Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 7

‘Ẹ Ronú Jinlẹ̀ Nípa Ẹni Tó Lo Ìfaradà’

‘Ẹ Ronú Jinlẹ̀ Nípa Ẹni Tó Lo Ìfaradà’

1-3. (a) Báwo ni ìdààmú ọkàn tó bá Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì ṣe le tó, kí ló sì fà á? (b) Kí la lè sọ nípa àpẹẹrẹ ìfaradà Jésù, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?

 WÀHÁLÀ tó bá a kọjá sísọ. Àníyàn àti ìdààmú ọkàn tó bá a kò pọ̀ tóyẹn rí. Wákàtí mélòó kan ló kù tó máa lò láyé. Ibi tóun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ti jọ máa ń wà tẹ́lẹ̀ náà ni wọ́n wá, ìyẹn nínú ọgbà Gẹtisémánì. Òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń pàdé níbẹ̀. Àmọ́ lálẹ́ ọjọ́ tá à ń wí yìí, ó pọn dandan kó dá wà lóun nìkan fúngbà díẹ̀. Ó fi àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sí tòsí, ó nìkan lọ sáàárín ọgbà náà nínú lọ́hùn-ún, ó kúnlẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà. Ó gbàdúrà náà taratara, nígbà tó yá, ó wà nínú ìroragógó, òógùn rẹ̀ sì wá “dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀.”—Lúùkù 22:39-44.

2 Kí ló wá kó ìdààmú bá Jésù tó bẹ́ẹ̀? Òótọ́ ni pé ó mọ̀ pé láìpẹ́ sígbà yẹn òun máa jẹ palaba ìyà, ṣùgbọ́n ìyẹn gan-an kọ́ ló ń kó ìdààmú bá a. Ohun kan tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ fíìfíì ló kó ìrònú bá a. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí rẹ̀ báyìí ni ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí orúkọ Bàbá rẹ̀, ó sì mọ̀ pé nítorí ọjọ́ ọ̀la ìràn èèyàn, àfi kóun jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀. Jésù mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ ní ìfaradà. Bó bá fi lè kùnà pẹ́rẹ́n, ẹ̀gàn tó máa bá orúkọ Jèhófà á ti pọ̀ jù. Ṣùgbọ́n Jésù lo ìfaradà. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, nígbà tó kù díẹ̀ kí ọkùnrin tó fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ nínú lílo ìfaradà láyé yìí gbẹ́mìí mì, ó ké ní ohùn rara bí aṣẹ́gun pé: “A ti ṣe é parí!”—Jòhánù 19:30.

3 Bíbélì rọ̀ wá pé ká ‘ronú jinlẹ̀ nípa Jésù ẹni tó lo ìfaradà.’ (Hébérù 12:3) Àwọn ìbéèrè pàtàkì mélòó kan tó jẹ yọ rèé: Kí ni díẹ̀ lára àwọn àdánwò tí Jésù fara dà? Kí ló jẹ́ kó lè fara dà wọ́n? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ohun tí ìfaradà túmọ̀ sí ná.

Kí Ni Ìfaradà?

4, 5. (a) Kí ni “ìfaradà” túmọ̀ sí? (b) Kí la lè fi ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ìfaradà kọjá kéèyàn wulẹ̀ bá ara rẹ̀ nínú ìṣòro tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀?

4 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo wa ni “onírúurú àdánwò” máa ń “kó ẹ̀dùn-ọkàn bá.” (1 Pétérù 1:6) Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a lè sọ pé bá a ṣe ń dojú kọ àdánwò túmọ̀ sí pé a ti fara dà á nìyẹn? Rárá o. Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìfaradà” túmọ̀ sí ni “kéèyàn mú ìṣòro mọ́ra láìbọ́hùn.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ̀rọ̀ nípa irú ìfaradà táwọn tó kọ Bíbélì ní lọ́kàn, ó ní: “Ìfaradà ni pé kéèyàn múra tán láti fàyà rán nǹkan, kì í ṣe pé kéèyàn kàn gba kámú ṣáá, bí kò ṣe pé kéèyàn ní ìrètí tó lágbára bó ṣe ń mú nǹkan mọ́ra . . . Ó jẹ́ ànímọ́ kan tó jẹ́ pé bí ìṣòro bá dé, bó ti wù kó le tó, onítọ̀hún ò ní bọ́hùn, yóò dúró gbọn-in. Ó jẹ́ ànímọ́ rere tó jẹ́ pé lójú àdánwò líle koko jù lọ pàápàá, onítọ̀hún yóò lẹ́mìí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, nítorí tó gbà pé bó ti wù kí nǹkan le tó, ó ń bọ̀ wá dẹ̀.”

5 Láti ní ìfaradà kọja kéèyàn wulẹ̀ bá ara rẹ̀ nínú ìṣòro tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Bí Bíbélì ṣe lò ó, ìfaradà tan mọ́ jíjẹ́ adúróṣinṣin, kéèyàn ní èrò tó tọ́, kó sì gbà pé kò sóhun tó le tí kì í rọ̀. Àpèjúwe kan rèé: Wọ́n fi àwọn ọkùnrin méjì kan sẹ́wọ̀n níbì kan náà àmọ́ nítorí ẹ̀sùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní wọ́n ṣe fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Ẹnì kan jẹ́ ọ̀daràn paraku tínú ń bí burúkú burúkú tó kàn gba kámú torí pé kò sóhun tó lè ṣe sí i. Èkejì jẹ́ Kristẹni tòótọ́ tó ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí pé ó ṣohun tó tọ́, ó dúró ṣinṣin lórí ìpinnu rẹ̀, inú rẹ̀ sì ń dùn torí ó mọ̀ pé àǹfààní nìyẹn jẹ́ láti fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́. A ò lè sọ pé ọ̀daràn yẹn ní ìfaradà, ṣùgbọ́n a lè rí i pé àpẹẹrẹ kan ni Kristẹni adúróṣinṣin yẹn jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká ní ànímọ́ àtàtà tó ń jẹ́ ìfaradà yìí.—Jákọ́bù 1:2-4.

6. Báwo la ṣe lè kọ́ ìfaradà?

6 Dandan ni ká ní ìfaradà ká tó lè ní ìgbàlà. (Mátíù 24:13) Àmọ́ o, a ò bí ànímọ́ pàtàkì yìí mọ́ wa. A ní láti kọ́ bá a ṣe máa ní ìfaradà ni. Lọ́nà wo? Róòmù 5:3 sọ pé: “Ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá.” Bẹ́ẹ̀ ni o, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ ní ìfaradà, a ò ní jẹ́ kí ìbẹ̀rù máa mú wa sá fún gbogbo àdánwò ìgbàgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la gbọ́dọ̀ máa fàyà rán an. Bá a bá lè máa fàyà rán àwọn àdánwò ńláńlá àti kéékèèké tó bá ń dojú kọ wá lójoojúmọ́, ìfaradà là ń ní yẹn. Bá a ṣe ń borí àdánwò tó ń dojú kọ wá la óò máa lágbára sí i láti kojú òmíràn. Ó ṣe tán, nípa mímọ̀ọ́ṣe wa kọ́ la fi ń ní ìfaradà. “Okun tí Ọlọ́run ń pèsè” la gbára lé. (1 Pétérù 4:11) Ká bàa lè máa jẹ́ adúróṣinṣin, Jèhófà ti fún wa ní ìrànlọ́wọ́ tó ju ìrànlọ́wọ́ lọ, ìyẹn ni àpẹẹrẹ ti Ọmọ rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wá fara balẹ̀ wo àpẹẹrẹ ìfaradà tí kò kù síbì kan tí Jésù fi lélẹ̀.

Àwọn Àdánwò Tí Jésù Fara Dà

7, 8. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, kí ló fara dà?

7 Bó ṣe kù díẹ̀ kí Jésù kú nígbà tó wà láyé, ó fara da oríṣiríṣi ìwà òǹrorò tí wọ́n hù sí i. Pẹ̀lú ìdààmú ọkàn tó ga tó bá a ní òru ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé, tún wo bí wọ́n ṣe já a kulẹ̀, tí wọ́n sì fi ìwọ̀sí lọ̀ ọ́. Ẹni tí wọ́n jọ ń jẹ, tí wọ́n jọ ń mu dà á, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ pa á tì, wọ́n fòfin gbé e lọ́nà èrú. Lásìkò yẹn kan náà, àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ gíga jù lọ tí wọ́n jẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n tutọ́ sí i lójú, wọ́n sì gbá a ní ẹ̀ṣẹ́. Síbẹ̀ ó fara dà á, ó ń wò wọ́n láìfọhùn, kò sì bara jẹ́.—Mátíù 26:46-49, 56, 59-68.

8 Láàárín wákàtí mélòó kan tó lò kẹ́yìn, ó fara da ìrora tó le dé góńgó. Wọ́n nà án lọ́rẹ́ débi pé “awọ ara rẹ̀ ń fàya, ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ sì dà nù lára rẹ̀.” Wọ́n kàn án mọ́ òpó igi, wọ́n jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í “kú díẹ̀ díẹ̀ nínú ìrora àti ìnira tó pọ̀ jọjọ.” Ìwọ wo bí ìrora tó ń jẹ á ṣe pọ̀ tó nígbà tí wọ́n ń fi àwọn ìṣó ńláńlá kan ọrùn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́ òpó igi yẹn. (Jòhánù 19:1, 16-18) Wo bí ìrora yẹn á ṣe wá gogò tó nígbà tí wọ́n ń gbé òpó yẹn nàró, tó jẹ́ pé ìṣó tí wọ́n fi kan ọwọ́ àtẹsẹ̀ rẹ̀ ló dì í mú pẹ̀lú bí ẹ̀yìn rẹ̀ tí ẹgba ti já jálajàla ṣe ń ha ara òpó yẹn. Gbogbo ìrora yìí ló fara dà pẹ̀lú adúrú ìdààmú ọkàn tó ní, èyí tá a ṣàlàyé níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.

9. Kí ló túmọ̀ sí láti gbé “òpó igi oró” wa ká sì máa tẹ̀ lé Jésù?

9 Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi, kí làwa náà lè ní láti fara dà? Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó . . . gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Ìyà, ìtìjú tàbí ikú pàápàá ni ọ̀rọ̀ náà, “òpó igi oró” ṣàpèjúwe. Kéèyàn máa tọ Jésù lẹ́yìn kì í ṣe ohun tó rọrùn. Ìlànà táwa Kristẹni ń tẹ̀ lé mú ká yàtọ̀. Ayé yìí kórìíra wa torí pé a kì í ṣe ara wọn. (Jòhánù 15:18-20; 1 Pétérù 4:4) Síbẹ̀síbẹ̀, a ṣe tán láti gbé òpó igi oró wa, ìyẹn ni pé, dípò tí a ó fi padà lẹ́yìn Jésù tó jẹ́ Àwòkọ́ṣe wa, bó bá jẹ́ pé ìyà ló gbà tàbí ikú pàápàá, a ṣe tán láti fara dà á.—2 Tímótì 3:12.

10-12. (a) Kí nìdí tí àìpé àwọn tó yí Jésù ká fi jẹ́ àdánwò ìfaradà fún un? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn àdánwò tí Jésù fara dà?

10 Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó dojú kọ àwọn àdánwò míì tí àìpé àwọn tó yí i ká fà fún un. Rántí pé òun ni “àgbà òṣìṣẹ́,” tí Jèhófà lò láti ṣẹ̀dá ayé àti gbogbo ohun alààyè tó wà nínú rẹ̀. (Òwe 8:22-31) Nítorí náà, Jésù mọ ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fáráyé; Jèhófà fẹ́ kí ànímọ́ Òun máa hàn lára wọn, kí wọ́n sì máa gbádùn ìwàláàyè pẹ̀lú ìlera pípé ní gbogbo ìgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28) Lásìkò tó wà láyé, lọ́nà kan tó tún yàtọ̀, Jésù rí aburú tí ẹ̀ṣẹ̀ fà. Èèyàn lòun náà, ìyẹn sì jẹ́ kó mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àti lọ́kàn èèyàn. Ẹ ẹ̀ rí bó ṣe máa dùn ún gan-an tó nígbà tó rí bí àìpé ti ṣe mú káwọn èèyàn yàtọ̀ sí bí Ádámù àti Éfà ṣe rí nígbà tí wọ́n ṣì jẹ́ ẹni pípé! Àdánwò ìgbàgbọ́ kan léyìí jẹ́ fún Jésù. Ṣó máa jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun kó sì bọ́hùn, kó sọ pé kò sọ́nà àbáyọ fáráyé mọ́? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.

11 Agídí ọkàn àwọn Júù ba Jésù nínú jẹ́ débi tó fi sunkún ní gbangba. Ṣó jẹ́ kí dídá tí wọ́n dágunlá sí ìwàásù òun paná ìtara tiẹ̀ tàbí kó mú kó ṣíwọ́ wíwàásù? Rárá o, dípò tí ì bá fi ṣèyẹn, ńṣe ló “ń kọ́ni lójoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì.” (Lúùkù 19:41-44, 47) Nítorí ìyigbì ọkàn àwọn Farisí tí wọ́n ń ṣọ́ Jésù tọwọ́tẹsẹ̀ bóyá ó máa wo ọkùnrin kan sàn lọ́jọ́ Sábáàtì, Jésù “ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi.” Ǹjẹ́ ó gbà káwọn alátakò tó jẹ́ pé lójú ara wọn, àwọn ló ya olódodo jù kó o láyà jẹ? Kò jẹ́ gbà! Ó wo ọkùnrin náà sàn láìmikàn, kódà àárín gbùngbùn nínú sínágọ́gù níbẹ̀ náà ló ti wò ó sàn!—Máàkù 3:1-5.

12 Nǹkan míì wà tó ní láti jẹ́ àdánwò fún Jésù, ìyẹn sì ni ìkùdíẹ̀-káàtó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù lọ. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ní Orí 3 ìwé yìí, léraléra ni wọ́n ń jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láàárín wọn. (Mátíù 20:20-24; Lúùkù 9:46) Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Jésù gbà wọ́n níyànjú lórí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Mátíù 18:1-6; 20:25-28) Síbẹ̀, wọn ò gbọ́ bọ̀rọ̀. Àní lóru ọjọ́ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn pàápàá, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ “awuyewuye gbígbónájanjan” nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù láàárín wọn. (Lúùkù 22:24) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ wọn sú Jésù débi táá fi gba kámú pé ọ̀rọ̀ wọn ti kọjá àtúnṣe? Rárá o. Gbogbo ìgbà ló máa ń ní sùúrù fún wọn, ó ṣì nírètí pé wọ́n á gbọ́n lọ́jọ́ kan, àti pé ànímọ́ rere tí wọ́n ní ló gbájú mọ́ tó ń wò. Ó mọ̀ pé nínú ọkàn wọn, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àti pé ìfẹ́ Rẹ̀ gan-an ni wọ́n fẹ́ ṣe.—Lúùkù 22:25-27.

Ṣé a óò jẹ́ kí àtakò mọ́kàn wa pami àbí ńṣe la óò máa fìtara wàásù nìṣó?

13. Irú àdánwò tí Jésù fara dà wo làwa náà lè dojú kọ?

13 Àdánwò tó máa dojú kọ wá lè jọ èyí tí Jésù fara dà. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣalábàápàdé àwọn èèyàn tí wọn ò fetí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tàbí àwọn tó ń ta kò ó. Ṣé a óò jẹ́ kí àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bomi sí wa lọ́kàn, àbí ńṣe la óò máa fìtara wàásù nìṣó? (Títù 2:14) Àìpé àwọn ará wa nínú ìjọ lè di àdánwò fún wa. Ẹnì kan lè sọ̀rọ̀ kan láìronújinlẹ̀ tàbí kó ṣe nǹkan tí kò yẹ kó ṣe, èyí sì lè dùn wá. (Òwe 12:18) Ṣé a máa jẹ́ kí àṣìṣe àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ mú ká pa wọ́n tì àbí a ó máa bá a lọ láti mú àṣìṣe wọn mọ́ra ká sì máa wo ànímọ́ rere tí wọ́n ní?—Kólósè 3:13.

Ohun Tó Mú Kí Jésù Lè Fara Dà Á

14. Ohun méjì wo ló ran Jésù lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin?

14 Kí ló ran Jésù lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin, kó sì jẹ́ olùṣòtítọ́ délẹ̀délẹ̀ láìwo ti gbogbo ìwọ̀sí tí wọ́n fi lọ̀ ọ́, gbogbo ìjákulẹ̀ tó rí àti ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́? Ohun pàtàkì méjì ló ran Jésù lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, ojú Ọlọ́run ló ń wò, ó ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí “Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà.” (Róòmù 15:5) Èkejì, Jésù ń wo ọjọ́ iwájú, ó pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ìfaradà rẹ̀ máa mú kó ṣeé ṣe. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn nǹkan wọ̀nyí yẹ̀ wò níkọ̀ọ̀kan.

15, 16. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ò gbára lé okun tara rẹ̀ láti lo ìfaradà? (b) Báwo ni ìgbọ́kànlé tí Jésù ní nínú Bàbá rẹ̀ ṣe lágbára tó, kí sì nìdí?

15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù àti pé kò lábùkù, síbẹ̀ kò gbára lé okun tara rẹ̀ láti fara da àwọn ìṣòro tó bá a. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bàbá rẹ̀ tó wà lọ́run ló yíjú sí, ó sì gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kristi ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là kúrò nínú ikú, pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé.” (Hébérù 5:7) Kíyè sí i pé kì í ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ nìkan ni Jésù “ṣe,” ó tún ṣe ìtọrọ. Ọ̀rọ̀ náà “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀” tọ́ka sí fífi tọkàntọkàn bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n tú sí “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀” jẹ́ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Jésù rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni, léraléra ni Jésù gbàdúrà kíkankíkan nínú ọgbà Gẹtisémánì.—Mátíù 26:36-44.

16 Ó dá Jésù lójú hán-únhán-ún pé Jèhófà á dáhùn ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ òun, nítorí ó mọ̀ pé “Olùgbọ́ àdúrà” ni Bàbá òun. (Sáàmù 65:2) Kí Ọmọ Ọlọ́run yìí tó wá sáyé, ó ti rí bí Bàbá ṣe máa ń dáhùn àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ adúróṣinṣin. Bí àpẹẹrẹ, ojú Ọmọ yìí ló ṣe nígbà tí Jèhófà rán áńgẹ́lì kan látọ̀run pé kó dáhùn àdúrà tí wòlíì Dáníẹ́lì gbà tọkàntọkàn. Kódà, Dáníẹ́lì ò tíì gba àdúrà náà tán tí áńgẹ́lì yẹn fi jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an. (Dáníẹ́lì 9:20, 21) Ṣé Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí Bàbá ní ló máa wá ṣí ọkàn rẹ̀ payá fún un “pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé” tí Bàbá ò ní gbọ́ kó sì dáhùn? Jèhófà dáhùn àwọn àdúrà ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ tí Ọmọ rẹ̀ gbà ó sì rán áńgẹ́lì kan pé kó lọ fún un lókun kó bàa lè fàyà rán àdánwò tó bá a.—Lúùkù 22:43.

17. Ká bàa lè ní ìfaradà, kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa wojú Ọlọ́run, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe é?

17 Káwa náà tó lè ní ìfaradà, ọ̀run la gbọ́dọ̀ máa wò, ìyẹn ni pé ká máa wo Ọlọ́run tó ń fún ẹ̀dá ní “agbára.” (Fílípì 4:13) Bí Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni pípé bá rí i pé ó pọn dandan fóun láti bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, mélòómélòó wá ni tiwa! Bíi ti Jésù, ó lè pọn dandan pé ká rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà léraléra. (Mátíù 7:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní máa retí pé kí áńgẹ́lì kan wá bẹ̀ wá wò, ohun kan dá wa lójú, pé: Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ á dáhùn àdúrà àwa Kristẹni adúróṣinṣin tá a bá ń “tẹpẹlẹ mọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti àdúrà lóru àti lọ́sàn-án.” (1 Tímótì 5:5) Àdánwò yòówù kó dé bá wa—ì báà jẹ́ àìlera, ikú èèyàn wa kan tàbí inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn alátakò—ó dájú pé Jèhófà á dáhùn àdúrà tá a bá gbà tọkàntọkàn pé kó fún wa ní ọgbọ́n, ìgboyà àti okun láti lè fara da ìṣòro.—2 Kọ́ríńtì 4:7-11; Jákọ́bù 1:5.

Jèhófà á dáhùn àdúrà tá a bá gbà tọkàntọkàn pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìfaradà

18. Báwo ni Jésù ṣe ń wo ọjọ́ iwájú, tí kò sì wo ìyà tó máa tó jẹ ẹ́ nìkan?

18 Ohun kejì tó jẹ́ kí Jésù ní ìfaradà ni pé ó ń wo ọjọ́ iwájú, ìyà tó máa tó jẹ ẹ́ nìkan kọ́ ló ń wò. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù ni pé: “Nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró.” (Hébérù 12:2) Àpẹẹrẹ Jésù yìí jẹ́ ká rí bí ìrètí, ayọ̀ àti ìfaradà ṣe lè ṣiṣẹ́ pọ̀. A lè pa gbogbo rẹ̀ pọ̀ báyìí: Ìrètí ń mú ká ní ayọ̀, ayọ̀ sì ń jẹ́ ká lè ní ìfaradà. (Róòmù 15:13; Kólósè 1:11) Ọ̀pọ̀ nǹkan dáadáa ló wà lọ́jọ́ iwájú fún Jésù. Ó mọ̀ pé bóun bá jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀, ó máa jẹ́ kí aráyé gbà pé Bàbá òun lọba aláṣẹ láyé àti lọ́run, ó sì máa jẹ́ kóun lè ra aráyé padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Jésù tún mọ̀ pé òun máa ṣàkóso bí Ọba àti pé òun ni òun máa jẹ́ Àlùfáà Àgbà tó máa ṣàlékún ìbùkún táwọn èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn máa ní. (Mátíù 20:28; Hébérù 7:23-26) Bí Jésù ṣe ń wo ohun tó ń dúró dè é àti ìrètí tó ní, ayọ̀ rẹ̀ kún àkúnwọ́sílẹ̀, ayọ̀ yẹn ló sì wá ràn án lọ́wọ́ láti lo ìfaradà.

19. Bí ìdánwò ìgbàgbọ́ bá dojú kọ wá, báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìrètí, ayọ̀ àti ìfaradà ṣiṣẹ́ pa pọ̀?

19 Bíi ti Jésù, àwa náà gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrètí, ayọ̀ àti ìfaradà ṣiṣẹ́ pa pọ̀ fún wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí. Ẹ máa ní ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú.” (Róòmù 12:12) Àbí ìwọ náà ń dojú kọ ìdánwò ìgbàgbọ́ tó le gan-an lọ́wọ́ báyìí? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ọjọ́ iwájú ni kó o máa wò. Má gbàgbé láé pé bó o bá fara dà á, ìyìn nìyẹn máa mú bá orúkọ Jèhófà. Pọkàn pọ̀ sórí ohun ṣíṣeyebíye tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa. Máa wo ara rẹ bí ẹni tó wà nínú ayé tuntun Ọlọ́run tó ń bọ̀, kó o sì máa fọkàn yàwòrán àwọn ìbùkún tí wàá rí nínú Párádísè. Bó o bá ń retí àwọn nǹkan mèremère tí Jèhófà ṣèlérí pé òun á ṣe—bẹ̀rẹ̀ látorí bí gbogbo ayé ṣe máa mọ̀ pé òun ni ọba láyé àtọ̀run, bí ìwà burúkú ṣe máa dàwátì láyé àti bí àìsàn àti ikú á ṣe ròkun ìgbàgbé—á mú kí ayọ̀ kúnnú ọkàn rẹ, ayọ̀ yẹn ló sì máa jẹ́ kó o lè fara da àdánwò èyíkéyìí tó lè bá ọ. Bá a bá fi ìnira tó wà nínú ètò àwọn nǹkan yìí wé bí Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí ṣe máa rí, a óò rí i pé ìyà yòówù ká jẹ nínú ayé yìí, “fún ìgbà díẹ̀” ni àti pé “ó sì fúyẹ́,” ìyẹn ni pé ó mọ níwọ̀n.—2 Kọ́ríńtì 4:17.

“Ẹ Tẹ̀ Lé Àwọn Ìṣísẹ̀ Rẹ̀ Pẹ́kípẹ́kí”

20, 21. Bó bá dọ̀rọ̀ ìfaradà, kí ni Jèhófà ń retí lọ́dọ̀ wa, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?

20 Jésù mọ̀ pé ẹni tó bá fẹ́ máa tọ òun lẹ́yìn ò ní ṣàìní ìwọ̀n ìnira tó máa béèrè pé kéèyàn ní ìfaradà. (Jòhánù 15:20) Ó múra tán láti ṣíwájú, torí ó mọ̀ pé àpẹẹrẹ òun á fún àwọn ẹlòmíì lókun. (Jòhánù 16:33) Òótọ́ ni pé Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ lórí ọ̀ràn ìfaradà, ṣùgbọ́n àwa kì í ṣe ẹni pípe. Kí ni Jèhófà ń retí lọ́dọ̀ wa? Pétérù ṣàlàyé pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Nínú ọ̀nà tí Jésù gbà kojú àdánwò, ó fi “àwòkọ́ṣe” tá a ní láti máa tẹ̀ lé lélẹ̀. a Àpẹẹrẹ ìfaradà tó fi lélẹ̀ dà bí “ìṣísẹ̀” tàbí ipa ẹsẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè tọ àwọn ìṣísẹ̀ yẹn lọ́nà tó pé pérépéré, ṣùgbọ́n a lè tẹ̀ lé e “pẹ́kípẹ́kí.”

21 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa sa gbogbo agbára wa láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé bá a bá ṣe ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí tó, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe gbára dì tó láti lè fara dà á “dé òpin,” èyí tó lè jẹ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí tàbí òpin ìgbésí ayé wa nísinsìnyí. Bá ò tiẹ̀ mọ èyí tó máa ṣíwájú, a ṣì mọ ohun kan dájú pé: Títí ayé àìnípẹ̀kun, Jèhófà ò ní ṣàìsan wá lẹ́san ìfaradà wa.—Mátíù 24:13.

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àwòkọ́ṣe” túmọ̀ sí “ṣíṣe àdàkọ.” Àpọ́sítélì Pétérù nìkan ni òǹkọ̀wé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó lo ọ̀rọ̀ yìí, èyí tí wọ́n sọ pé ó túmọ̀ sí “àwòrán tí ọmọdé kan ń wò yà sínú ìwé rẹ̀, àwòkọ tí ọmọdé kan ní láti wò kọ gẹ́lẹ́ bó bá ṣe lè ṣe é tó.”