Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Justin Paget/​Stone via Getty Images

Kí Lo Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kò Sẹ́ni Tó Rí Tiẹ̀ Rò?

Kí Lo Lè Ṣe Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kò Sẹ́ni Tó Rí Tiẹ̀ Rò?
  •   “Nǹkan bí ìdajì àwọn ọ̀dọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sọ pé ó ń ṣe wọ́n bíi pé kò sẹ́ni tó rí tàwọn rò, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló sì pọ̀ jù nínú wọn.”​—Ìṣòro Ìdánìkanwà Tó Gbòde Kan: The U.S. Surgeon General’s Advisory on the Healing Effects of Social Connection and Community, 2023.

  •   “[Àjọ Ìlera Àgbáyé] kéde pé wọ́n ti gbé àjọ kan kalẹ̀ táá máa rí sí ìṣòro ìdánìkanwà, torí pé ìṣòro yìí lè yọrí sí àìsàn. Bákan náà, àjọ yìí á máa gba àwọn èèyàn níyànjù láti ní àjọṣe tó dáa láàárín ara wọn ní gbogbo orílẹ̀-èdè láìka bí ipò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè naa ṣe rí.”​—Àjọ Ìlera Àgbáyé, November 15, 2023.

 Bíbélì fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká máa ronú pé a dá wà.

Àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́

 Dín àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o máa dá wà kù. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò ṣáá ní gbogbo ìgbà, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà. Dípò bẹ́ẹ̀, máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú kó o lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́.

  •   Ìlànà Bíbélì: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

 Máa wá bó o ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Tá a bá ń ṣe ohun rere fáwọn èèyàn, inú wọ́n máa dùn, àwa náà á sì láyọ̀.

  •   Ìlànà Bíbélì: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

 Lọ sórí ìkànnì wa kó o lè rí àwọn ìsọfúnni tó dá lórí Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi.