Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 1

Báwo La Ṣe Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run?

Báwo La Ṣe Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run?

Bíbélì ni Ọlọ́run fi ń bá wa sọ̀rọ̀. 2 Tímótì 3:16

Ọlọ́run tòótọ́ mú kí àwọn èèyàn kọ èrò òun sínú ìwé mímọ́ kan. Ìwé náà ni Bíbélì. Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tí Ọlọ́run fẹ́ kí o mọ̀ ló wà nínú rẹ̀.

Ọlọ́run mọ ohun tó dáa jù lọ fún wa, òun sì ni Orísun gbogbo ọgbọ́n. Tí o bá ń tẹ́tí sí i, ó dájú pé wàá di ọlọ́gbọ́n.​—Òwe 1:5.

Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn tó wà láyé máa ka Bíbélì. Ó ti wà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè báyìí.

Tí o bá fẹ́ tẹ́tí sí Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì, kí o sì lóye rẹ̀.

Ibi gbogbo ni àwọn èèyàn ti ń tẹ́tí sí Ọlọ́run. Mátíù 28:19

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè lóye Bíbélì.

Kárí ayé là ń fi òtítọ́ nípa Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn.

A kì í gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn torí pé à ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. O tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tí o bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ.