Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkùnrin Tó Ń Ṣàníyàn Lọ́wọ́?
Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó ń ṣàníyàn, a ó ṣeé ṣe kó o máa ronú nípa ẹni tí ẹ̀rù ń bà, tó ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tó jí láàárọ̀ àmọ́ tó ṣòro fún un láti dìde torí ìrònú tó bá a, tàbí ẹni tó máa ń ṣàròyé ṣáá nípa àwọn ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn.
Lóòótọ́, bí àwọn kan ṣe máa ń ṣe nìyẹn tí wọ́n bá ń ṣàníyàn. Àmọ́ àwọn tó ń ṣèwádìí rí i pé ìwà àwọn míì, ní pàtàkì àwọn ọkùnrin, máa ń yàtọ̀ tí wọ́n bá ń ṣàníyàn. Ìwádìí kan fi hàn pé àwọn ọkùnrin “ló ṣeé ṣe kí wọ́n máa fi ọtí àti oògùn tó le pàrònú rẹ́ jù, torí náà ẹnì kan lè máa mu ọtí ṣáá torí pé ìṣòro àníyàn ti wọ̀ ọ́ lára gan-an. Àwọn ọkùnrin tí àníyàn ń dà láàmú sábà máa ń bínú, wọ́n sì máa ń kanra.”
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe gbogbo ọkùnrin ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ láìka bí èèyàn ṣe hùwà tó bá ń ṣàníyàn, ìṣòro yìí túbò ń pọ̀ sí i láwọn ‘àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira’ yìí. (2 Tímótì 3:1) Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá ń ṣàníyàn?
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Borí Àníyàn
Ọ̀pọ̀ ìlànà ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń ṣàníyàn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mẹ́ta.
1. “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Wàhálà ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti tó fún un.”—Mátíù 6:34.
Ó túmọ̀ sí pé: Ó bọ́gbọ́n mu ká yẹra fún àníyàn àṣejù nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tàbí tó tiẹ̀ lè má ṣẹlẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ohun tí à ń bẹ̀rù pé ó máa ṣẹlẹ̀ kì í pa dà ṣẹlẹ̀. Ìgbà míì sì wà tí nǹkan lè yí pa dà sí rere láìròtẹ́lẹ̀.
Gbìyànjú èyí: Rántí àwọn ìgbà kan tó o ronú pé nǹkan tí kò dáa máa ṣẹlẹ̀, àmọ́ tí kò ṣẹlẹ̀. Wá ronú nípa ohun tó jẹ́ kó o máa ṣàníyàn báyìí, kó o sì fara balẹ̀ wò ó bóyá àwọn nǹkan tí ò ń ṣàníyàn nípa ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.
2. “Bí irin ṣe ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀.”—Òwe 27:17.
Ó túmọ̀ sí pé: Àwọn míì lè ràn wá lọ́wọ́ làti borí àníyàn wa tá a bá jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Torí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣe wọ́n rí, wọ́n lè fún wa láwọn àbá tó wúlò. Wọ́n sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ronú lọ́nà tá ò rò tẹ́lẹ̀, ká lè borí àníyàn.
Gbìyànjú èyí: Ronú nípa ẹnì kan tó lè fún ẹ ní ìmọ̀ràn gidi, ó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ti borí irú ìṣòro tó ò ń kojú. Ní kó sọ àwọn nǹkan tó ṣe àtàwọn nǹkan tí kò ṣe kó lè borí ìṣòro náà.
3. “Ẹ máa kó gbogbo àníyàn [tàbí “ohun tó ń jẹ yín lọ́kàn; ìdààmú,” àlàyé ìsàlẹ̀] yín lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó yín.”—1 Pétérù 5:7.
Ó túmọ̀ sí pé: Ọlọ́run bìkítà gan-an nípa àwọn tó ń kojú ìṣòro. Ó fẹ́ ká gbàdúrà sí òun nípa ohunkóhun tó ń jẹ wá lọ́kàn.
Gbìyànjú èyí: Kọ àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kó o máa ṣàníyàn sínú ìwé kan. Kó o wá sọ gbogbo ẹ̀ nínú àdúrà fún Ọlọ́run, kó o sì ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí wọn.
Ìgbà Tí Àníyàn Ò Ní Sí Mọ́
Kì í ṣe ìmọ̀ràn nìkan ni Bíbélì fún wa lórí bá a ṣe lè borí àníyàn. Ó tún ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ láìpẹ́, tí àwọn àníyàn tá a ní báyìí ò ní sí mọ́ títí láé. Báwo nìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀?
Ìjọba Ọlọ́run ló máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa àníyàn. (Ìfihàn 21:4) Kódà, a ò ní rántí àwọn aburú tí àníyàn àti ìdààmú ọkàn ti fà fún wa mọ́ nígbà tí Ìjọba yẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.—Àìsáyà 65:17.
Irú ọjọ́ ọ̀la yìí ni “Ọlọ́run tó ń fúnni ní àlàáfíà” fẹ́ kó o ní. (Róòmù 16:20) Ó sọ pé: “Mo mọ èrò tí mò ń rò nípa yín dáadáa, . . . èrò àlàáfíà, kì í ṣe ti àjálù, láti fún yín ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.”—Jeremáyà 29:11.
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a lo ọ̀rọ̀ náà “àníyàn” láti fi tọ́ka sí ìdààmú ọkàn àtàwọn ohun tó ń gbéni lọ́kàn sókè. Kì í ṣe àìsàn tó lágbára, tó lè gbẹ̀mí ẹni la lò ó fún. Àwọn tó ní àìsàn tó lágbára lè yàn láti gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà.—Lúùkù 5:31.