APÁ 5
Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?
Ìwà burúkú ni àwọn èèyàn tó pọ̀ jù nígbà ayé Nóà ń hù. Jẹ́nẹ́sísì 6:5
Ádámù àti Éfà bí àwọn ọmọ, àwọn èèyàn sì wá pọ̀ ní ayé. Nígbà tó yá, àwọn áńgẹ́lì kan dara pọ̀ mọ́ Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.
Wọ́n wá sí ayé, wọ́n sì gbé àwọ̀ ọkùnrin wọ̀ kí wọ́n lè gbé àwọn obìnrin níyàwó. Àwọn obìnrin yìí bí àwọn ọmọkùnrin tó jẹ́ òmìrán, wọ́n lágbára gan-an, wọ́n sì ya ẹhànnà.
Àwọn èèyàn tó ń hùwà ibi wá pọ̀ ní ayé. Bíbélì sọ pé: “Ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, . . . kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.”
Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 14, 18, 19, 22
Nóà tẹ́tí sí Ọlọ́run, ó sì kan ọkọ̀ áàkì.Èèyàn rere ni Nóà. Jèhófà sọ fún Nóà pé òun máa fi ìkún omi pa àwọn èèyàn burúkú run.
Ọlọ́run tún sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ ojú omi ńlá kan, tí Bíbélì pè ní áàkì, kí ó sì kó ìdílé rẹ̀ àti àwọn ẹranko lóríṣiríṣi sínú ọkọ̀ náà.
Nóà kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa Ìkún Omi tó ń bọ̀, àmọ́ wọn ò tẹ́tí sí i. Àwọn kan fi Nóà ṣe yẹ̀yẹ́, àwọn míì sì kórìíra rẹ̀.
Nígbà tí Nóà parí ọkọ̀ áàkì náà, ó kó àwọn ẹranko sínú rẹ̀.