Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Manuel Reino Berengui/DeFodi Images via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ṣé Lóòótọ́ Ni Ìdíje Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé Lè Mú Káwọn Èèyàn Ṣe Ara Wọn Lọ́kan?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Ṣé Lóòótọ́ Ni Ìdíje Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé Lè Mú Káwọn Èèyàn Ṣe Ara Wọn Lọ́kan?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Nǹkan bíi bílíọ̀nù márùn-ún èèyàn ló ṣeé ṣe kó wo ìdíje eré bọ́ọ̀lù ti Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé (ìyẹn FIFA World Cup) tí wọ́n máa gbá láti November 20 sí December 18, 2022. Ọ̀pọ̀ gbà pé irú àwọn eré ìdárayá yìí máa mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn èèyàn, kódà wọ́n gbà pé á ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.

  •   “Eré ìdárayá lè yí ayé yìí pa dà. Ó lágbára láti sún àwọn èèyàn ṣe nǹkan. Kódà, ó lè mú káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”​—Nelson Mandela, tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè South Africa.

  •   “Eré bọ́ọ̀lù . . . máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe ara wọn lóṣùṣù ọwọ̀ torí ó ń jẹ́ kí wọ́n nírètí, kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì máa gba tara wọn rò. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n fìfẹ́ hàn sáwọn míì torí pé ó máa ń so àwọn èèyàn pọ̀ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”​—Gianni Infantino tó jẹ́ ààrẹ àjọ FIFA. a

 Ṣé lóòótọ́ ni ìdíje Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé tàbí eré ìdárayá èyíkéyìí lè ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n sọ yìí? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó lè jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà.

Ṣé ìdíje yìí lè mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn èèyàn?

 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ bọ́ọ̀lù lásán ni ìdíje Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé tọdún yìí ti dá sílẹ̀. Ìdí ni pé ó ti dá àríyànjiyàn sílẹ̀ láwùjọ àwọn èèyàn àti lágbo àwọn olóṣèlú lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ipò ọrọ̀ ajé tí ò dọ́gba.

 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ máa ń gbádùn àtimáa wo eré ìdárayá irú bíi bọ́ọ̀lù Ife Ẹ̀yẹ Àgbáyé àtàwọn míì tí wọ́n máa ń ṣe kárí ayé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn máa ń gbádùn àwọn eré ìdárayá yìí, kò lè mú ìṣọ̀kan tó wà pẹ́ títí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń gbé ẹ̀mí ìkórìíra lárugẹ, èyí sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa jẹ́ àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”​—2 Tímótì 3:1-5.

Ohun tó máa jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà kárí ayé

 Àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ìṣọ̀kan máa wà kárí ayé. Ó sọ pé gbogbo ayé á wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìjọba kan tó máa ṣàkóso látọ̀run ìyẹn “Ìjọba Ọlọ́run.”​—Lúùkù 4:43; Mátíù 6:10.

 Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba Ìjọba náà máa rí i pé àlàáfíà délé dóko. Bíbélì sọ pé:

  •   “Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀, alàáfíà yóò sì gbilẹ̀.”​—Sáàmù 72:7.

  •   “Yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀. . . Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”​—Sáàmù 72:12, 14.

 Kódà ní báyìí, àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ tó ń fi ẹ̀kọ́ Jésù sílò ló wà níṣọ̀kan kárí ayé láwọn ilẹ̀ tó tó ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mọ́kàndínlógójì (239). Ẹ̀kọ́ yìí sì ti jẹ́ kí wọ́n jáwọ́ nínú ìwà tó ń mú kí wọ́n kórìíra àwọn míì. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó ní àkòrí náà “Bá A Ṣe Lè Borí Ìkórìíra.”

a Fédération Internationale de Football Association, ìyẹn àjọ tó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù lágbàáyé.