Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌSỌ̀RÍ 3

“Ìfẹ́ tí Kristi ní Sọ Ọ́ Di Ọ̀ranyàn fún Wa”

“Ìfẹ́ tí Kristi ní Sọ Ọ́ Di Ọ̀ranyàn fún Wa”

Kí ló ń mú ká máa tọ Jésù lẹ́yìn? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.” (2 Kọ́ríńtì 5:14) Ní ìsọ̀rí yìí, a óò jíròrò ìfẹ́ tí Jésù ní fún Jèhófà, èyí tó ní fún aráyé àtèyí tó ní fẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa. Irú ìjíròrò yìí á sún wa láti máa tẹ̀ lé Jésù, nítorí á jẹ́ ká lè rí ìdí tó fi jẹ́ ọ̀ranyàn fún wa láti ṣègbọràn, ká sì máa tẹ̀ síwájú nínú títẹ̀lé àpẹẹrẹ Ọ̀gá wa.