Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Yan Zabolotnyi/stock.adobe.com

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ìwà Ọ̀daràn Ń Peléke Sí I Kárí Ayé​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ìwà Ọ̀daràn Ń Peléke Sí I Kárí Ayé​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Àwọn ọmọ ìta tó ń jà ló kún ìgboro ní orílẹ̀-èdè Haiti. Ìwà ọ̀daràn ò jẹ́ kọ́kàn àwọn èèyàn balẹ̀ mọ́ ní South Africa, Mẹ́síkò àtàwọn orílẹ̀-èdè míì ní Latin America. Kódà láwọn ìlú tó dà bíi pé ìwà ọ̀daràn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, àyà àwọn èèyàn máa ń já bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ìròyìn nípa àwọn tó ń fọ́lé àtàwọn tó ń fa wàhálà káàkiri.

 Kí ni Bíbélì sọ nípa bí ìwà ọ̀daràn ṣe ń pọ̀ sí i kárí ayé?

Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìwà ọ̀daràn

 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà ọ̀daràn táwọn èèyàn ń hù máa jẹ́ àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3) Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ nípa àwọn nǹkan tó para pọ̀ jẹ́ àmì yìí, ó sọ pé:

  •   “Torí pé ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ máa tutù.”​—Mátíù 24:12.

 Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn máa jẹ́ “ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu, ẹni tó burú gan-an, ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn ìwà yìí ló ń dá kún ìwà ọ̀daràn tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri lónìí.

 Àmọ́ nǹkan ò ní máa bá a lọ báyìí. Bíbélì ṣèlérí pé láìpẹ́ ìwà ọ̀daràn ò ní sí mọ́.

  •   “Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́; wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọn ò ní sí níbẹ̀. Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”​—Sáàmù 37:10, 11.

 A rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó wà nínú Bíbélì, kó o sì ronú nípa ìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí ń fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. O tún lè ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí.

 Ìdí Tó Fi Dá Wa Lójú Pé Ọ̀la Máa Dáa

 Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,’ Tàbí ‘Òpin Ayé’?

 Ṣé Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Bí Àwọn Èèyàn Á Ṣe Máa Hùwà Lónìí?