Àwọn Ìmọ̀ràn Bíbélì Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Tí Iṣẹ́ Bá Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ
Tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹnì kan, àtigbọ́ bùkútà á dìṣòro, ọ̀kan ẹni náà ò sì ní balẹ̀. Kódà, àwọn èèyàn máa ń sọ pé àìlówó lọ́wọ́, baba ìjayà ni. Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.
Sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fáwọn míì.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo.”—Òwe 17:17.
Tí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ ẹ, ó dájú pé inú ẹ ò ní dùn. Inú tiẹ̀ lè máa bí ẹ tàbí kó o má mọ ohun tó o máa ṣe, kó o sì máa ronú pé aláìmọ̀-ọ́n-ṣe ni ẹ́. Tó o bá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fáwọn ará ilé ẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tó o fọkàn tán, ó dájú pé wọ́n á fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀. Wọ́n tiẹ̀ lè sọ àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe tá a mówó wọlé tàbí kí wọ́n bá ẹ wáṣẹ́ míì.
Má ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, torí ọ̀la máa ní àwọn àníyàn tirẹ̀.”—Mátíù 6:34.
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ronú nípa àwọn ohun tá a bá fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 21:5) Àmọ́, ó tún kìlọ̀ pé ká má ṣe máa da ara wa láàmú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan tó lè má ṣẹlẹ̀ ló máa ń kó wa lọ́kàn sókè. Ohun tó dáa jù ni pé ká má ṣe da àníyàn tọ̀la mọ́ tòní.
Bíbélì sọ àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe tó o bá rí i pé ọkàn ẹ ò balẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Kojú Àìbalẹ̀ Ọkàn.”
Máa ṣọ́wó ná.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Mo ti kọ́ . . . bí a ṣe ń ní púpọ̀ àti bí a ṣe ń jẹ́ aláìní.”—Fílípì 4:12.
Àwọn èèyàn máa ń sọ pé bí ọwọ́ eku ṣe mọ, ló fi ń bọ́jú. Torí náà, rọra máa náwó. Àwọn nǹkan tó o bá mọ̀ pé agbára ẹ gbé ni kó o rà. Kó o sì ṣọ́ra fún gbèsè.—Òwe 22:7.
Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè máa ṣọ́wó ná, ka àpilẹ̀kọ náà “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.”
Máa fọgbọ́n lo àkókò ẹ.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ẹ máa fi ọgbọ́n . . . lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”—Kólósè 4:5.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò ní àkókò pàtó tó ò ń lọ síbiṣẹ́ mọ́, kó yẹ kó o máa fàkókò ẹ ṣòfò. Tó o bá ń fi àkókò ẹ ṣe nǹkan gidi, ìyẹn á jẹ́ kínú ẹ máa dùn, ìgbésí ayé ẹ sì máa nítumọ̀.
Múra tán láti ṣe ìyípadà.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.”—Òwe 14:23.
Múra tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó yàtọ̀ sí èyí tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀. Kódà, ó lè gba pé kó o ṣe iṣẹ́ táwọn èèyàn ò kà sí iṣẹ́ gidi tàbí tí owó tó ò ń rí nídìí ẹ̀ kéré sí èyí tó ń ṣe tẹ́lẹ̀.
Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa wáṣẹ́.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Fún irúgbìn rẹ ní àárọ̀, má sì dẹwọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; nítorí o ò mọ èyí tó máa ṣe dáadáa.”—Oníwàásù 11:6.
Má jẹ́ kó sú ẹ láti máa wáṣẹ́. Sọ fún tẹbítọ̀rẹ́, àwọn ará àdúgbò títí kan àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ pé ò ń wáṣẹ́. O lè lọ sí àwọn iléeṣẹ́ tó ń báni wáṣẹ́. Bákan náà, máa kíyè sí àwọn iléeṣẹ́ tó bá gbé ìròyìn jáde pé àwọn ń wá òṣìṣẹ́, yálà lórí ìkànnì tàbí ládùúgbò rẹ. Fi sọ́kàn pé o lè fi ọ̀pọ̀ ìwé ìwáṣẹ́ ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́, kó o sì lọ fún onírúurú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kó o tó ríṣẹ́.