APÁ 11
Ṣé Jèhófà Máa Ń Tẹ́tí Gbọ́ Wa?
Ó dájú pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wa. 1 Pétérù 3:12
“Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà. (Sáàmù 65:2) Ó fẹ́ ká máa sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún òun.
Jèhófà ni kí o máa gbàdúrà sí, má ṣe gbàdúrà sí ẹlòmíì.
1 Jòhánù 5:14
A lè mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ nǹkan nínú àdúrà wa.Máa gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run àti ní ayé.
Máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù kí o lè fi hàn pé o mọyì ohun tó ṣe fún ọ.
Máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí o lè máa ṣe ohun tó dáa. O tún lè bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ, iṣẹ́, ilé gbígbé, aṣọ àti ìlera rẹ nínú àdúrà.