Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Àwọn Èèyàn Ò Fọkàn Tán Àwọn Olóṣèlú Mọ́—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ètò ìdìbò tó máa wáyé kárí ayé lọ́dún 2024 máa pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fọkàn tán àwọn olóṣèlú mọ́.
Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló sọ pé “èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn olóṣèlú ló jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa kówó jẹ ló gbà wọ́n lọ́kàn” kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa ran àwọn ará ìlú lọ́wọ́. a—Pew Research Center, September 19, 2023.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ náà ni ò fọkàn tán àwọn olóṣèlú.
“Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ máa ń ronú nípa bí àwọn ìṣòro tó wà lónìí ṣe máa yanjú, àmọ́ wọn ò gbà pé àwọn olóṣèlú lè yanjú ẹ̀.”—The New York Times, January 29, 2024.
“Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn èèyàn fọkàn tán àwọn tó máa ń gbé fídíò sórí ìkànnì Youtube ju bí wọ́n ṣe fọkàn tán àwọn olóṣèlú lọ.”—The Korea Times, January 22, 2024.
Ṣé a lè fọkàn tán àwọn olóṣèlú pé wọ́n máa mú kí nǹkan dáa sí i? Ta la lè fọkàn tán?
Ṣọ́ra kó o tó fọkàn tán ẹnì kan
Àwọn èèyàn máa ń fara balẹ̀ kíyè sí ẹnì kan dáadáa kí wọ́n tó fọkàn tán an. Ìyẹn sì dáa torí Bíbélì sọ pé “aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”—Òwe 14:15.
Tó ó bá fẹ́ àlàyé nípa bó o ṣe lè mọ̀ bóyá ìsọfúnni kan jóòótọ́ tàbí kì í ṣòótọ́, ka àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Ẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ìsọfúnni Tí Kì Í Ṣòótọ́.”
Yàtọ̀ síyẹn, tó bá tiẹ̀ wu olóṣèlú kan pé kó ṣe ohun tó dáa, ìwọ̀nba ló lè ṣe torí ó níbi tágbára ẹ̀ mọ. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé:
“Má gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè; eniyan ni wọ́n, kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ wọn.”—Sáàmù 146:3, Yoruba Bible.
Aṣáájú tó o lè fọkàn tán
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti yan aṣáájú kan tó kúnjú ìwọ̀n, tó sì ṣeé fọkàn tán. Aṣáájú náà ni Jésù Kristi. (Lúùkù 1:32, 33) Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìjọba kan tó ń ṣàkóso látọ̀run.—Mátíù 6:10.
Tó o bá fẹ́ mọ ìdí tó fi yẹ kó o fọkàn tán Jésù àti bó ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro wa, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run?” àti “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?”
a Pew Research Center, “Americans’ Dismal Views of the Nation’s Politics,” September 2023.