Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 18

“Máa Bá A Lọ ní Títọ̀ Mí Lẹ́yìn”

“Máa Bá A Lọ ní Títọ̀ Mí Lẹ́yìn”

1-3. (a) Báwo ni Jésù ṣe dágbére fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀, kí sì nìdí tíyẹn ò fi bà wọ́n nínú jẹ́? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tí Jésù ń ṣe lọ́run látìgbà tó ti lọ?

 ÀWỌN ọkùnrin mọ́kànlá kóra jọ sórí òkè. Ara ẹni tó ṣìkejìlá wọn lojú gbogbo wọn wà. Wọ́n ń wò ó tìfẹ́tìfẹ́, tìyanutìyanu. Jésù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jíǹde ni, ó kàn gbé agọ̀ èèyàn wọ̀ ni, torí ní báyìí, òun ló lágbára jù láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Jèhófà. Ó pe ìpàdé yìí sórí Òkè Ólífì kó bàa lè bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀ ìdágbére.

2 Kò síyè méjì pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù ń rántí bó ṣe dúró lórí òkè tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òkè ẹfun tó wà ní apá ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù yìí. Àfonífojì Kídírónì ló ya òkè yìí sọ́tọ̀ kúrò lára ìlú Jerúsálẹ́mù. Ní àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè yìí ni ìlú kan tó ń jẹ́ Bẹ́tánì wà, níbi tí Jésù ti jí Lásárù dìde. Bẹ́tánì yìí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Bẹtifágè, ìyẹn ìlú tí Jésù ti gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orí Òkè Ólífì yìí ni ọgbà Gẹtisémánì wà, ìyẹn ibi tí ìnira ti bá Jésù fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó wá mú un. Lórí òkè yìí kan náà ni Jésù ti fẹ́ ṣe ó dìgbóṣe fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jù lọ tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ìdágbére tó tura ló bá wọn sọ. Lẹ́yìn náà, ẹsẹ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò nílẹ̀! Àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ò lè tètè yísẹ̀ padà, ńṣe ni wọ́n dúró pa sójú kan, tí wọ́n ń wo Ọ̀gá wọn ọ̀wọ́n bó ṣe ń wọnú sánmà lọ. Níkẹyìn, àwọ̀ sánmà gbà á kúrò lójú wọn, wọn ò sì rí i mọ́.—Ìṣe 1:6-12.

3 Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe rí lójú rẹ? Ṣé àárò ọ̀gá wọn tó jíǹde tó tún wá ń fi wọ́n sílẹ̀ lọ yìí ò ní máa sọ wọ́n? Ó tì o. Kódà, ohun táwọn áńgẹ́lì méjì kan sọ mú káwọn àpọ́sítélì rántí pé Jésù ò tíì fi wọ́n sílẹ̀. (Ìṣe 1:10, 11) Lọ́pọ̀ ọ̀nà, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni lílọ sọ́rùn tí Jésù lọ sọ́rùn wulẹ̀ jẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò fi wá sókùnkùn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn tó ti kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ó ṣe pàtàkì ká mọ ohun tí Jésù ń ṣe látìgbà tó ti padà sọ́rùn. Kí nìdí? Rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Pétérù pé: “Máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.” (Jòhánù 21:19, 22) Gbogbo wa la ní láti máa ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn, kì í sì í ṣe fún ìwọ̀nba àkókò kan bí kò ṣe títí ayé. Ká bàa lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ, a ní láti mọ ohun tí Ọ̀gá wa ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́, ká sì mọ àyè tí Ọlọ́run tò ó sí lọ́run báyìí.

Ohun Tí Jésù Ń Ṣe Lọ́run Látìgbà Tó Ti Kúrò Láyé

4. Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ tipẹ́tipẹ́ nípa ohun tó máa wáyé lọ́run lẹ́yìn tí Jésù bá padà sọ́hùn-ún?

4 Ìwé Mímọ́ ò sọ nǹkan kan fún wa nípa ìgbà tí Jésù dé ọ̀run, kò sọ bí wọ́n ṣe kí i káàbọ̀, kò sì sọ bí ayọ̀ náà ṣe pọ̀ tó nígbà tóun àti Bàbá rẹ̀ tún padà wà pa pọ̀. Ṣùgbọ́n tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà tí Jésù bá padà sọ́run. Wàá rántí pé ó ju ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ táwọn Júù ti ń ṣe àjọyọ̀ mímọ́. Ní ọjọ́ kan lọ́dọọdún, àlùfáà àgbà máa ń lọ sínú ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì láti wọ́n ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fi ṣèrúbọ ní Ọjọ́ Ètùtù síwájú àpótí ẹ̀rí. Mèsáyà ni àlùfáà àgbà dúró fún ní ọjọ́ yẹn. Nígbà tí Jésù padà sọ́run, ó ṣe ohun tí àjọyọ̀ yẹn túmọ̀ sí ní ti gidi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé. Ó bọ́ síwájú ìtẹ́ Jèhófà ọlọ́lá ńlá lọ́run, ìyẹn ibi mímọ́ jù lọ ní gbogbo ayé àtọ̀run, ó sì fi ìtóye ẹbọ ìràpadà tó rú lé Bàbá rẹ̀ lọ́wọ́. (Hébérù 9:11, 12, 24) Ǹjẹ́ Jèhófà gbà á lọ́wọ́ rẹ̀?

5, 6. (a) Ẹ̀rí wo ló wà pé Jèhófà ti tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìràpadà Kristi? (b) Àwọn wo ni ìràpadà náà máa ṣe lóore, lọ́nà wo sì ni?

5 Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tí Jésù gòkè re ọ̀run ló jẹ́ ká rí ìdáhùn. Ọgọ́fà àwọn Kristẹni péré ló wà ní yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù, àfi lójijì tí gbogbo ilé náà kún fún ariwo tó ń dún gan-an bí ìgbà tí atẹ́gùn líle ń rọ́. Ẹ̀là iná tó dà bí ahọ́n sì fara hàn lórí wọn, ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ní onírúurú èdè àjèjì. (Ìṣe 2:1-4) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sàmì sí ìbí orílẹ̀-èdè tuntun kan, ìyẹn Ísírẹ́lì Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ “ẹ̀yà àyànfẹ́” àti “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” tuntun tí Ọlọ́run yàn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. (1 Pétérù 2:9) Ó hàn gbangba pé Jèhófà Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìràpadà tí Kristi wá sáyé wá rú. Ọ̀kan lára àǹfààní àkọ́kọ́ tí ẹbọ ìràpadà yẹn ṣe aráyé ni bíbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn àpọ́sítélì yẹn.

6 Látìgbà yẹn wá ni ẹbọ ìràpadà Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láǹfààní níbi yòówù kí wọ́n wà láyé. À báà jẹ́ ara àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “agbo kékeré” tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run tàbí ká jẹ́ ara àwọn “àgùntàn mìíràn” tí Kristi máa ṣàkóso lé lórí láyé níbí, kò sẹ́ni tí ìràpadà yẹn ò ṣe láǹfààní. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Ìràpadà ló jẹ́ ká lè ní ìrètí, ipasẹ̀ rẹ̀ la sì fi lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà. Níwọ̀n ìgbà tá a bá ti “ń lo ìgbàgbọ́” nínú ìràpadà yẹn, tá à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lójoojúmọ́, a óò ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, a ò sì ní máa ṣiyè méjì nípa ọjọ́ ọ̀la.—Jòhánù 3:16.

7. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run gbé lé Jésù lọ́wọ́ nígbà tó padà dé ọ̀run, báwo lo sì ṣe lè fi hàn pé tiẹ̀ lò ń ṣe?

7 Kí ni Jésù ń ṣe lọ́run látìgbà tó ti padà sọ́hùn-ún? Gbogbo àṣẹ láyè àti lọ́run ló bọ́ síkàáwọ́ rẹ̀. (Mátíù 28:18) Kò síyè méjì pé Jèhófà ti yàn án láti máa ṣàkóso ìjọ Kristẹni, ó sì ń ṣàkóso náà tìfẹ́tìfẹ́. (Kólósè 1:13) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀, Jésù ti yan àwọn ọkùnrin tó mọṣẹ́ níṣẹ́ láti máa bójú tó agbo rẹ̀. (Éfésù 4:8) Bí àpẹẹrẹ, ó yan Pọ́ọ̀lù láti jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” ó sì rán an lọ́ láti tan ìhìn rere kálẹ̀ dé àwọn ibi tó jìnnà. (Róòmù 11:13; 1 Tímótì 2:7) Nígbà tí ọ̀rúndún kìíní ń parí lọ, onírúurú iṣẹ́ ni Jésù rán sáwọn ìjọ méje tó wà ní àgbègbè Éṣíà tó wà lábẹ́ àkóso Róòmù. Nínú iṣẹ́ náà, ó gbóríyìn fáwọn kan, ó gba àwọn míì nímọ̀ràn, ó sì bá àwọn kan wí. (Ìṣípayá, orí 2 àti 3) Ǹjẹ́ o gba Jésù ní Orí ìjọ Kristẹni? (Éfésù 5:23) Kó o lè láàfààní àtimáa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn nìṣó, o ní láti máa ṣègbọràn nínú ìjọ, kó o sì máa bá àwọn ará ìjọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀.

8, 9. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run gbé lé Jésù lọ́wọ́ lọ́dún 1914, báwo sì nìyẹn ṣe ní láti kan àwọn ìpinnu tá a bá ń ṣe?

8 Ọlọ́run tún gbé àṣẹ mìíràn lé Jésù lọ́wọ́ lọ́dún 1914. Ọdún yẹn ló di Ọba Ìjọba Mèsáyà tí Jèhófà yàn. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, “ogun . . . bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run.” Kí ni ìyẹn yọrí sí? Ó fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé, èyí sì wá fa ègbé tó ń rọ́ wá sórí ayé yìí. Ogun, ìwà ọ̀daràn, ìpayà, àìsàn, ìmìtìtì ilẹ̀ àti ìyàn tó ń han aráyé òde òní léèmọ̀ yìí ń rán wa létí pé Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run báyìí. Àmọ́, Sátánì ṣì ni “olùṣàkóso ayé yìí” fún “sáà àkókò kúkúrú.” (Ìṣípayá 12:7-12; Jòhánù 12:31; Mátíù 24:3-7; Lúùkù 21:11) Síbẹ̀, títí di báyìí Jésù ṣì ń fún àwọn èèyàn ní àǹfààní láti fara mọ́ ìṣàkóso Rẹ̀.

9 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Mèsáyà Ọba. Nínú gbogbo ìpinnu tá a bá ń ṣe lójoojúmọ́, a ní láti rí i pé ohun tí Jésù fẹ́ là ń ṣe, pé kì í ṣe ohun tí ayé burúkú yìí fẹ́. Bí “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa” yìí ṣe ń bojú wolẹ̀ wo àwọn ọmọ aráyé, ńṣe ni ọkàn rẹ̀ tó kún fún òdodo ń ru fùù fún ìbínú, bákan náà ni ayọ̀ ọkàn rẹ̀ sì ń kún àkúnwọ́sílẹ̀. (Ìṣípayá 19:16) Kí ló fà á?

Ìbínú àti Ayọ̀ Mèsáyà Ọba

10. Irú ẹni wo ni Jésù Ọ̀gá wa, síbẹ̀ kí ló mú kí inú bí i lọ́nà ẹ̀tọ́?

10 Bíi ti Bàbá rẹ̀, Ọ̀gá wa náà jẹ́ aláyọ̀. (1 Tímótì 1:11) Nígbà tí Jésù wà láyé bí èèyàn, kì í ṣèèyàn líle tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ láyé lónìí tó yẹ kó múnú bí i lọ́nà ẹ̀tọ́. Ó dájú pé gbogbo àwọn ìsìn ayé tó ń parọ́ pé Jésù làwọn ń tẹ̀ lé ló ń bínú sí. Ó tiẹ̀ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa wáyé nígbà tó sọ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha . . . ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:21-23.

11-13. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ líle tí Jésù sọ sáwọn tí wọ́n ti ń ṣe “ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára” lórúkọ rẹ̀ ṣe máa ṣe àwọn kan ní kàyéfì, síbẹ̀ kí nìdí tó fi ń bínú sí wọn? Ṣàpèjúwe.

11 Ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni lónìí lọ̀rọ̀ yìí lè máa ṣe ní kàyéfì. Kí nìdí tí Jésù fi lè sọ irú ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́ẹ̀ sáwọn tí wọ́n ti ń ṣe “ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára” ní orúkọ rẹ̀? Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣagbátẹrù onírúurú ètò ìrànwọ́, wọ́n ti ran àwọn tálákà lọ́wọ́, wọ́n ti kọ́ àwọn ilé ìwòsàn àtàwọn ilé ìwé, wọ́n sì ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ míì. Àmọ́ kó o bàa lè mọ ohun tó jẹ́ kí Jésù bínú sí wọn, wo àpèjúwe yìí ná.

12 Bàbá kan àti ìyá kan ní láti rìnrìn àjò. Wọ́n ò lè mú àwọn ọmọ wọn dání, nítorí náà, wọ́n gba naní kan pé kó máa bá wọn tọ́jú àwọn ọmọ wọn. Ohun tí wọ́n sọ fún naní yẹn ò le, wọ́n sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá wa bójú tó àwọn ọmọ wa yìí dáadáa. Má febi pa wọ́n, máa wẹ̀ fún wọn déédéé, kó o sì rí i pé wọn ò ṣèṣe.” Àmọ́, ìgbà táwọn òbí yìí máa tàjò dé, inú wọn bà jẹ́ láti rí i pé ebi ti han àwọn ọmọ wọn léèmọ̀. Wọ̀ṣìwọṣi ni wọ́n rí, wọ́n rù hangogo, kódà àánú wọn á ṣèèyàn. Bí wọ́n ṣé sunkún tó, naní yẹn ò tọ́jú wọn, kò ráyè tiwọn. Kí ló dé? Ìdí ni pé, fèrèsé ló ń fọ̀ lọ ràì ní tiẹ̀. Tìbínútìbínú làwọn òbí àwọn ọmọ náà fi béèrè ìdí tí ò fi bójú tó àwọn ọmọ tí wọ́n fi síkàáwọ́ rẹ̀. Naní náà wá kó àlàyé pàlẹ̀, ó ní: “Ṣé bẹ́yin náà rí gbogbo làálàá tí mo ń ṣe yìí! Ṣé ẹ ò rí báwọn fèrèsé wọ̀nyí ti mọ́ tónítóní tó ni? Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo inú ilé ni mo ti tún ṣe, bẹ́ẹ̀ torí yín náà ni mo ṣe ń ṣe gbogbo kòókòó-jàn-ánjàn-án yìí!” Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo àlàyé rẹ̀ yìí á mú kí inú àwọn òbí yẹn dùn? Kò dájú! Iṣẹ́ tí wọ́n rán an kọ́ ló ń jẹ́; gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ kó ṣe ò ju pé kó tọ́jú àwọn ọmọ wọn. Bí naní yìí ò ṣe tẹ̀ lé ìtọni tí wọ́n fún un yìí ní láti bí àwọn òbí náà nínú gidigidi.

13 Bíi ti naní yẹn gẹ́lẹ́ làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń ṣe. Jésù fún àwọn tó ní kí wọ́n ṣojú fóun ní ìtọ́ni pé kí wọ́n fún àwọn èèyàn òun ní oúnjẹ tẹ̀mí nípa kíkọ́ wọn ní òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà ní mímọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí. (Jòhánù 21:15-17) Síbẹ̀, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò tiẹ̀ ṣú já ìtọ́ni yẹn. Wọ́n ti febi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa àwọn èèyàn, wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ èké da gbogbo nǹkan rú mọ́ àwọn èèyàn lójú, wọ́n sì ń fi òtítọ́ inú Bíbélì pa mọ́ fún wọn. (Aísáyà 65:13; Ámósì 8:11) Nítorí náà, àwíjàre wọn pé ṣe làwọ́n ń ṣakitiyan láti mú kí ìlú tòrò ò lè mú wọn jàre ìwà àìgbọràn tí wọ́n ń hù. Ó ṣe tán, ètò ayé yìí ò yàtọ̀ sí ilé tí wọ́n ti sàmì sí pé wọ́n máa wó lulẹ̀! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere pé ìṣàkóso Sátánì lórí ilẹ̀ ayé yìí máa tó pa run.—1 Jòhánù 2:15-17.

14. Iṣẹ́ wo ló ń múnú Jésù dùn lónìí, kí sì nìdí?

14 Lọ́wọ́ kejì, kò sí kí inú Jésù má dùn tó bá bojú wolẹ̀ látọ̀run tó sì rí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tó gbé lé àwọn ọmọlẹ́yìn lọ́wọ́ kó tó kúrò láyè. (Mátíù 28:19, 20) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti lọ́wọ́ nínú ohun tó ń ṣàlékún ayọ̀ Mèsáyà Ọba! Ǹjẹ́ ká pinnu láti má ṣe dẹwọ́ nínú ríran “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” lọ́wọ́. (Mátíù 24:45) Láìdàbí àṣáájú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí ti mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ti ń fi ìṣòtítọ́ bọ́ àwọn àgùntàn Kristi.

15, 16. (a) Báwo ni àìsí ìfẹ́ tó wà káàkiri láyé yìí ṣe rí lára Jésù, báwo la sì ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? (b) Kí ló jẹ́ kí Jésù bínú sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

15 Ó dá wa lójú pé inú Ọba náà ò dùn bó ṣe rí i pé kò sí ìfẹ́ láyé lónìí. A lè rántí báwọn Farisí ṣe ń ta ko Jésù torí pé ó ṣe iṣẹ́ ìwòsàn lọ́jọ́ Sábáàtì. Wọn ò láàánú kankan lójú, tiwọn nìkan ló ń yé wọn débi pé ibi tó bá wù wọ́n láti tú Òfin Mósè àti òfin àtẹnudẹ́nu wọn sí ni wọ́n ń tú u sí. Àìmọye oore ni iṣẹ́ ìyanu Jésù ṣe fáwọn èèyàn! Ṣùgbọ́n lójú àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn, gbogbo bí iṣẹ́ ìyanu Jésù ṣe mú ayọ̀ bá àwọn èèyàn, tó ń mára tù wọ́n, tó sì ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn jinlẹ̀ sí i ò já mọ́ nǹkan kan. Ojú wo ni Jésù fi wò wọ́n? Ìgbà kan wà tó “wò wọ́n yí ká pẹ̀lú ìkannú, nítorí tí ó ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi sí yíyigbì ọkàn-àyà wọn.”—Máàkù 3:5.

16 Lónìí, àìmọye irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ló wà tó ń mú kí “ìkannú” Jésù ru. Àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu táwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ń dì mú ti fọ́ wọn lójú. Síwájú sí i, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń bí wọn nínú. Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, àwọn àlùfáà ìsìn ti dáná inúnibíni tó le mọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n ń gbìyànjú láti fi òtítọ́ inú wàásù ìhìn tí Jésù wàásù. (Jòhánù 16:2; Ìṣípayá 18:4, 24) Lọ́wọ́ kan náà, irú àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn ń gba àwọn ọmọlẹ́yìn wọn níyànjú pé kí wọ́n lọ jagun, kí wọ́n gbẹ̀mí àwọn ẹlòmíì, àfi bíi pé ìyẹn ló máa múnú Jésù Kristi dùn!

17. Báwo làwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe ń múnú rẹ̀ dùn?

17 Ní ti àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́, ńṣe ni wọ́n máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. Wọ́n máa ń wàásù ìhìn rere fún “gbogbo onírúurú ènìyàn” bíi ti Jésù láìfi àtakò pè. (1 Tímótì 2:4) Ìfẹ́ tí wọ́n sì fi ń bára wọn lò yàtọ̀; ìfẹ́ yẹn làwọn èèyàn sì fi mọ̀ wọ́n. (Jòhánù 13:34, 35) Bí wọ́n ṣe ń fi ìfẹ́, ọ̀wọ̀ àti iyì bá àwọn Kristẹni bíi tiwọn lò ń fi hàn pé lóòótọ́, ọmọlẹ́yìn Jésù ni wọ́n, wọ́n sì ń múnú Mèsáyà Ọba dùn!

18. Kí ló máa ń ba Ọ̀gá wa nínú jẹ́, síbẹ̀ báwo la ṣe lè múnú rẹ̀ dùn?

18 Ẹ jẹ́ ká tún fi sọ́kàn pé inú Ọ̀gá wa máa ń bà jẹ́ nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá kọ̀ tí wọn ò ní ìfaradà, tí wọ́n wá jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà di tútù, tí wọ́n sì láwọn kì í ṣe ìránṣẹ́ Rẹ̀ mọ́. (Ìṣípayá 2:4, 5) Àmọ́ o, inú Jésù máa ń dùn sáwọn tó bá ní ìfaradà títí dópin. (Mátíù 24:13) Bó bá ṣe wù kó rí, ní gbogbo ìgbà ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa rántí àṣẹ Kristi yìí, pé: “Máa bá a lọ ní títọ̀ mí lẹ́yìn.” (Jòhánù 21:19) Ẹ wá jẹ́ ká jíròrò díẹ̀ lára ìbùkún tí Mèsáyà Ọba máa rọ̀jò rẹ̀ sórí àwọn tó bá fara dà á dópin.

Ìbùkún Jaburata Fáwọn Adúróṣinṣin Ìránṣẹ́ Ọba Náà

19, 20. (a) Àǹfààní wo ló wà nínú títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù nísinsìnyí? (b) Ọ̀nà wo ni Kristi máa gbà jẹ́ ‘Baba Ayérayé’ fún wa bá a bá ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?

19 Títọ Jésù lẹ́yìn nìkan ni ohun tó lè jẹ́ kéèyàn gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀ nísinsìnyí. Bá a bá gba Kristi ní Ọ̀gá wa, tá a ń tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀, tá a sì ń jẹ́ káwọn àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ fún wa máa tọ́ wa sọ́nà, a óò rí ìṣúra tó ti di àléèbá fáwọn èèyàn inú ayé. Iṣẹ́ tó ń mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀ la ó máa ṣe, a óò wà láàárín ìdílé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tí ìfẹ́ tó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé so pọ̀, a óò ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Lọ́rọ̀ kan, ìgbésí ayé wa á dùn bí oyin. Kódà á tún dùn joyin lọ.

20 Jèhófà ti fún gbogbo àwọn tó ń retí àtiwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ní Jésù gẹ́gẹ́ bíi “Baba Ayérayé.” Jésù ni Jèhófà fi rọ́pò bàbá ẹ̀dá èèyàn, ìyẹn Ádámù tó kó gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ sí wàhálà yìí. (Aísáyà 9:6, 7) Bá a bá gba Jésù bíi “Bàbá Ayérayé,” tá à ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tá a ní dájú. Bákan náà, a óò máa tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run síwájú àti síwájú sí i. Pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tá a ti kọ́ nínú ìwé yìí, ń ṣe ló yẹ ká làkàkà láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lójoojúmọ́ torí pé èyí ni ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà máa ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—Éfésù 5:1.

21. Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé tó ṣókùnkùn yìí?

21 Àǹfààní tí ò láfiwé la ní bá a ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti Jèhófà Bàbá rẹ̀. Ńṣe la óò máa tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀. Nínú ayé tí òkùnkùn bò yìí, níbi tí Sátánì ti ń ṣi ọ̀kẹ́ àìmọye lọ́nà, táwọn náà sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ńṣe làwa tá à ń tọ Kristi lẹ́yìn ń tan ìmọ́lẹ̀ títàn yòò kárí ayé. Ìmọ́lẹ̀ yẹn ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́, ìmọ́lẹ̀ àwọn ìwà àtàtà tàwa Kristẹni ń hù, ìmọ́lẹ̀ ojúlówó ayọ̀ àti àlàáfíà àti ti ìfẹ́ tòótọ́. Bákan náà, a kì í yé ṣe ohun tó ń mú ká máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Èyí sì ni olórí ohun tá a fẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ̀, òun ni gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè gbọ́dọ̀ máa lé.

22, 23. (a) Ìbùkún wo ló ń dúró de àwọn tó bá ń fi ìdúróṣinṣin tọ Jésù lẹ́yìn? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

22 Tún ronú lórí ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún ọ lọ́jọ́ iwájú nípasẹ̀ Mèsáyà Ọba. Láìpẹ́, Ọba yẹn á ja ìjà òdodo pẹ̀lú ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì yìí. Ó dájú pé Jésù ló máa borí! (Ìṣípayá 19:11-15) Lẹ́yìn ìyẹn, Kristi máa bẹ̀rẹ̀ Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún rẹ̀ lé ilẹ̀ ayé lórí. Ìjọba yẹn tó máa fi ọ̀run ṣe ibùjókòó á mú kí gbogbo èèyàn tó bá jẹ́ olóòótọ́ jọlá ìràpadà, èyí tó máa sọ wọ́n dẹni pípé. Fojú inú wo bó ṣe máa rí, pé o ní ìlera tó jí pépé, tára rẹ ń jà yọ̀yọ̀ tó o sì lágbára, tó ò ń ṣiṣẹ́ láàárín ìdílé ẹ̀dá èèyàn tó wà níṣọ̀kan láti sọ ayé di Párádísè! Nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún yẹn bá parí, Jésù á dá àkóso padà fún Bàbá rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:24) Bó o bá lè máa bá a lọ láti máa fi ìdúróṣinṣin tọ Kristi lẹ́yìn, èrè tó gọntíọ tíwọ fúnra rẹ ò tiẹ̀ ronú kàn rí lo máa rí gbà, ìyẹn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run”! (Róòmù 8:21) Bó ṣe máa rí nìyẹn o, gbogbo ìbùkún tí a ò rí gbà lọ́dọ̀ Ádámù àti Éfà la máa rí jogún. Nígbà yẹn, gbogbo àwa ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Jèhófà tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé á bọ́ lọ́wọ́ àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. Ní tòótọ́, “ikú kí yóò sì sí mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.

23 Ṣó o ṣì rántí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó tún jẹ́ olùṣàkóso tá a mẹ́nu bà ní Orí 1 ìwé yìí. Ó kọ pípè tí Jésù pè é, pé: “Wá di ọmọlẹ́yìn mi.” (Máàkù 10:17-22) Kí ìwọ yáa má ṣerú àṣìṣe yẹn ní tiẹ̀ o! Ńṣe ni kó o yáa jẹ́ ìpè Jésù tayọ̀tayọ̀, tìtaratìtara. Ǹjẹ́ kó o pinnu láti máa ní ìfaradà, kó o máa tọ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà lẹ́yìn láti ọjọ́ dé ọjọ́ àti ọdún dé ọdún, kó o bàa lè wà láàyè láti rí i nígbà tó bá ń mú gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣètò wá sí ìmúṣẹ ológo nígbẹ̀yìngbẹ́yín!