ORÍ 15
“Àánú Ṣe É”
1-3. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà táwọn afọ́jú méjì tó ń ṣagbe bẹ̀ ẹ́ pé kò ran àwọn lọ́wọ́? (b) Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà ‘àánú ṣe é’? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
ÀWỌN ọkùnrin afọ́jú méjì kan jókòó sí ẹ̀bá ọ̀nà nítòsí Jẹ́ríkò. Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń wá síbẹ̀, wọ́n á wá ibi tí wọ́n rò pé ọ̀pọ̀ èèyàn á máa gbà kọjá, wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣagbe níbẹ̀. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, nǹkan kan máa tó ṣẹlẹ̀ sí wọn tó máa yí ìgbésí ayé wọn padà pátápátá.
2 Lójijì, àwọn alágbe yẹn gbọ́ ariwo. Nítorí pé wọn ò lè rí ohun tó ń lọ, ọ̀kan lára wọn béèrè ohun tó ń ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn sì dá a lóhùn pé: “Jésù ará Násárétì ni ó ń kọjá lọ!” Ìgbà ìkẹyìn rèé tí Jésù ń lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n òun nìkan kọ́ ló ń lọ; ọ̀pọ̀ èrò ló ń wọ́ tẹ̀ lé e. Kí làwọn alágbe náà gbọ́ pé Jésù ló ń kọjá sí, ńṣe ni wọ́n ṣe ohun kan tó lè bí àwọn èèyàn nínú. Ohun tí wọ́n ṣe náà sì ni ariwo tí wọ́n ń pa pé: “Olúwa, ṣàánú fún wa, Ọmọkùnrin Dáfídì!” Ìyẹn bí àwọn ogunlọ́gọ̀ náà nínú, wọ́n sì ní káwọn alágbe yẹn panu mọ́, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ò gbọ́. Wọ́n kọ̀ láti panu mọ́.
3 Pẹ̀lú bí ariwo ogunlọ́gọ̀ náà ṣe ròkè tó, Jésù ṣì gbọ́ igbe àwọn alágbe náà. Kí ló máa ṣe o? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló gbé sọ́kàn. Nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan péré ló kù kó lò láyé. Ó mọ̀ pé dẹndẹ ìyà àti ikú oró ń dúró de òun ní Jerúsálẹ́mù. Síbẹ̀ kò tìtorí ìyẹn fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́ bí àwọn alágbe yẹn ò ṣe yéé bẹ̀ ẹ́. Ó tẹsẹ̀ dúró díẹ̀, ó wá ní kí wọ́n mú àwọn alágbe tó ń kígbe yẹn sún mọ́ òun. Àwọn alágbe náà bẹ̀bẹ̀ pé: “Olúwa, jẹ́ kí ojú wa là.” “Bí àánú ti ṣe é,” ó fọwọ́ kan ojú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ríran. a Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jésù.—Lúùkù 18:35-43; Mátíù 20:29-34.
4. Báwo ni Jésù ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé ó máa “káàánú ẹni rírẹlẹ̀” ṣẹ?
4 Kì í ṣe ìgbà kan ṣoṣo tí Jésù fi àánú hàn nìyẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà àti lónírúurú ipò, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn dun Jésù dọ́kàn débi tó fi ṣàánú fún wọn. Bíbélì tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa “káàánú ẹni rírẹlẹ̀.” (Sáàmù 72:13) Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe sọ gẹ́lẹ́ ni Jésù ṣe, ó máa ń kíyè sí ohun tó ń da àwọn ẹlòmíì láàmú. Ó máa ń dìídì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n tó kọnu ìrànlọ́wọ́ sí i. Ìyọ́nú tó ní sáwọn èèyàn wà lára ohun tó ń mú un wàásù. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe jẹ́ ká rí bí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ àtàwọn ohun tó ṣe ṣe fi hàn pé ẹlẹ́yinjú àánú ni, ká sì rí báwa náà ṣe lè máa firú ìyọ́nú bẹ́ẹ̀ hàn.
Bó Ṣe Máa Ń Gba Tàwọn Ẹlòmíì Rò
5, 6. Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù máa ń fọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara rẹ̀ wò?
5 Jésù jẹ́ ẹnì kan tó máa ń fọ̀ràn ro ara rẹ̀ wò gan-an. Ó máa ń mọ bí ìṣòro àwọn èèyàn ṣe rí lára wọn, ó sì máa ń bá wọn kẹ́dùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ohun tó ń ṣe wọ́n yẹn kọ́ ló ti ṣeé rí, síbẹ̀ nínú ọkàn rẹ̀ lọ́hùn-ún, ó mọ bí ìrora yẹn ṣe lè rí lára. (Hébérù 4:15) Nígbà tó wo obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá sàn, ó pe àìsàn náà ní “àìsàn burúkú,” èyí tó túmọ̀ sí pé ó mọ ìnira àti ìpọ́njú tí àìsàn yẹn ti kó bá obìnrin náà. (Máàkù 5:25-34) Nígbà tó rí Màríà àtàwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nítorí ikú Lásárù, ìbànújẹ́ tó bá wọn dùn ún wọra débi tí kò fi lè mú un mọ́ra mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé òun máa lọ jí i dìde, síbẹ̀ ó dùn ún gan-an débi tó fi da omijé lójú.—Jòhánù 11:33, 35.
6 Ìgbà kan tún wà tí adẹ́tẹ̀ kan tọ Jésù wá tó sì bẹ̀ ẹ́ pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Báwo ni Jésù tó jẹ́ ẹni pípé tí ò ṣàìsàn rí ṣe fèsì? Ńṣe ni àánú adẹ́tẹ̀ yẹn ṣe é. Nítòótọ́, “àánú ṣe é.” (Máàkù 1:40-42) Ó sì ṣe ohun àrà kan. Ó mọ̀ dáadáa pé aláìmọ́ làwọn adẹ́tẹ̀ lábẹ́ Òfin Mósè àti pé wọn ò gbọ́dọ̀ wá sáàárín àwọn èèyàn. (Léfítíkù 13:45, 46) Jésù ní agbára tó fi lè mú ọkùnrin yìí lára dá láìfi ọwọ́ kàn án. (Mátíù 8:5-13) Síbẹ̀, ó pinnu láti nawọ́ sí adẹ́tẹ̀ náà, ó fọwọ́ kàn án, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Lójú ẹsẹ, ẹ̀tẹ̀ yẹn dàwátì. Àbí ẹ ò rí i pé Jésù máa ń lo ìyọ́nú nípa fífi ọ̀ràn ro ara rẹ̀ wò!
7. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìyọ́nú, ọ̀nà wo la sì lè gbà fi hàn pé oníyọ̀ọ́nú èèyàn ni wá?
7 Ó yẹ káwa Kristẹni máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú fífi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara wa wò. Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn.” b (1 Pétérù 3:8) Ó lè má rọrùn láti mọ bó ṣe ń ṣe àwọn tí àìsàn líle ń bá fínra tàbí àwọn tí wọ́n ní ìsoríkọ́, pàápàá bí irú rẹ̀ ò bá tíì ṣe wá rí. Máa rántí pé kò dìgbà téèyàn bá nírú ìṣòro tẹ́nì kan ní kéèyàn tó lè káàánú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Jésù fọ̀rọ̀ àwọn aláìsàn ro ara ẹ̀ wò, bẹ́ẹ̀ sì rèé òun ò ṣàìsàn rí. Báwo làwa náà ṣe lè wá kọ́ bá a ṣe máa fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara wa wò? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífetísílẹ̀ dáadáa nígbà táwọn tójú ń pọ́n bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn àti ohun tó ń ṣe wọ́n. A lè bi ara wa pé, ‘Bó bá jẹ́ pé èmi ni mo nírú ìṣòro yìí, kí ni màá ṣe?’ (1 Kọ́ríńtì 12:26) Bá a bá jẹ́ ẹni tó tètè ń kíyè sí ìṣesí àwọn èèyàn, ó máa rọrùn fún wa láti “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Nígbà míì, tá a bá fi ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara wa wò, omijé á gbọ̀n wá, á ṣe wá kọjá ká kàn máa sọ̀rọ̀. Róòmù 12:15 sọ pé: “Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.”
8, 9. Báwo ni Jésù ṣe ń fi ìgbatẹnirò hàn fáwọn ẹlòmíì?
8 Jésù máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò, ó sì máa ń ṣe ohun to fi hàn bẹ́ẹ̀. Wàá rántí ìgbà kan tí wọ́n mú ọ̀gbẹ́ni tó dití tí kò sì lè sọ̀rọ̀ dáadáa wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tó kíyè sí i pé ara ń ti ọ̀gbẹ́ni yẹn, ó ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan tí kì í sábà ṣe bó bá ń wo àwọn èèyàn sàn. Ó mú ọ̀gbẹ́ni yẹn “lọ kúrò lọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ náà.” Ní òun nìkan, níbi táwọn èèyàn ò ti ní máa wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ló ti wo ọkùnrin yẹn sàn.—Máàkù 7:31-35.
9 Ohun tó jọ ìyẹn náà ni Jésù ṣe nígbà táwọn èèyàn mú ọkùnrin afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kó wò ó sàn. Jésù “di ọwọ́ ọkùnrin afọ́jú náà mú,” ó sì “mú un jáde sẹ́yìn òde abúlé náà.” Ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo ọkùnrin náà sàn díẹ̀ díẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló ṣe báyẹn torí kí ọpọlọ ọkùnrin náà bàa lè gba àwọn ohun tójú rẹ̀ á rí, títí kan onírúurú ohun tó wà nínú ayé tí oòrùn tàn rekete sí. (Máàkù 8:22-26) Ìgbatẹnirò tí Jésù lò yìí mà ga o!
10. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé à ń ro bọ́ràn ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíì?
10 Báwa náà bá máa jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù, àfi ká yáa máa ro bọ́ràn ṣe máa ń rí lára àwọn ẹlòmíì. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wa, ká máa rántí pé lílo ahọ́n wa láìkíyèsára lè mú ká kó ìbànújẹ́ bá àwọn ẹlòmíì. (Òwe 12:18; 18:21) Kòbákùngbé ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ èébú àti sísọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn kì í ṣe àṣà àwọn Kristẹni tí ò fẹ́ ba àwọn ẹlòmíì lọ́kàn jẹ́. (Éfésù 4:31) Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fi hàn pé ẹ̀ ń ro bọ́ràn ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíì? Nígbà tẹ́ ẹ bá ń gbani nímọ̀ràn, ẹ máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn tútù, kẹ́ ẹ fọ̀wọ̀ ẹni náà wọ̀ ọ́. (Gálátíà 6:1) Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè fi ìgbatẹnirò hàn fáwọn ọmọ yín? Tẹ́ ẹ bá ń bá ọmọ yín wí, ẹ rí i pé ìbáwí tẹ́ ẹ bá máa fún un kò ní kàn án lábùkù.—Kólósè 3:21.
Bó O Ṣe Lè Lo Ìdánúṣe Láti Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́
11, 12. Àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì wo ló fi hàn pé Jésù kì í dúró dìgbà tí wọ́n bá sọ fún un kó tó fi ìyọ́nú hàn sáwọn ẹlòmíì?
11 Jésù kì í dúró dìgbà tí wọ́n bá pè é kó tó ṣe ohun táwọn èèyàn nílò fún wọn. Ó ṣe tán, ìyọ́nú kì í ṣe ànímọ́ téèyàn á kàn fẹnu lásán sọ pé òun ní, kàkà bẹ́ẹ̀ ànímọ́ tó máa ń mú ká ṣe nǹkan kan láti ran ẹlòmíì lọ́wọ́ ni. Abájọ tí ìyọ́nú fi mú kí Jésù dìídì fẹ́ ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láìṣe pé wọ́n bẹ̀ ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí ogunlọ́gọ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, láìjẹ-láìmu, ẹnì kan ò ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún Jésù pé ebi ti ń pa wọ́n tàbí pé kó ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì wí pé: ‘Àánú ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe mí, nítorí pé ó ti di ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí wọ́n ti wà pẹ̀lú mi, wọn kò sì ní nǹkan kan láti jẹ; èmi kò sì fẹ́ rán wọn lọ ní gbígbààwẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí okun wọn tán ní ojú ọ̀nà.’” Lẹ́yìn náà, láìjẹ́ pé ẹnì kan sọ fún un, òun fúnra rẹ̀ pinnu, ó sì bọ́ ogunlọ́gọ̀ náà lọ́nà ìyanu.—Mátíù 15:32-38.
12 Jẹ́ ká gbé àkọsílẹ̀ míì yẹ̀ wò. Lọ́dún 31 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jésù sún mọ́ ìlú Náínì, ó rí ohun ìbànújẹ́ kan tó ṣẹlẹ̀. Àwọn kan ń gbókùú jáde kúrò nílùú náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibojì kan tó wà lórí òkè nítòsí ni wọ́n fẹ́ lọ sin “ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo” tí “opó” kan báyìí ní sí. Wo bí ìbànújẹ́ tó gba ọkàn opó yẹn á ṣe pọ̀ tó? Ọmọ kan ṣoṣo tó ní ló fẹ́ lọ gbé sin yẹn, kò sì sí ọkọ tí wọ́n lè jọ máa tura wọn nínú. Láàárín gbogbo àwọn èèyàn náà, Jésù “tajú kán rí” opó tó ti di aláìlọ́mọ yìí. Ohun tó rí yìí dùn ún dọ́kàn, àní sẹ́, “àánú rẹ̀ ṣe é.” Kò dúró dìgbà tẹ́nì kan bá wá bẹ̀ ẹ́ pé kó wá nǹkan kan ṣe sí ìṣòro náà. Ìyọ́nú tó wà lọ́kàn rẹ̀ ló mú kó dìídì fẹ́ ṣèrànlọ́wọ́. Ó sì “sún mọ́ ọn, ó sì fọwọ́ kan agà ìgbókùú náà,” ó jí ọ̀dọ́kùnrin náà dìde. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Jésù ò tìtorí ìyẹn sọ pé kí ọ̀dọ́kùnrin yẹn wá dara pọ̀ mọ́ Òun àti ogunlọ́gọ̀ yẹn nínú ìrìn àjò wọn o. Dípò ìyẹn, ńṣe ni Jésù “fi í fún ìyá rẹ̀,” ó padà sọ wọ́n di ìdílé, èyí jẹ́ kí opó yẹn ní ẹni táá máa bójú tó o.—Lúùkù 7:11-15.
13. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ṣíṣe ohun tó yẹ láti ran ẹni tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́, láìdúró dìgbà tí wọ́n bá tó bẹ̀ wá?
13 Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Òótọ́ ni pé àwa ò lè pèsè oúnjẹ lọ́nà ìyanu, a ò sì lè jí òkú dìde. Àmọ́ a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà tá a bá dìídì ṣèrànwọ́ fáwọn ẹlòmíì, láìdúró dìgbà tí wọ́n bá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀ wá. Ọrọ̀ ajé lè dẹnu kọlẹ̀ fún onígbàgbọ́ kan bíi tiwa tàbí kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 3:17) Ó ṣeé ṣe kí ilé opó kan nílò àtúnṣe lójú méjèèjì. (Jákọ́bù 1:27) A lè mọ ìdílé kan tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ tí wọ́n sì nílò ìtùnú tàbí tí wọ́n nílò àwọn nǹkan tara míì. (1 Tẹsalóníkà 5:11) Tó bá di pé àwọn ará wa níṣòro, a ò ní láti dúró dìgbà tẹ́nì kan bá ní ká ṣèrànwọ́ ká tó ṣe é. (Òwe 3:27) Ìyọ́nú tá a ní sáwọn èèyàn ló máa jẹ́ ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ bá a bá ṣe lè ṣe tó láìjẹ́ pé wọ́n bẹ̀ wá. Má gbàgbé pé ìrànlọ́wọ́ tá a bá ṣe bó ṣe wù kó kéré tó tàbí ọ̀rọ̀ ìtùnú tá a bá sọ látọkànwá fẹ́nì kan lè fi hàn pé oníyọ̀ọ́nú èèyàn ni wá.—Kólósè 3:12.
Ìyọ́nú Ló Mú Kó Wàásù
14. Kí nìdí tí Jésù fi ka iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere sì pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
14 Bá a ṣe rí i ní Ìsọ̀rí 2 nínú ìwé yìí, Jésù fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ fún wa nínú wíwàásù ìhìn rere. Ó ní: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Kí nìdí tó fi ka iṣẹ́ yìí sí pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ nǹkan míì wà: Jíjẹ́ tó jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú máa ń jẹ́ kó lè ṣe ohun tó máa pòùngbẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń gbẹ àwọn èèyàn. Nínú gbogbo ọ̀nà tó ti fi ìyọ́nú hàn, kò séyìí tó ṣe pàtàkì tó bó ṣe bọ́ àwọn tébi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń pa. Ẹ jẹ́ ká gbé méjì yẹ̀ wò lára ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ká rí ojú tí Jésù fi ń wo àwọn tó ń wàásù fún. Bá a ṣe ń ṣàgbéyẹ̀wò yìí, á ràn wá lọ́wọ́ láti yẹ ara wa wò láti mọ ohun tó ń mú káwa náà máa ṣiṣẹ́ ìwàásù.
15, 16. Ṣàpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ méjì tó jẹ́ ká mọ ojú tí Jésù fi ń wo àwọn tó ń wàásù fún.
15 Lọ́dún 31 Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì tí Jésù ti ṣiṣẹ́ àṣekára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó wá tẹ̀ síwájú láti “mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n nínú ìrìn àjò ìbẹ̀wò sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé” Gálílì. Ohun tó rí wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Àpọ́sítélì Mátíù sọ pé: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:35, 36) Jésù fọ̀rọ̀ àwọn mẹ̀kúnnù ro ara rẹ̀ wò. Ó máa ń tètè mọ̀ pé ìmọ̀ tí wọ́n ní nípa Ọlọ́run ò tó. Ó mọ̀ pé àwọn tó yẹ kó bójú tó wọn gan-an, ìyẹn àwọn aṣáájú-ìsìn, ló ń ṣàìdáa sí wọn tí wọn ò sì bìkítà fún wọn. Nítorí bí ìyọ́nú tí Jésù ní fún wọn ṣe pọ̀ tó, ó sapá gidigidi láti lè rí i pé òun wàásù ìhìn rere tó ń fúnni ní ìrètí fún wọn. Kò sí nǹkan míì tí wọ́n nílò tó tó ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
16 Ohun tó jọ èyí wáyé ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà nígbà tí Àjọ Ìrékọjá ti ọdún 32 Sànmánì Kristẹni kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Lákòókò tá à ń sọ yìí, ńṣe ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ wọkọ̀ ojú omi kọjá lórí Òkun Gálílì láti lè wá ibi tó dákẹ́ rọ́rọ́ kí wọ́n lè sinmi. Ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ ti sáré dé etíkun kí ọkọ ojú omi tí Jésù wà nínú rẹ̀ tó débẹ̀. Kí ni Jésù ṣe? “Ní jíjáde, ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:31-34) Lẹ́ẹ̀kan sí i, “àánú wọ́n ṣe é” nítorí bí òùngbẹ tẹ̀mí ṣe ń gbẹ àwọn èèyàn náà. Bí “àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,” kò sẹ́ni táá máa fún àwọn èèyàn yìí ní oúnjẹ tẹ̀mí, tó sì jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ni wọ́n ní láti mọ àtiṣe ara wọn. Ìyọ́nú tí Jésù ní ló sún un láti máa wàásù kì í ṣe torí pé ó di dandan kó wàásù.
17, 18. (a) Kí ló ń jẹ́ ká máa wàásù fáwọn èèyàn? (b) Báwo la ṣe lè máa fi ìyọ́nú hàn sáwọn ẹlòmíì?
17 Kí ló jẹ́ káwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù máa wàásù? Bá a ṣe rí i ní Orí 9 nínú ìwé yìí, a ní iṣẹ́ kan níkàáwọ́ wa tó jẹ́ ojúṣe wa, ìyẹn ni iṣẹ́ wíwàásù àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn. (Mátíù 28:19, 20; 1 Kọ́ríńtì 9:16) Ṣùgbọ́n kì í ṣe torí pé iṣẹ́ ìwàásù pọn dandan tàbí pó jẹ́ ojúṣe wa nìkan la fi ní láti máa wàásù o. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kó mú ká máa lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bí àánú àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwa ṣe ń ṣe wá tún wà lára ohun tó ń jẹ́ ká máa wàásù. (Máàkù 12:28-31) Báwo la ṣe wá lè máa fi ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn?
18 Ó pọn dandan ká máa wo àwọn èèyàn bí Jésù ṣe ń wò wọ́n, ó rí i pé wọ́n ti “bó wọn láwọ,” wọ́n “sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Wo bó ṣe máa rí lára rẹ bó o bá rí ọ̀dọ́ àgùntàn kan tó ti sọ nù sínú igbó, tí ò sì mọ̀nà àbáyọ. Òùngbẹ á ti máa gbẹ ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn, ebi á sì ti máa pa á torí kò sí olùṣọ́ àgùntàn tó máa mú un lọ síbi tí koríko tútù wà àti ibi tó ti lè rí omi mu. Ṣé àánú ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn ò ní ṣe ọ́? Ṣé kò ní wù ọ́ láti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti fún ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn ní oúnjẹ àti omi? Ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn ò yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọn ò tíì gbọ́ ìhìn rere lónìí. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn èké ti pa wọ́n tì, ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń pa wọ́n, òùngbẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbẹ wọ́n, wọn ò sì ní ìrètí kankan pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Àwa ní ohun tí wọn ò ní: ìyẹn oúnjẹ tẹ̀mí aṣaralóore àti omi atura òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Aísáyà 55:1, 2) Bá a ṣe ń ronú nípa ipò tẹ̀mí àwọn tó wà láyìíká wa, àánú wọn ń ṣe wá. Bí àánú àwọn èèyàn bá ṣe wá bó ṣe máa ń ṣe Jésù, a ó ṣe gbogbo ohun tó yẹ láti jẹ́ kí wọ́n gbọ́ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe.
19. Báwo la ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tó ti kúnjú ìwọ̀n láti di akéde lọ́wọ́ kó lè wù ú láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù?
19 Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Ká sọ pé a fẹ́ gba akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ti yẹ lẹ́ni tó lè bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sóde ẹ̀rí níyànjú pé kó bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Tàbí kó jẹ́ pé ńṣe la fẹ́ ran akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù lẹ́ẹ̀kan sí i. Báwo la ṣe lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? A gbọ́dọ̀ wá bí ọ̀rọ̀ wa ṣe máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn ni. Rántí pé ohun àkọ́kọ́ tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí Jésù ni pé “àánú” àwọn èèyàn máa ń “ṣe é,” á wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. (Máàkù 6:34) Nítorí náà, bá a bá ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tí wọ́n á fi máa ní ìyọ́nú fún àwọn ẹlòmíì, àwọn náà á fẹ́ dà bíi Jésù ní ti pé ọkàn wọn á sún wọn láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíì. A lè bi wọ́n pé: “Ọ̀nà wo ni gbígbà tẹ́ ẹ gba ìhìn rere gbọ́ gbà yí ìgbésí ayé yín padà? Àwọn tí ò tíì gbọ́ nípa ìhìn rere yìí ńkọ́, ǹjẹ́ kò yẹ káwọn náà gbọ́? Kí lẹ lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?” A ò ní gbàgbé ṣá o, pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti bó ṣe ń wù wá láti jọ́sìn rẹ̀ lolórí ohun tó ń mú ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù.
20. (a) Kí ni jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ń béèrè lọ́wọ́ wa? (b) Kí la máa jíròrò ní orí tó kàn?
20 Jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ju kéèyàn kàn máa kọ́ ẹlòmíì ní àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tàbí kéèyàn kàn máa fi àwọn ọ̀rọ̀ náà ṣèwà hù lójú ayé lásán. Ó pọn dandan pé káwa náà nírú “ẹ̀mí ìrònú yìí,” tí Jésù ní. (Fílípì 2:5) Nítorí náà, a dúpẹ́ gan-an pé Bíbélì jẹ́ ká mọ èrò Jésù àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ tó fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ àtàwọn nǹkan tó gbé ṣe! Bá a bá mọ “èrò inú Kristi” lámọ̀dunjú, a óò túbọ̀ mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà kọ́ bá a ṣe lè máa kíyè sí ohun tó ń ṣe àwọn èèyàn, a ó sì lè máa fi ìyọ́nú hàn sí wọn. Nípa báyìí, a óò lè máa bá àwọn èèyàn lò lọ́nà tí Jésù gbà bá wọn lò. (1 Kọ́ríńtì 2:16) Ní orí tó kàn, a óò jíròrò onírúurú ọ̀nà tí Jésù gbà fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.
a Wọ́n ní ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó tíì dáa jù láti fi ṣàpèjúwe ìyọ́nú ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sì ‘àánú ṣe é.’ Ìwé kan sọ pé “kì í ṣe pé kéèyàn rí ìyà tó ń jẹ ọmọlàkejì kó sì dunni nìkan ni, ṣùgbọ́n ó ní nínú kéèyàn fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti gba onítọ̀hún sílẹ̀ lọ́wọ́ ìnira yẹn tàbí kéèyàn bá a fòpin sí ìyà náà.”
b Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé lédè Gíríìkì tó túmọ̀ sí “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” ṣeé tú ní olówuuru sí “bá jìyà.”