Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 9

Ìgbà Wo Ni Ayé Máa Di Párádísè?

Ìgbà Wo Ni Ayé Máa Di Párádísè?

Àwọn wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó dé. Lúùkù 21:​10, 11; 2 Tímótì 3:​1-5

Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ni Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n á máa ṣàìgbọràn sí òbí, wọ́n á burú gan-an, wọn ò sì ní mọ̀ ju fàájì lọ.

Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára, ogun, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn máa wà. Àwọn nǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí.

Bákan náà, Jésù sọ pé a ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé.​—Mátíù 24:14.

Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò. 2 Pétérù 3:13

Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo èèyàn burúkú run.

Jèhófà máa fìyà jẹ Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù.

Àwọn tó bá tẹ́tí sí Ọlọ́run máa gbé nínú ayé tuntun tí òdodo wà, níbi tí kò ní sí ìbẹ̀rù mọ́, tí àwọn èèyàn máa finú tán ara wọn, tí wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn.