“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”

Kì í ṣe ká lè sọ ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ tó ṣe la fi ṣe ìwé yìí, ká rí bá a ṣe lè tẹ̀lé Jésù la ṣe ṣeé.

Ọ̀rọ̀ Iṣáájú

Ohun tó wù wá ni pé kí ìfẹ́ tó o ní fún Jésù túbọ̀ máa pọ̀ sí i, kó o sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí, kó o bàa lè máa múnú Jèhófà dùn nísinsìnyí àti títí láé.

ORÍ 1

“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”—Kí Ni Jésù Ní Lọ́kàn?

Kéèyàn jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọjá pé ká kàn sọ bẹ́ẹ̀ lẹ́nu tàbí kó máa wù wá.

ORÍ 2

“Ọ̀nà àti Òtítọ́ àti Ìyè”

Ipasẹ̀ Jésù, tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, nìkan la lè gbà sún mọ́ Baba. Jésù ni ẹni tí Bàbá máa lò láti mú gbogbo ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.

ÌSỌ̀RÍ  1

‘Wá Wo’ Kristi

ORÍ 3

“Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-Àyà Ni Èmi”

Jálẹ̀ gbogbo iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé ló fi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

ORÍ 4

“Wò Ó! Kìnnìún Tí Ó Jẹ́ ti Ẹ̀yà Júdà”

Jésu ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta tó fi hàn pé ó nígboyà bíi kìnnìún: Ọ̀nà kìíní ni bó ṣe dúró lórí òtítọ́; ọ̀nà kejì ni bó ṣe ń ṣẹ̀tọ́; ọ̀nà kẹta sì ni bó ṣe kojú àtakò.

ORÍ 5

“Gbogbo Ìṣúra Ọgbọ́n”

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù ń sọ àtohun tó ń ṣe ń fi ọgbọ́n tó ju ọgbọ́n lọ hàn.

ORÍ 6

“Ó Kọ́ Ìgbọràn”

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ délẹ̀délẹ̀, kí nìdí tá a fi wá lè sọ pé Jésù “kọ́ ìgbọràn” ó sì di ẹni tí a sọ “di pípé”?

ORÍ 7

‘Ẹ Ronú Jinlẹ̀ Nípa Ẹni Tó Lo Ìfaradà’

Jésù fara dà á nígbà tó wà láyé, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ láì kù síbì kan. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á? Báwo làwa náà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀?

ORÍ 8

“Tìtorí Èyí Ni A Ṣe Rán Mi Jáde”

Wàá rí ìdí tí Jésù fi ń wàásù, ohun tó ń kọ́ni, àti irú ọwọ́ tó fi mú iṣẹ́ ìwàásù nígbà tó wà láyé.

ORÍ 9

“Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn . . . Di Ọmọ Ẹ̀yìn”

Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó máa fi hàn pé a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù lóòótọ́ ni pé ká máa tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.

ORÍ 10

“A Ti Kọ Ọ́ Pé”

Tá a bá fẹ́ máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bíi ti Jésù, àá máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àá máa gbèjà rẹ̀, àá sì máa ṣàlàyé rẹ̀.

ORÍ 11

“Ènìyàn Mìíràn Kò Tíì Sọ̀rọ̀ Báyìí Rí”

Ka orí yìí kó o lè mọ mẹ́ta lára àwọn ọ̀nà tí Jésù ń gbà kọ́ni àti bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

ORÍ 12

“Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”

Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí méjì tí Jésù fi máa ń lo àpèjúwe.

ORÍ 13

“Mo Nífẹ̀ẹ́ Baba”

Báwo la ṣe lè ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà bíi ti Jésù?

ORÍ 14

“Àwọn Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Tọ̀ Ọ́ Wá”

Ó máa ń rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn ọmọdé láti wá sọ́dọ̀ Jésù. Kí ló mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ Jésù?

ORÍ 15

“Àánú Ṣe É”

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fàánú hàn bíi ti Jésù?

ORÍ 16

“Jésù . . . Nífẹ̀ẹ́ Wọn Dé Òpin”

Ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bíi ti Jésù?

ORÍ 17

“Kò Sí Ẹni Tí Ó Ní Ìfẹ́ Tí Ó Tóbi Ju Èyí Lọ”

Báwo la ṣe lè máa fi ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ hàn bíi ti Jésù?

ORÍ 18

“Máa Bá A Lọ ní Títọ̀ Mí Lẹ́yìn”

Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lójoojúmọ́, a máa ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, a ò sì ní máa ṣiyè méjì nípa ọjọ́ ọ̀la.