Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Photo by Zhai Yujia/China News Service/VCG via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Omíyalé Ṣe Ń Ba Ọ̀pọ̀ Nǹkan Jẹ́ Kárí Ayé?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Omíyalé Ṣe Ń Ba Ọ̀pọ̀ Nǹkan Jẹ́ Kárí Ayé?

 Ìṣòro omíyalé ń fojú ọ̀pọ̀ èèyàn rí màbo kárí ayé. Ẹ kíyè sí àwọn ìròyìn yìí:

  •   “Òjò tó ń rọ̀ ní olú ìlú Ṣáínà lásìkò yìí kúrò ní kèrémí. Kódà, irú ẹ̀ ò rọ̀ rí láti nǹkan bí ogóje (140) ọdún sẹ́yìn. Ọwọ́ òjò yìí tún wá le gan-an láti ọjọ́ Saturday sí Wednesday.”​—AP News, August 2, 2023.

  •   “Ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Khanun mú kí òjò àrọ̀rọ̀ọ̀dá bẹ̀rẹ̀ ní gúúsù orílẹ̀-èdè Japan. Nígbà tó fi máa dọjọ́ kejì ìyẹn ọjọ́ Thursday, ìjì yẹn le débi pé èèyàn méjì ló kú. . . . Ó ṣeé ṣe kí ìjì yẹn mú kí òjò tó pọ̀ gan-an ṣì rọ̀ láwọn agbègbè olóke Taiwan.”​—Deutsche Welle, August 3, 2023.

  •   “Ó ti lé ní àádọ́ta (50) ọdún tí irú òjò tó rọ̀ láwọn agbègbè etí òkun orílẹ̀-èdè Kánádà ti rọ̀ kẹ́yìn. Òjò yìí mú kí omíyalé ṣẹlẹ̀ ní agbègbè Nova Scotia.”​—BBC News, July 24, 2023.

 Kí ni Bíbélì sọ nípa irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí?

Àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé lásìkò wa yìí, àá máa rí “àwọn ohun tó ń bani lẹ́rù.” (Lúùkù 21:11) Ojú ọjọ́ tó ń burú sí i ti dá kún àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé, àwọn àjálù yìí ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́, ó sì ń burú sí i.

Ohun tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ káwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé lákòókò yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀. Kí nìdí? Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá rí i tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.”​—Lúùkù 21:31; Mátíù 24:3.

 Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó tún ayé yìí ṣe. Gbogbo ohun tó ń fa àjálù, ì báà jẹ́ ìjì, àrọ̀rọ̀ọ̀dá òjò tàbí omíyalé kò ní sí mọ́.​—Jóòbù 36:27, 28; Sáàmù 107:29.

 Tó o bá fẹ́ mọ bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ló Máa Tún Ayé Yìí Ṣe?