Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 10

Àwọn Ìbùkún Wo Ni Àwọn Tó Bá Tẹ́tí sí Ọlọ́run Máa Rí Gbà?

Àwọn Ìbùkún Wo Ni Àwọn Tó Bá Tẹ́tí sí Ọlọ́run Máa Rí Gbà?

Ọlọ́run máa jí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ti kú dìde sí ayé. Ìṣe 24:15

Ronú nípa àwọn ìbùkún tí o máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú tí o bá tẹ́tí sí Jèhófà! Wàá ní ìlera pípé, ẹnì kankan ò ní ṣàìsàn mọ́. Àwọn èèyàn burúkú ò ní sí mọ́, wàá sì lè fọkàn tán gbogbo èèyàn.

Kò ní sí ìrora, ìbànújẹ́ àti ẹkún mọ́. A ò ní darúgbó mọ́, a ò sì ní kú mọ́.

Àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí ló máa yí ọ ká. Párádísè máa dùn-ún gbé gan-an ni.

Kò ní sí ìbẹ̀rù. Inú àwọn èèyàn máa dùn gan-an.

Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Ìfihàn 21:​3, 4