Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 2

Ṣé Òótọ́ Ni Pé O Lè “Sún Mọ́ Ọlọ́run”?

Ṣé Òótọ́ Ni Pé O Lè “Sún Mọ́ Ọlọ́run”?

1, 2. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé kò ṣeé ṣe láé, àmọ́ kí ni Bíbélì fi dá wa lójú? (b) Kí ni Jèhófà sọ pé Ábúráhámù jẹ́ sí òun, kí sì nìdí?

 BÁWO ló ṣe máa rí lára ẹ ká sọ pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé pè ẹ́, tó sì sọ fún ẹ pé, “Màá fẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ mi”? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ láé. Wọ́n rò pé àwa èèyàn lásánlàsàn ò lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Àmọ́, Bíbélì fi dá wa lójú pé a lè sún mọ́ Ọlọ́run, ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

2 Ábúráhámù tó gbé ayé nígbà àtijọ́ nírú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Kódà, Jèhófà pè é ní “ọ̀rẹ́ mi.” (Àìsáyà 41:8) Àbẹ́ ò rí nǹkan, Jèhófà ka Ábúráhámù sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Kí ló mú kíyẹn ṣeé ṣe? Ìdí ni pé Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” (Jémíìsì 2:23) Bó ṣe rí nígbà yẹn náà ló rí lóde òní, inú Jèhófà máa ń dùn láti mú àwọn tó ń sìn ín lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì máa ń “fi ìfẹ́ hàn sí” wọn. (Diutarónómì 10:15) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jémíìsì 4:8) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ gan-an?

3. Kí ni Jèhófà rọ̀ wá láti ṣe, ìlérí wo ló sì ṣe fún wa tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?

3 Jèhófà ń rọ̀ wá pé ká sún mọ́ òun. Ìyẹn fi hàn pé ó fẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun. Abájọ tó fi ṣèlérí pé tá a bá gbìyànjú láti sún mọ́ òun, òun náà máa sún mọ́ wa. Àá wá tipa bẹ́ẹ̀ di ‘ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́’ pẹ̀lú Jèhófà. (Sáàmù 25:14) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ nìyẹn jẹ́! Tá a bá pe ẹni méjì ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ohun tá à ń sọ ni pé wọ́n máa ń finú han ara wọn, wọ́n sì máa ń fọkàn tán ara wọn.

4. Kí làwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ sábà máa ń ṣe, kí ló sì fi hàn pé irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà jẹ́ fún àwọn tó sún mọ́ ọn?

4 Ṣé ẹnì kan wà tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tó o máa ń finú hàn? Kò sí àní-àní pé onítọ̀hún kì í fọ̀rọ̀ rẹ ṣeré. Ó dájú pé o mọyì rẹ̀ gan-an torí pé ọ̀rẹ́ tó ń dúró tini ni. Ó máa ń yá ẹ lára láti sọ ohun tó ń múnú ẹ dùn fún un torí o mọ̀ pé ṣé ló máa bá ẹ yọ̀ dípò táá fi jowú ẹ. Tó bá sì jẹ́ ohun tó ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́ lo fẹ́ sọ fún un, ó ṣe tán láti gbọ́ ẹ lágbọ̀ọ́yé, á sì tù ẹ́ nínú. O mọ̀ pé tọ́rọ̀ ẹ ò bá tiẹ̀ yé ẹlòmíì, ọ̀rọ̀ ẹ á yé e. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run tó o sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. Ọkàn ẹ máa balẹ̀ torí pé Ọ̀rẹ́ tó ju ọ̀rẹ́ lọ ni, ó mọyì ẹ, kì í fọ̀rọ̀ ẹ ṣeré, ọ̀rọ̀ ẹ sì máa ń tètè yé e. (Sáàmù 103:14; 1 Pétérù 5:7) Ìwọ náà fọkàn tán an débi pé kò sóhun tó ò lè sọ fún un, nítorí o mọ̀ pé kì í fi àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i sílẹ̀. (Sáàmù 18:25) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe wa la fi di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀, òun ló mú kó ṣeé ṣe.

Jèhófà Ló Mú Kó Ṣeé Ṣe

5. Kí ni Jèhófà ṣe tó mú ká lè sún mọ́ ọn?

5 Láìsí pé Jèhófà mú kó ṣeé ṣe, kò sí bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run torí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. (Sáàmù 5:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àmọ́ Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ rẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Lédè míì, Jèhófà rán Jésù wá sáyé kó lè “fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mátíù 20:28) Bá a ṣe fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà yẹn ló mú ká lè sún mọ́ Ọlọ́run. Ó ṣe kedere nígbà náà pé Ọlọ́run “ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa,” torí náà òun ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀.​—1 Jòhánù 4:19.

6, 7. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà kò fi ara ẹ̀ pa mọ́ fún wa? (b) Àwọn nǹkan wo ló mú ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́?

6 Jèhófà tún ṣe ohun míì tó mú ká lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀, ohun náà ni pé ó jẹ́ ká mọ ẹni tóun jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, kó o tó lè mú ẹnì kan lọ́rẹ̀ẹ́, ó ní láti jẹ́ pé o mọ onítọ̀hún dáadáa, ìwà àti ìṣe ẹ̀ sì bá ẹ lára mu. Ìbéèrè náà ni pé, ká sọ pé Jèhófà fi ara ẹ̀ pa mọ́, tí kò sì jẹ́ ká mọ òun, ṣé àá lè di ọ̀rẹ́ ẹ̀? A dúpẹ́ pé Jèhófà kò fara rẹ̀ pa mọ́ rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló sọ irú ẹni tóun jẹ́ fún wa. (Àìsáyà 45:19) Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo èèyàn ni Jèhófà mú kó ṣeé ṣe fún láti mọ òun, títí kan àwọn táráyé ń fojú àbùkù wò tàbí tí wọ́n kà sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.​—Mátíù 11:25.

Jèhófà mú ká túbọ̀ mọ òun nípasẹ̀ àwọn nǹkan tó dá àti nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀

7 Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe tó jẹ́ ká lè mọ̀ ọ́n? Àkọ́kọ́, àwọn nǹkan tó dá sáyé mú ká mọ irú ẹni tó jẹ́ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tó dá jẹ́ ká mọ bó ṣe lágbára tó, bí ọgbọ́n rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó àti bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. (Róòmù 1:20) Bó ti wù kó rí, kì í ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà dá nìkan ló jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Jèhófà tún tipasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣàlàyé irú ẹni tóun jẹ́ fún wa, ó ṣe tán Ọ̀gá ni Jèhófà tó bá di ká ṣàlàyé nǹkan.

Ohun Tí Jèhófà Sọ Nípa Ara Rẹ̀ Nínú Bíbélì

8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ Bíbélì fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

8 Bí wọ́n ṣe kọ Bíbélì lọ́nà tó rọrùn lóye fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi ṣàlàyé irú ẹni tóun jẹ́ kò ṣòro láti lóye rárá, ìyẹn sì jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé yàtọ̀ sí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó tún fẹ́ ká mọ òun ká sì nífẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú. Torí náà, bá a ṣe ń ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣe ló ń mú kó túbọ̀ máa wù wá láti sún mọ́ ọn. (Sáàmù 1:1-3) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó fani mọ́ra, tó sì ń múnú ẹni dùn tí Jèhófà sọ nípa ara rẹ̀ nínú Bíbélì.

9. Sọ díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà.

9 Àwọn gbólóhùn kan wà nínú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀. “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 37:28) “Agbára rẹ̀ pọ̀ gan-an.” (Jóòbù 37:23) “ ‘Adúróṣinṣin ni mí,’ ni Jèhófà wí.” (Jeremáyà 3:12) “Ọlọ́gbọ́n ni.” (Jóòbù 9:4) Ó jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Ẹ́kísódù 34:6) “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Paríparí ẹ̀, bá a ṣe sọ ní orí kìíní ìwé yìí, èyí tó ta yọ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà ni ìfẹ́. Ó ṣe tán, Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ó dájú pé tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa Jèhófà Baba wa ọ̀run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀, ṣe lá máa wù wá pé ká túbọ̀ sún mọ́ ọn ká sì di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

10, 11. (a) Kí lohun míì tí Jèhófà mú kí wọ́n kọ sínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí sì nìdí? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ bí agbára Ọlọ́run ṣe kàmàmà tó àti bó ṣe ń lò ó?

10 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà sọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ fún wa, ó tún rí i dájú pé wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àpẹẹrẹ bó ṣe fàwọn ànímọ́ yìí sílò. Bá a ṣe ń ka àwọn àkọsílẹ̀ yìí, ṣe ló ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí Jèhófà ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà. Ìyẹn ń jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́, ká sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan ká lè lóye ohun tá à ń sọ.

Bíbélì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà

11 Bíbélì sọ pé ‘agbára Ọlọ́run ń bani lẹ́rù.’ (Àìsáyà 40:26) Àmọ́, téèyàn bá kà nípa bó ṣe lo agbára rẹ̀ tó kàmàmà náà, èèyàn á túbọ̀ mọyì Baba wa ọ̀run. Àpẹẹrẹ kan ni bó ṣe mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Òkun Pupa já tó sì tún bójú tó wọn fún ogójì ọdún nínú aginjù. Rónú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí alagbalúgbú omi òkun pínyà níwájú wọn táwọn èèyàn tó tó mílíọ̀nù mẹ́ta (3,000,000) sì ń rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ la àárín òkun náà kọjá. Omi òkun náà dì gbagidi, ó sì dà bí ògiri gàgàrà lọ́tùn-ún àti lósì. (Ẹ́kísódù 14:21; 15:8) Yàtọ̀ síyẹn, o tún rí i bí Jèhófà ṣe tọ́jú àwọn èèyàn ẹ̀ nínú aginjù, tó sì tún dáàbò bò wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta kí wọ́n lè rómi mu, ó tún fún wọn lóúnjẹ tó dà bí irúgbìn funfun. (Ẹ́kísódù 16:31; Nọ́ńbà 20:11) Àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe yìí fi hàn pé ó lágbára, ó tún jẹ́ ká rí i pé ó máa ń lo agbára ẹ̀ láti ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́. Ká sòótọ́, ọkàn wa balẹ̀ gan-an bá a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run alágbára là ń gbàdúrà sí àti pé ó jẹ́ “ibi ààbò wa àti okun wa, ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.”​—Sáàmù 46:1.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣàpèjúwe ara ẹ̀ lọ́nà táá yé wa?

12 Àwọn nǹkan tó wà láyìíká wa láyé yìí làwa èèyàn lè rí, a ò lè rí àwọn nǹkan tó wà lọ́run. Ó ṣe tán, ọ̀run ni Jèhófà ń gbé, ẹ̀mí sì ni, síbẹ̀ ó mú kó rọrùn fún wa láti mọ òun. Bí Ọlọ́run bá ní kóun lo èdè tí òun àtàwọn áńgẹ́lì ń sọ láti fi ṣàpèjúwe bí òun ṣe rí fún wa, ó dájú pé kò lè yé wa rárá. Ṣe ló máa dà bí ìgbà tẹ́nì kan fẹ́ ṣàlàyé ìrísí ara rẹ̀ fún ẹnì kan tí wọ́n bí ní afọ́jú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà gba tiwa rò, ó sì ṣàpèjúwe bí òun ṣe rí lọ́nà tó lè yé wa. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń lo àfiwé, bíi kó fi ara rẹ̀ wé àwọn nǹkan tá a mọ̀ dáadáa. Kódà, a rígbà tó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ bíi pé ó ní àwọn ẹ̀yà ara kan bíi tàwa èèyàn. a

13. Kí ni Àìsáyà 40:11 fi Jèhófà wé, báwo ni àpèjúwe yẹn sì ṣe rí lára rẹ?

13 Kíyè sí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà nínú Àìsáyà 40:11, pé: “Ó máa bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ, Ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.” Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn tó máa ń fi “apá rẹ̀” gbé àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn. Èyí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, pàápàá jù lọ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lókun. Ó ń lo agbára ẹ̀ láti dáàbò bò wá, ó sì dájú pé tá a bá jólóòótọ́ sí i, kò ní fi wá sílẹ̀ láé. (Róòmù 8:38, 39) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé “àyà rẹ̀” ni Jèhófà Olùṣọ́ Àgùntàn ńlá náà gbé àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn rẹ̀ sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àyà ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn nílẹ̀ Ísírẹ́lì máa ń gbé àṣẹ̀ṣẹ̀bí ọ̀dọ́ àgùntàn sí, wọ́n á sì wá fi aṣọ wé e. Èyí jẹ́ kó dá wa lójú pé a ṣeyebíye lójú Jèhófà gan-an, ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ló sì fi ń mú wa. Ẹ gbọ́ ná, ṣéèyàn á fẹ́ jìnnà sírú Ọlọ́run yìí? Ó dájú pé ṣe la máa rọ̀ mọ́ ọn.

Ọmọ Fẹ́ Ká Mọ Baba

14. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ipasẹ̀ Jésù lọ́nà tó ṣe kedere jù tí Jèhófà gbà jẹ́ ká mọ òun?

14 Ipasẹ̀ Jésù, ààyò Ọmọ rẹ̀, ni ọ̀nà tó ṣe kedere jù tí Jèhófà gbà jẹ́ ká mọ òun. Tó bá di pé ká ṣàlàyé irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gangan, bó ṣe ń ronú àti bó ṣe ń hùwà, kò sẹ́ni tó lè ṣe é bíi ti Jésù. Ó ṣe tán, òun ni àkọ́bí, torí náà ó ti wà lọ́dọ̀ Jèhófà Baba rẹ̀ ṣáájú ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni láyé àti lọ́run. (Kólósè 1:15) Lédè míì, kò sí ẹni tó mọ Jèhófà dunjú tó Jésù. Ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé: “Kò sẹ́ni tó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba, kò sì sẹ́ni tó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.” (Lúùkù 10:22) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣí Bàbá rẹ̀ payá, tàbí lédè míì ọ̀nà wo ló gbà jẹ́ ká mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tó gbà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó wà láyé.

15, 16. Ọ̀nà méjì wo ni Jésù gbà jẹ́ ká mọ Jèhófà Bàbá rẹ̀?

15 Àkọ́kọ́, àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni jẹ́ ká mọ Jèhófà Bàbá rẹ̀. Bí Jésù ṣe ṣàlàyé irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ mú kó túbọ̀ wuni láti sún mọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù lo àkàwé kan láti mú káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ aláàánú, ó sì máa ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà. Nínú àkàwé yẹn, ó fi Jèhófà wé bàbá kan tí ọmọ rẹ̀ jẹ́ onínàákúnàá. Àmọ́ nígbà tó yá, ọmọ náà ronú pìwà dá, ó sì pa dà wálé. Kí ni bàbá inú àkáwé náà ṣe nígbà tó tajú kán rí ọmọ rẹ̀ lọ́ọ̀ọ́kán? Ṣe ni bàbá náà sáré pàdé ọmọ rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu. (Lúùkù 15:11-24) Jésù tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń “fa” àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ nítorí pé ó mọyì wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Jòhánù 6:44) Kódà, ó mọ̀ tí ẹyẹ ológoṣẹ́ tí kò ju bíńtín lọ bá fò wálẹ̀. Jésù wá ṣàlàyé pé: “Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí gan-an ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.” (Mátíù 10:29, 31) Kò sí àní-àní pé èèyàn á fẹ́ sún mọ́ irú Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ ẹni tó sì ń ṣìkẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀.

16 Ìkejì, àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Jésù fìwà jọ Bàbá rẹ̀ láìkù síbì kan débi tó fi lè sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòhánù 14:9) Nípa bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ka ọ̀rọ̀ nípa Jésù nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, yálà bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ̀ ni o tàbí ọwọ́ tó fi mú àwọn èèyàn, ohun tí Bàbá rẹ̀ máa ṣe gẹ́lẹ́ náà nìyẹn. Tó bá di pé ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, kò sí ọ̀nà míì tó dáa ju pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

17. Sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká rí ohun tí Jèhófà ṣe ká lè lóye irú ẹni tí òun jẹ́.

17 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé o fẹ́ ṣàlàyé ohun tí inú rere túmọ̀ sí fún ẹnì kan. Ó ṣeé ṣe kó o kó àlàyé palẹ̀ kí onítọ̀hún lè mọ ohun tọ́rọ̀ náà túmọ̀ sí. Ṣùgbọ́n báwo ló ṣe máa rí ká sọ pé o tọ́ka sí ẹnì kan tó ń fi inúure hàn sí ẹlòmíì, tó o wá sọ pé, “Àpẹẹrẹ ohun tá à ń pè ní inú rere nìyí”? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ náà “inú rere” á túbọ̀ nítumọ̀ sí onítọ̀hún, á sì yé e dáadáa. Ohun tí Jèhófà ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn kó lè túbọ̀ rọrùn fún wa láti lóye irú ẹni tóun jẹ́. Yàtọ̀ sí pé ó sọ irú ẹni tóun jẹ́, ó tún rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé ká lè túbọ̀ lóye irú ẹni tóun jẹ́. Torí náà, ṣe ni Jésù gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀. Lédè míì, ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń lo àwọn àkọsílẹ̀ inú Ìwé Ìhìn Rere tó sọ nípa Jésù láti sọ fún wa pé: “Irú ẹni tí mo jẹ́ gangan lẹ̀ ń rí yìí o.” Kí làwọn àkọsílẹ̀ yẹn sọ nípa Jésù nígbà tó wà láyé?

18. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ní ọgbọ́n àti agbára, kí ló sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo?

18 Téèyàn bá fẹ́ lóye àwọn ànímọ́ mẹ́rin tó gbawájú lára àwọn ànímọ́ Jèhófà dáadáa, àfi kéèyàn fara balẹ̀ kíyè sí Jésù. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ní agbára láti mú àwọn aláìsàn lára dá, láti pèsè oúnjẹ fáwọn tí ebi ń pa, kódà ó lè jí òkú dìde. Síbẹ̀, kò sígbà kankan tó lo agbára tó ní láti fi gbọ́ tara ẹ̀ tàbí láti fi ṣe àwọn èèyàn níkà. Jésù yàtọ̀ pátápátá sáwọn onímọtara-ẹni-nìkan tó máa ń ṣi agbára lò. (Mátíù 4:2-4) Jésù fẹ́ràn kéèyàn máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Bí àpẹẹrẹ, inú bí i nígbà tó rí bí àwọn oníṣòwò ṣe ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. (Mátíù 21:12, 13) Kì í ṣe ojúsàájú. Bí àpẹẹrẹ, kò fojú pa àwọn aláìní rẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò tàbùkù àwọn tí kò lẹ́nu láwùjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń ṣèrànwọ́ fún wọn kí ‘ara lè tù’ wọ́n. (Mátíù 11:4, 5, 28-30) Àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù mọ̀ pé ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé. Kódà, ó hàn nínú ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni pé ọgbọ́n rẹ̀ “ju [ti] Sólómọ́nì lọ.” (Mátíù 12:42) Bó ti wù kó rí, Jésù ò gbéra ga, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣe fọ́ńté torí ọgbọ́n tó ní. Tọmọdétàgbà, títí kan àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé lọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀ lọ́kàn. Ìdí sì ni pé àwọn ohun tó fi ń kọ́ni kò ṣòroó lóye, ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣe kedere, ó rọrùn, ó sì ṣeé mú lò.

19, 20. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé kò sẹ́ni bíi Jésù láyé yìí tó bá di pé ká fìfẹ́ hàn? (b) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń kà nípa Jésù, tá a sì ń ronú lórí àpẹẹrẹ dáadáa tó fi lélẹ̀?

19 Tó bá di pé kéèyàn fi ìfẹ́ hàn, kò sẹ́ni bíi Jésù láyé yìí. Ní gbogbo ìgbà tó fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, onírúurú ọ̀nà téèyàn lè gbà fi ìfẹ́ hàn ló ti fi í hàn, kò sì kẹ̀rẹ̀ tó bá di pé kéèyàn gba tàwọn míì rò tàbí kéèyàn fàánú hàn. Tí Jésù bá rí i táwọn èèyàn ń jìyà, àánú wọn máa ń ṣe é. Kì í ṣe pé ó kàn máa ń káàánú àwọn èèyàn, táá sì fi wọ́n sílẹ̀ láìṣe ohunkóhun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, kódà àìmọye ìgbà ló ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 14:14) Òótọ́ ni pé Jésù wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì foúnjẹ bọ́ àwọn tí ebi ń pa, àmọ́ ohun tó ṣe fáwọn èèyàn náà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó mú kí wọ́n mọ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó tún kọ́ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ náà tí wọ́n á sì sọ ọ́ di tiwọn. Títí láé làwọn èèyàn yẹn á sì máa jàǹfààní Ìjọba náà. (Máàkù 6:34; Lúùkù 4:43) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìfẹ́ tí Jésù ní ló mú kó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí aráyé.​—Jòhánù 15:13.

20 Torí pé Jésù jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú, tó sì máa ń gba tẹni rò, kò yani lẹ́nu rárá pé gbogbo èèyàn ló fẹ́ sún mọ́ ọn. (Máàkù 10:13-16) Àmọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, tá a sì ń ronú lórí àpẹẹrẹ dáadáa tó fi lélẹ̀, ńṣe làá túbọ̀ máa mọ irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́.​—Hébérù 1:3.

Bí Ìwé Yìí Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

21, 22. Kí lẹni tó ń wá Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe, báwo sì ni ìwé yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?

21 Bí Jèhófà ṣe lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti mú ká mọ irú ẹni tí òun jẹ́, ńṣe ló fi ń dá wa lójú pé ó fẹ́ ká sún mọ́ òun. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé ó ń fipá mú wa pé ká di ọ̀rẹ́ òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa pinnu fúnra rẹ̀ láti wá Jèhófà ‘nígbà tí a lè rí i.’ (Àìsáyà 55:6) Ẹni tó ń wá Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kó lè túbọ̀ mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti bó ṣe ń ṣe nǹkan. Ohun tó jẹ́ ká ṣe ìwé yìí gan-an nìyẹn.

22 Tó o bá wo ìwé yìí dáadáa, wàá rí i pé ìsọ̀rí mẹ́rin la pín in sí. Kí nìdí? Bẹ́ẹ̀ ṣe mọ̀, mẹ́rin làwọn ànímọ́ Jèhófà tó gbawájú jù lọ, ìyẹn agbára, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Torí náà, ìsọ̀rí àkọ́kọ́ máa sọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ kan, ìkejì á sọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ kejì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, a máa sọ ohun tí ànímọ́ kan jẹ́. Lẹ́yìn náà, a máa lo orí mélòó kan lábẹ́ ìsọ̀rí yẹn láti fara balẹ̀ ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe lo ànímọ́ yẹn lóríṣiríṣi ọ̀nà. Yàtọ̀ síyẹn, a máa fi orí kan jíròrò bí Jésù ṣe fi hàn pé òun náà ní ànímọ́ náà. Paríparí ẹ̀, a máa fi orí kan ṣàlàyé bí àwa náà ṣe lè fara wé Jèhófà àti Jésù.

23, 24. (a) Kí ni àpótí náà “Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé” wà fún? (b) Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ tàbí ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?

23 Bẹ̀rẹ̀ láti orí tá a wà yìí, ẹ máa rí àpótí kan tá a pè ní “Àwọn Ìbéèrè Tó Yẹ Ká Ronú Lé.” Àpẹẹrẹ kan ni  àpótí tó wà lójú ìwé 24. Tẹ́ ẹ bá kíyè sí i dáadáa, ẹ̀ẹ́ rí i pé a ò lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti ìbéèrè tó wà níbẹ̀ láti ṣe àtúnyẹ̀wò orí yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tá a tìtorí ẹ̀ ṣe é ni pé kó o lè túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí kókó tá a jíròrò ẹ̀ nínú orí yẹn. Kí lo lè ṣe táá jẹ́ káwọn ohun tó wà nínú àpótí yẹn ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an? Á dáa kó o fara balẹ̀ ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì ibẹ̀. Lẹ́yìn náà, ka ìbéèrè tó wà níwájú ẹsẹ Bíbélì yẹn, kó o wá ronú ohun tó lè jẹ́ ìdáhùn. Kódà, o lè ṣe ìwádìí kó o lè túbọ̀ lóye àwọn kókó kan. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi ara rẹ ní àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí nibí yìí ń sọ fún mi nípa Jèhófà? Báwo ni mo ṣe lè fi ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò? Báwo ni mo ṣe lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́?’

24 Tá a bá ń fara balẹ̀ ronú jinlẹ̀ tàbí ṣàṣàrò lọ́nà yìí, á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Lọ́nà wo? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé téèyàn bá ń ronú jinlẹ̀ lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, á jẹ́ kéèyàn lè mọ irú ẹni tóun jẹ́ nínú. (Sáàmù 19:14) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá à ń kọ́ nípa Jèhófà, á jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Àá lè máa ronú bó ṣe ń ronú, àá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, á sì túbọ̀ máa wù wá láti máa ṣe ohun táá múnú rẹ̀ dùn. Ó ṣe tán, òun ni Ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ téèyàn lè ní láyé yìí. (1 Jòhánù 5:3) Àmọ́ o, kéèyàn tó lè di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó ṣe pàtàkì ká mọ irú ẹni tó jẹ́ gangan, ká mọ ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́, àá sì rí ìdí tó fi yẹ ká sún mọ́ ọn.

a Bí àpẹẹrẹ, àwọn apá kan wà nínú Bíbélì tó sọ nípa Jèhófà bíi pé ó ní ojú, etí, imú, ẹnu, apá àti ẹsẹ̀. (Sáàmù 18:15; 27:8; 44:3; Àìsáyà 60:13; Mátíù 4:4; 1 Pétérù 3:12) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ní ojú, etí, imú, ẹnu, apá àti ẹsẹ̀ bíi tàwa èèyàn. Ó ṣe tán, a ò ní ronú pé Jèhófà jẹ́ òkè gìrìwò torí pé Bíbélì pè é ní “Àpáta náà” bẹ́ẹ̀ la ò sì ní ronú láé pé ó dà bí irin tọ́mọ ogun kan fi ń dáàbò bo ara ẹ̀ torí pé Bíbélì pè é ní “apata.”​—Diutarónómì 32:4; Sáàmù 84:11.