Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Sean Gladwell/Moment via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Iye Tí Wọ́n Ti Ná Lórí Nǹkan Ìjà Ogun Kárí Ayé Ti Lé Ní Tírílíọ̀nù Méjì Dọ́là​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Iye Tí Wọ́n Ti Ná Lórí Nǹkan Ìjà Ogun Kárí Ayé Ti Lé Ní Tírílíọ̀nù Méjì Dọ́là​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Ó lé ní tírílíọ̀nù méjì dọ́là tí wọ́n ná lórí nǹkan ìjà ogun kárí ayé lọ́dún 2022 látàrí ogun tó ń jà láàárín ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti Ukraine. Ìròyìn tí àjọ Stockholm International Peace Research Institute (SIPRI) gbé jáde ní April 2023 fi hàn pé, lọ́dún 2022:

  •   Iye tí wọ́n ń ná lórí àwọn nǹkan ìjà ogun “nílẹ̀ Yúróòpù ti fi ìdá mẹ́tàlá nínú ọgọ́rùn-ún lé sí ti tẹ́lẹ̀, èyí ló sì tíì pọ̀ jù lọ nínú owó tí wọ́n ná láàárín ọdún kan ṣoṣo látìgbà tí ìjọba Soviet Union ti kógbá wọlé lọ́dún 1991.”

  •   ‘Owó tí ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń ná lórí àwọn nǹkan ìjà ti lọ sókè gan-an ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, èyí ti mú kó bọ́ sí ipò kẹta láti ìkarùn-ún tó wà tẹ́lẹ̀ lágbo àwọn ilẹ̀ tó ń náwó lórí nǹkan ìjà ogun jù láyé.’

  •   Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń náwó jù lọ láyé lórí nǹkan ìjà ogun, “tá a bá pín gbogbo owó táwọn orílẹ̀-èdè ń ná lórí nǹkan ìjà ogun sí mẹ́wàá, Amẹ́ríkà ló máa fẹ́rẹ̀ẹ́ kó ìdá mẹ́rin nínú ẹ̀.”

 Ọ̀mọ̀wé Nan Tian, tó jẹ́ òǹkọ̀wé kan lára àjọ SIPRI sọ pé: “Bí iye tí wọ́n ń ná sórí àwọn nǹkan ìjà ogun ṣe ń pọ̀ sí i láwọn ọdún àìpẹ́ yìí jẹ́ ká rí i pé ayé yìí ti túbọ̀ léwu ju bá a ṣe rò lọ.”

 Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ńṣe làwọn alágbára ayé á máa figẹ̀wọngẹ̀ lásìkò tá a wà yìí, ó sì jẹ́ ká mọ ọ̀nà kan ṣoṣo tí ayé fi lè ní àlàáfíà.

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun á máa pọ̀ sí i

  •   Bíbélì pe àsìkò wà yìí ní “àkókò òpin.”​—Dáníẹ́lì 8:19.

  •   Ìwé Dáníẹ́lì sọ pé lásìkò náà, àwọn agbára ayé á máa figa gbága. Àwọn agbára ayé yìí á máa ‘kọ lu’ ara wọn tàbí kí wọ́n máa jà lórí ẹni tí àṣẹ rẹ̀ máa múlẹ̀. Lásìkò ìfigagbága yìí, wọ́n máa lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ “ìṣúra,” wọ́n sì máa ná òbítíbitì owó.​—Dáníẹ́lì 11:40, 42, 43.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń mórí ẹni wú yìí, wo fídíò Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣẹ​—Dáníẹ́lì Orí 11.

Bí àlàáfíà ṣe máa dé sáyé

  •   Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìjọba èèyàn. Ó “máa gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé. A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì. Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú, ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé.”​—Dáníẹ́lì 2:44.

  •   Láìpẹ́, Jèhófà a Ọlọ́run máa ṣe ohun tí ìjọba èèyàn ò lè ṣe, ó máa mú kí àlàáfíà àti ààbò wà kárí ayé títí láé. Lọ́nà wo? Ìjọba Rẹ̀ máa palẹ̀ gbogbo nǹkan ìjà mọ́, á sì fòpin sí ogun kárí ayé.​—Sáàmù 46:8, 9.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, ka àpilẹ̀kọ náà “Àlàáfíà Máa Pọ̀ Yanturu Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.