Ọ̀rọ̀ Iṣáájú
Òǹkàwé Wa Ọ̀wọ́n:
“Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” (Mátíù 4:19) Gbogbo wa ni Jésù ń pè pé ká máa tẹ̀ lé òun. Ǹjẹ́ ò ń jẹ́ ìpè yìí? Bó o bá lè tẹ̀ lé Jésù, kékeré kọ́ ni oore tó máa ṣe ọ́ nígbèésí ayé rẹ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ìdí ni pé Jèhófà rán ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sáyé kó bàa lè fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe pàṣípààrọ̀ fún wa. (Jòhánù 3:16) Yàtọ̀ sí pé ó kú nítorí wa, Ọmọ yẹn jẹ́ ká mọ béèyàn ṣe ń gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀. Nínú gbogbo ohun tó ṣe, ó jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ ó sì múnú Bàbá rẹ̀ dùn. Jésù tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè dà bíi Bàbá rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ àti àwọn ohun tó gbé ṣe fi àwọn ọ̀nà Bàbá rẹ̀ hàn ó sì tún jẹ́ ká mọ ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́.—Jòhánù 14:9.
Bíbélì sọ fún wa pé “àwòkọ́ṣe” ni Jésù jẹ́ “fún [wa ká] lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Bá a bá fẹ́ sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí, tá a fẹ́ káyé wa nítumọ̀, tá a sì fẹ́ wà lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, àfi ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi.
Láti lè ṣe ohun tá a sọ yìí, ó pọn dandan pé ká mọ bí Jésù ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀. Nítorí ìdí yìí, ó ṣe pàtàkì pé ká fara balẹ̀ kọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù. Bá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jésù sọ, àtàwọn ohun tó ṣe tá a sì ronú lórí bá a ṣe lè fara wé e nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti rí bá a ṣe lè tẹ̀ lé e dáadáa.
Ǹjẹ́ kí ìwé yìí ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù àti Jèhófà. Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ yẹn sì mú kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí kó o bàa lè máa múnú Jèhófà dùn nísinsìnyí àti títí láé.
Àwa Òǹṣèwé