìí wéra pẹ̀lú ti Jónà, ẹ̀kọ́ ńlá la máa rí kọ́. Ní ti Jèhófà, ó yí èrò padà, ó sọ ara rẹ̀ di Olùdáríjini lọ́tẹ̀ yìí dípò jíjẹ́ “akin lójú ogun.” * (Ẹ́kísódù 15:3) Àmọ́ Jónà fàáké kọ́rí ní tirẹ̀, kò lo ojú àánú bíi ti Jèhófà. Dípò tí ì bá fi gbé ẹ̀mí ìfòyebánilò Jèhófà yọ, ńṣe ló ṣe bí ọkọ̀ rélùwéè akẹ́rù ńlá tàbí ọkọ̀ òkun gìrìwò agbépo tá a mẹ́nu kàn níṣàájú. Nígbà tó ti sọ pé ìlú yẹn á pa run, ó fẹ́ kó pa run dandan! Ṣùgbọ́n Jèhófà fi sùúrù kọ́ wòlíì rẹ̀ aláìnísùúrù yìí lẹ́kọ̀ọ́ mánigbàgbé kan nípa ìfòyebánilò àti àánú.—Jónà, orí 4.

Jèhófà jẹ́ afòyebánilò ó sì mọ ibi tí agbára wa mọ

19. (a) Kí nìdí tá a fi lè ní ìdánilójú pé Jèhófà ń fòye bá wa lò ní ti ohun tó ń retí látọ̀dọ̀ wa? (b) Báwo ni Òwe 19:17 ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ọ̀gá “rere àti afòyebánilò” àti pé ó níwà ìrẹ̀lẹ̀ lọ́nà tó jinlẹ̀ jù lọ?

19 Níkẹyìn, Jèhófà ń fòye bá wa lò ní ti ohun tó ń retí látọ̀dọ̀ wa. Dáfídì Ọba sọ pé: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ àti àìpé wa ju àwa fúnra wa lọ. Kì í retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ rárá. Bíbélì fi oríṣi ọ̀gá méjì hàn nípa fífi àwọn èèyàn tó jẹ́ ọ̀gá “rere àti afòyebánilò” wéra pẹ̀lú àwọn tó “ṣòro láti tẹ́ lọ́rùn.” (1 Pétérù 2:18) Irú Ọ̀gá èwo ni Jèhófà jẹ́? Kíyè sí ohun tí Òwe 19:17 sọ, ó ní: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín.” Dájúdájú, ọ̀gá rere àti afòyebánilò nìkan ló máa ń ṣàkíyèsí gbogbo oore tá a bá ṣe fáwọn ẹni rírẹlẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ìwé Mímọ́ yìí ń fi hàn pé ńṣe ni Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ka ara rẹ̀ sẹ́ni tó yẹ kó tún máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ aráyé lásánlàsàn fún oore tí wọ́n bá ṣe! Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó jinlẹ̀ jùyẹn lọ ò mà tún sí mọ́ o.

20. Ìdánilójú wo la ní pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà wa àti pé ó ń dáhùn wọn?

20 Ìwà pẹ̀lẹ́ àti ìfòyebánilò kan náà yìí ni Jèhófà ṣì fi ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò lóde òní. Nígbà tí a bá fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà sí i, ó ń gbọ́ wa. Bí kò bá tilẹ̀ rán áńgẹ́lì láti wá bá wa sọ̀rọ̀, ká má rò pé kò gbọ́ àdúrà wa o. Rántí pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ pé kí wọ́n “máa bá a lọ ní gbígbàdúrà” kí wọ́n dá òun sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó fi kún un pé: “Kí a lè tètè mú mi padà bọ̀ sípò sọ́dọ̀ yín.” (Hébérù 13:18, 19) Ìyẹn fi hàn pé àdúrà wa lè sún Jèhófà láti ṣe ohun tí kì bá má ti ṣe!—Jákọ́bù 5:16.

21. Kí ni kò yẹ ká ronú pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà jẹ́ láé, kàkà bẹ́ẹ̀, kí ló yẹ kó yé wa nípa Jèhófà?

21 Àmọ́ ṣá o, èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn yìí, ìyẹn ìwà tútù rẹ̀, bí ó ṣe ń fẹ́ láti fetí síni, sùúrù rẹ̀, ìfòyebánilò rẹ̀, kò fi hàn pé Jèhófà máa ń bomi la àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ o. Àwọn àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lè máa rò pé àwọn ń fi òye bá àwọn ọmọ ìjọ wọn lò nígbà tí wọ́n bá ń bomi la ìlànà ìwà híhù Jèhófà kí wọ́n lè máa fi rìn wọ́n létí. (2 Tímótì 4:3) Ṣùgbọ́n ìwà pé kéèyàn bomi la òótọ́ ọ̀rọ̀ nítorí àtilé ṣàṣeyọrí kò bá ẹ̀mí ìfòyebánilò ti Ọlọ́run mu rárá. Mímọ́ ni Jèhófà jẹ́; kò ní sọ ìlànà òdodo rẹ̀ di eléèérí rárá. (Léfítíkù 11:44) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fẹ́ràn ìfòyebánilò Jèhófà, pàápàá nítorí pé ó jẹ́ àmì ìrẹ̀lẹ̀. Ǹjẹ́ kò wú ọ lórí gidigidi pé Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́gbọ́n jù lọ láyé lọ́run, ṣì tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lọ́nà tí kò láfiwé? Ohun ayọ̀ mà ni o, pé ká sún mọ́ Ọlọ́run yìí, tó jẹ́ pé ó tóbi lọ́ba, síbẹ̀ tó ṣì jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́, onísùúrù àti afòyebánilò!

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn akọ̀wé ìgbàanì kan, ìyẹn àwọn Sófẹ́rímù, yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí padà sí pé Jeremáyà ló tẹ̀ ba mọ́lẹ̀, dípò Jèhófà. Àwọn gbà pé kó bójú mu rárá láti sọ pé odindi Ọlọ́run ṣe irú nǹkan tó rẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ kókó inú ẹsẹ pàtàkì yìí nù. Ṣùgbọ́n, Bíbélì The New English Bible sọ ọ̀rọ̀ Jeremáyà bó ṣe tọ́, ó ní ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Rántí, jọ̀wọ́ rántí, kó o tẹ̀ ba mọ́lẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi.”

^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn ẹ̀dà Bíbélì mìíràn pè é ní “ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó tinú ọgbọ́n wá” àti “ìwà pẹ̀lẹ́ tó ń fi ọgbọ́n hàn.”

^ ìpínrọ̀ 12 Ó dára láti mọ̀ pé Bíbélì fi hàn pé sùúrù jẹ́ òdìkejì ìrera. (Oníwàásù 7:8) Sùúrù Jèhófà sì tún jẹ́ ẹ̀rí síwájú sí i pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.—2 Pétérù 3:9.

^ ìpínrọ̀ 18 Sáàmù 86:5 sọ pé Jèhófà jẹ́ “ẹni rere” àti pé ó “ṣe tán láti dárí jini.” Nígbà tí wọ́n máa tú gbólóhùn náà “ṣe tán láti dárí jini” inú sáàmù náà lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì, wọ́n pè é ní e·pi·ei·kesʹ tàbí pé ó “ń fòye báni lò.”