Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ohun Tó Lè Fi Wá Lọ́kàn Balẹ̀ Lọ́dún 2024—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ọ̀pọ̀ ló gbà pé kò lè sí ojútùú sáwọn ìṣòro táwọn èèyàn máa ní kárí ayé lọ́dún 2024. Síbẹ̀, a mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
Bíbélì sọ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa yanjú gbogbo ìṣòro tí aráyé rò pé kò lè lójútùú láé tó sì ń kó wọn lọ́kàn sókè. Láìpẹ́, Ọlọ́run “máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú [wa], ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìfihàn 21:4.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sì i nípa ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, ka àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa.”
Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lónìí
Àwọn ohun rere tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lè jẹ́ ká nírètí, kó sì tún dá wa lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Róòmù 15:13) Àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì máa jẹ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro wa, irú bí ipò òṣì, ìwà ìrẹ́jẹ, àti àìsàn.
Kó o lè mọ bí Bíbélì ṣe ran ọkùnrin kan lọ́wọ́ kó lè láyọ̀, kọ́kàn ẹ̀ sì balẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé tálákà ni, Wo fídíò náà Juan Pablo Zermeño: Jèhófà Ti Jẹ́ Káyé Mi Nítumọ̀.
Tó o bá fẹ́ mọ bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ń dá ara ẹ lẹ́bi torí ohun kan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, tínú ẹ ò dùn, tọ́kàn ẹ ò balẹ̀, tàbí tí èèyàn ẹ kan kú. Ka àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Mo Lè Rí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Máa Tù Mí Nínú Bíbélì?”
Wo bí obìnrin ológun kan tó sọ pé “mo burú léèyàn mi ò sì rí tẹni kẹ́ni rò” ṣe ní ìrètí látinú Bíbélì. Wo fídíò náà Mi Ò Gbé Ìbọn Mọ́
Ṣe ohun to máa ṣe ìwọ àti ìdílé rẹ làǹfààní lọ́dún 2024. Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ bó o ṣe lè ṣe é. O lè ní kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Wàá ri bí Ọlọ́run ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní “èrò àlàáfíà” ní báyìí, kó o sì ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.”—Jeremáyà 29:11.