Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú

Ọlọ́run jẹ́ bàbá tó nífẹ̀ẹ́ wa. 1 Pétérù 5:6, 7

Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún. Bí bàbá tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe máa ń kọ́ wọn ni Ọlọ́run ń kọ́ àwa èèyàn níbi gbogbo nípa bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ.

Ọlọ́run ń jẹ́ ká mọ òtítọ́ tó ṣeyebíye tó ń fún wa láyọ̀ tó sì ń jẹ́ ká nírètí.

Tí o bá tẹ́tí sí Ọlọ́run, á tọ́ ẹ sọ́nà, á dáàbò bò ẹ́, á sì jẹ́ kó o lè borí àwọn ìṣòro.

Kò tán síbẹ̀ o, wàá tún wà láàyè títí láé!

Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ẹ . . . wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ ó sì máa wà láàyè nìṣó.” Àìsáyà 55:3