ÌSỌ̀RÍ 2
“Ó Ń Kọ́ni . . . Ó Sì Ń Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Náà”
Iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà. Iṣẹ́ ìyanu. Iṣẹ́ ìwòsàn. Gbogbo iṣẹ́ yìí ni Jésù ṣe, ó tiẹ̀ tún ṣe àwọn míì. Síbẹ̀ àwọn èèyàn ò fi ìkankan lára àwọn orúkọ iṣẹ́ tó ṣe wọ̀nyí pè é. Olùkọ́ ni wọ́n ń pè é. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, iṣẹ́ tó yàn ní ìgbésí ayé ẹ̀ nìyẹn, gbogbo ìgbà ló “ń kọ́ni . . . ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 4:23) Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Jésù, iṣẹ́ yìí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe. Nínú apá yìí, a óò kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa ṣe é.