Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 3

“Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-Àyà Ni Èmi”

“Ẹni Rírẹlẹ̀ ní Ọkàn-Àyà Ni Èmi”

“Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá”

1-3. Báwo ni Jésù ṣe wọ̀lú Jerúsálẹ́mù, kí sì nìdí tíyẹn fi lè ya àwọn kan nínú ogunlọ́gọ̀ àwọn aráàlú tó ń wò ó lẹ́nu?

 ŃṢE ni gbogbo Jerúsálẹ́mù ń kùn yùnmùyùnmù. Èèyàn ńlá kan ló fẹ́ dé bá Jerúsálẹ́mù lálejò! Gbogbo aráàlú ti wà lẹ́bàá ọ̀nà lẹ́yìn òde ìlú Jerúsálẹ́mù. Torí ohun méjì kọ́, torí àtikí ọkùnrin yìí káàbọ̀ ni, àwọn kan tiẹ̀ ń sọ pé ajogún Ọba Dáfídì ni, pé òun lẹni tó tọ́ láti jẹ́ Alákòóso Ísírẹ́lì. Àwọn kan ń mi imọ̀ ọ̀pẹ gẹ́gẹ́ bí àmì ìkíni; àwọn míì tẹ́ aṣọ àtàwọn ewé igi sójú ọ̀nà kí ọ̀nà bàa lè tẹ́ dáadáa níwájú àlejò pàtàkì náà. (Mátíù 21:7, 8; Jòhánù 12:12, 13) Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ nínú wọn ti máa retí àrà tẹ́ni yìí máa dá nígbà tó bá ń wọ̀lú bọ̀.

2 Ó lè jẹ́ pé ohun táwọn kan ń retí ni pé kó wọ̀lú tìlù-tìfọn. Wọn ò ṣàìmọ àwọn lóókọlóókọ tó ti wọ̀lú tìlù-tìfọn bẹ́ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, Ábúsálómù ọmọ Dáfídì pera ẹ̀ lọ́ba; àádọ́ta ọkùnrin ló ní kí wọ́n máa gẹṣin lọ níwájú òun. (2 Sámúẹ́lì 15:1, 10) Júlíọ́sì Késárì tó jẹ́ Olùṣàkóso Róòmù fẹlá jù bẹ́ẹ̀ lọ; ìgbà kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé torí pé ó jáwé olùborí, ńṣe ló kó èrò rẹpẹtẹ sẹ́yìn tí wọ́n sì jọ wọlé òrìṣà Júpítà tí wọ́n kọ́ sórí òkè, ìyẹn òkè tó kéré jù lára àwọn òkè méje tó wà nílùú Róòmù. Ogójì erin tò sápá ọ̀tún, ogójì tò sápá òsì, gbogbo wọn ló sì gbéná lérí. Àmọ́, ẹni táwọn aráàlú Jerúsálẹ́mù ń retí lọ́tẹ̀ yìí kì í ṣẹgbẹ́ àwọn tá a sọ yẹn lọ́nà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n. Yálà ó yé àwọn ogunlọ́gọ̀ náà o tàbí kò yé wọn o, Mèsáyà lèyí, ẹni bíi tiẹ̀ ò tíì sí láyé rí. Ìgbà tí Ọba lọ́la yìí sì fi máa wá wọ̀lú Jerúsálẹ́mù, ohun táwọn kan nínú wọn rí ní láti yà wọ́n lẹ́nu.

3 Wọn ò rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin, kò sí àwọn sárésáré, kò sí ẹṣin, ó sì dájú pé kò sí erin kankan. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lásánlàsàn, ẹran arẹrù tẹ́nikẹ́ni ò kà sí ni Jésù gùn wọ Jerúsálẹ́mù. a Ẹni tó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yìí ò wọṣọ gẹ̀gẹ̀-ruru kan sọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò dáṣọ sọ́rùn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó gùn lárà ọ̀tọ̀. Èyí táwọn ọlọ́lá kan á fi fawọ olówó iyebíye di ẹṣin wọn ní gàárì, aṣọ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó sún mọ́ ọn tẹ́ sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ni Jésù jókòó lé. Kí ni ì báà dé tí Jésù fi ní láti wọ̀lú Jerúsálẹ́mù láìpàfíyèsí bẹ́ẹ̀ nígbà táwọn tí ò tiẹ̀ lọ́lá tó o rárá àti rárá ń wọ̀lú tìlù-tìfọn?

4. Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Mèsáyà Ọba ṣe máa wọ Jerúsálẹ́mù?

4 Àsọtẹ́lẹ̀ kan báyìí ni Jésù ń mú ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Kún fún ìdùnnú gidigidi . . . Kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù. Wò ó! Ọba rẹ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá. Ó jẹ́ olódodo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni ìgbàlà; onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ẹran tí ó ti dàgbà tán, ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” (Sekaráyà 9:9) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé lọ́jọ́ kan, Ẹni tí Ọlọ́run dìídì yàn, ìyẹn Mèsáyà á fira rẹ̀ han àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù pé òun ni Ọba tí Ọlọ́run yàn. Síwájú sí í, bó ṣe máa wọ̀lú àti irú ẹran tó máa gùn wọ̀lú á jẹ́ káwọn èèyàn lè rí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ rere tó ní. Ànímọ́ ọ̀hún sì ni ìrẹ̀lẹ̀.

5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé bá a bá ronú nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù, á wuni láti sún mọ́ ọn, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kọ́ láti fìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ Jésù?

5 Ìrẹ̀lẹ̀ Jésù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó wuni jù lọ, tó jẹ́ pé téèyàn bá ronú nípa rẹ̀, á wu èèyàn láti sún mọ́ Jésù. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ní orí 2 ìwé yìí, Jésù nìkan ni “ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” (Jòhánù 14:6) Ó dájú pé kò sí ẹ̀dá èèyàn náà lára ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó tíì gbé ayé yìí rí tá a lè kà sí èèyàn pàtàkì bí Ọmọ Ọlọ́run. Síbẹ̀, kò sígbà kan rí tí Jésù ṣe ohun tó jọ ìgbéraga, kò wú fùkẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jọra rẹ̀ lójú bíi táwọn ẹ̀dá èèyàn aláìpé. Bá a bá fẹ́ máa tọ Kristi lẹ́yìn, a ní láti yàgò fún ìgbéraga. (Jákọ́bù 4:6) Rántí pé, Jèhófà kórìíra ìgbéraga. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká fìwà jọ Jésù nípa jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

Ó Pẹ́ Tó Ti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

6. Irú ẹni wo la lè pè ní onírẹ̀lẹ̀, báwo ni Jèhófà sì ṣe mọ̀ pé Mèsáyà á jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

6 Onírẹ̀lẹ̀ lẹni tí kì í jọra rẹ̀ lójú, tí ìgbéraga ò sí lọ́kàn rẹ̀. Inú ọkàn ni ìrẹ̀lẹ̀ yìí máa ń wà, ó sì máa ń hàn nínú ọ̀rọ̀, ìwà àti ìṣe èèyàn sáwọn ẹlòmíì. Báwo ni Jèhófà ṣe mọ̀ pé Mèsáyà á jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Jèhófà mọ̀ pé àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀ òun tí kò kù síbì kan ni Ọmọ òun máa tẹ̀ lé. (Jòhánù 10:15) Àti pé Ọmọ rẹ̀ yìí ti fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn níṣojú rẹ̀ rí. Nígbà wo nìyẹn?

7-9. (a) Nígbà tí Máíkẹ́lì ń bá Sátánì ṣe awuyewuye, ọ̀nà wo ló gbà fìrẹ̀lẹ̀ hàn? (b) Báwo làwa Kristẹni ṣe lè fìwà jọ Máíkẹ́lì nínú jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

7 Ìwé Júdà fún wa ní àpẹẹrẹ kan tó wuni: “Nígbà tí Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì ní aáwọ̀ pẹ̀lú Èṣù, tí ó sì ń ṣe awuyewuye nípa òkú Mósè, kò dá a láṣà láti mú ìdájọ́ wá lòdì sí i ní àwọn ọ̀rọ̀ èébú, ṣùgbọ́n ó wí pé: ‘Kí Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná.’” (Júdà 9) Máíkẹ́lì ni Orúkọ Jésù kó tó wá sáyé àti lẹ́yìn tó padà sí ọ̀run. Orúkọ yìí fi í hàn bí olú-áńgẹ́lì tàbí olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn áńgẹ́lì Jèhófà lájùlé ọ̀run. b (1 Tẹsalóníkà 4:16) Àmọ́ ṣá, kíyè sí ohun tí Máíkẹ́lì ṣe sí ọ̀rọ̀ tó wáyé láàárín òun àti Sátánì yẹn.

8 Àkọsílẹ̀ Júdà ò sọ ohun tí Sátánì fẹ́ fi òkú Mósè ṣe, ṣùgbọ́n ohun tó dájú ni pé láabi kan ló wà lọ́kàn Èṣù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló fẹ́ sọ òkú ọkùnrin olódodo yìí di ohun tí wọ́n á máa lò nínú ìjọsìn èké. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Máíkẹ́lì bá Sátánì fà á kó má bàa ráyè hùwà láabi tó wà lọ́kàn rẹ̀, ó rí i pé òun kó ara òun níjàánu. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, Sátánì yẹ lẹ́ni tí Jésù á ké ègbé lé lórí, ṣùgbọ́n níwọ̀n bó ti jẹ́ pé lásìkò tó ń bá Sátánì ṣe awuyewuye yẹn, Baba ò tíì fi “gbogbo ìdájọ́ ṣíṣe” lé e lọ́wọ́, ó ṣì gbà pé Jèhófà Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 5:22) Gẹ́gẹ́ bí olú-áńgẹ́lì, Máíkẹ́lì ní àṣẹ tó ga lórí àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà tó wà lọ́run. Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ló fi fi ìdájọ́ sílẹ̀ sọ́wọ́ Jèhófà dípò tí ì bá fi máa wá àṣẹ kún àṣẹ. Yàtọ̀ sí ìrẹ̀lẹ̀, ó tún fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun tàbí ká kúkú sọ pé kò kọjá àyè rẹ̀.

9 Ó nídìí tí Ọlọ́run fi mí sí Júdà láti kọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan láyé ìgbà Júdà ò nírẹ̀lẹ̀. Ńṣe ni wọ́n “ń sọ̀rọ̀ tèébútèébú nípa gbogbo ohun tí wọn kò mọ̀” dáadáa. (Júúdà 10) Ẹ ẹ̀ rí i bó ṣe rọrùn tó fáwa ẹ̀dá aláìpé láti jẹ́ kí ìgbéraga wọ̀ wá lẹ́wù! Bí nǹkan kan ò bá yé wa lára àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ, bóyá tó jẹ mọ́ ìpinnu kan tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ṣe, kí la máa ń ṣe? Bá a bá lọ ń kùn tàbí tá à ń ṣàròyé nípa ìpinnu kan bẹ́ẹ̀ nígbà tá ò sì mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó mú wọn ṣèpinnu ọ̀hún, ṣé ìyẹn á fi wá hàn bí ẹni tó nírẹ̀lẹ̀? Rára. Nítorí náà, Máíkẹ́lì, ìyẹn Jésù ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa fìwà jọ, ká má ṣe máa dá ẹjọ́ tí Ọlọ́run ò gbé lé wa lọ́wọ́.

10, 11. (a) Kí ni nǹkan tó jọni lójú nínú gbígbà tí Ọmọ Ọlọ́run gbà láti wá sáyé? (b) Báwo la ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù?

10 Ọmọ Ọlọ́run tún fìrẹ̀lẹ̀ hàn nípa bó ṣe gbà láti wá sáyé. Ìwọ wo adúrú ohun tó yááfì kó bàa lè wá sáyé. Olú-áńgẹ́lì ni. Òun tún ni “Ọ̀rọ̀,” ìyẹn Agbọ̀rọ̀sọ Jèhófà. (Jòhánù 1:1-3) Ọ̀run ló ń gbé, ní ibùjókòó Jèhófà “gíga fíofío ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà.” (Aísáyà 63:15) Síbẹ̀síbẹ̀, Ọmọ yìí “sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.” (Fílípì 2:7) Tiẹ̀ wo ohun tó wé mọ́ wíwá tó wá sáyé ná! Ọlọ́run fi ìwàláàyè rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá kan tó jẹ́ Júù, ibẹ̀ ló sì wà fún oṣù mẹ́sàn-án kó tó di pé ó bí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ tuntun jòjòló. Káfíńtà kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ ni baálé ilé tí wọ́n ti bí i. Inú àìsí yẹn náà ni wọ́n sì ti tọ́ ọ dàgbà díẹ̀díẹ̀ bí ìkókó kó tó wá di ọ̀dọ́kùnrin. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni òun fúnra rẹ̀, síbẹ̀ ó gbọ́ràn sí àwọn òbí aláìpé tó tọ́ ọ dàgbà lẹ́nu. (Lúùkù 2:40, 51, 52) Ìrẹ̀lẹ̀ yẹn mà pọ̀ o!

11 Ṣé àwa náà lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù nígbà tí wọ́n bá fún wa ní iṣẹ́ kan tá a rò pé ó rẹlẹ̀ sí wa nínú ìjọ? Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lè dá bí iṣẹ́ kan tó rẹlẹ̀, àgàgà nígbà táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́rọ̀ wa, tí wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tí wọ́n ń ṣàtakò sí wa. (Mátíù 28:19, 20) Síbẹ̀ bá a bá lè lo ìfaradà lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ó ṣeé ṣe ká gbẹ̀mí àwọn èèyàn là. Yálà a gbẹ̀mí là o, a ò gbẹ̀mí là o, a máa rí ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye kọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀, àá sì lè máa tẹ̀ lé ipasẹ̀ Ọ̀gá wa, Jésù Kristi.

Bí Jésù Ṣe Fìrẹ̀lẹ̀ Hàn Gẹ́gẹ́ bí Èèyàn

12-14. (a) Báwo ni Jésù ṣe máa ń fìrẹ̀lẹ̀ hàn báwọn èèyàn bá yìn ín? (b) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fìrẹ̀lẹ̀ bá àwọn ẹlòmíì lò? (d) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ìrẹ̀lẹ̀ Jésù kì í ṣe ọ̀ràn ìwà ọmọlúwàbí lásán?

12 Látìbẹ̀rẹ̀ dópin, ìrẹ̀lẹ̀ ni Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó fìyẹn hàn lọ́nà tó gbà darí ìyìn àti ògo sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀. Àwọn èèyàn nígbà míì máa ń yin Jésù torí bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe máa ń fọgbọ́n yọ, torí agbára tó fi ń ṣiṣẹ́ ìyanu àti torí ìwà ọmọlúwàbí tó ní. Àìmọye ìgbà ni Jésù máa ń gbé irú ògo bẹ́ẹ̀ kúrò lórí ara rẹ̀ tó sì máa gbé e fún Jèhófà.—Máàkù 10:17, 18; Jòhánù 7:15, 16.

13 Ọ̀nà tí Jésù máa ń gbà bá àwọn èèyàn lò fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ ni. Kódà ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé torí kóun lè sin àwọn èèyàn lòun ṣe wá sáyé kì í ṣe torí kí wọ́n lè sin òun. (Mátíù 20:28) Ó fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú bó ṣe máa ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti òye bá àwọn èèyàn lò. Láwọn ìgbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá ṣe ohun tí ò fẹ́, kì í bẹnu àtẹ́ lù wọ́n; ńṣe ló máa ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Mátíù 26:39-41) Nígbà kan tó fẹ́ lọ síbi tó pa rọ́rọ́ táá ti lè ráyè sinmi, táwọn èèyàn ò sì wá jẹ́ kó ráyè sinmi, kò lé wọn padà; ńṣe ló tiraka, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní “ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:30-34) Nígbà tí obìnrin kan báyìí tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀ ẹ́ pé kó bá òun mú ọmọbìnrin òun lára dá, ó kọ́kọ́ jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò fẹ́ ṣe ohun tó ń béèrè yẹn fún un. Síbẹ̀, kò lé e tìbínú tìbínú; nígbà tó sì kíyè sí í pé ìgbàgbọ́ obìnrin náà ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ṣe ohun tí obìnrin yẹn fẹ́ gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa jíròrò rẹ̀ nínú Orí 14 níwájú.—Mátíù 15:22-28.

14 Àìmọye ọ̀nà ni ìgbésí ayé Jésù fi bá ohun tó sọ nípa ara rẹ̀ mu pé: “Onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi.” (Mátíù 11:29) Ìrẹ̀lẹ̀ Jésù kì í ṣe ìrẹ̀lẹ̀ ojú ayé, kì í sì í ṣe ọ̀rọ̀ ìwà ọmọlúwàbí kan ṣá. Inú ọkàn rẹ̀ ló ti wá, ìyẹn ni pé onírẹ̀lẹ̀ ni látọkànwá. Abájọ tó fi jẹ́ pé báwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ló ń kọ́ wọn ṣáá!

Bó Ṣe Kọ́ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

15, 16. Ìyàtọ̀ wo ni Jésù sọ pó gbọ́dọ̀ wà láàárín ìwà àwọn ọmọlẹ́yìn òun àti ìwà àwọn alákòóso ayé?

15 Àwọn àpọ́sítélì ò tètè mọ bó ṣe yẹ káwọn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ó wá di dandan pé kí Jésù máa kọ́ wọn léraléra bí ẹní ń kọ́lé. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jákọ́bù àti Jòhánù sọ fún ìyá wọn pé kó báwọn sọ fún Jésù pé kó ṣèlérí pé òun á gbé àwọn sípò ńlá nínú Ìjọba Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó fún wọn lésì pé: “Jíjókòó yìí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọwọ́ Baba mi.” “Ìkannú” àwọn àpọ́sítélì mẹ́wàá yòókù “ru sí” Jákọ́bù àti Jòhánù fún ohun tí wọ́n ṣe yẹn. (Mátíù 20:20-24) Báwo ni Jésù ṣe wá yanjú wàhálà yìí?

16 Ó fi pẹ̀lẹ́tù bá gbogbo wọn wí nípa sísọ pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.” (Mátíù 20:25-27) Ó ṣeé ṣe káwọn àpọ́sítélì náà mọ bí “àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè” ṣe máa ń gbéra ga, tí wọ́n máa ń fẹ́ wá agbára kún agbára, tí wọn kì í sì í ro tẹlòmíì mọ́ tiwọn. Jésù fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ yàtọ̀ sírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tí ń wá agbára lójú méjèèjì láti lè jẹ gàba lé ẹlòmíì lórí. Dandan ni kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ kí wọ́n kọ́ yé wọn?

17-19. (a) Nígbà tó ku ọ̀la kí Jésù kú, ọ̀nà tí kò ṣeé gbàgbé wo ló gbà kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ tó lágbára jù lọ wo nípa ìrẹ̀lẹ̀ ni Jésù, gẹ́gẹ́ bí èèyàn fi kọ́ni?

17 Kò tètè yé wọn. Ìgbà yẹn kọ́ nìgbà àkọ́kọ́ tí Jésù kọ́ wọn nírú ẹ̀kọ́ yẹn, kì í sì í ṣe ìgbà yẹn ló kọ́ wọn gbẹ̀yìn. Ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n ń jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù láàárín wọn, ó pe ọmọdé kan sáàárín wọn, ó sì sọ fún wọn pé wọ́n ní láti rí bí ọmọ kékeré yẹn, torí pé àwọn ọmọdé ò dà bí àwọn àgbàlagbà ní ti pé wọn kì í gbéra ga, wọn kì í wá ipò àti ọlá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í jọra wọn lójú. (Mátíù 18:1-4) Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, nígbà tó ku ọ̀la tó máa kú, ó ṣì tún rí i pé àwọn àpọ́sítélì ò tíì fi ìgbéraga sílẹ̀. Ìgbà yẹn ló wá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọn ò jẹ́ gbàgbé láé. Ó fi aṣọ ìnura di ara rẹ̀ lámùrè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ kan tó rẹlẹ̀ gan-an, èyí tó jẹ́ pé lákòókò yẹn, ìránṣẹ́ nìkan ló máa ń ṣe é fún àwọn àlejò tó bá wá kí ọ̀gá rẹ̀. Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan títí kan ẹsẹ̀ Júdásì, ẹni tó máa dà á láìpẹ́ sí àkókò yẹn!—Jòhánù 13:1-11.

18 Jésù jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ tóun ń lò níbẹ̀ yẹn yé wọn nígbà tó sọ fún wọn pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 13:15) Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ yẹn wọ̀ wọ́n lọ́kàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn? Ẹ jẹ́ mọ̀ pé lóru yẹn kan náà, wọ́n tún jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù láàárín wọn! (Lúùkù 22:24-27) Síbẹ̀, Jésù ò jẹ́ kó sú òun láti máa ní sùúrù pẹ̀lú wọn, ó sì ń fi ìrẹ̀lẹ̀ kọ́ wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ tó tíì lágbára jù lọ nípa ìrẹ̀lẹ̀: “Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílípì 2:8) Jésù fi tinútinú yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti kú ikú ẹ̀sín, ó gbà kí wọ́n dá òun lẹ́bi gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn àti asọ̀rọ̀-òdì. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọmọ Ọlọ́run fira ẹ̀ hàn lẹ́dàá tó yàtọ̀, nítorí pé láàárín gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà, ara òun nìkan la ti rí ohun tó ń jẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ tó pé pérépéré láìkù síbì kan.

19 Àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé ọ̀nà tó gbà kọ́ wọn ní ìrẹ̀lẹ̀ kẹ́yìn yìí gẹ́gẹ́ bí èèyàn ló jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ ráyè jókòó lọ́kàn àwọn àpọ́sítélì olóòótọ́ náà. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé lẹ́yìn ìgbà yẹn, kódà fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn fi ń fìrẹ̀lẹ̀ bá iṣẹ́ wọn lọ. Ṣé àwa náà ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Ṣé Wàá Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀?

20. Báwo la ó ṣe mọ̀ pé ìrẹ̀lẹ̀ wà nínú ọkàn wa?

20 Pọ́ọ̀lù gba ẹnì kọ̀ọ̀kan wa níyànjú pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú.” (Fílípì 2:5) Gẹ́gẹ́ bíi Jésù, ó pọn dandan ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn. Báwo la ṣe lè mọ̀ pé ìrẹ̀lẹ̀ wà nínú ọkàn wa? Gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù rán wa létí ná, pé a ò gbọ́dọ̀ ṣe ‘ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ká máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ (Fílípì 2:3) Nítorí náà, ohun tá a máa fi mọ̀ bóyá ìrẹ̀lẹ̀ wà lọ́kàn wa ni ojú tá a fi ń wo ara wa láwùjọ àwọn ẹlòmíì. Ńṣe ló yẹ ká máa wò wọ́n bí ẹni tó lọ́lá jù wá lọ, àní bí ẹni tó ṣe pàtàkì jù wá lọ. Ṣé wàá fi ìmọ̀ràn yìí sílò?

21, 22. (a) Kí nìdí táwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni fi gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fi ìrẹ̀lẹ̀ di ara wa lámùrè?

21 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, àpọ́sítélì Pétérù ṣì ń ronú nípa bí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ṣe pàtàkì tó. Pétérù kọ́ àwọn alábòójútó nínú ìjọ pé kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, pé kí wọ́n má ṣe máa jẹ gàba lé àwọn àgùntàn Jèhófà lórí. (1 Pétérù 5:2, 3) Pé ẹnì kan ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan kò ní kó di agbéraga. Ohun tí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn téèyàn lè ní wà fún ni láti jẹ́ kéèyàn túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Lúùkù 12:48) Àmọ́ ṣá, gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ ní ànímọ́ tó ṣe kókó yìí, kì í ṣe àwọn alábòójútó nìkan.

22 Ó dájú pé Pétérù ò jẹ́ gbàgbé ohun tí Jésù ṣe ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù fọ ẹsẹ̀ rẹ̀, pẹ̀lú bí Pétérù ṣe kọ́kọ́ kọ̀ jálẹ̀! (Jòhánù 13:6-10) Pétérù kọ̀wé sáwọn Kristẹni pé: “Gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pétérù 5:5) Gbólóhùn náà, “di ara yín lámùrè” jẹ́ ká ronú nípa bí ìránṣẹ́ kan ṣe máa ń wọ aṣọ iṣẹ́, táá ta mọ́ra bí ìgbà tó di àmùrè nígbà tó bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ilé. Ó ṣeé ṣe kí àpólà gbólóhùn yìí rán wa létí ìgbà tí Jésù mú aṣọ ìnura tó sì di ara rẹ̀ lámùrè kó tó kúnlẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ fífọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Bá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ǹjẹ́ iṣẹ́ kan á wà tí Ọlọ́run á yàn fún wa tá a máa wò bí èyí tó rẹlẹ̀ sí wa? Bá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, gbogbo èèyàn ló yẹ kó rí i lára wa bí ìgbà tá a wọ̀ ọ́ sọ́rùn bí aṣọ.

23, 24. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká yàgò fún ohunkóhun tó bá lè sọ wá di agbéraga? (b) Èrò tí kò tọ́ wo nípa ìrẹ̀lẹ̀ la máa ṣàlàyé tó tọ́ nípa rẹ̀ nínú orí tó kàn?

23 Bíi májèlé ni ìgbéraga rí. Ohun tó máa ń yọrí sí kì í dáa. Ànímọ́ kan tó lè mú kí ẹ̀bùn yòówù tẹ́nì kan ní dìdàkudà mọ́ ọn lára níwájú Ọlọ́run ni. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrẹ̀lẹ̀ lè mú kí ẹni tí ò tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan di ẹni tó máa wúlò fún Jèhófà. Bá a bá kọ́ ànímọ́ ṣíṣeyebíye yìí nípa sísapá láti máa fìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi, àǹfààní tá a máa rí níbẹ̀ kọjá sísọ. Pétérù kọ̀wé pé: “Nítorí náà ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ.” (1 Pétérù 5:6) Ó dájú pé Jèhófà gbé Jésù ga torí pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá. Inú Ọlọ́run wa á dùn láti san ọ́ lẹ́san rere bó o bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.

24 Àmọ́, ó dunni pé àwọn kan ń rò pé béèyàn bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé ojo lẹni náà. Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé irọ́ pọ́ńbélé ni, torí pé àwọn onírẹ̀lẹ̀ náà ló sábà máa ń ní ìgboyà jù. Èyí la máa jíròrò ní orí tó kàn.

a Nígbà tí ìwé kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ní “ẹran tí kò jọjú” ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Ó fi kún un pé: “Wọn ò kì í ṣe ẹran tó já fáfá, wọ́n lórí kunkun, ẹran táwọn tálákà sábà máa ń fi ṣiṣẹ́ ni àti pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́wà.”

b Fún ẹ̀rí síwájú sí í nípa bó ṣe jẹ́ pé Jésù ni Máíkẹ́lì, wo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ojú ìwé 218 àti 219. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.