Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TheCrimsonMonkey/E+ via Getty Images

ÀKÀNṢE ÌWÀÁSÙ

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àyíká Tó Ń Bà Jẹ́

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe sí Àyíká Tó Ń Bà Jẹ́

 “Ojú ọjọ́ tó ń burú sí i ń fa ọ̀pọ̀ ìṣòro kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, ó ti ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ó ń dákún ìṣòro ìlú, ó sì ń ba àyíká jẹ́. Kò tán síbẹ̀ o, ó ń mú káwọn ìjì tó ń jà lásìkò yìí túbọ̀ le sí i, ìyẹn sì ń ba ilé àti ohun ìní àwọn èèyàn jẹ́ kárí ayé. Bákan náà, ó ń mú kí omi òkun máa gbóná, ìyẹn sì ń mú kí ọ̀pọ̀ ohun ẹlẹ́mìí máa kú àkúrun.”​—Inger Andersen, igbá kejì àkọ̀wé àgbà Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé àti ọ̀gá àgbà Àjọ Tó Ń Rí Sọ́rọ̀ Àyíká lábẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbàyé, July 25, 2023.

 Ṣé àwọn ìjọba lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro tó ń bá aráyé fínra yìí? Ṣé wọ́n tiẹ̀ lágbára láti yanjú ìṣòro yìí, kó má sì gbérí mọ́?

 Bíbélì sọ nípa ìjọba kan tó lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro yìí, táá sì fòpin sí i. Ó sọ pé “Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,” ìjọba yìí lá sì máa darí bí nǹkan ṣe ń lọ láyé. (Dáníẹ́lì 2:44) Lábẹ́ ìjọba yìí, àwọn èèyàn “ò ní fa ìpalára kankan, tàbí ìparun kankan” fáwọn míì, wọn ò sì ní ba ayé jẹ́.​—Àìsáyà 11:9.