Tó O Bá Láwọn Ọ̀rẹ́, O Lè Borí Ìṣòro Ìdánìkanwà—Bí Bíbélì Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
Ní ọdún 2023, àwọn elétò ìlera sọ pé ìdánìkanwà ti di ìṣòro tó kárí ayé tá a gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí. Báwo la ṣe lè yanjú ìṣòro yìí?
Dókìtà Vivek Murthy tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Tẹ́nì kan bá ń dá wà, tó sì ń ronú pé òun ò rẹ́ni fojú jọ, ó lè ṣàkóbá fún ìlera ẹ̀, inú ẹ̀ ò sì ní máa dùn.” Ó tún sọ pé: “A lè yanjú ìṣoro yìí tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan kéékèèké tó máa mú kí àárín àwa àtawọn míì túbọ̀ dáa sí i” a
Ẹnì kan lè wà láàárín àwọn èèyàn síbẹ̀ kó máa ṣe é bíi pé òun dá wà. Ohun yòówù kó mú kó máa ṣe wá bíi pé a dá wà, Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́. Àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú ẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ láti borí ìṣoro yìí, kó sì mú kí àárín àwa àtawọn míì dáa sí i.
Àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́
Máa bá àwọn míì sọ̀rọ̀, kó o sì máa tẹ́tí sí wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kó o máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fáwọn míì, ó tún ṣe pàtàkì kó o máa tẹ́tí sí wọn. Tó o ba jẹ́ káwọn míì rí i pé ò ń gba tiwọn rò, okùn ọ̀rẹ́ yín á túbọ̀ lágbára.
Ìlànà Bíbélì: “Bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:4.
Máa bá onírúurú èèyàn ṣọ̀rẹ̀ẹ́. O lè mú àwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ tàbí tó kéré sí ẹ lọ́rẹ̀ẹ́, o sì tún lè di ọ̀rẹ́ àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tìẹ.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀ pátápátá.”—2 Kọ́ríńtì 6:13.
To o bá fé mọ̀ sí i nípa ohun tó o lè ṣe kí okùn ọ̀rẹ́ ìwọ àtàwọn míì lè lágbára sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́.”
a Our Epidemic of Loneliness and Isolation: The U.S. Surgeon General’s Advisory on the Healing Effects of Social Connection and Community, 2023.