ORÍ 21
Jésù Fi “Ọgbọ́n Ọlọ́run” Hàn
1-3. Ojú wo làwọn èèyàn tó wà níbi tí Jésù gbé dàgbà fi wo ẹ̀kọ́ rẹ̀, kí sì ni wọn ò mọ̀ nípa rẹ̀?
ẸNU ya àwọn èèyàn gan-an bí wọ́n ṣe rí i tí Jésù tó jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin dúró níwájú wọn nínú sínágọ́gù, tó sì ń kọ́ wọn. Ẹni tí wọ́n mọ̀ dáadáa ni Jésù. Ìlú wọn ló gbé dàgbà, ó sì ti fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ káfíńtà níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù wà lára àwọn tó kọ́ ilé tí àwọn kan nínú wọn ń gbé, tàbí kó jẹ́ pé òun ló tiẹ̀ bá àwọn kan ṣe àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò lóko. a Àmọ́ ṣé wọ́n máa fẹ́ gbọ́ ohun tí ẹni tí wọ́n mọ̀ sí káfíńtà tẹ́lẹ̀ yìí fẹ́ kọ́ wọn?
2 Ẹnu ya ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù, tó fi jẹ́ pé wọ́n ń béèrè pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí?” Àmọ́ wọ́n tún ń sọ pé: “Ṣebí káfíńtà yẹn nìyí, ọmọ Màríà?” (Mátíù 13:54-58; Máàkù 6:1-3) Ó mà ṣe o, ńṣe làwọn èèyàn tó wà níbi tí Jésù gbé dàgbà yìí ń rò ó pé, ‘Ṣebí káfíńtà tó wà ládùúgbò wa yẹn náà ni, kí ló fẹ́ kọ́ wa?’ Pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣe kọ́ni lọ́gbọ́n tó, wọn ò fetí sí i. Wọn ò mọ̀ pé ọgbọ́n ara ẹ̀ kọ́ ló fi ń kọ́ wọn.
3 Ibo ni Jésù ti rí ọgbọ́n tó fi ń kọ́ àwọn èèyàn? Jésù sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti ẹni tó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù “fi ọgbọ́n Ọlọ́run . . . hàn wá.” (1 Kọ́ríńtì 1:30) Jèhófà fi ọgbọ́n rẹ̀ hàn nípasẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀. Kódà, Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.” (Jòhánù 10:30) Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tí Jésù gbà fi “ọgbọ́n Ọlọ́run” hàn.
Ohun Tó Fi Kọ́ni
4. (a) Kí ni ìwàásù Jésù dá lé, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an? (b) Kí nìdí tí ìmọ̀ràn Jésù fi máa ń wúlò ní gbogbo ìgbà, tó sì máa ń ṣe àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ láǹfààní?
4 Àkọ́kọ́, Jésù fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nínú ohun tó kọ́ àwọn èèyàn. Ohun tí ọ̀rọ̀ ẹ̀ dá lé ni “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an torí pé Ìjọba yìí ni Jèhófà máa lò láti dá orúkọ rẹ̀ láre, láti fi hàn pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Alákòóso ayé àtọ̀run, Ìjọba yìí náà ló sì máa lò láti bù kún aráyé títí láé. Nínú ẹ̀kọ́ Jésù, ó tún fún wa nímọ̀ràn ọlọ́gbọ́n nípa bá a ṣe lè máa gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́. Ìyẹn fi hàn pé òun ni “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn” tí wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀. (Àìsáyà 9:6) Kí nìdí tí ìmọ̀ràn Jésù fi wúlò tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó sì mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ó tún mọ bí àwa èèyàn ṣe máa ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an. Ìdí nìyẹn tí ìmọ̀ràn ẹ̀ fi máa ń wúlò ní gbogbo ìgbà, tó sì máa ń ṣe àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ láǹfààní. “Ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun” ló máa ń ti ẹnu Jésù jáde. Torí náà, ó dájú pé tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ẹ̀, a máa rí ìgbàlà.—Jòhánù 6:68.
5. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè?
5 Àpẹẹrẹ kan tó ta yọ tó jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n tó wà nínú ẹ̀kọ́ Jésù ò láfiwé ni Ìwàásù Orí Òkè. Ó wà nínú Mátíù 5:3–7:27. Téèyàn bá fẹ́ sọ ọ́ bó ṣe wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn, ó lè má gbà ju ogún (20) ìṣẹ́jú lọ. Àmọ́ títí láé ni ìmọ̀ràn inú ẹ̀ á máa wúlò, torí bó ṣe wúlò láyé ìgbà tí Jésù sọ ọ́ náà ló ṣe wúlò lóde òní. Oríṣiríṣi nǹkan ni Jésù sọ nínú ìwàásù yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ bá a ṣe lè jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú àwọn míì dáa sí i (5:23-26, 38-42; 7:1-5, 12), bá a ṣe lè sá fún ìṣekúṣe (5:27-32), àti bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀ (6:19-24; 7:24-27). Àmọ́ Jésù ò kàn sọ àwọn ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, ó tún ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kéèyàn máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì fi àpẹẹrẹ ti ọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn. Ìyẹn jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ rí ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀.
6-8. (a) Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé ìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàníyàn? (b) Kí ló fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run ni Jésù ń lò?
6 Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Jésù fún wa nínú Mátíù orí kẹfà, nípa bá ò ṣe ní máa ṣàníyàn nípa nǹkan ìní tara. Jésù sọ pé: “Ẹ yéé ṣàníyàn nípa ẹ̀mí yín, ní ti ohun tí ẹ máa jẹ tàbí tí ẹ máa mu tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ máa wọ̀.” (Ẹsẹ 25) Gbogbo wa la nílò oúnjẹ àti aṣọ, torí náà, kò sí béèyàn ò ṣe ní máa ronú nípa bó ṣe máa ní wọn. Àmọ́ Jésù sọ pé ká “yéé ṣàníyàn” nípa àwọn nǹkan yẹn. b Kí nìdí?
7 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe ṣàlàyé ìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣàníyàn. Ó sọ pé Jèhófà ló jẹ́ ká wà láàyè, tó sì dá ara wa, torí náà, ó dájú pé ó máa pèsè oúnjẹ fún wa láti gbé ẹ̀mí wa ró, á sì pèsè aṣọ tá a máa wọ̀. (Ẹsẹ 25) Tí Ọlọ́run bá lè pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ, tó sì ṣe àwọn òdòdó lọ́ṣọ̀ọ́, ó dájú pé ó máa bójú tó àwa èèyàn tá à ń sìn ín! (Ẹsẹ 26, 28-30) Ká sòótọ́, tá a bá ń ṣàníyàn, kò lè ṣe wá láǹfààní kankan. Kódà, kò lè fi bín-ín-tín kún ìwàláàyè wa. c (Ẹsẹ 27) Báwo la ṣe lè yẹra fún ṣíṣe àníyàn? Jésù gbà wá nímọ̀ràn pé ká máa fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ torí ó dájú pé gbogbo ohun tá a nílò lójoojúmọ́ ni Baba wa ọ̀run “máa fi kún un” fún wa. (Ẹsẹ 33) Jésù wá fi ìmọ̀ràn kan tó wúlò gan-an parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní ká má da àníyàn tọ̀la pọ̀ mọ́ tòní. (Ẹsẹ 34) Nígbà míì, àwọn ohun tá à ń ṣàníyàn nípa ẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀ rárá, kí wá nìdí tí àá fi máa da ara wa láàmú? Tá a bá fi ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí Jésù fún wa yìí sílò, a ò ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá ara wa bíi tọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, àá sì máa láyọ̀.
8 A ti wá rí i báyìí pé bí ìmọ̀ràn Jésù ṣe wúlò ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì (2,000) sẹ́yìn náà ló ṣe wúlò lóde òní. Ẹ̀rí kan nìyẹn pé ọgbọ́n Ọlọ́run ni Jésù ń lò. Kódà, tí àwọn agbaninímọ̀ràn tó dáa jù nínú ọmọ aráyé bá fúnni nímọ̀ràn, tó bá yá, kò ní bágbà mu mọ́, á wá di dandan pé kí wọ́n tún un ṣe tàbí kí wọ́n fi òmíràn rọ́pò ẹ̀. Àmọ́ ní ti ẹ̀kọ́ Jésù, kò sígbà tí kì í wúlò. Ìyẹn ò sì yà wá lẹ́nu, torí pé “àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn yìí ń sọ.—Jòhánù 3:34.
Ọ̀nà Tó Gbà Ń Kọ́ni
9. Kí làwọn ọmọ ogun kan sọ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni, kí sì nìdí tí kò fi jẹ́ àsọdùn?
9 Ọ̀nà kejì tí Jésù tún gbà fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn ni ọ̀nà tó gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà kan, àwọn ọmọ ogun tí wọ́n rán lọ mú Jésù pa dà lọ́wọ́ òfo, wọ́n ní: “Èèyàn kankan ò sọ̀rọ̀ báyìí rí.” (Jòhánù 7:45, 46) Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe àsọdùn. Torí nínú gbogbo èèyàn tó ti gbé láyé, Jésù tó “wá láti òkè” ló ní ìmọ̀ àti ìrírí tó pọ̀ jù lọ. (Jòhánù 8:23) Ká sòótọ́, kò sí èèyàn míì tó lè kọ́ni lọ́nà tí Jésù gbà kọ́ni. Jẹ́ ká wo méjì péré nínú àwọn ọ̀nà tí Olùkọ́ tó gbọ́n yìí gbà kọ́ni.
“Bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò náà lẹ́nu”
10, 11. (a) Kí nìdí tí ọ̀nà tí Jésù gbà ń lo àkàwé fi yani lẹ́nu? (b) Kí ni àkàwé, àpẹẹrẹ wo ló sì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àkàwé Jésù máa ń wọni lọ́kàn?
10 Ó máa ń lo àpèjúwe lọ́nà tó dáa. Bíbélì sọ pé: “Jésù fi àpèjúwe [sọ̀rọ̀] fún àwọn èrò náà. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìlo àpèjúwe.” (Mátíù 13:34) Ó gbàfiyèsí gan-an bí Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ ohun táwọn èèyàn ń rí lójoojúmọ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀. Lára ohun táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tí Jésù fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni: Àgbẹ̀ tó ń fúnrúgbìn, obìnrin tó fẹ́ ṣe búrẹ́dì, àwọn ọmọ tó ń ṣeré níbi ọjà, àwọn apẹja tó ń fa àwọ̀n sókè látinú omi àti olùṣọ́ àgùntàn tó ń wá àgùntàn tó sọ nù. Tó bá jẹ́ pé ohun tẹ́nì kan mọ̀ dáadáa ni wọ́n fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún un, ó máa tètè yé e, á wọ̀ ọ́ lọ́kàn, kò sì ní gbàgbé.—Mátíù 11:16-19; 13:3-8, 33, 47-50; 18:12-14.
11 Jésù sábà máa ń lo àkàwé, ìyẹn ìtàn ṣókí kan tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìwà rere tàbí èyí tó ń mú kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run. Ó ṣe tán, ìtàn máa ń tètè yé èèyàn, ó sì máa ń jẹ́ kọ́rọ̀ wọni lọ́kàn. Ìdí nìyẹn tí àwọn àkàwé tí Jésù fi ń kọ́ni fi máa ń wọni lọ́kàn. Ọ̀pọ̀ àkàwé ni Jésù fi ṣàpèjúwe Bàbá rẹ̀ lọ́nà téèyàn ò fi ní gbàgbé. Bí àpẹẹrẹ, kò sẹ́ni tí àkàwé ọmọ onínàákúnàá ò ní yé. Àkàwé yẹn jẹ́ ká rí i pé tẹ́nì kan bá fi Jèhófà sílẹ̀ àmọ́ tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa ṣàánú ẹ̀, á sì gbà á pa dà tìfẹ́tìfẹ́.—Lúùkù 15:11-32.
12. (a) Kí nìdí tí Jésù fi máa ń lo ìbéèrè tó bá ń kọ́ni? (b) Báwo ni Jésù ṣe pa àwọn tó ń ta kò ó lẹ́nu mọ́?
12 Ó máa ń lo ìbéèrè lọ́nà tó dáa. Jésù máa ń lo ìbéèrè káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀ lè ronú fúnra wọn, kí wọ́n sì ṣèpinnu tó dáa. (Mátíù 12:24-30; 17:24-27; 22:41-46) Nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn bi Jésù bóyá Ọlọ́run ló fún un láṣẹ, Jésù fèsì pé: “Ṣé láti ọ̀run ni ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn ti wá àbí látọ̀dọ̀ èèyàn?” Wọn ò mọ nǹkan tí wọ́n lè sọ, wọ́n wá ń sọ láàárín ara wọn pé: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á gbọ́?’ Àmọ́, ṣé a lè sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn’?” Ṣùgbọ́n, “wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èrò, torí gbogbo àwọn yìí gbà pé wòlíì ni Jòhánù lóòótọ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n ro ọ̀rọ̀ yẹn, wọ́n wá dáhùn pé: “A ò mọ̀.” (Máàkù 11:27-33; Mátíù 21:23-27) Ìbéèrè tí Jésù béèrè wẹ́rẹ́ yìí pa wọ́n lẹ́nu mọ́, ó sì jẹ́ kó hàn pé èrò ibi ló wà lọ́kàn wọn.
13-15. Báwo ni ìtàn aláàánú ará Samáríà ṣe fi hàn pé Jésù jẹ́ ọlọ́gbọ́n?
13 Nígbà míì, Jésù tún máa ń lo àkàwé àti ìbéèrè pa pọ̀. Ó máa ń lo ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ kí àwọn àkàwé ẹ̀ lè yé àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀. Nígbà tí Júù kan tó jẹ́ amòfin bi Jésù nípa ohun tó yẹ kóun ṣe kí òun lè rí ìyè àìnípẹ̀kun, Jésù rán an létí Òfin Mósè tó sọ pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì ẹ̀. Àmọ́, torí pé amòfin yìí fẹ́ fi hàn pé olódodo lòun, ó béèrè pé: “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?” Jésù wá sọ ìtàn kan láti fi dáhùn ìbéèrè ẹ̀. Ó sọ pé lọ́jọ́ kan, ọkùnrin Júù kan ń dá rìnrìn àjò, ló bá bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n lù ú débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Àwọn Júù méjì bá a níbẹ̀. Àkọ́kọ́ jẹ́ àlùfáà, ọmọ Léfì lẹnì kejì, àmọ́ àwọn méjèèjì ò yà sọ́dọ̀ ẹ̀. Kò pẹ́ ni ará Samáríà kan débẹ̀. Àánú ọkùnrin yẹn ṣe é, torí náà ó bá a tọ́jú egbò ẹ̀, ó sì rọra gbé e lọ sílé ìgbàlejò kan títí tára ẹ̀ á fi yá. Nígbà tí Jésù parí ìtàn yẹn, ó bi amòfin náà pé: “Lójú tìẹ, èwo nínú àwọn mẹ́ta yìí ló fi hàn pé òun jẹ́ ọmọnìkejì ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà?” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló fèsì pé: “Ẹni tó ṣàánú rẹ̀ ni.”—Lúùkù 10:25-37.
14 Báwo ni ìtàn yìí ṣe fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni Jésù? Nígbà ayé Jésù, àwọn tí àwọn Júù kà sí “ọmọnìkejì” wọn ni àwọn Júù ẹgbẹ́ wọn tí wọ́n jọ ń pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ mọ́, wọn ò ka àwọn ará Samáríà sí “ọmọnìkejì” wọn rárá. (Jòhánù 4:9) Ká ní ará Samáríà ni Jésù sọ pé ó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, tó wá sọ pé Júù lẹni tó ràn án lọ́wọ́, ó dájú pé èrò tí ọkùnrin yìí ní nípa àwọn ará Samáríà lè má yí pa dà. Torí náà, Jésù fọgbọ́n sọ ìtàn yẹn lọ́nà tó fi jẹ́ pé ará Samáríà ló ṣàánú Júù yẹn, tó sì fìfẹ́ tọ́jú ẹ̀. Jésù tún fẹ́ kí amòfin náà túbọ̀ lóye ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ “ọmọnìkejì” ẹ̀, torí náà ó bi í ni ìbéèrè kan nígbà tó parí ìtàn yẹn. Ẹ rántí pé ohun tí amòfin náà fẹ́ mọ̀ gan-an ni ẹni tó yẹ kóun kà sí ọmọnìkejì òun, tó sì yẹ kí òun nífẹ̀ẹ́. Àmọ́ Jésù bi í pé: ‘Lójú tìẹ, èwo nínú àwọn mẹ́ta yìí ló fi hàn pé òun jẹ́ ọmọnìkejì ọkùnrin náà?’ Kíyè sí i pé kì í ṣe ẹni tí wọ́n ṣe lóore, ìyẹn ẹni tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà ni Jésù pàfiyèsí sí bí kò ṣe ẹni tó ṣe oore náà, ìyẹn ará Samáríà. Tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíì tọkàntọkàn, á máa fàánú hàn sí wọn láìka ẹ̀yà wọn tàbí ibi tí wọ́n ti wá sí. Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu jù lọ ni Jésù gbà ṣàlàyé kókó yìí!
15 Abájọ tí ẹnu fi máa ń ya àwọn èèyàn tí wọ́n bá gbọ́ bí Jésù “ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́,” tó sì máa ń wù wọ́n pé kí wọ́n tẹ́tí sí i. (Mátíù 7:28, 29) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí “èrò rẹpẹtẹ” wà lọ́dọ̀ Jésù fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko, tí wọn ò sì lọ wá ohun tí wọ́n máa jẹ!—Máàkù 8:1, 2.
Ìgbé Ayé Jésù
16. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ‘fi hàn’ pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí òun?
16 Ọ̀nà kẹta tí Jésù gbà fi ọgbọ́n Ọlọ́run hàn ni àwọn nǹkan tó ṣe nígbà tó wà láyé. Ohun tẹ́nì kan bá ń ṣe ló máa fi hàn pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jémíìsì béèrè pé: “Ọlọ́gbọ́n . . . wo ló wà láàárín yín?” Ó wá dáhùn ìbéèrè yìí fúnra ẹ̀ pé, béèyàn ṣe lè fi hàn pé òun gbọ́n ni pé: “Kó fi ìwà rere rẹ̀ hàn.” (Jémíìsì 3:13) Ìwà àti ìṣe Jésù nígbà tó wà láyé ‘fi hàn’ pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe lo ọgbọ́n àti òye nínú ìgbé ayé rẹ̀ àti bó ṣe ṣe sáwọn èèyàn.
17. Kí làwọn nǹkan tí Jésù ṣe tó fi hàn pé ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì?
17 Ṣó o kíyè sí i pé àwọn tí kì í lo òye sábà máa ń ṣe àṣejù tàbí kí wọ́n má ṣe ohun tó yẹ? Ká sòótọ́, kéèyàn tó lè ṣe ohun tó yẹ, kó má sì ṣàṣejù, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Jésù gbé ọgbọ́n Ọlọ́run yọ, ní ti pé ó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ohun gbogbo. Ohun tí Jésù kà sí pàtàkì jù ni àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Ó máa ń fìtara wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Kódà, ó sọ pé: “Ìdí tí mo ṣe wá nìyí.” (Máàkù 1:38) Èyí fi hàn pé owó àtàwọn nǹkan tara míì kọ́ ló ṣe pàtàkì sí Jésù, ó sì jọ pé àwọn nǹkan tara díẹ̀ ló ní. (Mátíù 8:20) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé Jésù fìyà jẹ ara ẹ̀. Bíi ti Baba rẹ̀ tó jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe jẹ́ aláyọ̀, ó sì tún ṣe ohun tó mú káwọn míì láyọ̀. (1 Tímótì 1:11; 6:15) Nígbà tí Jésù lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan, tí wọ́n sábà máa ń ṣe tìlù torin, táwọn èèyàn á sì máa fẹsẹ̀ rajó, kò ṣe ohun tó máa ba ayọ̀ wọn jẹ́. Nígbà tí ọtí wáìnì tiẹ̀ tán, ṣe ló sọ omi di wáìnì tó dáa gan-an, tó “ń mú ọkàn èèyàn yọ̀.” (Sáàmù 104:15; Jòhánù 2:1-11) Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn pe Jésù wá jẹun nílé wọn, ó sì máa ń lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.—Lúùkù 10:38-42; 14:1-6.
18. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú bó ṣe máa ń ṣe sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀?
18 Bí Jésù ṣe máa ń ṣe sáwọn èèyàn fi hàn pé ó ní ọgbọ́n àti òye tó jinlẹ̀. Èyí jẹ́ kó mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ àti bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ṣe ń ronú. Ó mọ̀ pé aláìpé ni wọ́n. Síbẹ̀, ó kíyè sí àwọn ìwà dáadáa tí wọ́n ní. Ó mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́, ó sì tún mọ̀ pé wọ́n máa wúlò fún Jèhófà. (Jòhánù 6:44) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n sì máa ń ṣàṣìṣe nígbà míì, ó ṣe tán láti fọkàn tán wọn. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó fa iṣẹ́ pàtàkì lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́. Ó rán wọn lọ wàásù ìhìn rere, ó sì dá a lójú pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. (Mátíù 28:19, 20) Ìwé Ìṣe jẹ́ ká rí i pé àwọn ọmọ èyìn náà ṣe ohun tí Jésù sọ pé kí wọ́n ṣe lóòótọ́. (Ìṣe 2:41, 42; 4:33; 5:27-32) Bó sì ṣe fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ọlọ́gbọ́n ni.
19. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé “oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn” lòun?
19 Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ ní Orí ogún (20) nínú ìwé yìí, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó bá gbọ́n máa ń ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwà tútù. Àpẹẹrẹ tó sì dáa jù ni Jèhófà fi lélẹ̀. Jésù wá ńkọ́? Òun náà níwà ìrẹ̀lẹ̀ púpọ̀, ó sì hàn nínú bó ṣe ń ṣe sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù tó sì yàtọ̀ pátápátá sáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, kò kà wọ́n sí aláìjámọ́ nǹkan kan. Kò sì ṣe ohun tí wọ́n á fi máa rò pé aláìmọ̀kan lásánlàsàn làwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ ibi tí agbára wọ́n mọ, ó sì ní sùúrù fún wọn. (Máàkù 14:34-38; Jòhánù 16:12) Kódà, ọkàn àwọn ọmọdé pàápàá máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ Jésù. Ó sì dájú pé ohun tó mú kí wọ́n sún mọ́ ọn ni pé wọ́n rí i pé ó jẹ́ “oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn.”—Mátíù 11:29; Máàkù 10:13-16.
20. Nígbà tí obìnrin Kèfèrí kan bẹ Jésù pé kó wo ọmọ òun tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu sàn, báwo ló ṣe fòye bá obìnrin náà lò?
20 Jésù tún fi hàn pé òun níwà ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Ọlọ́run lọ́nà pàtàkì míì. Ó máa ń fòye báni lò, ó sì máa ń yí èrò ẹ̀ pa dà kó lè fàánú hàn nígbà tó bá yẹ. Àpẹẹrẹ kan ni ìgbà tí obìnrin kan tó jẹ́ Kèfèrí bẹ Jésù pé kó wo ọmọ òun tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu gidigidi sàn. Ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù ṣe láti fi hàn pé òun ò ní ṣe ohun tí obìnrin náà fẹ́. Ohun àkọ́kọ́ ni pé kò dá a lóhùn; ìkejì, ó sọ fún un ní tààràtà pé àwọn Júù la rán òun sí kì í ṣe àwọn Kèfèrí; ìkẹta, ó sọ àpèjúwe kan láti fi tẹ kókó kan náà mọ́ ọn létí. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jésù ṣe yìí, obìnrin náà ò rẹ̀wẹ̀sì torí ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára gan-an. Torí pé obìnrin yìí fi hàn pé òun nígbàgbọ́ tó lágbára, kí ni Jésù wá ṣe? Ohun tó sọ pé òun ò ní ṣe yẹn gangan ló ṣe. Ó wo ọmọ obìnrin yẹn sàn. (Mátíù 15:21-28) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ẹni tó bá sì níwà ìrẹ̀lẹ̀ la lè sọ pé ó gbọ́n lóòótọ́.
21. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà, ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù?
21 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa ní Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ìwà àti ìṣe Jésù, ẹni tó gbọ́n jù lọ nínú gbogbo èèyàn tó ti gbé ayé rí! Àmọ́, ẹ jẹ́ ká rántí pé ńṣe ni Jésù fìwà jọ Baba ẹ̀ lọ́nà pípé. Torí náà tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà, ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù, ńṣe là ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣèwà hù. Ní orí tó kàn, a máa rí bá a ṣe lè túbọ̀ máa lo ọgbọ́n Ọlọ́run nínú ìgbé ayé wa.
a Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn káfíńtà ló máa ń bá àwọn èèyàn kọ́lé, wọ́n máa ń bá àwọn èèyàn kan àwọn nǹkan bí àga, tábìlì tàbí àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò lóko. Justin Martyr tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni sọ nípa Jésù pé: “Nígbà tó wà láyé, ó máa ń ṣiṣẹ́ káfíńtà, ó sì máa ń bá àwọn èèyàn ṣe àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò lóko, bí ohun ìtúlẹ̀ àti àjàgà.”
b Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Gíríìkì tá a tú sí “ṣàníyàn” túmọ̀ sí “kí ọkàn èèyàn má pa pọ̀.” Bí wọ́n ṣe lò ó nínú Mátíù 6:25, ó túmọ̀ sí kí nǹkan máa ba èèyàn lẹ́rù, kí ọkàn ẹ̀ má sì balẹ̀ débi pé nǹkan yẹn lá máa rò ṣáá, tíyẹn ò sì jẹ́ kó láyọ̀.
c Ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe fi hàn pé téèyàn bá ń ṣe àníyàn àṣejù, tó sì ń ṣe wàhálà jù, ó lè ní àrùn ọkàn àtàwọn àìsàn míì tó lè gbẹ̀mí ẹni.