Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Runlé-Rùnnà ní Orílẹ̀-Èdè Tọ́kì àti Síríà—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ní Monday, February 6, 2023, ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Tọ́kì àti Síríà.
“Ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára pa ohun tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (3,700) èèyàn lọ lápá ibi tó pọ̀ jù lórílẹ̀-èdè Tọ́kì àti ní àríwá ìwọ̀ oòrùn Síríà lọ́jọ́ Monday. Òtútù tó lágbára tún mú, ìyẹn sì dá kún ìṣòro ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó fara pa tàbí tí wọn ò nílé mọ́. Bí ojú ọjọ́ ṣe rí yìí mú kó ṣòro láti rí àwọn tó fara pa níbi tí wọ́n há sí.”—Reuters, February 6, 2023.
Irú àwọn ìròyìn yìí máa ń bà wá nínú jẹ́ gan-an. Ọ̀dọ̀ Jèhófà “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” la ti lè rí ìrànlọ́wọ́ lásìkò tí àjálù bí èyí bá ṣẹlẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 1:3) Ó ń jẹ́ ‘ká lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.’—Róòmù 15:4.
Bíbélì jẹ́ ká mọ:
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmìtìtì ilẹ̀.
Ẹni tó lè tù wá nínú, táá sì fún wa nírètí.
Bí Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìyà.
Tó o bá fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn kókó yìí, ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí:
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.