Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 12

“Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”

“Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”

1-3. (a) Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó bá a rìnrìn àjò ní, báwo ni Jésù sì ṣe mú kó rọrùn fún wọn láti máa rántí ohun tó kọ́ wọn? (b) Kí nìdí tó fi máa ń rọrùn láti rántí àwọn àpèjúwe tó múná dóko?

 ÀǸFÀÀNÍ àrà ọ̀tọ̀ gbáà làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n ń bá a rìnrìn àjò káàkiri ní. Ọ̀dọ̀ Olùkọ́ Ńlá náà fúnra rẹ̀ ni wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ tààràtà. Etí ara wọn ni wọ́n fi ń gbọ́ bó ṣe ń ṣe àwọn àlàyé ìtúmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti bó ṣe ń kọ́ wọn láwọn òtítọ́ tó fa kíki. Títí dìgbà tó fi máa ṣeé ṣe láti kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sínú ìwé, ṣe ni wọ́n ní láti jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wọn wà nínú ọpọlọ wọn àti ọkàn wọn digbí. a Àmọ́ o, Jésù jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti máa rántí ohun tó ń kọ́ wọn. Báwo ló ṣe ṣe é? Ọ̀nà tó ń gbà kọ́ wọn ni kì í jẹ́ kí wọ́n gbàgbé, pàápàá bó ṣe máa ń lo àpèjúwe.

2 Ká sòótọ́, a kì í tètè gbàgbé àpèjúwe tó bá múná dóko. Òǹkọ̀wé kan sọ pé “àpèjúwe máa ń mú kí ohun téèyàn fetí gbọ́ dà bí èyí téèyàn fojú rí,” ó sì máa ń jẹ́ káwọn tó ń gbọ́rọ̀ “fọkàn yàwòrán ohun tí wọ́n ń gbọ́.” Àpèjúwe lè jẹ́ káwọn kókó téèyàn ń kọ́ tètè yéni nítorí pé àwọn ohun téèyàn bá fọkàn yàwòrán tètè máa ń jẹ́ kí nǹkan tètè yéni. Àpèjúwe máa ń jẹ́ kí òye ọ̀rọ̀ yéni sí i, ó sì ń jẹ́ káwọn ẹ̀kọ́ téèyàn kọ́ dúró síni lọ́pọlọ.

3 Kò sí olùkọ́ náà láyé yìí tó tíì mọ àpèjúwe bíi Jésù Kristi. Títí dòní olónìí, tìrọ̀rùntìrọ̀rùn làwọn èèyàn máa ń rántí àpèjúwe rẹ̀. Kí nìdí tí Jésù fi sábà máa ń lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí? Kí ló jẹ́ káwọn àpèjúwe rẹ̀ múná dóko tó bẹ́ẹ̀? Báwo la ṣe lè mọ bá a ṣe lè máa lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yẹn?

Ìdí Tí Jésù Fi Máa Ń Fi Àpèjúwe Kọ́ni

4, 5. Kí nìdí tí Jésù fi máa ń lo àpèjúwe?

4 Bíbélì sọ ìdí pàtàkì méjì tí Jésù fi máa ń lo àpèjúwe. Àkọ́kọ́, lílò tó ń lo àpèjúwe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Ní Mátíù 13:34, 35, a kà pé: “Jésù fi àwọn àpèjúwe sọ [ọ̀rọ̀] fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe; kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì náà bàa lè ṣẹ, ẹni tí ó wí pé: ‘Ṣe ni èmi yóò la ẹnu mi pẹ̀lú àwọn àpèjúwe.’” Ẹni tó kọ Sáàmù 78:2 ni wòlíì tí Mátíù ń sọ yẹn o. Ọlọ́run ló mí sí onísáàmù yẹn láti kọ ohun tó kọ yẹn sílẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kí wọ́n tó bí Jésù. Ìwọ wo ohun tíyẹn túmọ̀ sí. Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú, Jèhófà ti pinnu pé àpèjúwe ni Mèsáyà á máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ó dájú nígbà náà pé Jèhófà fẹ́ràn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí gan-an ni.

5 Èkejì, Jésù ṣàlàyé pé òun lo àpèjúwe láti ya àwọn tí ọkàn wọn ti “sébọ́” sọ́tọ̀. (Mátíù 13:10-15; Aísáyà 6:9, 10) Báwo ni àpèjúwe rẹ̀ ṣe máa fi ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn hàn? Láwọn ìgbà míì, ó máa ń fẹ́ káwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ béèrè ìtumọ̀ àpèjúwe náà, kí wọ́n bàa lè lóye rẹ̀ dáadáa. Àwọn tó nírẹ̀lẹ̀ nìkan ló máa ń béèrè, àwọn tó gbéra ga kì í béèrè. (Mátíù 13:36; Máàkù 4:34) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn àpèjúwe Jésù máa ń fi òtítọ́ han àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa; àwọn àpèjúwe rẹ̀ sì tún máa ń fi òtítọ́ pa mọ́ fáwọn tí ọkàn wọn gbéra ga.

6. Àwọn nǹkan tó ṣàǹfààní wo ni àpèjúwe Jésù wà fún?

6 Àpèjúwe tí Jésù lò ṣíṣẹ fáwọn nǹkan míì tó ṣàǹfààní. Ó máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ fa àwọn èèyàn mọ́ra, débi pé wọ́n á fẹ́ gbọ́ ni ṣáá. Àwọn àpèjúwe náà máa ń jẹ́ kéèyàn lè fọkàn ya àwòrán tó rọrùn láti lóye. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, àpèjúwe Jésù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìwàásù Lórí Òkè, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Mátíù 5:3 sí 7:27, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀pọ̀ ibi tí Jésù ti lo àpèjúwe tó pọ̀ gan-an. Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan tó kà á ṣe sọ, àkànlò èdè tí Jésù lò nínú Ìwàásù Lórí Òkè lé ní àádọ́ta. Kí ohun tí wọ́n sọ yẹn bàa lè yé wa dáadáa, fi sọ́kàn pé, èèyàn lè ka ìwàásù náà tán láàárín nǹkan bí ogún ìṣẹ́jú. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé láàárín bíi ìṣẹ́jú kan ṣoṣo, Jésù á lo àkànlò èdè mẹ́ta! Ó ṣe kedere pé Jésù mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa lo àpèjúwe!

7. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe ń lo àpèjúwe?

7 Gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi, a fẹ́ máa tẹ̀ lé ọ̀nà tó gbà ń kọ́ni, títí kan bó ṣe ń lo àpèjúwe. Bí èròjà ṣe máa ń sọ oúnjẹ di àjẹpọ́nnulá, bẹ́ẹ̀ náà ni àpèjúwe ṣe lè mú kí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àwọn èèyàn máa dùn-ún gbọ́ létí wọn. Àpèjúwe tá a fara balẹ̀ gbé kalẹ̀ tún lè mú káwọn èèyàn tètè lóye àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì. Ẹ jẹ́ ká wá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó mú kí àpèjúwe Jésù múná dóko bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà la máa tó lè mọ bá a ṣe lè lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye yìí bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Àfiwé Tó Máa Ń Tètè Yéni Ló Máa Ń Lò

Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi àwọn ẹyẹ àtàwọn òdòdó ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó wa?

8, 9. Báwo ni Jésù ṣe lo àwọn àfiwé tí kò lọ́jú pọ̀, kí ló sì mú káwọn àfiwé náà múná dóko?

8 Nígbà tí Jésù bá ń kọ́ni, ó sábà máa ń lo àfiwé tí kò lọ́jú pọ̀, tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mélòó kan ló kàn fi máa ń sọ ọ́. Síbẹ̀ àwọn àlàyé tí kò lọ́jú pọ̀ yẹn náà máa ń yàwòrán ọ̀rọ̀ séèyàn lọ́kàn, ó sì máa ń jẹ́ ká lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì ibẹ̀, irú bí òtítọ́ nípa Ọlọ́run, àwọn ìlànà rẹ̀ àtohun tó fẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má máa ṣàníyàn nípa ohun tí wọ́n nílò fún ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́, ó tọ́ka sáwọn “ẹyẹ ojú ọ̀run” àti “àwọn òdòdó lílì pápá.” Àwọn ẹyẹ kì í fún irúgbìn tàbí kí wọ́n ká irúgbìn, bẹ́ẹ̀ sì làwọn òdòdó lílì pápá kì í ṣe làálàá tàbí kí wọ́n rànwú. Síbẹ̀ Ọlọ́run ń bójú tó wọn. Ẹ̀kọ́ tó fẹ́ kọ́ wọn ṣe kedere, ìyẹn ni pé, bí Ọlọ́run bá lè bójú tó àwọn ẹyẹ àtàwọn òdòdó, ó dájú pé ó máa bójú tó àwọn èèyàn tí wọ́n ń wá “Ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.”—Mátíù 6:26, 28-33.

9 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù tún máa ń lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́, èyí tó jẹ́ ọ̀nà míì tó lágbára láti fi nǹkan méjì wéra. Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ máa ń mú kí nǹkan kan rí bí òmíì. Nígbà tó sì tún ń lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń sọ yìí, ó rí i pé kò lọ́jú pọ̀. Ìgbà kan wà tó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Kò sí bọ́rọ̀ yẹn ò ṣe ní yé wọn kedere, pé ńṣe ni Jésù ń fi yé wọn pé wọ́n lè jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàn kí wọ́n sì ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti fògo fún Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti nípa ìwà wọn. (Mátíù 5:14-16) Tún kíyè sí àwọn àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ míì tí Jésù lò: “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ilẹ̀ ayé” àti “Èmi ni àjàrà náà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka.” (Mátíù 5:13; Jòhánù 15:5) Pẹ̀lú bí àwọn àkànlò èdè yẹn ṣe rọrùn láti lóye tó, ẹ̀kọ́ ńlá ki sínú wọn.

10. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ wo ló fi bó o ṣe lè lo àpèjúwe nígbà tó o bá ń kọ́ni hàn?

10 Báwo lo ṣe lè lo àpèjúwe nígbà tó o bá ń kọ́ni? Kò dìgbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ ìtàn tó gùn lọ jàn-ànrànjan-anran. Ṣáà kàn ronú àfiwé kan tó ṣe ṣókí. Ká gbà pé ọ̀rọ̀ nípa àjíǹde lò ń jíròrò, tó o sì fẹ́ lo àpèjúwe kan tó máa fi hàn pé àtijí àwọn òkú dìde kì í ṣe ohun tó le rárá fún Jèhófà. Àfiwé wo lo máa lò? Bíbélì fi oorun wé ikú. O lè sọ pé “Ọlọ́run lè jí òkú dìde wẹ́rẹ́ bí ìgbà tá a jí ẹni tó sùn dìde.” (Jòhánù 11:11-14) Ká wá sọ pé o fẹ́ ṣe àpèjúwe kan nípa báwọn ọmọdé ṣe nílò ìfẹ́ àti ìtọ́jú kí wọ́n tó lè gbádùn ìgbà èwe wọn, àpẹẹrẹ wo lo máa lò? Àwọn àfiwé kan tí Bíbélì lò rèé: Àwọn ọmọdé rí “bí àwọn àgélọ́ [àṣẹ̀ṣẹ̀yọ] igi ólífì.” (Sáàmù 128:3) O lè sọ pé, “Bí igi ṣe nílò omi àti oòrùn bẹ́ẹ̀ náà ni ọmọdé ṣe nílò ìfẹ́ àti àbójútó tó péye.” Bí àfiwé rẹ bá ṣe rọrùn láti lóye tó ló ṣe máa rọrùn tó fáwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti lóye ohun tó ò ń sọ.

Ohun Táwọn Èèyàn Ń Rí Lójoojúmọ́ Ló Máa Ń Fi Ṣe Àpèjúwe

11. Mẹ́nu ba àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn dájú pé àwọn nǹkan tí Jésù rí nígbà tó wà lọ́mọdé ní Gálílì ló fi ṣe àpèjúwe.

11 Ọ̀gá ni Jésù tó bá dọ̀rọ̀ lílo àpèjúwe tó jẹ mọ́ ìgbésí ayé àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ àwọn àpèjúwe rẹ̀ ló tan mọ́ ohun tó kíyè sí nígbà tó ń dàgbà ní Gálílì nípa báwọn èèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé wọn. Ìwọ ronú fúngbà díẹ̀ ná nípa ìgbà ọmọdé rẹ̀. Àìmọye ìgbà ló ti máa rí ìyá rẹ̀ nígbà tó ń lọ ọkà kó lè di ìyẹ̀fun, tó ń fi ìwúkàrà po àpòrọ́, tó ń tanná sí àtùpà tàbí tó ń gbálẹ̀ ilé. (Mátíù 13:33; 24:41; Lúùkù 15:8) Ta ló lè kaye ìgbà tó ti máa rí àwọn apẹja tí wọ́n ń ju àwọ̀n sínú Òkun Gálílì? (Mátíù 13:47) Ẹ̀ẹ̀melòó láá ti ráwọn ọmọdé tí wọ́n ṣeré lọ sáàárín ọjà. (Mátíù 11:16) Ó dájú pé gbogbo àwọn nǹkan míì tí Jésù fi ṣe àpèjúwe ló ti rí rí. Lára wọn làwọn nǹkan bí èso tó ń hù, àsè ìgbéyàwó tó ń dùn yùngbà àti oko ọkà tó ti funfun nínú oòrùn fún kíkórè.—Mátíù 13:3-8; 25:1-12; Máàkù 4:26-29.

12, 13. Nínú àpèjúwe aláàánú ará Samáríà, kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé Jésù lo ọ̀nà tó gba “Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò” kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bàa lè yé wọn?

12 Nínú àwọn àpèjúwe rẹ̀, Jésù máa ń mẹ́nu ba kúlẹ̀kúlẹ̀ kan táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ̀ dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe aláàánú ará Samáríà ni pé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà, àwọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ, tí wọ́n sì lù ú, . . . ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán.” (Lúùkù 10:30) Ó yẹ ká kíyè sí i pé ọ̀nà “láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò” ni Jésù fi ṣe àpèjúwe náà. Nígbà tó sì ń sọ àpèjúwe yìí, Jùdíà ló wà, èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Jerúsálẹ́mù; nípa bẹ́ẹ̀ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ mọ ọ̀nà yẹn lámọ̀dunjú. Wọ́n mọ̀ pé ọ̀nà náà léwu, àgàgà fẹ́ni tó ń dá rìnrìn àjò. Ọ̀nà náà rí kọ́lọkọ̀lọ ó sì máa ń dá páropáro, èyí ló jẹ́ káwọn ọlọ́ṣà lè máa fara pa mọ́ síbẹ̀.

13 Jésù tún sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì nípa ọ̀nà tó gba “Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò” yìí. Gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe yẹn ṣe lọ, àlùfáà ló kọ́kọ́ gba ọ̀nà yẹn kọjá, lẹ́yìn náà ni ọmọ Léfì kan tún kọjá níbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìkankan lára àwọn méjèèjì tó dúró ṣaájò ọ̀gbẹ́ni náà. (Lúùkù 10:31, 32) Inú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù làwọn àlùfáà ti ń sìn, àwọn ọmọ Léfì sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì ni wọ́n máa ń lọ sun Jẹ́ríkò bí wọ́n ò bá sí lẹ́nu iṣẹ́ ní tẹ́ńpìlì; ó ṣe tán, kìlómítà mẹ́tàlélógún [ìyẹn bí ibùsọ̀ mẹ́rìnlá] ni Jẹ́ríkò sí Jerúsálẹ́mù. Ìdí rèé tí wọ́n fi máa ń gba ọ̀nà yẹn kọjá. Tún kíyè sí i pé Jésù sọ pé ọ̀gbẹ́ni náà ń “sọ̀ kalẹ̀,” kò sọ pé ó ń gòkè “láti Jerúsálẹ́mù.” Ọ̀rọ̀ yìí yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ dáadáa. Gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ nísàlẹ̀ ni Jẹ́ríkò wà sí Jerúsálẹ́mù. Nítorí náà, béèyàn bá ń rìnrìn àjò “láti Jerúsálẹ́mù,” ẹni náà ní láti “sọ̀ kalẹ̀” ni. b Ó hàn gbangba pé Jésù fi àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sọ́kàn.

14. Nígbà tá a bá fẹ́ lo àpèjúwe, báwo la ṣe lè fi àwọn olùgbọ́ wa sọ́kàn?

14 Báwa náà bá ń lo àpèjúwe, a ní láti máa fi àwọn olùgbọ́ wa sọ́kàn. Kí làwọn nǹkan díẹ̀ tó yẹ ká fi sọ́kàn nípa àwọn olùgbọ́ wa tó lè mú ká pinnu irú àpèjúwe tá a máa lò? A lè kíyè sí àwọn nǹkan bí ọjọ́ orí wọn, àṣà ìbílẹ̀ wọn tàbí ìdílé tí wọ́n ti wá àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àpèjúwe tó bá sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀ á dáa fáwọn tó wà níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ ju fún àwọn tó wà láàárín ìlú ńlá lọ. Báwọn olùgbọ́ wa ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn àti ohun tí wọ́n ń ṣe lójoojúmọ́ tún lè ṣeé lò láti fi gbé àpèjúwe tó máa bá wọn mu kalẹ̀. Lára irú rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ wọn, ilé wọn, eré ọwọ́dilẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe àti oúnjẹ wọn.

Ó Máa Ń Fi Ìṣẹ̀dá Ṣe Àpèjúwe

15. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá?

15 Ọ̀pọ̀ àwọn àpèjúwe Jésù ló fi hàn pé ó ní ìmọ̀ nípa ìṣẹ̀dá, ìyẹn àwọn nǹkan bí ewéko, ẹranko àti ojú ọjọ́. (Mátíù 16:2, 3; Lúùkù 12:24, 27) Ibo ló ti rí irú ìmọ̀ yẹn? Nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà ní Gálílì, ó dájú pé ó láǹfààní tó pọ̀ láti mọ̀ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jésù ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” òun sì ni “àgbà òṣìṣẹ́” tí Jèhófà lò láti dá ohun gbogbo. (Kólósè 1:15, 16; Òwe 8:30, 31) Ǹjẹ́ ó wá yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá? Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe fọgbọ́n lo ìmọ̀ tó ní yẹn.

16, 17. (a) Kí ló fi hàn pé Jésù mọ ìṣe àwọn àgùntàn dáadáa? (b) Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé lóòótọ́ làwọn àgùntàn máa ń fetí sí ohùn olùṣọ́ wọn?

16 Rántí pé Jésù pera rẹ̀ ní “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” ó sì pe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní “àgùntàn.” Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn pé ó mọ ìṣe àwọn àgùntàn tó jẹ́ ẹran agbéléjẹ̀ dáadáa. Ó mọ̀ pé ìdè ìfẹ́ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wà láàárín olùṣọ́ àgùntàn àti àgùntàn. Ó kíyè sí i pé àwọn ẹranko tó gbẹ́kẹ̀ lé olùṣọ́ wọn yìí máa ń fira wọn sílẹ̀ fún olùṣọ́ àgùntàn láti darí wọn àti pé ibikíbi tí olùṣọ́ àgùntàn bá darí wọn sí ni wọ́n máa ń lọ. Kí nìdí táwọn àgùntàn fi máa ń tẹ̀ lé olùṣọ́ wọn? Jésù sọ pé “nítorí pé wọ́n mọ ohùn rẹ̀.” (Jòhánù 10:2-4, 11) Ṣé lóòótọ́ làwọn àgùntàn mọ ohùn olùṣọ́ wọn?

17 Ọ̀gbẹ́ni George A. Smith kọ ohun tó fojú ara rẹ̀ rí sínú ìwé kan tó pè ní Historical Geography of the Holy Land, ó sọ pé: “Nígbà míì, ẹ̀gbẹ́ ọ̀kan lára àwọn kànga tó wà nílẹ̀ Jùdíà la ti máa ń sinmi ọ̀sán. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn bíi mẹ́ta tàbí mẹ́rin máa ń kó agbo àgùntàn wọn wá síbẹ̀. Gbogbo àwọn àgùntàn náà á dà pọ̀ mọ́ra wọn, a sì máa ń rò ó pé báwo ni darandaran kọ̀ọ̀kan á ṣe dá àgùntàn tiẹ̀ mọ̀. Àmọ́ táwọn àgùntàn náà bá ti mu omi tán, tí wọ́n sì ti ṣeré tán, darandaran kọ̀ọ̀kan á gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nínú àfonífojì náà. Kálukú wọ́n á wá máa pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ bó ṣe máa ń pè wọ́n. Àwọn àgùntàn darandaran kọ̀ọ̀kan á sì máa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n á tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe tò wá sídìí omi tẹ́lẹ̀.” Kò jọ pé àpèjúwe mìíràn wà tó tún dáa ju èyí tí Jésù lò yìí láti fa kókó tó fẹ́ mú jáde yọ. Ìyẹn ni pé tá a bá gba àwọn ohun tó ń kọ́ wa tá a sì fi wọ́n sílò, tá a tún jẹ́ kó máa darí wa, nígbà náà, a lè sọ pé a wà lábẹ́ àbójútó “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” náà.

18. Ibo la ti lè rí àlàyé nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá?

18 Báwo la ṣe lè mọ ọ̀nà tá a lè gbà máa fi àwọn ohun tí Jèhófà dá ṣe àpèjúwe? Ànímọ́ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ táwọn ẹranko ní lè ṣèrànwọ́ láti mọ àfiwé tó máa ṣe ṣókí táá sì múná dóko. Ibo la ti lè rí àlàyé nípa àwọn ẹ̀dá Jèhófà? Àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa onírúurú àwọn ẹranko wà nínú Bíbélì, láwọn ìgbà míì sì rèé, Bíbélì fúnra rẹ̀ máa ń fi ìwà àwọn ẹranko kan ṣe àfiwé. Bí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nǹkan tó yára, ó sábàá máa ń fi wé àgbàlàǹgbó àti àmọ̀tẹ́kùn, tó bá ń sọ nípa jíjẹ́ oníṣọ̀ọ́ra, ó máa ń lo ejò, ó sì fi jíjẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ wé àdàbà. c (1 Kíróníkà 12:8; Hábákúkù 1:8; Mátíù 10:16) Àwọn àlàyé mìíràn tó wúlò wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àtàwọn ìtẹ̀jáde míì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. O lè rí nǹkan púpọ̀ kọ́ tó o bá kíyè sí báwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ṣe fi àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà dá ṣe àfiwé tó rọrùn láti lóye.

Ó Máa Ń Lo Àpẹẹrẹ Ohun Táwọn Èèyàn Mọ̀

19, 20. (a) Báwo ni Jésù ṣe lo ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà yẹn láti járọ́ ẹ̀kọ́ èké? (b) Báwo la ṣe lè lo àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ayé àtàwọn ìrírí nígbà tá a bá ń kọ́ni?

19 Ó lè jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ayé lèèyàn máà fi ṣe àpèjúwe tó múná dóko. Lákòókò kan, Jésù lo ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà yẹn láti fi hàn pé irọ́ ni èrò táwọn èèyàn ń ní pé àwọn ẹni búburú nìkan ni ibi máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Ó sọ pé: “Àwọn méjìdínlógún wọnnì tí ilé gogoro tí ń bẹ ní Sílóámù wó lé lórí, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n, ṣé ẹ lérò pé a fi wọ́n hàn ní ajigbèsè [ẹlẹ́ṣẹ̀] ju gbogbo ènìyàn mìíràn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù lọ ni?” (Lúùkù 13:4) Kì í ṣe pé àwọn méjìdínlógún yìí ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ kan tó mú kí wọ́n rí ìbínú Ọlọ́run ló jẹ́ kí wọ́n kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ló fa jàǹbá tó pa wọ́n lójijì. (Oníwàásù 9:11) Jésù tipa báyìí lo ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ̀ dáadáa láti fi já ẹ̀kọ́ èké kan ní koro.

20 Báwo la ṣe lè lo ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ayé àtàwọn ìrírí nígbà tá a bá ń kọ́ni? Ká sọ pé bí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ ṣe nímùúṣẹ lò ń jíròrò. (Mátíù 24:3-14) O lè mẹ́nu ba ìròyìn kan tó ń jà ràn-ìn nílẹ̀ nípa ogun, ìyàn tàbí ìmìtìtì ilẹ̀ láti fi hàn pé onírúurú apá tí àmì yẹn ní ló ti ń ṣẹ. Tàbí kẹ̀, ká sọ pé ìrírí lo fẹ́ lò láti fi ṣàpèjúwe àyípadà tó máa wáyé béèyàn bá gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. (Éfésù 4:20-24) Ibo lo ti lè rí irú ìrírí bẹ́ẹ̀? O lè ronú nípa onírúurú ipò táwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ wà tẹ́lẹ̀ tàbí kó o tiẹ̀ mú lára àwọn ìrírí tá a tẹ̀ sínú ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

21. Èrè wo ló wà nínú kéèyàn jẹ́ olùkọ́ tó mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kọ́ni dáadáa?

21 Kò sí àní-àní, Àgbà Olùkọ́ ni Jésù! Iṣẹ́ ìgbésí ayé ló fi iṣẹ́ ìwàásù ṣe gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ìsọ̀rí yìí tá a pè ní “ó ń kọ́ni . . . ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 4:23) Iṣẹ́ ìgbésí ayé tiwa náà ni. Èrè tó wà nínú kéèyàn jẹ́ olùkọ́ tó mọṣẹ́ níṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ńṣe là ń fúnni, irú fífúnni bẹ́ẹ̀ ló sì máa ń fún èèyàn láyọ̀. (Ìṣe 20:35) Ayọ̀ yẹn ni bí inú wa á ṣe máa dùn pé a ti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn òtítọ́ nípa Jèhófà tá à ń kọ́ wọn. A óò tún ní ìbàlẹ̀ ọkàn nítorí mímọ̀ tá a mọ̀ pé àpẹẹrẹ Jésù tó jẹ́ Olùkọ́ tí kò sírú rẹ̀ láyé ńbí là ń tẹ̀ lé.

a Ẹ̀rí wà pé ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn tí Jésù kú ni wọ́n tó ṣe àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere Mátíù, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára àwọn àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí nípa ohun tí Jésù gbélé ayé ṣe.

b Jésù tún sọ pé àlùfáà àti ọmọ Léfì ń bọ̀ “láti Jerúsálẹ́mù,” èyí tó túmọ̀ sí pé wọ́n ti kúrò ní tẹ́ńpìlì. Nítorí náà, kò sí àwíjàre kankan fún bí wọn ò ṣe ran ẹni tó ń kú lọ yẹn lọ́wọ́. Wọn ò lè sọ pé torí bó ṣe dà bí ẹni pé ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà ti kú ni ò jẹ́ káwọn ṣaájò rẹ̀, nítorí pé táwọn bá fọwọ́ kan òkú, kò ní jẹ́ káwọn lè ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì fún ìwọ̀n àkókò kan.—Léfítíkù 21:1; Númérì 19:16.

c Fún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ibi tí Bíbélì ti fi ìṣe àwọn ẹranko ṣe àpèjúwe, wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 268 àti 270 sí 271 tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.