Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Anna Moneymaker/Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Sọ Pé Àwa Èèyàn Ò Ní Pẹ́ Fọwọ́ Ara Wa Pa Ayé Yìí Run​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Sọ Pé Àwa Èèyàn Ò Ní Pẹ́ Fọwọ́ Ara Wa Pa Ayé Yìí Run​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Ní January 24, 2023, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yí ọwọ́ aago kan tí wọ́n ń pè ní Doomsday Clock a síwájú, ohun tí wọ́n ń fi èyí ṣàpẹẹrẹ ni pé ayé yìí ò ní pẹ́ pa run.

  •   “Aago tí wọ́n ń pè ní ‘Doomsday Clock’ yìí ń ṣàpẹẹrẹ ìgbà tí àwọn èèyàn máa fọwọ́ ara wọn pa ayé yìí run. Lọ́jọ́ Tuesday, wọ́n yí aago yìí kó lè sún mọ́ ìgbà tó máa dún. Ohun tó sì fà á ni ogun tó ń jà ní Ukraine, títí kan bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń fi bọ́ǹbù átọ́míìkì halẹ̀ mọ́ra wọn àti bí ojú ọjọ́ ṣe ń burú sí i.”​—AFP International Text Wire.

  •   “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ lọ́jọ́ Tuesday pé wọ́n ti sún aago ‘Doomsday Clock’ yìí tó fi jẹ́ pé ìṣẹ́jú kan ààbọ̀ ló kù tó fi máa dún. Èyí fi hàn pé àwa èèyàn ti sún mọ́ amágẹ́dọ́nì gan-an.”​—ABC News.

  •   “Àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan kárí ayé kìlọ̀ pé tí nǹkan bá ń bá a lọ báyìí, àwa èèyàn ò ní pẹ́ fọwọ́ ara wa pa ayé yìí run.”​—The Guardian.

 Ṣé lóòótọ́ ni pé ayé yìí àti gbogbo àwa tá a wà nínú ẹ̀ máa tó pa run? Ṣé ó yẹ ká máa bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Kí ni Bíbélì sọ?

Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú

 Bíbélì sọ pé, ‘ayé máa wà títí láé’ àti pé àwọn èèyàn á “máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Oníwàásù 1:4; Sáàmù 37:29) Torí náà, àwọn èèyàn ò ní pa ayé yìí run tàbí kí wọ́n sọ ọ́ di ibi tí kò ní ṣeé gbé mọ́.

 Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìparun kan tó ń bọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé “ayé ń kọjá lọ.”​—1 Jòhánù 2:17.

Ohun tó máa fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀

 Láìka àwọn ìṣòro tá à ń bá yí nínú ayé yìí, Bíbélì lè fi wá lọ́kàn balẹ̀. Lọ́nà wo?

 Tó o bá fẹ́ túbọ̀ lóye àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì, a rọ̀ ẹ́ pé kó o jẹ́ kí ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́.

a “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló ṣe aago tí wọ́n ń pè ní Doomsday Clock. Aago yìí ni wọ́n fi ń mọ bí ìparun ayé yìí ṣe sún mọ́ tó àti bí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tá à ń fi ọwọ́ ara wa ṣe ṣe máa fa ìparun náà. Ohun kan ni pé àfiwé lásán ni aago yìí, ó kàn ń jẹ́ ká mọ àwọn ìṣòro tá a gbọ́dọ̀ yanjú káwa èèyàn má bàa fọwọ́ ara wa pa ayé yìí run.”​—Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists.