Báwo Ni Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
Báwo lo ṣe máa dáhùn ìbéèrè yìí?
IPASẸ̀ KÍ NI ÌWÀLÁÀYÈ FI WÀ . . .
ẸFOLÚṢỌ̀N
ÌṢẸ̀DÁ
Àwọn kan lè rò pé “ẹfolúṣọ̀n” ni ẹni tó bá mọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì máa mú, àti pé “ìṣẹ̀dá” ni ẹni tó bá fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn máa mú.
Àmọ́ gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń rí bẹ́ẹ̀.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó kàwé—títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan—ló ń ṣiyèméjì pé bóyá ni ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n jẹ́ òótọ́.
Ẹ wo ohun tí Gerard sọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa àwọn kòkòrò ni, wọ́n sì kọ́ òun náà ní ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n nílé ẹ̀kọ́ gíga. Ó sọ pé, “Táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n bá ti fún wa ní ìdánwò, ìdáhùn tí wọ́n máa ń fẹ́ níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n kọ́ wa ni mo máa ń kọ sílẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò gba ohun tí wọ́n kọ́ wa gbọ́.”
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í rọrùn fún àwọn kan tó nímọ̀ sáyẹ́ǹsì pàápàá láti gbà pé ipasẹ̀ ẹfolúṣọ̀n ni ìwàláàyè fi wà? Ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká wo ìbéèrè méjì tó ń da ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣèwádìí lọ́kàn rú: (1) Báwo ni ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀? àti (2) Báwo ni àwọn ohun alààyè ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wà?
Báwo Ni Ìwàláàyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ. Àtinú àwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí ni ìwàláàyè ti ṣàdédé wá.
ÌDÍ TÍ ÌDÁHÙN YẸN Ò FI TẸ́ ÀWỌN ÈÈYÀN KAN LỌ́RÙN.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìwàláàyè ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, síbẹ̀ wọn ò lè fi ìdánilójú sọ ohun tí ìwàláàyè jẹ́ gan-an. Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà láàárín nǹkan tí kò lẹ́mìí àti sẹ́ẹ̀lì ẹlẹ́mìí tó kéré jù lọ pàápàá.
Ṣe làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kàn máa ń méfò nípa bí nǹkan ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún sẹ́yìn. Èrò wọn ò ṣọ̀kan lórí ibi tí ìwàláàyè ti bẹ̀rẹ̀—bí àpẹẹrẹ, wọn ò mọ̀ bóyá inú òkè ayọnáyèéfín kan tó bú gbàù ni àbí nísàlẹ̀ òkun. Ohun míì tí wọ́n gbà gbọ́ ni pé ibòmíì ní àgbáálá ayé yìí ni ohun tó pilẹ̀ ìwàláàyè ti jáde, kó tó di pé àwọn iná aláràbarà tó wà ní gbalasa òfuurufú gbé wọn wá sílẹ̀ ayé. Àmọ́ ìyẹn ò dáhùn ìbéèrè tó wà nílẹ̀ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀; ṣe ló kàn ń ṣàlàyé pé ayé kọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀, pé ibòmíì ni.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ohun tín-tìn-tín kan ló di ohun tá a mọ̀ sí àpilẹ̀ àbùdá ohun alààyè lónìí. Wọ́n ní ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ara ohun tí kò lẹ́mìí ni wọ́n ti dédé jáde wá, tí ìkọ̀ọ̀kan sì ń ṣe ẹ̀dà ara ẹ̀. Síbẹ̀, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò tíì rí ẹ̀rí kankan pé irú àwọn ohun tín-tìn-tín bẹ́ẹ̀ ti fìgbà kan wà, wọn ò sì tíì rí irú ẹ̀ ṣe jáde nínú àwọn ilé oògùn wọn.
Báwọn ohun alààyè ṣe máa ń tọ́jú ìsọfúnni, tí wọ́n sì ń lò ó kò láfiwé. Ìsọfúnni tó bá wà nínú àpilẹ̀ àbùdá sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan ló máa ń pinnu ohun tí sẹ́ẹ̀lì náà máa ṣe. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fi sẹ́ẹ̀lì wé kọ̀ǹpútà, wọ́n sì fi ìsọfúnni tó wà nínú àpilẹ̀ àbùdá wé ìsọfúnni tó máa ń wà lórí kọ̀ǹpútà. Àmọ́ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò lè ṣàlàyé bí ìsọfúnni ọ̀hún ṣe débẹ̀.
Èròjà purotéènì ṣe kókó kí sẹ́ẹ̀lì lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa. Èròjà purotéènì kọ̀ọ̀kan máa ń ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èròjà kéékèèké tí wọ́n ń pè ní amino acid tó máa ń so kọ́ra lọ́nà tó ṣe pàtó. Yàtọ̀ síyẹn, èròjà purotéènì náà gbọ́dọ̀ ká jọ lọ́nà kan pàtó kó tó lè wúlò. Ibi táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan parí èrò sí ni pé bóyá ló lè ṣẹlẹ̀ kí purotéènì kan ṣoṣo pàápàá ṣàdédé wà. Onímọ̀ kan nípa physics tó ń jẹ́ Paul Davies kọ̀wé pé, “Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé oríṣiríṣi ẹgbẹẹgbẹ̀rún purotéènì ló gbọ́dọ̀ wà nínú sẹ́ẹ̀lì kan, kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ láti ronú pé ṣe ni wọ́n kàn ṣàdédé wà.”
ÌPARÍ ÈRÒ. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fi ṣèwádìí, tó sì jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni wọ́n ti ṣèwádìí ọ̀hún, òtítọ́ yẹn ṣì wà pé àtara ohun alààyè tó ti wà ṣáájú nìkan ni ìwàláàyè ti lè jáde.
Báwo Ni Àwọn Ohun Alààyè Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wà?
OHUN TÁWỌN KAN SỌ. Ṣe ni ohun alààyè àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà díẹ̀díẹ̀, tó sì wá ń para dà di oríṣiríṣi ohun alààyè, títí kan èèyàn.
ÌDÍ TÍ ÌDÁHÙN YẸN Ò FI TẸ́ ÀWỌN ÈÈYÀN KAN LỌ́RÙN. Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan díjú ju àwọn míì lọ. Ìwé kan sọ pé tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ́ àdììtú, lẹ́yìn tá a bá mú ọ̀rọ̀ bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀, ọ̀rọ̀ bí sẹ́ẹ̀lì kéékèèké ṣe ń di sẹ́ẹ̀lì tó túbọ̀ díjú la máa mú ṣìkejì.”
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí ẹ̀ pé nínú sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan, àwọn ohun kan tó díjú gan-an tó dà bíi maṣíìnì, tí wọ́n ní èròjà purotéènì nínú wà níbẹ̀ tí wọ́n máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè jọ ṣe àwọn iṣẹ́ kan tó díjú. Lára iṣẹ́ tí wọ́n máa ń ṣe ni kí wọ́n máa gbé àwọn èròjà tó ṣara lóore kiri, kí wọ́n sọ ọ́ di ohun tó ń fún sẹ́ẹ̀lì lókun, kí wọ́n tún ohun tó bá bà jẹ́ lára sẹ́ẹ̀lì ṣe, kí wọ́n sì máa jẹ́ oríṣiríṣi iṣẹ́ nínú sẹ́ẹ̀lì. Ṣé àwọn ohun tín-tìn-tín tó ń para dà di oríṣiríṣi àwọn nǹkan míì ló wá ṣàdédé di irú àwọn èròjà tó díjú tó báyìí nínú sẹ́ẹ̀lì? Ó níra fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà bẹ́ẹ̀.
Ẹyin àti àtọ̀ ló para pọ̀ di ọlẹ̀ bíńtín kan, tó wá dàgbà di àwa èèyàn. Bó ṣe rí lọ́rọ̀ àwọn ẹranko náà nìyẹn. Àwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú ọlẹ̀ yẹn máa ń pọ̀ sí i, wọ́n á wá pínra sí àwùjọ-àwùjọ. Ìrísí àwùjọ kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra, àwọn ló sì máa ń para pọ̀ di àwọn ẹ̀yà ara lóríṣiríṣi. Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò lè ṣàlàyé bí sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan ṣe “mọ” ohun tó yẹ kóun dà àti ibi tó yẹ kó dúró sí nínú ọlẹ̀ náà.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti wá rí i pé tí oríṣi ẹranko kan bá máa yí pa dà di oríṣi míì, inú sẹ́ẹ̀lì ni ìyípadà ọ̀hún ti gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tó sì jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè fi ẹfolúṣọ̀n ṣàlàyé bí sẹ́ẹ̀lì tó “kéré jù” pàápàá ṣe wà, ṣé ó wá ṣeé gbà gbọ́ pé àwọn ohun tín-tìn-tín kan ló yíra pa dà di oríṣiríṣi ẹranko tó wà láyé? Michael Behe tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ohun alààyè sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ẹranko ṣe rí, ó ní bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí “ti fi hàn pé ìyàlẹ́nu ni ọ̀rọ̀ wọn jẹ́ torí pé wọ́n díjú gan-an, kò tíì sí àlàyé tó nítumọ̀ nípa bí irú àwọn ohun tó díjú tó bẹ́ẹ̀ ṣe kàn lè ṣàdédé wà láìsí pé ẹnì kan tó gbọ́n ló wà nídìí ẹ̀.”
Àwa èèyàn mọ ohun tó ń lọ láyìíká wa, a lè ronú, a sì láwọn ìwà tó dáa bíi ká lawọ́ sáwọn míì, a máa ń fi nǹkan du ara wa torí àwọn ẹlòmíì, a sì mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tó dáa àtohun tí ò dáa. Ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ò lè ṣàlàyé bó ṣe jẹ́ pé àwọn nǹkan bíńtín kan ló para dà di àwọn ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ táwa èèyàn ní yìí.
ÌPARÍ ÈRÒ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ránnu mọ́ ọn pé òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro lọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n, síbẹ̀ ohun tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ nípa bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bí àwọn ohun alààyè ṣe wà ò tẹ́ àwọn kan lọ́rùn.
Ìdáhùn Tó Yẹ Ká Gbé Yẹ̀ Wò
Lẹ́yìn ẹ̀rí tá a ti rí, ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn parí èrò sí ni pé ẹnì kan tó ga ju ẹ̀dá lọ ló mú kí ìwàláàyè wà. Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Antony Flew tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ èrò orí. Ìgbà kan wà tóun náà wà lára àwọn òléwájú tó ń kéde pé kò sí Ọlọ́run. Nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìwàláàyè ṣe díjú tó, tó sì kọ́ nípa àwọn òfin àdáyébá tó ń darí àgbáálá ayé yìí, Flew tún èrò ẹ̀ pa. Ó kọ èrò táwọn onímọ̀ èrò orí ayé àtijọ́ máa ń ní, ó sọ pé: “Èyí tó bá ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ la gbọ́dọ̀ fara mọ́.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Flew rí i ní tiẹ̀ pé ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ wà pé Ẹlẹ́dàá wà.
Ibì kan náà ni Gerard tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí náà parí èrò sí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó kàwé gan-an, tó sì nímọ̀ nípa àwọn kòkòrò, ó sọ pé: “Mi ò rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ṣe ni ìwàláàyè kàn ṣàdédé wá látinú ohun tí ò lẹ́mìí. Bí àwọn ohun alààyè ṣe wà létòlétò, tí wọ́n sì díjú jẹ́ kó dá mi lójú pé Ẹnì kan gbọ́dọ̀ wà tó ṣètò wọn, tó sì ṣe wọ́n lọ́nà àrà bẹ́ẹ̀.”
Bó ṣe jẹ́ pé èèyàn lè mọ̀ nípa ayàwòrán kan tó bá ń yẹ àwọn iṣẹ́ tó ti ṣe wò, bẹ́ẹ̀ náà ni Gerard ṣe wá mọ àwọn ànímọ́ tí Ẹlẹ́dàá ní nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó dá. Gerard tún fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìwé kan tó jẹ́ ti Ẹlẹ́dàá, ìyẹn Bíbélì. (2 Tímótì 3:16) Ibẹ̀ ló ti rí àwọn ìdáhùn tó tẹ́ ẹ lọ́rùn nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ aráyé sẹ́yìn àtàwọn ojútùú tó gbéṣẹ́ sí àwọn ìṣòro táwọn èèyàn ń kojú lónìí. Ìgbà yẹn ló wá dá a lójú pé ẹnì kan tó ga ju ẹ̀dá lọ náà ló ni Bíbélì.
Gerard rí i pé ó yẹ ká gbé àwọn ìdáhùn tó wà nínú Bíbélì yẹ̀ wò. A rọ̀ ẹ́ kíwọ náà yẹ̀ ẹ́ wò.