Ṣé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Júù Nígbèkùn Bábílónì Jóòótọ́?
Ní nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún méjì lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (2600) ọdún sẹ́yìn, wọ́n fipá kó àwọn Júù lọ sí Bábílónì, wọ́n sì lo àádọ́rin (70) ọdún nígbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, Ọlọ́run ti sọ àwọn ohun kan nípa bí ìgbésí ayé àwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì ṣe máa rí, ó ní: “Ẹ kọ́ ilé, kí ẹ sì máa gbé inú wọn. Ẹ gbin ọgbà kí ẹ sì máa jẹ èso wọn. Ẹ fẹ́ ìyàwó kí ẹ sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. . . . Ẹ máa wá àlàáfíà ní ìlú tí mo kó yín lọ ní ìgbèkùn.” (Jeremáyà 29:1, 4-7) Ṣé bí àwọn Júù ṣe gbé ìgbésí ayé wọn nìyẹn lóòótọ́?
Àwọn tó ń ṣèwádìí ti ṣàyẹ̀wò àwọn wàláà alámọ̀ tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) tó jọ pé Bábílónì àtijọ́ tàbí itòsí rẹ̀ ni wọ́n ti rí wọn. Àwọn wàláà náà fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wà nígbèkùn ṣì ń tẹ̀ lé àṣà àti ẹ̀sìn wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ara wọn sábẹ́ àkóso Bábílónì láìjanpata. Àwọn wàláà náà ti wà láti ọdún 572 sí 477 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ara àwọn ohun tó wà nínú wọn ni àdéhùn yíyá nǹkan, àdéhùn ìṣòwò, ìwé àdéhùn àti àwọn àkọsílẹ̀ owó míì. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, “Àwọn àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ bí ìgbésí ayé àwọn ìgbèkùn tó ń gbé ní ìgbèríko ṣe rí, wọ́n ń dáko, wọ́n ń kọ́lé, wọ́n n sanwó orí, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba.”
Àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì yìí tún fi hàn pé ibì kan tó tóbi díẹ̀ wà tí àwọn Júù ń gbé tí wọ́n ń pè ní AlYahudu tàbí ìlú Júdà. Wọ́n kọ orúkọ ìdílé ìran Júù mẹ́rin sára àwọn wàláà náà, wọ́n sì fi àwọn lẹ́tà Hébérù àtijọ́ kọ àwọn kan. Kí wọ́n tó ṣàwárí àwọn wàláà náà, ohun díẹ̀ ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n mọ̀ nípa ìgbésí ayé àwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Filip Vukosavović tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Nílẹ̀ Ísírẹ́lì sọ pé: “Nígbà tá a ka àwọn wàláà yìí, ó jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn Júù tó gbé nígbèkùn, orúkọ wọn, ibi tí wọ́n gbé, ìgbà tí wọ́n gbé ibẹ̀ àti iṣẹ́ tí wọ́n ṣe.”
Àwọn Júù tó wà nígbèkùn náà gbádùn òmìnira dé àyè kan láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Vukosavović sọ pé: “Kìí ṣe “Al-Yahudu nìkan ni wọ́n gbé, wọ́n tún ń gbé àwọn ìlú míì.” Àwọn kan lára wọn kọ́ oríṣiríṣi iṣẹ́ tó wá wúlò nígbà tí wọ́n ń tún Jerúsálẹ́mù kọ́. (Nehemáyà 3:8, 31, 32) Àwọn wàláà Al-Yahudu tún jẹ́rìí sí i pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù pinnu láti dúró sí Bábílónì kódà lẹ́yìn tí ìgbèkùn náà parí. Èyí fi hàn pé wọ́n gbádùn gbígbé ní Bábílónì ní àlàáfíà bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ.